Fi Àwọn Ohun Tó Ò Ń lé Nípa Tẹ̀mí Yin Ẹlẹ́dàá Rẹ Lógo
“NÍGBÀ tí ẹnì kan ò bá mọ èbúté tí òun ń rè, ibikíbi ni ẹ̀fúùfù lè gbé e lọ.” Ọmọ ilẹ̀ Róòmù kan tó gbáyé ní ọ̀rúndún kìíní, tó tún jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí ni wọ́n sọ pé ó sọ ọ̀rọ̀ yẹn. Ohun tó sọ yìí tọ́ka sí òdodo ọ̀rọ̀ kan pé tí ìgbésí ayé ẹni bá máa nítumọ̀, èèyàn gbọ́dọ̀ ní ohun kan tó ń lé.
Bíbélì fún wa ní àpẹẹrẹ àwọn tó ní ohun tí wọ́n ń lé. Lẹ́yìn tí Nóà ti fi nǹkan bí àádọ́ta ọdún ṣiṣẹ́, ó “kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀.” Wòlíì Mósè “tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà.” (Hébérù 11:7, 26) Ọlọ́run fún Jóṣúà tó rọ́pò Mósè ní ohun àfojúsùn kan, ìyẹn ni láti gba gbogbo ilẹ̀ Kénáánì.—Diutarónómì 3:21, 22, 28; Jóṣúà 12:7-24.
Ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé “a ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé” ní ipa tó lágbára gan-an lórí àwọn nǹkan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń lé nípa tẹ̀mí ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. (Mátíù 24:14) Pọ́ọ̀lù rí ìṣírí gbà látinú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù Olúwa fúnra rẹ̀ bá a sọ àtàwọn ìran tó fi hàn án títí kan iṣẹ́ tó yàn fún un láti “gbé orúkọ [Jésù] lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,” èyí sì mú kí ó kó ipa pàtàkì nínú dída àwọn ìjọ Kristẹni sílẹ̀ káàkiri Éṣíà Kékeré àti ní ilẹ̀ Yúróòpù.—Ìṣe 9:15; Kólósè 1:23.
Bẹ́ẹ̀ ni o, kò sígbà kan nínú ìtàn tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kò ní ohun rere kan tí wọn ń le, ọwọ́ wọn sì máa ń tẹ àwọn nǹkan ọ̀hún fún ògo Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè gbé àwọn nǹkan tẹ̀mí tí a óò máa lépa ka iwájú wa lónìí? Kí làwọn nǹkan tá a lè gbé ka iwájú wa, kí sì làwọn ohun tá a lè ṣe kí ọwọ́ wa lè tẹ̀ wọ́n?
Ẹ̀mí Tí Ó Tọ́ Ṣe Pàtàkì
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nínú gbogbo ìgbòkègbodò ìgbésí ayé lèèyàn ti lè gbé ohun kan ka iwájú tí yóò máa lé, àwọn tó wà nínú ayé pàápàá ní ohun tí wọ́n ń lé. Àmọ́ ṣá o, àwọn nǹkan tá à ń lé nípa tẹ̀mí yàtọ̀ sí àwọn nǹkan táráyé ń lé o. Ohun tó ń mú káwọn tó wà nínú ayé máa lé ọ̀pọ̀ lára ohun tí wọ́n ń lé ni pé wọ́n fẹ́ di ọlọ́rọ̀ lọ́nàkọnà, wọ́n tún ń wá ipò àti agbára lójú méjèèjì. Á mà burú o tó bá jẹ́ pé bí a óò ṣe di alágbára àti gbajúmọ̀ là ń lépa! Àwọn ìlépa tó ń fi ògo fún Jèhófà Ọlọ́run ni èyí tó wé mọ́ ìjọsìn wa sí Ọlọ́run àti ire Ìjọba rẹ̀. (Mátíù 6:33) Ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run àti ọmọnìkejì ẹni ló ń mú ká máa lé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ìfọkànsìn Ọlọ́run sì ni ohun tá à ń lépa.—Mátíù 22:37-39; 1 Tímótì 4:7.
