ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 3/1 ojú ìwé 17-21
  • Eré Ìnàjú Tó Dára Tó Sì Ń tuni Lára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Eré Ìnàjú Tó Dára Tó Sì Ń tuni Lára
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Yan Eré Ìnàjú Tó Bójú Mu
  • Bá A Ṣe Lè Rí Eré Ìnàjú Tó Bójú Mu
  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Máa Fi Sọ́kàn Àtàwọn Ohun Tó Yẹ Ká Yẹra Fún
  • Ṣé Eré Ìtura Tó O Yàn Máa Ṣe Ẹ́ Láǹfààní?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Eré-Ìnàjú Ẹgbẹ́-Òun-Ọ̀gbà—Gbadun Awọn Anfaani Rẹ̀, Yẹra fun Awọn Idẹkun Rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Eré Ìtura
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Agbára Ìdarí Apanirun
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 3/1 ojú ìwé 17-21

Eré Ìnàjú Tó Dára Tó Sì Ń tuni Lára

“Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 10:31.

1, 2. Kí nìdí tá a fi pe ayọ̀ yíyọ̀ ní “ẹ̀bùn Ọlọ́run,” síbẹ̀ ìkìlọ̀ wo ni Bíbélì fún wa?

Ó MÁA ń wu àwa èèyàn láti ṣe àwọn ohun tó máa múnú wa dùn. Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run ayọ̀ fẹ́ ká gbádùn ayé wa, ó sì pèsè ọ̀pọ̀ yanturu ohun tá a lè fi gbádùn ara wa. (1 Tímótì 1:11; 6:17) Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba kọ̀wé pé: “Mo ti wá mọ̀ pé kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí wọ́n máa yọ̀ . . . pẹ̀lúpẹ̀lù, pé kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—Oníwàásù 3:12, 13.

2 Irú ayọ̀ yìí máa ń mú ìtura wá téèyàn bá ń ronú lórí iṣẹ́ rere tóun ti gbé ṣe, pàápàá tó bá jẹ́ lásìkò téèyàn ń ṣe yọ̀tọ̀mì pẹ̀lú ìdílé ẹni tàbí àwọn ọ̀rẹ́ ẹni. A lè pe irú ayọ̀ yíyọ̀ bẹ́ẹ̀ ní “ẹ̀bùn Ọlọ́run.” Àmọ́ ṣá o, pípèsè tí Ẹlẹ́dàá pèsè àwọn ohun rere lọ́pọ̀ yanturu kò sọ pé ká kàn máa jẹ̀gbádùn lọ láìbojúwẹ̀yìn. Bíbélì sọ pé àmujù ọtí, àjẹkì, àti ìṣekúṣe kò dára, ó sì kìlọ̀ pé àwọn tó bá ń ṣe irú nǹkan báwọ̀nyí “kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Òwe 23:20, 21; 1 Pétérù 4:1-4.

3. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò, ká sì máa fi ọjọ́ ńlá Jèhófà sọ́kàn?

3 Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó le koko yìí, ó ti wá ṣòro ju ti tẹ́lẹ̀ lọ fáwọn Kristẹni láti máa fọgbọ́n gbénú ayé tó ti dìdàkudà yìí láìṣe ohun tí ayé ń ṣe. (Jòhánù 17:15, 16) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn òde òní ti di “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run” débi tí wọn ‘kò fi fiyè sí’ ẹ̀rí tó fi hàn pé “ìpọ́njú ńlá” ti sún mọ́lé gan-an. (2 Tímótì 3:4, 5; Mátíù 24:21, 37-39) Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.” (Lúùkù 21:34, 35) Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run, a ti pinnu láti máa kọbi ara sí ìkìlọ̀ Jésù. A kò ṣe bí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run tó yí wa ká. À ń sapá láti wà lójúfò, a sì ń fi ọjọ́ ńlá Jèhófà sọ́kàn.—Sefanáyà 3:8; Lúùkù 21:36.

4. (a) Kí nìdí tó fi ṣòro láti rí eré ìnàjú tó bojú mu? (b) Ìmọ̀ràn wo ló wà ní Éfésù 5:15, 16 tá a fẹ́ láti máa mú lò?

