Jẹ́ Kí Ìfòyemọ̀ Dáàbò Bò ọ́
“Agbára ìrònú fúnra rẹ̀ yóò ṣíji bò ọ́, ìfòyemọ̀ fúnra rẹ̀ yóò dáàbò bò ọ́.”—ÒWE 2:11, NW.
1. Ìfòyemọ̀ lè dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ kí ni?
JÈHÓFÀ fẹ́ kí o lo ìfòyemọ̀. Èé ṣe? Nítorí, ó mọ̀ pé yóò dáàbò bò ọ́ kúrò nínú onírúurú ewu. Òwe 2:10-19 (NW) bẹ̀rẹ̀ ní sísọ pé: “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọ inú ọkàn àyà rẹ lọ, tí ìmọ̀ fúnra rẹ̀ sì di ohun dídùn fún ọkàn rẹ gan-an, agbára ìrònú fúnra rẹ̀ yóò ṣíji bò ọ́, ìfòyemọ̀ fúnra rẹ̀ yóò dáàbò bò ọ́.” Dáàbò bò ọ́ kúrò lọ́wọ́ kí ni? Kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun bí “ọ̀nà búburú,” àwọn tí ń fi ojú ọ̀nà títọ́ sílẹ̀, àti àwọn oníbékebèke.
2. Kí ni ìfòyemọ̀, irú èwo ní pàtàkì sì ni àwọn Kristẹni ń fẹ́ láti ní?
2 Ó ṣeé ṣe kí o rántí pé, ìfòyemọ̀ jẹ́ ọgbọ́n èrò inú tí ń fi ìyàtọ̀ hàn láàárín ohun kan àti òmíràn. Ẹni tí ó ní ìfòyemọ̀ ń wòye ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín èrò tàbí àwọn nǹkan, ó sì ń ṣe ìpinnu gígún régé. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, àwa ní pàtàkì ń fẹ́ ìfòyemọ̀ tẹ̀mí, tí a gbé ka ìmọ̀ pípéye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ṣe ni ó dà bí ẹni pé a ń yọ bíríkì tí a óò fi kọ́ ilé ìfòyemọ̀ tẹ̀mí. Ohun tí a bá kọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tí yóò mú inú Jèhófà dùn.
3. Báwo ni a ṣe lè jèrè ìfòyemọ̀ tẹ̀mí?
3 Nígbà tí Ọlọ́run bi Sólómọ́nì, Ọba Ísírẹ́lì, léèrè irú ìbùkún tí ó ń fẹ́, ọ̀dọ́ olùṣàkóso náà sọ pé: “Fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ, láti mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú.” Sólómọ́nì béèrè fún ìfòyemọ̀, Jèhófà sì fún un lọ́nà pípabanbarì. (Àwọn Ọba Kìíní 3:9; 4:30) Láti ní ìfòyemọ̀, a ní láti gbàdúrà, a sì ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ìtẹ̀jáde tí ń lani lóye, tí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” ń pèsè. (Mátíù 24:45-47) Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìfòyemọ̀ tẹ̀mí títí dé ìwọ̀n tí a óò fi “dàgbà di géńdé nínú agbára òye,” láti lè “fi ìyàtọ̀ sáàárín [tàbí, láti fòye mọ] ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Kọ́ríńtì Kíní 14:20; Hébérù 5:14.
Àìní Àrà Ọ̀tọ̀ fún Ìfòyemọ̀
4. Kí ni ó túmọ̀ sí láti ní ojú tí ó “mú ọ̀nà kan,” báwo sì ni ó ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
4 Pẹ̀lú ìfòyemọ̀ yíyẹ, a lè hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Kristi pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan [ti ara] mìíràn wọ̀nyí ni a óò sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:33) Jésù tún sọ pé: “Fìtílà ara ni ojú rẹ. Nígbà tí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan, gbogbo ara rẹ pẹ̀lú á mọ́lẹ̀ yòò.” (Lúùkù 11:34) Ojú dà bíi fìtílà. Ojú tí ó “mú ọ̀nà kan” kì yóò tàn wá jẹ, yóò darí àfiyèsí sí ọ̀nà kan. Pẹ̀lú irú ojú bẹ́ẹ̀, a lè fi ìfòyemọ̀ hàn, kí a sì rìn láìfi ẹsẹ̀ kọ nípa tẹ̀mí.
