Ìròyìn Ìjọba Tí Ó Bá Àkókò Mu Tí A Óò Pín Kárí Orílẹ̀-Èdè
1 Ní Sunday, October 1, 1995, alága yóò mú Ìròyìn Ìjọba olójú-ìwé mẹ́rin tí ń múni ronú jinlẹ̀, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Èéṣe Tí Ìgbésí-Ayé fi Kún fún Ìṣòro Tóbẹ́ẹ̀? Paradise Kan Láìsí Wàhálà Ha Ṣeé Ṣe Bí?” jáde, ní òpin ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn. A óò fún ìhìn iṣẹ́ tí ó bá àkókò mu, tí ó wà nínú rẹ̀, ní ìpínkiri kárí orílẹ̀-èdè láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, bẹ̀rẹ̀ láti October 1 sí 22.
2 Ní apá ibi gbogbo ní orí ilẹ̀ ayé ni nǹkan ti dojú rú fún àwọn ènìyàn. Àwọn ìṣòro ń dààmú wọn ní ibi yòówù kí wọ́n máa gbé. Àwọn tí ń ṣàníyàn gidigidi nípa àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ yóò lọ́kàn ìfẹ́ gidigidi nínú Ìròyìn Ìjọba náà, níwọ̀n bí yóò ti darí wọn sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí orísun ìtọ́sọ́nà tí kò ní àṣìṣe fún ènìyàn. (Orin Da. 119:105) Gbogbo wa ń fojú sọ́nà fún gbígba ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba kan nígbà tí a bá mú un jáde ní October 1, 1995, ní àwọn èdè wọ̀nyí: Efik, Gẹ̀ẹ́sì, Hausa, Igala, Igbo, Isoko, Tiv, àti Yorùbá. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, púpọ̀ wà láti ṣe ní mímúra sílẹ̀ fún ìgbétáásì ńlá ọlọ́sẹ̀-mẹ́ta yìí.
3 Fún Gbogbo Ènìyàn Níṣìírí Láti Fi Ìtara Ṣàjọpín: Àwọn wo ni ó lè ṣàjọpín nínú iṣẹ́ náà? Dájúdájú, gbogbo ẹni tí ó ti di akéde yóò hára gàgà láti ṣe bẹ́ẹ̀! Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí wọ́n ń wá sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé ńkọ́? Àwọn kan ti ń dara pọ̀ mọ́ wa fún ìgbà díẹ̀ báyìí, tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú láìsọsẹ̀. Bí wọ́n bá ti mú ìgbésí ayé wọn bá àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ mu, wọ́n ha tóótun láti kà sí olùpòkìkí Ìjọba bí? Akéde tí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lè jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ náà, bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá sì nífẹ̀ẹ́ láti ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, àwọn alàgbà méjì yóò ṣàtúnyẹ̀wò àkójọ ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ojú ìwé 98 àti 99 nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni a ní láti ṣe bí ó bá ti tètè lè yá tó, kí àwọn tí ó bá tóótun gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi baà lè ní ìpín kíkún nínú ìgbétáásì náà. A ṣì lè fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, tí wọn kò tí ì tóótun láti kà sí akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi, níṣìírí láti ṣàjọpín Ìròyìn Ìjọba tí ó bá àkókò mu yìí, pẹ̀lú àwọn ojúlùmọ̀ tàbí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wọn.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, November 15, 1988, ojú-ìwé 17, ìpínrọ̀ 8.
4 Iṣẹ́ yìí kò nira; gbogbo ènìyàn lè ṣàjọpín nínú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí apá kan ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn òbí lè fi ìdánrawò Ìròyìn Ìjọba kún un, kí gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé baà lè gbara dì dáradára láti fi í lọni láti ilé dé ilé. Ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn sábà máa ń dára jù. Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kúkúrú kan, fi Ìròyìn Ìjọba lọ onílé náà, kí o sì fún un níṣìírí láti kà á. Bí onílé bá fi ìfẹ́ hàn, ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀, kí o baà lè padà láti mú ọkàn ìfẹ́ náà dàgbà. (1 Kor. 3:6, 7) Kọ́kọ́rọ́ sí àṣeyọrí ni láti ní ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn, tí a ti múra sílẹ̀ dáradára.
5 A óò ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ lati ṣe” ní October. Nínú àkìbọnú ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí, a pèsè ìsọfúnni síwájú sí i nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ti a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Púpọ̀ Rẹpẹtẹ Lati Ṣe Ninu Iṣẹ́ Oluwa.” A óò gbé èyí yẹ̀ wò ní ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀, nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn.—1 Kor. 15:58, NW.