Ẹ̀yin Èwe—Kí Ni Àwọn Góńgó Yín Nípa Tẹ̀mí?
1 Jèhófà mọ bí iṣẹ́ tí ó ní ète àti bí àwọn góńgó tí ọwọ́ lè tẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó láti mú ayọ̀ wá. (Wo Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15, 19.) Lónìí, Jèhófà ti fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní iṣẹ́ àyànfúnni láti wàásù àti láti kọ́ni. A tún ní góńgó tí ó kẹ́yìn náà ti gbígba ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè. Ní báyìí ná, a ní láti gbé àwọn góńgó tẹ̀mí tí ń tẹ̀ síwájú kalẹ̀ bí a óò bá yẹra fún dídarí agbára àti ohun ìní wa sí ibi tí kò tọ́.—1 Kọ́r. 9:26.
2 Àwọn Góńgó Tí Ọwọ́ Lè Tẹ̀ fún Àwọn Ọ̀dọ́: Ó yẹ kí àwọn èwe ní àwọn góńgó ti ìṣàkóso Ọlọ́run tí wọ́n lè lé bá ní ìbámu pẹ̀lú agbára ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. (1 Tím. 4:15) Àwọn kan tí wọ́n kéré gan-an lọ́jọ́ orí ti lé góńgó kíkọ́ àkọ́sórí àwọn ìwé Bíbélì bá àní kí wọ́n tó mọ bí a ti ń kàwé pàápàá. Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, àwọn ọmọ ń kẹ́kọ̀ọ́ láti múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ kí ọwọ́ wọn baà lè tẹ góńgó sísọ àwọn ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí tí ó nítumọ̀, kí wọ́n sì forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Nígbà tí àwọn ọmọ bá bá àwọn òbí wọn lọ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ láti ṣàjọpín nínú jíjẹ́rìí bí wọ́n ti ń tẹ̀ síwájú síhà góńgó dídi akéde tí kò tí ì ṣe batisí. Ó yẹ kí àwọn òbí gbé góńgó ìyàsímímọ́ àti batisí ka iwájú àwọn ọmọ wọn kéékèèké.
3 Bí o bá jẹ́ ọ̀dọ́langba, kí ni àwọn góńgó rẹ nípa tẹ̀mí ní nínú? “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí” nípa pípọkànpọ̀ sórí àwọn góńgó tí ó ṣe pàtàkì ní ti gidi nínú ìgbésí ayé. (Oníw. 12:1, NW; Orin Dá. 71:17) Èé ṣe tí o kò fi ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní àwọn oṣù tí o bá gba ìsinmi kúrò ní ilé ẹ̀kọ́? O ha ti ronú lórí títẹ́wọ́gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà fún àkókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé bí? Kíkọ́ èdè tuntun kí ó baà lè ṣèrànwọ́ ní ọjọ́ iwájú fún àwùjọ tàbí ìjọ tí ń sọ èdè míràn ní àgbègbè rẹ tàbí ní ibòmíràn ńkọ́? Ọ̀pọ̀ tí ń ṣiṣẹ́ sìn nísinsìnyí ní Bẹ́tẹ́lì tàbí tí ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe tàbí míṣọ́nnárì gbé iṣẹ́ ìsìn àkànṣe alákòókò kíkún kalẹ̀ bíi góńgó wọn nígbà tí wọ́n ṣì wà ní ilé ẹ̀kọ́. Èé ṣe tí ìwọ pẹ̀lú kò fi ṣe bẹ́ẹ̀?
4 Nígbà tí ọjọ́ orí rẹ ṣì kéré, sakun láti fara wé àpẹẹrẹ Jésù. Àní nígbà tí ó wà ní ọ̀dọ́mọdé ọmọ ọdún 12 pàápàá, ó fi ìmúratán sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí. (Lúùk. 2:42-49, 52) Gbígbé àwọn góńgó tí ń ṣàǹfààní kalẹ̀ fún ara rẹ láti máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, àti láti máa dara pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn Kristẹni tí ó dàgbà dénú ní àwọn ìpàdé àti nínú iṣẹ́ ìsìn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jèrè òye iṣẹ́ láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tí Jésù gbà ṣe é.