5. Ní ti okòwò, kí ni ó yẹ kí a ní lọ́kàn nípa ète ìjọ Kristẹni?
5 Dípò mímú kí ojú wọn mú ọ̀nà kan, àwọn kan ti mú kí ìgbésí ayé tiwọn àti ti àwọn ẹlòmíràn lọ́jú pọ̀, nípa àwọn òwò fífanimọ́ra. Ṣùgbọ́n, ó yẹ kí a rántí pé, ìjọ Kristẹni jẹ́ “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” (Tímótì Kíní 3:15) Gẹ́gẹ́ bí ọwọ̀n ilé, òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìjọ gbé ró, kì í ṣe òwò ẹnikẹ́ni. A kò dá ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ibi tí a ti lè polówó òwò, ọjà, tàbí iṣẹ́. A gbọ́dọ̀ yẹra fún ṣíṣòwò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ìfòyemọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé, Gbọ̀ngàn Ìjọba, Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ibi ojúkò fún ìkẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni àti ìjíròrò tẹ̀mí. Bí a bá ní láti lo ipò ìbátan tẹ̀mí láti polówó irú ìṣòwò èyíkéyìí, èyí kì yóò ha fi àìnímọrírì tí ó tó hàn fún àwọn ìlànà tẹ̀mí bí? A kò gbọ́dọ̀ lo àǹfààní ipò ìbátan inú ìjọ láè fún jíjèrè owó.
6. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a tà tàbí polówó ọjà àti iṣẹ́ ní àwọn ìpàdé ìjọ?
6 Àwọn kan ti lo ìkẹ́gbẹ́pọ̀ ti ìṣàkóso Ọlọ́run láti ta egbòogi amárale tàbí ti ìṣaralóge, àwọn èròjà fítámìn, ohun èèlò ìbánisọ̀rọ̀, ohun èèlò ìkọ́lé, ètò ìrìn àjò, àwọn ètò àti ohun èèlò ìmúkọ̀ǹpútà-ṣiṣẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìpàdé ìjọ kì í ṣe ibi ìtajà tàbí ibi ìpolówó ọjà tàbí iṣẹ́. A lè fòye mọ ìlànà ìpìlẹ̀ náà, tí a bá rántí pé Jésù “lé gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n ní àgùntàn àti màlúù jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì, ó sì da ẹyọ owó àwọn olùpààrọ̀ owó sílẹ̀ ó sì sojú àwọn tábìlì wọn dé. Ó sì wí fún àwọn wọnnì tí ń ta àwọn àdàbà náà pé: ‘Ẹ kó nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín! Ẹ dẹ́kun sísọ ilé Bàbá mi di ilé ọjà títà!’”—Jòhánù 2:15, 16.
Ìdókòwò Ńkọ́?
7. Èé ṣe tí a fi nílò ìfòyemọ̀ àti ìṣọ́ra nínú ọ̀ràn okòwò?
7 Ìfòyemọ̀ àti ìṣọ́ra ṣe pàtàkì nígbà tí a bá ń gbé dídókòwò tí ó léwu yẹ̀ wò. Kí a sọ pé, ẹnì kan fẹ́ yáwó, tí ó sì ń ṣe irú ìlérí wọ̀nyí: “Mo fọwọ́ sọ̀yà pé ìwọ yóò jèrè gọbọi.” “O kò lè pàdánù kọ́bọ̀. Okòwò yí dá mi lójú hán-únhán-ún.” Ṣọ́ra nígbà tí ẹnì kan bá ń fọwọ́ sọ̀yà lọ́nà bẹ́ẹ̀. Yálà kí ó jẹ́ pé òun kò ní ojú ìwòye bí nǹkan ṣe rí gan-an tàbí kí ó jẹ́ alábòsí, nítorí pé okòwò kì í ṣe ohun tí a lè fọwọ́ sọ̀yà lé lórí. Ní ti gidi, àwọn ẹlẹ́nuúdùn, afàwọ̀rajà ẹ̀dá ti lu àwọn mẹ́ńbà ìjọ ní jìbìtì. Èyí mú wa rántí “àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” tí wọ́n yọ́ wọ inú ìjọ ọ̀rúndún kìíní, tí wọ́n sì “sọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa di àwáwí fún ìwà àìníjàánu.” Wọ́n dà bí àpáta mímú bérébéré tí ń bẹ nísàlẹ̀ omi, tí àwọn òmùwẹ̀ lè forí sọ, kí wọ́n sì kú. (Júúdà 4, 12) Òótọ́ ni pé èrò ọkàn àwọn oníjìbìtì yàtọ̀, ṣùgbọ́n àwọn pẹ̀lú ń fi àwọn mẹ́ńbà ìjọ ṣèjẹ.
