Jóṣúà
12 Àwọn ọba ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun nìyí, tí wọ́n gba ilẹ̀ wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, láti Àfonífojì Áánónì+ dé Òkè Hámónì+ àti gbogbo Árábà lápá ìlà oòrùn:+ 2 Síhónì+ ọba àwọn Ámórì, tó ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì, tó sì ń jọba láti Áróérì,+ tó wà létí Àfonífojì Áánónì+ àti láti àárín àfonífojì náà àti ìdajì Gílíádì títí dé Àfonífojì Jábókù, ààlà àwọn ọmọ Ámónì. 3 Ó tún jọba lé Árábà títí dé Òkun Kínérétì*+ lápá ìlà oòrùn títí dé Òkun Árábà, Òkun Iyọ̀,* ní ìlà oòrùn sí Bẹti-jẹ́ṣímótì àti sí apá gúúsù lábẹ́ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.+
4 Ó tún gba ilẹ̀ Ógù+ ọba Báṣánì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Réfáímù+ tó kẹ́yìn, tó ń gbé ní Áṣítárótì àti Édíréì, 5 tó sì jọba ní Òkè Hámónì, ní Sálékà àti gbogbo Báṣánì,+ títí lọ dé ààlà àwọn ará Géṣúrì àti àwọn ará Máákátì+ àti ìdajì Gílíádì, títí dé ilẹ̀ Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì.+
6 Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun wọn,+ Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà sì fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní ilẹ̀ àwọn ọba yìí pé kó di tiwọn.+
7 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọba ilẹ̀ tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun lápá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì, láti Baali-gádì,+ ní Àfonífojì Lẹ́bánónì+ títí dé Òkè Hálákì,+ tó lọ dé Séírì,+ tí Jóṣúà wá fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ àwọn ọba náà pé kó di tiwọn, bí ìpín wọn,+ 8 ní agbègbè olókè, ní Ṣẹ́fẹ́là, Árábà, àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, ní aginjù àti ní Négébù,+ ìyẹn ilẹ̀ àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì:+
9 Ọba Jẹ́ríkò,+ ọ̀kan; ọba Áì,+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bẹ́tẹ́lì, ọ̀kan;
10 ọba Jerúsálẹ́mù, ọ̀kan; ọba Hébúrónì,+ ọ̀kan;
11 ọba Jámútì, ọ̀kan; ọba Lákíṣì, ọ̀kan;
12 ọba Ẹ́gílónì, ọ̀kan; ọba Gésérì,+ ọ̀kan;
13 ọba Débírì,+ ọ̀kan; ọba Gédérì, ọ̀kan;
14 ọba Hóómà, ọ̀kan; ọba Árádì, ọ̀kan;
15 ọba Líbínà,+ ọ̀kan; ọba Ádúlámù, ọ̀kan;
16 ọba Mákédà,+ ọ̀kan; ọba Bẹ́tẹ́lì,+ ọ̀kan;
17 ọba Tápúà, ọ̀kan; ọba Héfà, ọ̀kan;
18 ọba Áfékì, ọ̀kan; ọba Lasiṣárónì, ọ̀kan;
19 ọba Mádónì, ọ̀kan; ọba Hásórì,+ ọ̀kan;
20 ọba Ṣimuroni-mérónì, ọ̀kan; ọba Ákíṣáfù, ọ̀kan;
21 ọba Táánákì, ọ̀kan; ọba Mẹ́gídò, ọ̀kan;
22 ọba Kédéṣì, ọ̀kan; ọba Jókínéámù+ ní Kámẹ́lì, ọ̀kan;
23 ọba Dórì ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Dórì,+ ọ̀kan; ọba Góíímù ní Gílígálì, ọ̀kan;
24 ọba Tírísà, ọ̀kan; gbogbo àwọn ọba náà jẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31).