4 Kò rọrùn láti yẹra fáwọn ìwà ìbàjẹ́ inú ayé yìí, nítorí pé Èṣù ti mú kí wọ́n túbọ̀ fani mọ́ra gan-an tó sì wà níbi gbogbo. Ìgbà tá a bá fẹ́ yan eré ìnàjú ló tiẹ̀ wá ṣòro jù láti yẹra fáwọn ìwà ìbàjẹ́ wọ̀nyí. ‘Ìfẹ́ ti ara’ lọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ohun tí ayé ń gbé jáde wà fún. (1 Pétérù 2:11) Àwọn ohun ìnàjú tí kò dára wà káàkiri, kódà wọ́n ń yọ́ kẹ́lẹ́ wọnú ilé ẹni nípasẹ̀ ìwé, tẹlifíṣọ̀n, Íńtánẹ́ẹ̀tì, àti fídíò. Ìdí nìyí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe fún àwọn Kristẹni nímọ̀ràn ọlọgbọ́n yìí pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.” (Éfésù 5:15, 16) Àfi tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí dáadáa nìkan ni eré ìnàjú tí kò dára kò fi ní máa wù wá tàbí kó máa gba àkókò wa, àní títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí ni àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà kò fi ní bà jẹ́, kó sì yọrí sí ìparun wa!—Jákọ́bù 1:14, 15.

5. Kí lohun tó ń fún wa ní ìtura tó ga jù lọ?

5 Níwọ̀n bọ́wọ́ àwa Kristẹni ti máa ń dí gan-an, a máa ń fẹ́ láti gbádùn eré ìnàjú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àní, Oníwàásù 3:4 sọ pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín” àti “ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” wà. Nítorí náà, Bíbélì kò ka eré ìnàjú sí fífi àkókò ṣòfò. Àmọ́ ńṣe ló yẹ kí eré ìnàjú tuni lára o, kò yẹ kó ṣàkóbá fún àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run tàbí kó dí iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run lọ́wọ́. Àwọn Kristẹni tó jẹ́ olóye mọ̀ pé ṣíṣe nǹkan fáwọn èèyàn máa ń fúnni láyọ̀ gan-an. Ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà ni wọ́n ń fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn, wọ́n sì ń rí ‘ìtura fún ọkàn wọn’ nítorí pé wọ́n gba àjàgà Jésù tó jẹ́ ti inú rere sọ́rùn wọn.—Mátíù 11:29, 30; Ìṣe 20:35.

Bá A Ṣe Lè Yan Eré Ìnàjú Tó Bójú Mu

6, 7. Kí ló máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá eré ìnàjú kan bojú mu tàbí kò bójú mu?

6 Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá eré ìnàjú kan bójú mu fún Kristẹni tàbí kò bójú mu? Àwọn òbí ló máa ń fún àwọn ọmọ ní ìtọ́sọ́nà, àwọn alàgbà sì máa ń fúnni nímọ̀ràn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Àmọ́ ká sòótọ́, kò yẹ kó jẹ́ pé àwọn ẹlòmíràn ni yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ fún wa pé ìwé kan, fíìmù kan, eré kan, ijó kan, tàbí orin kan pàtó kò dára. Pọ́ọ̀lù sọ pé ‘àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, máa ń tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.’ (Hébérù 5:14; 1 Kọ́ríńtì 14:20) Bíbélì fúnni láwọn ìlànà tó lè tọ́ wa sọ́nà. Ẹ̀rí ọkàn rẹ tó o ti fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ tó o bá fetí sí i.—1 Tímótì 1:19.