8. Kí ní ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn òwò kan tí ó jọ bíi pé yóò mú èrè wá?
8 Àní àwọn Kristẹni tí wọ́n ní èrò rere pàápàá ti ṣàjọpín ìsọfúnni nípa òwò tí ó dà bí èyí tí yóò mówó wọlé pẹ̀lú àwọn Kristẹni arákùnrin wọn, kìkì láti rí i pé, àwọn àti àwọn tí ó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn pàdánù owó tí wọ́n fi dókòwò. Nítorí èyí, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ Kristẹni ti pàdánù àwọn àǹfààní nínú ìjọ. Nígbà tí òwò asọni-dọlọ́rọ̀-òjijì bá di ètò gbájú-ẹ̀, ẹnì kan ṣoṣo tí yóò jèrè nínú rẹ̀ ni oníjìbìtì náà, tí yóò ti fẹsẹ̀ fẹ kí á tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́. Báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti yẹra fún irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀?
9. Èé ṣe tí a fi nílò ìfòyemọ́ láti baà lè yiiri ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa okòwò kan wò?
9 Ìfòyemọ̀ ní ìtumọ̀ jíjẹ́ ẹni tí ó lè lóye ohun tí ó fara sin. A nílò agbára yìí kí a baà lè yiiri ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa okòwò kan wò. Àwọn Kristẹni máa ń ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara wọn, àwọn kan sì lè ronú pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin àwọn nípa tẹ̀mí kì yóò lọ́wọ́ nínú òwò tí ó lè mú kí owó àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn wọmi. Ṣùgbọ́n òtítọ́ náà pé oníṣòwò kán jẹ́ Kristẹni kì í ṣe ẹ̀rí pé ògbóǹkangí ni nínú ọ̀ràn òwò tàbí pé òwò rẹ̀ yóò kẹ́sẹ járí.
10. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni kan fi ń wá owó yá lọ́wọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, kí ní sì lè ṣẹlẹ̀ sí irú okòwò bẹ́ẹ̀?
10 Àwọn Kristẹni kan ń fẹ́ láti yáwó lọ́wọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin láti fi dókòwò, nítorí pé, àwọn ilé iṣẹ́ ayánilówó tí a mọ̀ bí ẹni mowó kì yóò yá wọn ní irú owó bẹ́ẹ̀ láé fún okòwò eléwu tí wọ́n fẹ́ dáwọ́ lé. A ti tan ọ̀pọ̀ jẹ láti gbà gbọ́ pé, bí wọ́n bá ṣáà lè fi owó wọn dókòwò, kíá ni nǹkan yóò rọ̀ ṣọ̀mù fún wọn, láìṣe làálàá púpọ̀ tàbí láìṣe làálàá kankan rárá. Okòwò kan ń fa àwọn kan mọ́ra nítorí bí a ṣe pọ́n ọn tó, kìkì láti pàdánù owó tí wọ́n ti fi gbogbo ìgbésí ayé wọn tù jọ! Kristẹni kan fi owó tàbùà-tabua kan dókòwò, ní ríretí láti jèrè ìpín 25 lórí ọgọ́rùn-ún láàárín ọ̀sẹ̀ méjì péré. Gbogbo owó náà wọmi nígbà tí a kéde pé ilé iṣẹ́ náà ti wọko gbèsè. Nínú ọ̀ràn òwò míràn, alábòójútó ètò ilé àti ilẹ̀ kán yáwó tàbùà-tabua lọ́wọ́ àwọn kan nínú ìjọ. Ó ṣèlérí pé òun yóò san èlé gọbọi pa dà, ṣùgbọ́n, ó wọko gbèsè, ó sì pàdánù gbogbo owó tí ó yá.