Ẹ jẹ́ ká ní ẹ̀mí tí ó tọ́ bá a ṣe ń gbé àwọn nǹkan tẹ̀mí ka iwájú wa tá a sì ń lépa wọn, ì báà jẹ́ pé à ń lépa àfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ni o tàbí à ń fẹ́ ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí. Síbẹ̀ náà, ìgbà míì wà tí ọwọ́ wa lè máà tẹ àwọn nǹkan tá à ń fi ẹ̀mí tó dára lépa. Báwo la ṣe lè gbé àwọn ohun kan ka iwájú wa tọ́wọ́ wa yóò sì tẹ̀ wọ́n?
Ohun Tá À Ń Lé Gbọ́dọ̀ Jẹ Wá Lọ́kàn
Gbé àpẹẹrẹ ọ̀nà tí Jèhófà gbà ṣẹ̀dá ọ̀run òun ayé yẹ̀ wò. Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé “alẹ́ sì wá wà, òwúrọ̀ sì wá wà,” ló fi pààlà sí àwọn sáà kọ̀ọ̀kan tó fi ṣẹ̀dá àwọn nǹkan. (Jẹ́nẹ́sísì 1:5, 8, 13, 19, 23, 31) Níbẹ̀rẹ̀ sáà kọ̀ọ̀kan tí Ọlọ́run fi ṣiṣẹ́ ìṣẹ̀dá, ó mọ ohun tóun ń lé tàbí ohun tóun fẹ́ ṣe ní sáà náà. Ọlọ́run sì mú ète rẹ̀ láti ṣẹ̀dá àwọn nǹkan ṣẹ. (Ìṣípayá 4:11) Baba ńlá náà Jóòbù sọ pé, “Ọkàn [Jèhófà] sì fẹ́ ohun kan, òun yóò sì ṣe é.” (Jóòbù 23:13) Inú Jèhófà mà dùn gan-an o láti rí “ohun gbogbo tí ó ti ṣe” tí ó sì sọ pé “ó dára gan-an”!— Jẹ́nẹ́sísì 1:31.
Kí ọwọ́ àwa náà tó lè tẹ ohun tá à ń lé, nǹkan ọ̀hún gbọ́dọ̀ jẹ wá lọ́kàn gan-an. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní irú ìfẹ́ ọ̀kan bẹ́ẹ̀? Àní nígbà tí ilẹ̀ ayé wà ní bọrọgidi tó sì ṣófo, Jèhófà ti mọ ohun tí ilẹ̀ ayé máa dà nígbà tó bá yá, ó mọ̀ pé ó máa di ibi ẹlẹ́wà kan tó máa fi ògo àti ọlá fún òun. Bákan náà, tí àwa náà bá ń ronú nípa ohun tó máa jẹ́ àbájáde nǹkan tá à ń lé àti àǹfààní tí a óò rí níbẹ̀ nígbà tí ọwọ́ wa bá tẹ nǹkan náà, a óò túbọ̀ sapá kí ọwọ́ wa lè tẹ ohun tá a pinnu pé a fẹ́ ṣe. Ohun tí ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tony ṣe nìyẹn. Gbogbo ìgbà ló máa ń rántí ohun tó rí nígbà tó lọ wo ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù. Ìbéèrè tó máa ń wà lọ́kàn rẹ̀ látìgbà yẹn ni pé, ‘Báwo ló ṣe máa rí téèyàn bá ń gbé ní irú ibẹ̀ yẹn tó sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀?’ Tony ò yéé ronú nípa bóun ṣe lè débẹ̀, ó sì ń sapá gidigidi kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ̀ ẹ́. Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tí wọ́n fọwọ́ sí ìwé rẹ̀ pé kó wá sìn ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ náà ní ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn àkókò yẹn!
Tí a bá ń bá àwọn tọ́wọ́ wọn ti tẹ nǹkan kan tí wọ́n ń lépa kẹ́gbẹ́, èyí lè mú kí àwa náà fẹ́ láti rí i pé ọwọ́ wa tẹ ohun tá à ń lépa. Jayson, tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún, kì í fẹ́ lọ sóde ẹ̀rí nígbà tó wà ní ọ̀dọ́langba. Àmọ́, bó ṣe parí ilé ìwé girama báyìí ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tó ǹ fi àkókò kíkún pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run. Kí ló ran Jayson lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà? Ó fèsì pé: “Bíbá àwọn tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sọ̀rọ̀ àti bíbá wọn ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ nípa lórí mi gan-an.”
