‘Ẹ Pa Agbára Ìmòye Yín Mọ́ Délẹ̀délẹ̀’
“Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—ÒWE 14:15.
1, 2. (a) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lọ́ọ̀tì ní Sódómù? (b) Kí lohun tí gbólóhùn náà “pa agbára ìmòye [rẹ] mọ́” túmọ̀ sí?
NÍGBÀ tí Ábúráhámù fún Lọ́ọ̀tì láǹfààní pé kó kọ́kọ́ yan ilẹ̀ tó wù ú, ilẹ̀ tó lómi dáadáa tó dà “bí ọgbà Jèhófà” ló wu Lọ́ọ̀tì. Níwọ̀n bí “Lọ́ọ̀tì [ti] yan gbogbo Àgbègbè Jọ́dánì fún ara rẹ̀” tó sì tẹ̀dó sẹ́bàá Sódómù, ó ní láti jẹ́ pé ibẹ̀ yẹn ni ibi tó dára jù lọ tóun àti ìdílé rẹ̀ lè fìdí kalẹ̀ sí. Àmọ́ ṣá o, gbogbo ohun tó ń dán kọ́ ni wúrà, nítorí pé “àwọn ọkùnrin Sódómù [tí wọ́n] burú, [tí] wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku sí Jèhófà” ló ń gbé itòsí ibẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 13:7-13) Bí àjálù ti ń gorí àjálù, ohun kékeré kọ́ ni Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ wá pàdánù. Níkẹyìn, òun àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ wá dẹni tó ń gbé inú ihò àpáta. (Jẹ́nẹ́sísì 19:17, 23-26, 30) Ohun tó dára gan-an lójú rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ wá di ohun tí kò dára mọ́.
2 Àríkọ́gbọ́n lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lọ́ọ̀tì jẹ́ fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí. Tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu, a gbọ́dọ̀ kíyè sí àwọn jàǹbá tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ ká sì ṣọ́ra káwọn ohun tó bá kọ́kọ́ dà bíi pé ó dára lójú wa má bàa mú wa ṣìnà. Abájọ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi rọ̀ wá pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́ lọ́nà pípé pérépéré.” (1 Pétérù1:13) Ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “pa agbára ìmòye [rẹ] mọ́” túmọ̀ sí ni “kéèyàn jẹ́ aláròjinlẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí R. C. H. Lenski tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì ti wí, jíjẹ́ aláròjinlẹ̀ túmọ̀ sí “kéèyàn jẹ́ ẹni tó fara balẹ̀, tí kì í ṣe wàdùwàdù, tó máa ń gbé ọ̀ràn yẹ̀ wò dáadáa, téyìí sì ń mú kó ṣe ìpinnu tó tọ́.” Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ipò kan yẹ̀ wò tó gba pé ká jẹ́ ẹni tó ń ronú jinlẹ̀.
Ronú Dáadáa Tí Wọ́n Bá Fi Okòwò Kan Lọ̀ Ọ́
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra tí wọ́n bá fi okòwò kan lọ̀ wá?
3 Ká ní ẹnì kan tó o fọkàn tán fi okòwò kan lọ̀ ọ́, bóyá ẹni tẹ́ ẹ tiẹ̀ jọ ń sin Jèhófà lonítọ̀hún. Ẹni náà ń fọwọ́ sọ̀yà pé okòwò náà yóò mówó gọbọi wá, ó sì ń rọ̀ ọ́ gidigidi pé kó o tètè gba iṣẹ́ náà kó o má bàa jẹ́ kí àǹfààní náà bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé iṣẹ́ náà á mú kí ìgbésí ayé rẹ àti ti ìdílé rẹ túbọ̀ dára sí i, àní o tiẹ̀ tún lè máa rò ó pé èyí yóò mú kó o lè lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Àmọ́ ṣá o, Òwe 14:15 kìlọ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Ìdùnnú pé èèyàn fẹ́ bẹ̀rẹ̀ okòwò tuntun lè máà jẹ́ kéèyàn rí àdánù tó lè tibẹ̀ wá, èèyàn sì lè gbójú fo àwọn ewu ibẹ̀ dá àti ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde okòwò náà lọ́jọ́ iwájú. (Jákọ́bù 4:13, 14) Nírú ipò yìí, ẹ ò rí i pé ó yẹ kéèyàn jẹ́ aláròjinlẹ̀!