Nígbà Tí Òwò Bá Forí Ṣánpọ́n
11. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fúnni nípa ìwọra àti ìfẹ́ owó?
11 Ìforíṣánpọ́n òwò ti yọrí sí ìjákulẹ̀ àti pàápàá sí pípàdánù ipò tẹ̀mí níhà ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni kan tí wọ́n wọnú òwò tí ó léwu. Àìjẹ́ kí ìfòyemọ̀ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ààbò ti fa ìrora ọkàn àti ìbìnújẹ́ kíkorò. Ìwọra ti dẹkùn mú ọ̀pọ̀lọpọ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan . . . ìwà ìwọra láàárín yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́.” (Éfésù 5:3) Ó sì kìlọ̀ pé: “Àwọn wọnnì tí wọ́n pilẹ̀ pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ àwọn ìfẹ́ ọkàn òpònú àti aṣenilọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ìrunbàjẹ́. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́ wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—Tímótì Kíní 6:9, 10.
12. Bí àwọn Kristẹni bá dòwò pọ̀, kí ni ó yẹ kí wọ́n rántí ní pàtàkì?
12 Bí Kristẹni kan bá ní ìfẹ́ owó, ó lè mú ìpalára púpọ̀ nípa tẹ̀mí bá ara rẹ̀. Àwọn Farisí nífẹ̀ẹ́ owó, èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ìwà àwọn ènìyàn ní àwọn ìkẹyìn ọjọ́ wọ̀nyí. (Lúùkù 16:14; Tímótì Kejì 3:1, 2) Ní ìyàtọ̀ pátápátá, ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni kan yẹ kí ó “wà láìsí ìfẹ́ owó.” (Hébérù 13:5) Dájúdájú, àwọn Kristẹni lè dòwò pọ̀ tàbí da iṣẹ́ pọ̀. Ṣùgbọ́n, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò gbọ́dọ̀ pa ìjíròrò àti ìdúnàádúrà pọ̀ mọ́ ọ̀ràn ìjọ. Sì rántí pé: Kódà láàárín àwọn arákùnrin nípa tẹ̀mí, ẹ máa kọ àdéhùn òwò yín sílẹ̀ nígbà gbogbo. Àpilẹ̀kọ tí a pè ní “Kọ Ọ Silẹ Sori Iwe!” tí a tẹ̀ jade nínú Jí!, July 8, 1984, ojú ìwé 13 sí 15, ṣàǹfààní lórí ọ̀ràn yí.
13. Báwo ni ìwọ yóò ṣe so Òwe 22:7 mọ́ okòwò?
13 Òwe 22:7 (NW) sọ fún wa pé: ‘Ẹni tí ó yá nǹkan ni ìránṣẹ́ ẹni tí ó wínni.’ Kò sábà bọ́gbọ́n mu fún wa láti fi ara wa tàbí arákùnrin wa sípò irú ìránṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ẹnì kan bá rọ̀ wá pé kí a yá òun lówó láti dókòwò, yóò dára kí a ronú lórí agbára rẹ̀ láti san owó náà pa dà. A ha mọ̀ ọ́n sì ẹni tí ó ṣeé gbára lé, tí ó sì ṣeé fọkàn tẹ̀ bí? Àmọ́ ṣáá o, a ní láti mọ̀ pé yíyáni ní irú owó bẹ́ẹ̀ lè túmọ̀ sí pípàdánù owó náà, nítorí pé, ọ̀pọ̀ okòwò máa ń forí ṣánpọ́n. Wíwọnú àdéhùn kì í ṣe ẹ̀rí pé òwò yóò kẹ́sẹ járí. Ó sì dájú gbangba pé kò bọ́gbọ́n mu fún ẹnì kan láti gbà láti yani ní iye owó tí ó ju iye tí ó lè fara mọ́ láti pàdánù lọ.