Ṣíṣe Àkọsílẹ̀ Àwọn Ohun Tá A Fẹ́ Máa Lépa Lè Ṣèrànwọ́
Ìgbà tá a bá sọ èrò kan tó wà lọ́kàn wa jáde ni èrò ọ̀hún tó máa ṣe kedere tá sì ṣe pàtó. Sólómọ́nì sọ pé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yíyẹ ṣe lè ní agbára láti fúnni ní ìtọ́sọ́nà nínú ìgbésí ayé ẹni. (Oníwàásù 12:11) Tá a bá kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà sínú ìwé kan, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ ní ipa tó jinlẹ̀ lórí ọkàn wa. Kí lẹ̀ rò pé ó fà á tí Jèhófà fi pàṣẹ fáwọn ọba Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣe ẹ̀dà ìwé òfin fún ìlò ara wọn? (Diutarónómì 17:18) Nítorí náà, a lè kọ àwọn ohun tá a fẹ́ máa lé sínú ìwé, kí a kọ ọ̀nà tá a fẹ́ gbé e gbà tí ọwọ́ wa yóò fi tẹ̀ wọ́n, kí á sì kọ àwọn ìṣòro tá a rò pé ó lè yọjú àtàwọn nǹkan tá a lè ṣe láti yanjú wọn. Yóò tún ṣèrànwọ́ tí a bá mọ ohun tá a fẹ́ ní ìmọ̀ nípa rẹ̀, nǹkan tá a fẹ́ kọ́ àti ẹni tó lè ràn wá lọ́wọ́ tó sì máa tì wá lẹ́yìn.
Geoffrey jẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ àdádó kan ní ilẹ̀ Éṣíà. Nítorí pé ó ní àwọn nǹkan tó ń lé nípa tẹ̀mí ni kò jẹ́ kó mikàn nígbà ìṣòro. Ìbànújẹ́ wá dorí rẹ̀ kodò nígbà tí aya rẹ̀ kú lójijì. Àmọ́ lẹ́yìn tí Geoffrey ti gba kámú, ó pinnu láti lo gbogbo ara rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà tó ń ṣe nípa gbígbé àwọn ohun kan tó fẹ́ máa lépa ka iwájú. Lẹ́yìn tó kọ àwọn ohun tó fẹ ṣe sórí bébà, ó gbàdúrà, ó sì sọ pé òun fẹ́ ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun mẹ́ta níparí oṣù yẹn. Ojoojúmọ́ ló máa ń yẹ ìgbòkègbodò rẹ̀ wò, ó sì máa ń wo bóun ṣe tẹ̀ síwájú sí lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá-mẹ́wàá. Ǹjẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tẹ nǹkan tó lóun fẹ́ ṣe? Ó ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́rin, ayọ̀ ńlá lèyí sì jẹ́ fún un!
Àwọn Nǹkan Tí Ọwọ́ Rẹ Lè Tètè Tẹ̀ Ni Kó O Fi Bẹ̀rẹ̀
Àwọn nǹkan mìíràn lè kọ́kọ́ dà bí ohun tó máa ṣòro láti lé bá. Lójú Tony tá a mẹ́nu kan níṣàájú, ńṣe ni sísìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dà bí àlá tí kò lè ṣẹ. Ohun tó mú kí èyí rí bẹ́ẹ̀ ni pé ìgbésí ayé játijàti ló ń gbé, kò sì tíì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Àmọ́ Tony pinnu láti mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá àwọn ọ̀nà Jèhófà mú àti láti máa lépa àtiṣe ìrìbọmi. Nígbà tó ṣe ìrìbọmi tán, ó sọ pé òun fẹ́ ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ àti aṣáájú ọ̀nà déédéé, ó sì fàmì sí ọjọ́ tóun fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọ̀hún lórí kàlẹ́ńdà rẹ̀. Lẹ́yìn tó ti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà fúngbà díẹ̀, ó wá rí i pé sísìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì kì í ṣe ohun tí kò lè ṣeé ṣe fún òun.