7 Jésù sọ pé “nípasẹ̀ èso rẹ̀ ni a fi ń mọ igi” kan. (Mátíù 12:33) Bó bá jẹ́ pé èso búburú ni eré ìnàjú kan ń mú jáde, irú bíi nínífẹ̀ẹ́ sí ìwà ipá, ìṣekúṣe, tàbí bíbá ẹ̀mí lò, a gbọ́dọ̀ yẹra fún irú eré ìnàjú bẹ́ẹ̀. Bákan náà, bí eré ìnàjú kan bá lè gbẹ̀mí ẹni tàbí tó lè sọni di aláàbọ̀ ara, tó lè kóni sí gbèsè tàbí tó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn èèyàn tàbí kẹ̀ tó lè mú wọn kọsẹ̀, kò bójú mu nìyẹn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún wa pé bá a bá ṣèpalára fún ẹ̀rí ọkàn arákùnrin wa, ẹ̀ṣẹ̀ la dá yẹn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí ẹ bá ń tipa báyìí ṣẹ̀ sí àwọn arákùnrin yín, tí ẹ sì ṣá ẹ̀rí-ọkàn wọn tí ó jẹ́ aláìlera lọ́gbẹ́, ẹ ń ṣẹ̀ sí Kristi. Nítorí náà, bí oúnjẹ bá mú arákùnrin mi kọsẹ̀, dájúdájú, èmi kì yóò tún jẹ ẹran láé, kí n má bàa mú arákùnrin mi kọsẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 8:12, 13.

8. Ewu wo ló wà nínú ṣíṣe àwọn eré orí kọ̀ǹpútà?

8 Àwọn eré orí kọ̀ǹpútà pọ̀ jaburata láwọn ilé ìtajà nísinsìnyí. Àwọn kan lára wọn lè dáni lára yá kí wọ́n sì tuni lára, àmọ́ ohun tí Bíbélì dá lẹ́bi làwọn eré orí kọ̀ǹpútà túbọ̀ ń gbé jáde. Dájúdájú kì í ṣe eré lásán mọ́ tí eré kọ̀ǹpútà kan bá ń mú kó dà bíi pé ẹni tó ń fi ṣeré ló ń ṣe àwọn èèyàn léṣe tàbí tó dà bíi pé òun ló ń pa èèyàn tàbí pé òun ló ń ṣe ìṣekúṣe tó légbá kan tó wà nínú eré náà! Jèhófà kórìíra àwọn tó “nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5; Òwe 3:31; Kólósè 3:5, 6) Bí eré kọ̀ǹpútà tó ò ń ṣe bá ń mú kó o ya olójúkòkòrò, tó ń sọ ẹ́ di oníjàgídíjàgan, tó ń bà ọ́ lọ́kàn jẹ́, tàbí tó ń fi àkókò rẹ ṣòfò, ó yẹ kó o mọ̀ pé inú ewu tẹ̀mí lo wà yẹn, kó o sì tètè jáwọ́ níbẹ̀.—Mátíù 18:8, 9.

Bá A Ṣe Lè Rí Eré Ìnàjú Tó Bójú Mu

9, 10. Àwọn nǹkan wo làwọn tó jẹ́ olóye èèyàn lè ṣe láti gbádùn eré ìnàjú?

9 Nígbà mìíràn, àwọn Kristẹni máa ń béèrè pé: “Eré ìnàjú wo ló bójú mu? Ọ̀pọ̀ ohun ìnàjú táwọn èèyàn ń ṣe jáde ni kò bá ìlànà Bíbélì mu.” Jẹ́ kó dá ọ lójú pé eré ìnàjú tó dára wà, àmọ́ ó gba ìsapá. Èèyàn ní láti ronú kó sì wéwèé rẹ̀ dáadáa, àwọn òbí ló sì ń kó ipa tó pọ̀ jù nínú èyí. Ọ̀pọ̀ ti rí i pé àwọn lè bá ìdílé wọn tàbí àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú ìjọ ṣe àwọn eré ìnàjú tó ń ṣeni láǹfààní. Gbígbádùn oúnjẹ bá a ti ń fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòjọ́ tàbí nípa àkòrí ọ̀rọ̀ kan nínú Bíbélì máa ń tuni lára ó sì máa ń gbéni ró. Èèyàn lè ṣètò fún lílọ sí ọgbà ẹranko, ọgbà ìṣiré, títa lúdò àti eré ayò. Irú àwọn eré ìnàjú tó bójú mu bẹ́ẹ̀ lè dá ni lára yá kó sì tuni lára.