14. Èé ṣe tí a fi ní láti lo ìfòyemọ̀, bí a bá ti yá Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa tí òwò rẹ̀ forí ṣánpọ́n lówó?
14 A ní láti fi ìfòyemọ̀ hàn bí a bá ti yá Kristẹni kan lówó láti dókòwò, tí owó náà sì ti wọmi, bí ìwà àbòsí kankan kò tilẹ̀ wọ inú rẹ̀. Bí ìforíṣánpọ́n òwò náà kì í bá á ṣe ẹ̀bi onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí ó yáwó lọ́wọ́ wa, a ha lè sọ pé ó ti hùwà láìfí sí wa bí? Rárá o, nítorí pé a fínnúfíndọ̀ yá a lówó náà ni, bóyá a sì ti ń gba èlé lórí rẹ̀, tí kò sì sí ìwà àbòsí kan tí ó jẹ yọ. Níwọ̀n bí kò ti ki ìwà àbòsí bọ̀ ọ́, a kò ní ìdí kankan láti pe ẹni tí a yá lówó lẹ́jọ́. Èrè wo ni yóò tẹ̀yìn rẹ̀ yọ bí a bá pé Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni tí ó jẹ́ aláìlábòsí lẹ́jọ́, tí ó ní láti jẹ́wọ́ pé òun ti wọko gbèsè, nítorí òwò tí a fi ọkàn rere dá kalẹ̀ ti forí ṣánpọ́n?—Kọ́ríńtì Kíní 6:1.
15. Àwọn kókó wo ni ó ṣe pàtàkì pé kí a gbé yẹ̀ wò, bí a bá kéde pé ẹni tí a yá lówó ti wọko gbèsè?
15 Nígbà míràn, àwọn ènìyàn tí òwò wọn forí ṣánpọ́n máa ń wá ọ̀nà àtimóríbọ́ nípa sísọ pé àwọn ti wọko gbèsè. Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni ti ka gbèsè tí wọ́n jẹ sí, kódà lẹ́yìn tí a bá ti fi ẹsẹ òfin tọ yíyọ àwọn gbèsè kan lọ́rùn wọn, ẹ̀rí ọkàn àwọn kan ti sún wọn láti gbìyànjú láti san gbèsè tí a ti fagi lé náà bí ẹni tí wọ́n jẹ́ ni gbèsè yóò bá gba àsanpadà. Ṣùgbọ́n, bí ẹnì kan tí a yá lówó bá pàdánù owó arákùnrin rẹ̀, tí ó sì wá ń gbé ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì lẹ́yìn náà ńkọ́? Tàbí bí ẹni tí a yá lówó náà bá rí owó tí ó tó gbà láti san gbèsè rẹ̀ pa dà, ṣùgbọ́n tí kò sú já gbèsè tí ó jẹ arákùnrin rẹ̀ ńkọ́? Lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀, ìtóótun ẹni tí a yá lówó náà láti ṣiṣẹ́ sìn nínú ipò ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ yóò kọni lóminú.—Tímótì Kíní 3:3, 8; wo Ilé-Ìṣọ́nà, September 15, 1994, ojú ìwé 30 àti 31.
Bí Jìbìtì Bá Wọ̀ Ọ́ Ńkọ́?
16. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni a lè gbé, bí ó bá jọ bí ẹni pé a ti lù wá ní jìbìtì?
