Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọrun
1 Ẹ wo bí ó ti ń tuni lára tó láti kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa! (1 Kor. 16:17, 18) A máa ń ṣe èyí ní àwọn ìpàdé, àwọn àpéjọ, àwọn àpéjọpọ̀, àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. A tún máa ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ ní àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò jẹ́ bí àṣà, bíi nígbà tí a bá ní àwọn àlejò tí ń bẹ̀ wá wò ní ilé. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ń fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn, a sì ń fún ara wa ní ìṣírí. (Romu 12:13; 1 Pet. 4:9) Nígbà tí o bá ń ṣètò fún ìṣenilálejò ìgbeyàwó, fi àwọn ìmọ̀ràn àtàtà tí ó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti October 15, 1984, sọ́kàn.
2 Àwọn Àlámọ̀rí Ẹgbẹ́-Òun-Ọ̀gbà Tí A Ṣètò: Yálà a ‘ń jẹ tabi a ń mu tabi a ń ṣe ohunkóhun mìíràn,’ a ní láti “ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọrun.” (1 Kor. 10:31-33, NW) Àwọn kan kò tẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí, àwọn ìṣòro sì ń bá a lọ láti yọjú, nítorí àwọn àpéjọ onípọ̀pọ̀ṣìnṣìn tí ó ti tóbi jù láti bójú tó lọ́nà yíyẹ, irú bí níbi ìṣenilálejò ìgbeyàwó. Ní àwọn ọ̀ràn kan, a ti ké sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn sí àwọn àpèjẹ ńlá, níbi tí a ti fi eré ìnàjú ayé dá wọn lára yá. Ó ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn ibì kan pé, a sún àwọn tí ó péjọ láti fi owó ṣe pàṣípàrọ̀ obì. Irú àwọn àpéjọ bẹ́ẹ̀ jọ ti ayé lọ́pọ̀lọpọ̀, ẹ̀mí èyí tí kò sí ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó bójú mu àti àwọn ìlànà Bibeli.—Romu 13:13, 14; Efe. 5:15-20.
3 A ti ròyìn rẹ̀ pé, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ti péjọ sínú ilé tí a háyà, níbi tí eré ìnàjú náà kò ti gbámúṣe, tí ó sì jẹ́ ti ayé, tí kò sì sí àbójútó tí ó yẹ. Àwọn ìgbòkègbodò tí ó fara jọra tí a polówó gẹ́gẹ́ bí ayẹyẹ ìgbéyàwó ìbílẹ̀ ti “àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa” ni a ti ṣe ní àwọn hòtẹ́ẹ̀lì tàbí ní àwọn ibi ìnajú. Àwọn ìṣòro ti yọjú nítorí ìṣòro bíbójú tó irú àwùjọ ńlá bẹ́ẹ̀. Ó ti yọrí sí rìgbòrìyẹ̀, ìmùtípara, àní ìwà pálapàla pàápàá, ní àwọn ìgbà mìíràn. (Efe. 5:3, 4) Àwọn àpéjọ onípọ̀pọ̀ṣìnṣìn níbi tí irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ti ń ṣẹlẹ̀ kì í bu ọlá fún Jehofa. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń mú ẹ̀gàn wá bá orúkọ rere tí ìjọ ní, wọ́n sì ń mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀.—1 Kor. 10:23, 24, 29.
4 A rọ àwọn Kristian láti jẹ́ aláájò àlejò, ṣùgbọ́n ṣíṣe pàṣípààrọ̀ tẹ̀mí ni ó yẹ kí ó jẹ wọ́n lógún jù lọ. (Romu 1:11, 12) Àwọn àpéjọ kékeré ni ó dára jù lọ. Ìwé Iṣetojọ sọ ní ojú ìwé 135 sí 136 pé: “Nigba miiran, a lè kesi awọn idile bii mélòó kan lati wá si ile kan fun ikẹgbẹpọ Kristian. . . . Lọna tí ó lọgbọn-ninu, awọn wọnni tí wọn jẹ alásè labẹ iru awọn ipo bẹẹ nilati nimọlara rẹ̀ pe awọn ni yoo dahun fun ohun tí ó bá ṣẹlẹ nibẹ. Pẹlu èrò yii lọkan, awọn Kristian olùwòyemọ̀ ti rí ọgbọn tí ó wà ninu mímú ki titobi iru awọn awujọ bẹẹ mọniwọn ati kíké gígùn akoko ipejọpọ naa kuru.” Jesu fi hàn pé a kò nílò àwọn nǹkan púpọ̀ bí góńgó wa bá jẹ́ láti fún àwọn ọ̀rẹ́ wa níṣìírí nípa tẹ̀mí.—Luku 10:40-42.
5 Ohun àtàtà ni láti fi aájò àlejò hàn sí àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa. Bí ó ti wù kí ó rí, ìyàtọ̀ ńlá gbáà wà láàárín àpéjọ tí ó mọ níwọ̀n ní ilé wa àti àpèjẹ onípọ̀pọ̀ṣìnṣìn tí ń fi ẹ̀mí ayé hàn ní ilé tí a háyà. Nígbà tí o bá ké sí àwọn ẹlòmíràn láti wá bá ọ ní àlejò, ó yẹ kí o rí i dájú pé o lè dáhùn fún gbogbo ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà ti August 15, 1992, ojú ìwé 17 sí 20.
6 Ní tòótọ́, Jehofa ti fi ẹgbẹ́ àwọn ará bù kún wa, níbi tí a ti ń rí ìṣírí tí ń tuni lára, tí ń sún wa láti máa bá àwọn iṣẹ́ àtàtà nìṣó. (Matt. 5:16; 1 Pet. 2:12) Nípa fífi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìfòyebánilò hàn nínú àwọn ìgbòkègbodò ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, a óò máa mú ògo wá fún Ọlọrun wa nígbà gbogbo, a óò sì máa gbé àwọn ẹlòmíràn ró.—Romu 15:2.