Ohun kan tó tún dára ni pé ṣísẹ̀-ń-tẹ̀lé ni ká máa lépa ohun tó máa gbà wá ní ọ̀pọ̀ ọdún kí ọwọ́ wa tó tẹ̀ ẹ́. A lè fi ìgbésẹ̀ kan tó wà láàárín ohun tá à ń lé ṣe àtẹ̀gùn sí òmíràn tó máa gbà ọ̀pọ̀ ọdún kọ́wọ́ wa tó tẹ̀ ẹ́. Yíyẹ ìtẹ̀síwájú wa wò déédéé láti lè mọ ibi tá a ti dé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ohun tá à ń lépa. Gbígbàdúrà sí Jèhófà léraléra nípa nǹkan tá a fẹ́ ṣe yóò jẹ́ ká lè máa bá a lọ ní ṣíṣe ohun tó máa mú kọ́wọ́ wa tẹ nǹkan tá à ń lé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé, “ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀.”—1 Tẹsalóníkà 5:17.
Dúró Lórí Ìpinnu Rẹ
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè ti ronú lórí àwọn nǹkan tá a gbé ka iwájú wa dáadáa tá a sì fẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ́ ẹ̀, síbẹ̀ àwọn nǹkan míì wà tọ́wọ́ wa lè má tẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó dun Jòhánù Máàkù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù gan-an nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò fẹ́ jẹ́ kó tẹ̀ lé òun nínú ìrìn àjò míṣọ́nnárì tí Pọ́ọ̀lù rìn lẹ́ẹ̀kejì! (Ìṣe 15:37-40) Ó yẹ kí Máàkù kọ́ ẹ̀kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, kó sì ṣe ìyípadà sí àwọn nǹkan tó ń lé kí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lè pọ̀ sí i. Ẹ̀rí fi hàn pé ó ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó dáa nípa Máàkù, òun àti àpọ́sítélì Pétérù sì tún jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ tímọ́tímọ́ ní Bábílónì. (2 Tímótì 4:11; 1 Pétérù 5:13) Àǹfààní tó ní láti kọ ìwé onímìísí nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ló fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi jù lọ nínú gbogbo àǹfààní tó ní.
Àwa náà lè ko ìṣòro bá a ṣe ń lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Àmọ́, dípò tá ò fi juwọ́ sílẹ̀, a ní láti wo bá a ṣe ń tẹ̀ síwájú sí, ká rí i dájú pé ohun tá à ń lé ṣì yẹ ní ohun téèyàn ń lépa, ká sì ṣe ìyípadà nínú ohun tá à ń lé tó bá jẹ́ pé ohun tó gbà nìyẹn. Nígbà tí ìṣòro bá yọjú, ó yẹ ká sapá gidigidi láti tẹ̀ síwájú, ká dúró ti ìpinnu wa ká má sì ṣe juwọ́ sílẹ̀. Sólómọ́nì tó jẹ́ ọlọgbọ́n ọba mú un dá wa lójú pé, ká ‘yí àwọn iṣẹ́ wa lọ sọ́dọ̀ Jèhófà tìkára rẹ̀, a ó sì fìdí àwọn ìwéwèé wa múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.’—Òwe 16:3.
Àmọ́, ìgbà mìíràn wà tí ipò nǹkan máa ń mú kí nǹkan tèèyàn ń lé di àléèbá. Bí àpẹẹrẹ, àìlera tàbí ojúṣe wa nínú ìdílé lè mú kí ọwọ́ wa má lè tẹ ohun tí à ń lé. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé olórí èrè wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, ì báà jẹ́ ní ọ̀run tàbí nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43; Fílípì 3:13, 14) Báwo la ṣe lè rí èrè yìí gbà? Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé, “ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò wa lè máà jẹ́ kí ọwọ́ wa tẹ nǹkan kan tá à ń lé, a ṣì lè “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí [á] sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (Oníwàásù 12:13) Àwọn nǹkan tá à ń lé nípa tẹ̀mí máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi àwọn ohun tá à ǹ lé nípa tẹ̀mí yin Ẹlẹ́dàá wa lógo.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Tá A Lè Máa Lépa
○ Kíka Bíbélì lójoojúmọ́
○ Kíka ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
○ Mímú kí àdúra wa túbọ̀ sunwọ̀n sí i
○ Fífi èso ti ẹ̀mí hàn nínú ìgbésí ayé wa
○ Mímú kí iṣẹ́ ìsìn wa túbọ̀ pọ̀ sí i
○ Títúbọ̀ di ọ̀jáfáfá nínú wíwàásù àti kíkọ́ni
○ Kíkọ́ bá a ṣe ń wàásù lórí tẹlifóònù, bí a ṣe ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà àti bá a ṣe ń wàásù ní àgbègbè iṣẹ́ ajé