4. Báwo la ṣe lè ‘ronú nípa ìṣísẹ̀ wa’ nígbà tá a bá ń gbé okòwò kan tí wọ́n fi lọ̀ wá yẹ̀ wò?
4 Olóye èèyàn áfara balẹ̀ gbé okòwò kan tí wọ́n bá fi lọ̀ ọ́ yẹ̀ wò kó tó ó tẹ́wọ́ gbà á. (Òwe 21:5) Irú àgbéyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ sábà máa ń jẹ́ kéèyàn rí àwọn ewu tó wà níbẹ̀ kedere. Gbé ipò yìí yẹ̀ wò ná: Ẹnì kan fẹ́ kó o yá òun lówó nítorí okòwò tó fẹ́ ṣe, ó sì sọ pé òun á fún ọ ní èrè gọbọi tó o bá lè yá òun lówó náà. Ohun tó fi lọ̀ ọ́ náà lè wù ọ́ gan-an, àmọ́ àwọn ewu wo ló wà níbẹ̀? Ṣé ẹni tó fẹ́ yá owó náà gbà láti sàn án padà tí okòwò náà bá tiẹ̀ forí ṣánpọ́n àbí kìkì ìgbà tí okòwò náà bá yọrí sí rere nìkan lẹni náà máa san owó ọ̀hún padà? Lédè mìíràn, ṣé wàá lè fara mọ́ ọn tówó rẹ bá wọgbó bí okòwò náà bá lọ forí ṣánpọ́n? O tún lè béèrè pé: “Kí nìdí tí kò fi lọ yáwó náà ní báńkì tó fi jẹ́ pé ọ̀dọ̀ mi ló wá? Ṣé kì í ṣe pé àwọn báńkì wò ó pé ewu tó rọ̀ mọ́ okòwò náà ti pọ̀ jù?” Fífarabalẹ̀ ronú lórí àwọn ewu tó wà níbẹ̀ yóò jẹ́ kó o lè mọ̀ bóyá kó o gba ohun tó fi lọ̀ ọ́ náà tàbí kó o má gbà á.—Òwe 13:16; 22:3.
5. (a) Ohun tó bọ́gbọ́n mu wo ni Jeremáyà ṣe nígbà tó ra ilẹ̀ kan? (b) Kí nìdí tó fi dára láti ṣe ìwé àdéhùn fún gbogbo ètò okòwò?
5 Nígbà tí wòlíì Jeremáyà ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà bíi tirẹ̀, ó ṣe ìwé lórí ilẹ̀ tó rà náà níwájú àwọn ẹlẹ́rìí. (Jeremáyà 32:9-12) Ọlọ́gbọ́n èèyàn yóò rí i pé gbogbo ètò tóun ṣe nípa okòwò kan, títí kan okòwò tó ṣe pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run ló wà nínú ìwé àdéhùn.a Ìwé àdéhùn tá a kọ dáadáa tó sì ṣe kedere kò ní jẹ́ kí èdèkòyédè wáyé bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní jẹ́ kí ìyapa wà. Àmọ́, àìsí ìwé àdéhùn ló sábà máa ń dá kún ìṣòro nígbà tí ọ̀rọ̀ okòwò bá dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Ó bani nínú jẹ́ pé irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ lè fa ìbànújẹ́ ọkàn, ìkùnsínú, àní ó tiẹ̀ lè mú kéèyàn pàdánù àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run pàápàá.
6. Kí nìdí tó fi yẹ ká yẹra fún ojúkòkòrò?
6 A tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ojúkòkòrò. (Lúùkù 12:15) Ìrètí láti rí èrè gọbọi nínú okòwò kan lè máà jẹ́ kéèyàn rí àwọn ewu tó wà nínú àwọn okòwò tí kò fi bẹ́ẹ̀ dára. Kódà, àwọn kan tí wọ́n ti láwọn àǹfààní pàtàkì nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ti kó sínú páńpẹ́ yìí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (Hébérù 13:5) Nígbà tí Kristẹni kan bá ń gbé ọ̀rọ̀ okòwò kan yẹ̀ wò, ó yẹ kó ronú pé, ‘Ṣé ó tiẹ̀ pọn dandan kí n ṣe òwò náà ni?’ Tá a bá rọra ń gbé ìgbésí ayé wa, tá ò lépa ọrọ̀, tá a sì gbájú mọ́ ìjọsìn Jèhófà, a óò bọ́ lọ́wọ́ “onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.”—1 Tímótì 6:6-10.
