Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún September
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 4
Orin 224
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò àti Àwọn Ìfilọ̀ tí a ṣàyàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Ìròyìn Ìjọba Tí Ó Bá Àkókò Mu Tí A Óò Pín Kárí Orílẹ̀-Èdè.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà kan. Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìgbòkègbodò àkànṣe tí ń bọ̀ lọ́nà yìí ní October. Rọ gbogbo àwùjọ, títí kan àwọn ẹni tuntun, láti wéwèé fún ṣíṣàjọpín ní kíkún.
20 min: “Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Ṣe Ara Wọn Láǹfààní.” Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dámọ̀ràn, lẹ́yìn náà, jẹ́ kí a ṣe àwọn àṣefihàn kúkúrú méjì.
Orin 204 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 11
Orin 216
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
25 min: “Púpọ̀ Rẹpẹtẹ Lati Ṣe Ninu Iṣẹ́ Oluwa.” Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn kárí rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìṣètò tí a mú gbòòrò sí i fún ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba àkànṣe láti ilé dé ilé. Jíròrò àwọn ìwéwèé tí ẹ ní fún kíkárí gbogbo ìpínlẹ̀ tí a yàn fún ìjọ yín. Ṣàlàyé ohun tí ó yẹ kí a ṣe láti ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìsìn fún ìgbà àkọ́kọ́. Ka gbogbo ìpínrọ̀ náà.
12 min: “Àwọn Góńgó Wo Ni O Ti Gbé Kalẹ̀ fún Àwọn Ọmọ Rẹ?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Jẹ́ kí ọ̀kan tàbí méjì lára àwọn èwe àwòfiṣàpẹẹrẹ tàbí àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ti ń sin Jehofa láti ìgbà èwe wọn, sọ ní ṣókí, bí àwọn òbí wọn ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yan àwọn góńgó tí ó níláárí tí a gbé karí àwọn ire Ìjọba.
Orin 187 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 18
Orin 168
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò àti Àpótí Ìbéèrè. Fi ìsọfúnni lórí àpò ẹ̀rí tí ó wà létòlétò àti ní mímọ́ tónítóní kún un, ní ṣíṣàlàyé àwọn ohun tí ó ṣe kókó tí ó yẹ kí ó wà nínú rẹ̀.
15 min: “Fi Tọkàntọkàn Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá.” Ìpínrọ̀ 1 sí 6. Ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
20 min: “Padà Sọ́dọ̀ Gbogbo Àwọn Tí Wọ́n Fi Ìfẹ́ Hàn Láti Ṣe Àwọn Ẹlòmíràn Láǹfààní.” Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dámọ̀ràn fún ìpadàbẹ̀wò. Arákùnrin tí ń bójú tó apá yìí jíròrò ohun tí wọn yóò sọ pẹ̀lú àwọn akéde méjì tàbí mẹ́ta, ó sì wí fún wọn lẹ́yìn náà láti ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ wọn.
Orin 162 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 25
Orin 177
5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọrun.” Ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ láti ẹnu alàgbà kan. Bí àkókò bá ti yọ̀ǹda tó, fi àlàyé tí a gbé ka orí Ilé-Ìṣọ́nà ti August 15, 1992, ojú ìwé 15 sí 20 kún un.
25 min: “Fi Tọkàntọkàn Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá.” Ìpínrọ̀ 7 sí 15. Ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 193 àti àdúrà ìparí.