10 Alàgbà kan àti ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n ti tọ́ ọmọ mẹ́ta dàgbà sọ pé: “Látìgbà táwọn ọmọ wa ti wà ní kékeré la ti máa ń jẹ́ káwọn náà dábàá ibi tí wọ́n rò pé a lè lọ lákòókò ìsinmi. Nígbà mìíràn, a máa ń yọ̀ǹda fún ọmọ kọ̀ọ̀kan láti pe ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti bá wa lọ, èyí sì máa ń mú kí àkókò ìsinmi náà lárinrin. A máa ń ṣàjọyọ̀ ohun pàtàkì táwọn ọmọ wa bá gbé ṣe. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń pe ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ wá sílé wa. A máa ń lọ sáwọn ibì kan láti se oúnjẹ, àá jẹ ẹ́ níbẹ̀, àá sì tún ṣe oríṣiríṣi eré. A máa ń wakọ̀ lọ sáwọn òkè ńlá tàbí ká fẹsẹ̀ rìn láàárín àwọn òkè náà. A sì máa ń fi àwọn àkókò yẹn kọ́ nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá.”

11, 12. (a) Nígbà tó o bá ń wéwèé fún eré ìnàjú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kí lo lè ṣe láti fi àwọn mìíràn kún ìwéwèé rẹ? (b) Irú àwọn àpèjẹ wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn kì í gbàgbé?

11 Nígbà tó o bá ń wéwèé fún eré ìnàjú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ǹjẹ́ o lè ronú nípa àwọn mìíràn tó lè wà pẹ̀lú rẹ tàbí ìdílé rẹ? Àwọn kan, irú bí àwọn opó, àpọ́n, tàbí ìdílé olóbìí-kan nílò ìṣírí. (Lúùkù 14:12-14) O tún lè pe àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ẹni tuntun, àmọ́ ṣá o, o ní láti ṣọ́ra kó o má ṣe jẹ́ káwọn ará bá ẹni tí ìwà rẹ̀ kò dára kẹ́gbẹ́. (2 Tímótì 2:20, 21) Báwọn aláìlera ò bá lè wá, o lè ṣètò pé kí a gbé oúnjẹ lọ fún wọn nílé wọn.—Hébérù 13:1, 2.

12 Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í gbàgbé àpèjẹ kan tí wọ́n ti gbádùn oúnjẹ ráńpẹ́, tí wọ́n gbọ́ nípa bí àwọn tó wá síbẹ̀ ṣe di Kristẹni, tí wọ́n sì gbọ́ nípa ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run nìṣó. A lè jíròrò àwọn kókó ọ̀rọ̀ látinú Bíbélì, kí gbogbo àwọn tó wá síbẹ̀, títí kan àwọn ọmọdé, sì sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó náà. Irú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè ṣeni láǹfààní láìsí pé ara ń ni ẹnì kankan tàbí kójú máa ti ẹnikẹ́ni.

13. Àpẹẹrẹ rere wo ni Jésù àti Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ fún wa nígbà tí wọ́n ṣe àwọn èèyàn lálejò àti nígbà táwọn èèyàn gbà wọ́n lálejò?

13 Jésù fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún wa nígbà tó ṣe àwọn èèyàn lálejò àti nígbà tí wọ́n gbà á lálejò. Ó máa ń lo irú àkókò bẹ́ẹ̀ láti sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. (Lúùkù 5:27-39; 10:42; 19:1-10; 24:28-32) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ìjímìjí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Ìṣe 2:46, 47) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Aáyun ń yun mí láti rí yín, kí n lè fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀ fún yín, kí a lè fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in; tàbí, kí a kúkú wí pé, kí pàṣípààrọ̀ ìṣírí lè wà láàárín yín, láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kejì, tiyín àti tèmi.” (Róòmù 1:11, 12) Nígbà táwa náà bá kóra jọ, ó yẹ ká lo àkókò náà láti fún ara wa níṣìírí.—Róòmù 12:13; 15:1, 2.