Ìṣòro Tó Dojú Kọ Àwọn Kristẹni Tí Kò Tíì Ṣègbéyàwó
7. (a) Àwọn ìṣòro wo lọ̀pọ̀ àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó dojú kọ? (b) Báwo lọ̀ràn ẹni tá a fẹ́ fi ṣe ọkọ tàbí aya ṣe kan ìṣòtítọ́ wa sí Ọlọ́run?
7 Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló wù láti ṣègbéyàwó àmọ́ tí wọn ò rí ẹní tó tẹ́ wọn lọ́rùn. Láwọn ilẹ̀ kan, ó máa ń wu àwọn kan láti ṣègbéyàwó nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe é. Àmọ́, wọ́n lè máà tíì rí ẹni tó wù wọ́n láàárín àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (Òwe 13:12) Síbẹ̀, àwọn Kristẹni mọ̀ pé ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì pé ká gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa” fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Àwọn Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń ronú jinlẹ̀ kí àwọn ìṣòro àti àdánwò tó dojú kọ wọ́n má bàa mú wọn juwọ́ sílẹ̀.
8. Ìṣòro wo ni Ṣúlámáítì dojú kọ, báwo sì làwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni lónìí ṣe dojú kọ irú ìṣòro yẹn?
8 Nínú Orin Sólómọ́nì, ojú ọba Sólómọ́nì wà lára ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Ṣúlámáítì tó wá láti ìgbèríko. Ọba yìí fẹ́ fi ọrọ̀, ipò iyì, àti ọ̀rọ̀ dídùn fà á mọ́ra, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ ọ̀dọ́kùnrin kan ti wà lọ́kàn ọmọbìnrin náà. (Orin Sólómọ́nì 1:9-11; 3:7-10; 6:8-10, 13) Bó o bá jẹ́ Kristẹni obìnrin, ẹnì kan lè máa fa ojú rẹ mọ́ra, kó o má sì nífẹ̀ẹ́ sí i. Ẹnì kan níbi iṣẹ́ rẹ, bóyá ẹni tó wà nípò àṣẹ, lè máa yìn ọ́, ó lè máa ṣe ojú rere sí ọ, kó sì máa wá ọ̀nà láti wà pẹ̀lú rẹ. Ṣọ́ra fún ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tó ń dá láti fa ojú rẹ mọ́ra lọ́nà yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tàbí ìṣekúṣe lonítọ̀hún ní lọ́kàn, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ohun tó máa wà lọ́kàn rẹ̀ nìyẹn. Jẹ́ “ògiri” bíi ti omidan Ṣúlámáítì. (Orin Sólómọ́nì 8:4, 10) Má ṣe fàyè gba irú ìfajú-ẹni-mọ́ra bẹ́ẹ̀ rárá. Àtìgbà tí wọ́n bá ti gbà ọ́ síṣẹ́ ni kó o ti jẹ́ káwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́, kó o sì máa lo àǹfààní tó o bá ní láti wàásù fún wọn. Ìyẹn yóò dáàbò bò ọ́.
9. Àwọn ewu wo ló wà nínú kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí bá àjèjì dọ́rẹ̀ẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? (Tún wo àpótí tó wà lójú ìwé 25.)
9 Àwọn ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fáwọn mò-ń-wọ́kọ àti mò-ń-wáya ti wá pọ̀ gan-an báyìí. Àwọn èèyàn kan ń wo èyí bí ọ̀nà kan láti gbà mọ àwọn èèyàn tí wọn ì bá má mọ̀ láé. Àmọ́ ṣá o, bíbẹ̀rẹ̀ sí dọ́rẹ̀ẹ́ láìronú jinlẹ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ àjèjì léwu gan-an. Ó ṣòro láti mọ irú ẹni tẹ́nì kan jẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. (Sáàmù 26:4) Kì í ṣe gbogbo ẹni tó sọ pé ìránṣẹ́ Jèhófà lòun ló jẹ́ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Síwájú sí i, ọkàn èèyàn lè tètè fà mọ́ ẹni téèyàn ń fẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn sì lè mú kéèyàn máa fojú pa àwọn ohun tó yẹ kéèyàn kíyè sí rẹ́. (Òwe 28:26) Yálà nípasẹ̀ Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí láwọn ọ̀nà mìíràn, kò bọ́gbọ́n mu láti bẹ̀rẹ̀ sí í dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ẹni téèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀.—1 Kọ́ríńtì 15:33.