16 Ìfòyemọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo okòwò ní ń mú èrè wá. Síbẹ̀, bí jìbìtì bá ti wọ̀ ọ́ ńkọ́? Jìbìtì jẹ́ “mímọ̀ọ́mọ̀ lo ẹ̀tàn, ọgbọ́n àyínìke, tàbí yíyí òtítọ́ po fún ète sísún ẹlòmíràn láti yọ̀ǹda ohun ìní rẹ̀ ṣíṣeyebíye tàbí láti yọ̀ǹda ẹ̀tọ́ rẹ̀ lábẹ́ òfin.” Jésù Kristi to àwọn ìgbésẹ̀ tí ẹnì kan lè gbé lẹ́sẹẹsẹ, nígbà tí ó bá ronú pé olùjọ́sìn ẹlẹgbẹ́ òun ti lu òun ní jìbìtì. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Mátíù 18:15-17 sọ, Jésù wí pé: “Bí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, lọ fi àlèébù rẹ̀ hàn án ní kedere láàárín ìwọ àti òun nìkan. Bí ó bá fetí sílẹ̀ sí ọ, ìwọ́ ti jèrè arákùnrin rẹ. Ṣùgbọ́n bí òun kò bá fetí sílẹ̀, mú ẹnì kan tàbí méjì sí i dání pẹ̀lú rẹ, kí a lè fi ìdí ọ̀ràn gbogbo múlẹ̀ ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta. Bí òun kò bá fetí sílẹ̀ sí wọn, sọ fún ìjọ. Bí òun kò bá fetí sílẹ̀ sí ìjọ pàápàá, jẹ́ kí ó rí sí ọ gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti gẹ́gẹ́ bí agbowó orí.” Àkàwé tí Jésù ṣe lẹ́yìn náà fi hàn pé òun ní irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn owó lọ́kàn, títí kan jìbìtì.—Mátíù 18:23-35.
17, 18. Bí ẹni tí ó bá pe ara rẹ̀ ní Kristẹni bá lù wá ní jìbìtì, báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe lè dáàbò bò wá?
17 Àmọ́ ṣáá o, kì yóò sí ìdí kankan tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí a là lẹ́sẹẹsẹ sínú Mátíù 18:15-17 bí kò bá sí ẹ̀rí tàbí àmì jìbìtì. Síbẹ̀, bí ẹnì kan tí ó pe ara rẹ̀ ní Kristẹni bá lù wá ní jìbìtì ní ti gidi ńkọ́? Ìfòyemọ̀ lè dáàbò bò wá láti yẹra fún gbígbé ìgbésẹ̀ tí ó lè ba orúkọ ìjọ jẹ́. Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti jẹ́ kí á hùwà àìtọ́ sí wọn, àní kí a tilẹ̀ lù wọ́n ní jìbìtì pàápàá, dípò tí wọn yóò fi gbé arákùnrin wọn lọ sí ilé ẹjọ́.—Kọ́ríńtì Kíní 6:7.
18 Àwọn ojúlówó arákùnrin àti arábìnrin wa kò ‘kún fún jìbìtì àti ìwà aṣa,’ bí oníṣẹ́ oṣó náà, Baa-Jésù. (Ìṣe 13:6-12) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a lo ìfòyemọ̀ nígbà tí a bá pàdánù owó nínú okòwò kan tí ó ní àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nínú. Bí a bá ń ronú pé kí a fi ẹsẹ̀ òfin tọ̀ ọ́, ó yẹ kí a ronú lórí ìyọrísí tí ó ṣeé ṣe kí ó ní lórí àwa fúnra wa, lórí ẹni tọ̀hún tàbí àwọn ẹlòmíràn, lórí ìjọ, àti lórí àwọn ará ìta. Fífẹ́ láti rí owó gbà-máà-bínú gbà lè gba ọ̀pọ̀ àkókò, okun, àti ohun ìní wa mìíràn. Ó lè yọrí sí kìkì sísọ àwọn agbẹjọ́rò àti àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ mìíràn di ọlọ́rọ̀. Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn Kristẹni kan ti sọ àwọn àǹfààní ti ìṣàkóso Ọlọ́run nù, nítorí ríri ara wọn bọnú àwọn nǹkan wọ̀nyí. Títipa báyìí pín ọkàn wa níyà ń mú inú Sátánì dùn, ṣùgbọ́n inú Jèhófà ni a fẹ́ mú dùn. (Òwe 27:11) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, fífara mọ́ pípàdánù owó lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ìrora ọkàn, kí àwa àti àwọn alàgbà sì ní ọ̀pọ̀ àkókò fún ohun mìíràn. Yóò ṣèrànwọ́ láti pa àlàáfíà ìjọ mọ́, yóò sì mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti máa bá fífi ire Ìjọba náà sí ipò kíní nìṣó.