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Máa Fi Sọ́kàn Àtàwọn Ohun Tó Yẹ Ká Yẹra Fún

14. Kí nìdí tí àpèjẹ ńlá ò ṣe fi bẹ́ẹ̀ dára tó?

14 Kò fi bẹ́ẹ̀ dára tó láti pe èrò rẹpẹtẹ wá síbi àpèjẹ nítorí pé ó máa ń ṣòro gan-an láti bójú tó irú àpèjẹ bẹ́ẹ̀. Láwọn àkókò tí kò dí ìjọsìn lọ́wọ́, àwọn ìdílé bíi mélòó kan lè pinnu láti lọ ṣe fàájì tàbí láti ṣe eré tí kò ní ìdíje nínú. Táwọn alàgbà, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tàbí àwọn mìíràn tó dàgbà nípa tẹ̀mí bá wà níbi àpèjẹ kan, wọ́n máa ń pèsè ìtọ́sọ́nà rere, àkókò náà sì túbọ̀ máa ń tuni lára.

15. Kí nìdí tí pípe àpèjẹ kan fi gba kéèyàn bójú tó o bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ?

15 Àwọn tó ṣètò àpèjẹ kan gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn bójú tó ohun tó ń lọ níbẹ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Bí inú rẹ ti ń dùn pé o ṣe àwọn èèyàn lálejò, ǹjẹ́ inú rẹ ò ní bà jẹ́ tó o bá wá gbọ́ pé nítorí àìka-nǹkan-sí rẹ, ọ̀kan lára àwọn tó wá síbi àpèjẹ nílé rẹ ti kọsẹ̀ nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀? Gbé ìlànà tó wà nínú Diutarónómì 22:8 yẹ̀ wò. Ọmọ Ísírẹ́lì tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ilé tuntun ní láti ṣe ìgbátí sí etí òrùlé pẹrẹsẹ níbi tí wọ́n ti sábà máa ń ṣe àwọn èèyàn lálejò. Kí nìdí? Nítorí “kí ìwọ má bàa fi ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ sórí ilé rẹ nítorí pé ẹnì kan tí ń ṣubú lọ lè já bọ́ láti orí rẹ̀.” Lọ́nà kan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ò ní ṣe òfin má-ṣu-má-tọ̀ fáwọn àlejò rẹ, ohun tó o ṣe láti dáàbò bò wọ́n gbọ́dọ̀ fi hàn pé o ò fẹ́ kí aburú kankan ṣẹlẹ̀ sí wọn nípa tara àti nípa tẹ̀mí.

16. Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn kíyè sára tó bá dọ̀rọ̀ fífi ọtí ṣàlejò níbi àpèjẹ?

16 Bó o bá fẹ́ fi ọtí ṣe àwọn èèyàn lálejò níbi àpèjẹ kan, o ní láti kíyè sára gan-an. Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí wọ́n ń gbani lálejò kì í fún àwọn tí wọ́n gbà lálejò ní ọtí àyàfi tí wọ́n bá lè fúnra wọn mójú tó ọtí tí wọ́n máa fún àwọn àlejò náà. A ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ohunkóhun tó lè mú àwọn mìíràn kọsẹ̀ tàbí ohun tó lè mú ẹnikẹ́ni mu àmujù. (Éfésù 5:18, 19) Nítorí ìdí kan tàbí òmíràn, àwọn kan lára àwọn tó wá síbi àpèjẹ lè pinnu pé àwọn kò ní mutí rárá. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ní òfin tó sọ iye ọjọ́ orí téèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ kó tó lè mutí, àwọn Kristẹni sì gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí òfin ìjọba àní bí òfin ọ̀hún bá tiẹ̀ jọ pé ó le jù pàápàá.—Róòmù 13:5.

17. (a) Tá a bá fẹ́ gbọ́ orin níbi àpèjẹ kan, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kẹ́ni tó pe àpèjẹ náà yan orin tó bójú mu? (b) Tá a bá fẹ́ jó níbi àpèjẹ kan, ọ̀nà wo la lè gbà ṣe é láìṣe àṣejù?

17 Ẹni tó pe àpèjẹ náà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé orin, ijó tàbí ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe níbẹ̀ bá ìlànà Kristẹni mu. Ó ní irú orin tẹ́nì kọ̀ọ̀kan fẹ́ràn, oríṣiríṣi orin ló sì wà. Àmọ́ ṣá o, ohun tí ọ̀pọ̀ orin tó wà lóde òní dá lé lórí ni ẹ̀mí ọ̀tẹ̀, ìṣekúṣe àti ìwà ipá. Èèyàn gbọ́dọ̀ yan orin tó dára. Pé orin kan tuni lára kò túmọ̀ sí pé ó bójú mu. Bákan náà ni orin ọlọ́rọ̀kọrọ̀ tàbí orin arunisókè, tó ń pariwo gèè tàbí tí ìlù rẹ̀ ń dún lákọlákọ kò bójú mu. Má ṣe fi yíyan orin tó dára níbi àpèjẹ sí ìkáwọ́ ẹni tí kò tíì mọ̀ pé kò yẹ kí orin máa dún fatafata. Ijó tí kò bójú mu tó ń múni gbọn ìbàdí àti ọmú máa ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ, ó sì dájú pé irú ijó bẹ́ẹ̀ kò yẹ Kristẹni.—1 Tímótì 2:8-10.

18. Báwo làwọn òbí ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn tó bá dọ̀rọ̀ lílọ síbi àpèjẹ?

18 Ó yẹ káwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni wádìí ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe níbi àpèjẹ tí wọ́n pe àwọn ọmọ wọn sí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó bọ́gbọ́n mu pé kí wọ́n bá wọn lọ. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn òbí kan ti gba àwọn ọmọ wọn láyè láti lọ sáwọn àpèjẹ tí kò sí àbójútó níbẹ̀, tí ìyẹn sì ti mú kí àwọn kan lára àwọn tó wà níbẹ̀ dẹni tó lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe tàbí àwọn ìwà tí kò tọ́. (Éfésù 6:1-4) Àní, ká láwọn ọ̀dọ́ náà tiẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọmọ ogún ọdún pàápàá, tí wọ́n sì ti fi hàn pé àwọn jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, síbẹ̀, ó ṣì yẹ ká ràn wọ́n lọ́wọ́ láti “sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.”—2 Tímótì 2:22.

19. Kókó pàtàkì wo ló máa jẹ́ ká gbájú mọ́ ohun tó yẹ ká ‘kọ́kọ́ máa wá’?

19 Ṣíṣe eré ìnàjú tó dára lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ń mú kéèyàn túbọ̀ gbádùn ìgbésí ayé. Jèhófà kò fi irú ìgbádùn bẹ́ẹ̀ dù wá, àmọ́ ká sòótọ́, àwa náà mọ̀ pé àwọn eré ìnàjú wọ̀nyí kò lè ràn wá lọ́wọ́ láti kó ọrọ̀ tẹ̀mí jọ sí ọ̀run. (Mátíù 6:19-21) Jésù ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti lóye pé “wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́” lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé ẹni, kì í ṣe ohun tí a ó jẹ tàbí ohun tí a ó mu, tàbí ohun tí a ó wọ̀, “ìwọ̀nyí [sì] ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa.”—Mátíù 6:31-34.

20. Àwọn ohun rere wo ló yẹ káwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa wọ̀nà fún látọ̀dọ̀ Olùpèsè Ńlá náà?

20 Láìsí àní-àní, yálà ‘à ń jẹ tàbí à ń mu tàbí à ń ṣe ohunkóhun mìíràn,’ a lè ṣe “ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run,” tí a ó sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olùpèsè Ńlá tó fún wa ní gbogbo ohun rere tí à ń gbádùn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. (1 Kọ́ríńtì 10:31) Nínú Párádísè tó máa dé láìpẹ́, àkókò á wà rẹpẹtẹ láti gbádùn àwọn ohun tí Jèhófà pèsè. À ó sì tún gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin pẹ̀lú gbogbo àwọn tó ń ṣe ohun tí Ọlọ́run ní ká ṣe.—Sáàmù 145:16; Aísáyà 25:6; 2 Kọ́ríńtì 7:1.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tó fi ṣòro fáwọn Kristẹni láti rí eré ìnàjú tó dára lóde òní?

• Irú àwọn eré ìnàjú wo ló dára táwọn ìdílé Kristẹni lè ṣe?

• Nígbà tá a bá ń gbádùn eré ìnàjú tó dára, kí làwọn ohun tó yẹ ká fi sọ́kàn, kí sì làwọn ohun tó yẹ ká yẹra fún?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Yan eré ìnàjú tó ń ṣeni láǹfààní

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Irú àwọn eré ìnàjú wo làwọn Kristẹni kì í lọ́wọ́ sí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́