10. Báwo la ṣe lè fún àwọn Kristẹni tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọn kò tíì ṣègbéyàwó níṣìírí?
10 Jèhófà “jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni” fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (Jákọ́bù 5:11) Ó mọ̀ pé àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ àwọn Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó tí kò sì wù wọ́n láti wà bẹ́ẹ̀ máa ń bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ nígbà mìíràn, ó sì mọyì ìṣòtítọ́ wọn. Báwo làwọn tó yí wọn ká ṣe lè fún wọn níṣìírí? Ó yẹ ká máa yìn wọ́n déédéé nítorí ìgbọ́ràn wọn àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n ní. (Onídàájọ́ 11:39, 40) A tún lè pè wọ́n síbi ìkórajọ kan tá a ṣètò láti gbé ara wa ró. Ǹjẹ́ o ti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ láìpẹ́ yìí? Síwájú sí i, a lè máa gbàdúrà fún wọn, ká máa bẹ Jèhófà pé kó ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè dúró nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì máa sìn ín tayọ̀tayọ̀. Ẹ jẹ́ ká máa fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sí àwọn olùṣòtítọ́ wọ̀nyí, ká máa fi hàn pé a mọyì wọn bí Jèhófà ṣe mọyì wọn.—Sáàmù 37:28.
Bá A Ṣe Lè Bójú Tó Ọ̀ràn Àìlera
11. Àwọn ìṣòro wo ni àìsàn tó le gan-an lè mú wá?
11 Ó máa ń bani nínú jẹ́ nígbà táwa tàbí èèyàn wa bá ní àìlera ara tó le gan-an! (Aísáyà 38:1-3) Ó ṣe pàtàkì pé ká rọ̀ mọ́ ìlànà Ìwé Mímọ́ bá a ti ń wá ọ̀nà láti rí ìwòsàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, kí wọ́n rí i pé àwọn ṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì tó sọ pé ká ta kété sí ẹ̀jẹ̀, kí wọ́n sì yẹra fún àwọn ìlànà àyẹ̀wò tàbí ìtọ́jú ara tó ní ìbẹ́mìílò nínú. (Ìṣe 15:28, 29; Gálátíà 5:19-21) Àmọ́ ṣá o, ní ti àwọn tí kò mọ̀ nípa ìṣègùn, gbígbé oríṣiríṣi ìtọ́jú yẹ̀ wò lè pin wọ́n lẹ́mìí kó sì máa dáyà já wọn. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀?
12. Kí ló máa jẹ́ kí Kristẹni kan ṣe ohun tó bójú mu nígbà tó bá ń gbé onírúurú ìtọ́jú ara yẹ̀ wò?
12 “Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀” nípa ṣíṣe ìwádìí nínú Bíbélì àtàwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Òwe 14:15) Láwọn apá ibì kan láyé, tí àwọn dókítà àtàwọn ilé ìwòsàn kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí, ó lè jẹ́ kìkì oògùn ìbílẹ̀ tí wọ́n fi ewé àtegbò ṣe nìkan ni wọ́n fi ń wo aláìsàn. Bá a bá ń gbèrò láti lo irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀, a lè rí àwọn ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, 1987, ojú ìwé 26 sí 29. Ó sọ àwọn ewu tó wà níbẹ̀ fún wa. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ́ ká wádìí àwọn nǹkan bíi: Ǹjẹ́ oníṣègùn náà máa ń bá ẹ̀mí lò? Ǹjẹ́ ọ̀nà tó ń gbà tọ́jú aláìsàn fi hàn pé ó gbà gbọ́ pé àwọn òrìṣà tó ń bínú (ìyẹn ẹ̀mí àwọn baba-ńlá) tàbí àwọn ọ̀tá tó ń lo agbára òkùnkùn ló ń fa àìsàn àti ikú? Ṣé ó máa ń ṣe ẹbọ, àbí ó máa ń pọfọ̀ tàbí ó máa ń lọ́wọ́ nínú àwọn ààtò ìbẹ́mìílò mìíràn tó bá fẹ́ ṣe oògùn tàbí tó fẹ́ sọ bí wọ́n ṣe máa lò ó? (Diutarónómì 18:10-12) Irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn onímìísí náà pé: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.”b (1 Tẹsalóníkà 5:21) Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú ìwòsàn tó yẹ ká gbà.