Ìfòyemọ̀ àti Ìpinnu Ṣíṣe
19. Kí ni ìfòyemọ̀ tẹ̀mí àti àdúrà lè ṣe fún wa nígbà tí a bá ń ṣe àwọn ìpinnu tí ń fa másùnmáwo?
19 Ṣíṣe ìpinnu lórí ọ̀ràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú owó tàbí òwò lè fa másùnmáwo ní ti gidi. Ṣùgbọ́n, ìfòyemọ̀ tẹ̀mí lè ràn wá lọ́wọ́ láti yiiri ọ̀ràn wò, kí a sì ṣe àwọn ìpinnu tí ó lọ́gbọ́n nínú. Síwájú sí i, gbígbáralé Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà lè mú “àlàáfíà Ọlọ́run” wá fún wa. (Fílípì 4:6, 7) Ó jẹ́ ìparọ́rọ́ àti ìbàlẹ̀ ọkàn tí ń jẹ yọ láti inú ipò ìbátan pẹ́kípẹ́kí tí a ní pẹ̀lú Jèhófà. Dájúdájú, irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìwàdéédéé wa mọ́ nígbà tí a bá dóju kọ àwọn ìpinnu nínira.
20. Kí ni a ní láti pinnu láti ṣe nípa àwọn ọ̀ràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú òwò àti ìjọ?
20 Ẹ jẹ́ kí a pinnu láti má ṣe jẹ́ kí awuyewuye òwò da àlàáfíà wa tàbí ti ìjọ rú. A gbọ́dọ̀ rántí pé ìjọ Kristẹni ń ṣiṣẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, kì í ṣe láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ojúkò ìṣòwò. Ọ̀ràn òwò kò gbọ́dọ̀ pa pọ̀ mọ́ ìgbòkègbodò ìjọ. A gbọ́dọ̀ lo ìfòyemọ̀, kí a sì ṣọ́ra nígbà tí a bá ń dáwọ́ lé òwò èyíkéyìí. Ẹ sì jẹ́ kí a máa fìgbà gbogbo di ojú ìwòye tí ó wà déédéé mú nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ní wíwá ire Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́. Bí òwò àwọn olùjọ́sìn ẹlẹgbẹ́ wá bá forí ṣánpọ́n, ẹ jẹ́ kí a máa sakun láti ní ire gbogbo àwọn tí ọ̀ràn kàn lọ́kàn.
21. Báwo ni a ṣe lè lo ìfòyemọ̀, kí a sì gbé ìgbésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó wà nínú Fílípì 1:9-11?
21 Dípò jíjẹ́ kí àwọn ọ̀ràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú owó àti àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì míràn jẹ wá lógún ju bí ó ti yẹ lọ, ǹjẹ́ kí gbogbo wa jẹ́ kí ọkàn àyà wa fà sí ìfòyemọ̀, kí a gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, kí a sì fi ire Ìjọba sí ipò kíní. Ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà Pọ́ọ̀lù, ‘ǹjẹ́ kí ìfẹ́ wa lè túbọ̀ máa pọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún, kí a lè máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù, kí a má ṣe mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀’ tàbí mú ara wa kọsẹ̀. Nísinsìnyí tí Kristi Ọba ti gúnwà sórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run, ẹ jẹ́ kí a máa lo ìfòyemọ̀ tẹ̀mí nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wa. ‘Kí a sì lè kún fún èso òdodo nípasẹ̀ Jésù Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run wa,’ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.—Fílípì 1:9-11.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsì?
◻ Kí ni ìfòyemọ̀?
◻ Èé ṣe tí ìdí pàtàkì fi wà láti lo ìfòyemọ̀ nínú ọ̀ràn ìṣòwò láàárín àwọn Kristẹni?
◻ Báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́, bí a bá ronú pé onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ti lù wá ní jìbìtì?
◻ Ipa wo ni ó yẹ kí ìfòyemọ̀ kó nínú ìpinnu ṣíṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìfòyemọ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìmọ̀ràn Jésù láti máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ sílò
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ẹ máa kọ àdéhùn òwò yín sílẹ̀ nígbà gbogbo