13, 14. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé èrò wa kò pọ̀n sápá kan nígbà tá a bá ń bójú tó ìlera wa? (b) Kí nìdí ta a fi nílò ìfòyebánilò nígbà tá a bá ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìlera àti ìtọ́jú ara?
13 A nílò òye nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe nígbèésí ayé wa, títí kan ọ̀rọ̀ ìtọ́jú ara wa. (Fílípì 4:5) Bíbójútó ìlera wa lọ́nà tó bójú mu fi hàn pé a mọrírì bí ẹ̀bùn ìwàláàyè ti ṣeyebíye tó. Òótọ́ ni pé nígbà tá a bá ní àìlera ara kan, ó máa ń gba àfiyèsí wa gan-an. Àmọ́ ṣá o, èèyàn ò lè ní ìlera pípé nísinsìnyí àyàfi tí àkókò Ọlọ́run bá tó láti ‘wo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.’ (Ìṣípayá 22:1, 2) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìlera gbà wá lọ́kàn débi pé ohun tẹ̀mí tá a gbà pé ó ṣe pàtàkì jù lọ á wá di ohun tá a pa tì.—Mátíù 5:3; Fílípì 1:10.
14 Ó tún yẹ ká ní èrò tí kò pọ̀n sápá kan nígbà tá a bá ń bá àwọn mìíràn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìlera àti ọ̀rọ̀ ìtọ́jú ara. Kókó ọ̀rọ̀ yìí kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí a ó máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣáá nígbà tá a bá pé jọ fún oúnjẹ tẹ̀mí láwọn ìpàdé àti àpéjọ wa. Síwájú sí i, ìpinnu tẹ́nì kan ṣe nípa ọ̀rọ̀ ìtọ́jú ara sábà máa ń wé mọ́ ìlànà Bíbélì, ẹ̀rí ọkàn ẹni náà àti àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Nítorí náà, kò ní fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ tá a bá fẹ́ kí onígbàgbọ́ bíi tiwa kan gba èrò wa tipátipá tàbí tí à ń fúngun mọ́ ọn, tá ò jẹ́ kó tẹ̀ lé ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ń sọ fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè lọ bá àwọn tó túbọ̀ lóye nínú ìjọ pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́, síbẹ̀ Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa ‘ru ẹrù ara rẹ̀’ láti ṣe ìpinnu tó tọ́ àti pé “olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”—Gálátíà 6:5; Róòmù 14:12, 22, 23.
Nígbà Tá A Bá Ní Ìdààmú Ọkàn
15. Báwo ni ìdààmú ọkàn ṣe lè nípa lórí wa?
15 Ìdààmú ọkàn lè mú káwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà pàápàá sọ ohun tí kò bọ́gbọ́n mu tàbí kí wọ́n ṣe ohun tí kò bójú mu. (Oníwàásù 7:7) Nígbà tí Jóòbù wà nínú àdánwò tó le gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tó lòdì, Jèhófà sì ní láti tọ́ ìrònú rẹ̀ sọ́nà. (Jóòbù 35:2, 3; 40:6-8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘Mósè fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀,’ nígbà kan, wọ́n mú un bínú ó sì fìbínú sọ̀rọ̀. (Númérì 12:3; 20:7-12; Sáàmù 106:32, 33) Dáfídì kó ara rẹ̀ níjàánu gan-an, ìdí nìyẹn tí kò fi pa Sọ́ọ̀lù Ọba. Àmọ́ nígbà tí Nábálì fàbùkù kàn án, tó sọ̀kò ọ̀rọ̀ sáwọn ọkùnrin tí Dáfídì rán sí i, ńṣe ni Dáfídì gbaná jẹ tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣìwà hù. Ọpẹ́lọpẹ́ pé Ábígẹ́lì dá sí ọ̀ràn náà, èyí tó pe orí Dáfídì wálé tó sì yọ ọ́ nínú àṣìṣe ńlá tí ì bá ṣe.—1 Sámúẹ́lì 24:2-7; 25:9-13, 32, 33.
16. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún híhùwà láìronú jinlẹ̀?
16 Àwa náà lè ní ìdààmú ọkàn tó lè mú kéèyàn ṣìwà hù. Fífarabalẹ̀ gbé èrò àwọn mìíràn yẹ̀ wò bí Dáfídì ti ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe ṣìwà hù ká sì dẹ́ṣẹ̀. (Òwe 19:2) Síwájú sí i, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá nímọ̀ràn pé: “Kí inú yín ru, ṣùgbọ́n ẹ má ṣẹ̀. Ẹ sọ ohun tí ẹ ní í sọ ní ọkàn-àyà yín, lórí ibùsùn yín, kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.” (Sáàmù 4:4) Bó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká ní sùúrù títí tára wa á fi balẹ̀ ká tó ṣe ohunkóhun tàbí ká tó ṣèpinnu. (Òwe 14:17, 29) A lè gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà, “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà [wa] àti agbára èrò orí [wa] nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Àlàáfíà Ọlọ́run yìí yóò fẹsẹ̀ wa múlẹ̀ yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti pa agbára ìmòye wa mọ́ délẹ̀délẹ̀.
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a bá fẹ́ pa agbára ìmòye wa mọ́ délẹ̀délẹ̀?
17 Gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe láìka gbogbo ipá tá à ń sà sí láti yẹra fún ewu ká sì hùwà ọgbọ́n. (Jákọ́bù 3:2) Ó lè ṣẹlẹ̀ pé a fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ kan tó lè ṣàkóbá fún wa tá ò sì mọ̀ rárá. (Sáàmù 19:12, 13) Ká tún rántí pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn, a kò ní agbára tàbí ẹ̀tọ́ láti darí ìṣísẹ̀ ara wa àyàfi tí Jèhófà bá darí rẹ̀. (Jeremáyà 10:23) Ọpẹ́ wa mà pọ̀ o, pé Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sáàmù 32:8) Ó dájú pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè pa agbára ìmòye wa mọ́ délẹ̀délẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àkọsílẹ̀ àdéhùn okòwò, wo Ilé Ìṣọ́, August 1, 1997, ojú ìwé 30 sí 31; Ilé-Ìṣọ́nà, November 15, 1986, ojú ìwé 16-17; àti Jí! July 8, 1984, ojú ìwé 13 sí 15. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ wọ́n jáde.
b Irú ìwádìí yìí yóò tún ṣàǹfààní fáwọn tó ń gbé oríṣiríṣi ìtọ́jú ara tó ní àríyànjiyàn nínú yẹ̀ wò.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
Báwo la ṣe lè pa agbára ìmòye wa mọ́
• bí wọ́n bá fi okòwò kan lọ̀ wá?
• tá a bá ń wá ẹni tá a fẹ́ fẹ́?
• tá a bá ń ṣàìsàn?
• tá a bá ní ìdààmú ọkàn?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]
Ǹjẹ́ O Lè Fọkàn Tán Ohun Tó O Rí Níbẹ̀?
Àwọn ìkéde tó fara hàn lórí àwọn ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì tó wà fáwọn mò-ń-wọ́kọ àti mò-ń-wáya ṣèkìlọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí:
“Bó ti wù ká sapá tó, kò sí ọ̀nà tá a fi lè mọ irú ẹni tí ẹnì kan jẹ́ gan-an.”
“A kò lè fọwọ́ sọ̀yà pé ohun tá a bá kà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì jóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ tàbí pé ó ṣeé mú lò.”
“Èrò, ìmọ̀ràn, àlàyé, ìpolówó ọjà, ìsọfúnni tàbí ohun mìíràn tó wà lórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì [yìí] wá látọ̀dọ̀ àwọn tó fi wọ́n síbẹ̀, . . . a ò sì lè gbára lé wọn pátápátá.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
“Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Báwo làwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni ṣe lè fara wé omidan Ṣúlámáítì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
“Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin”