ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 5/1 ojú ìwé 28-31
  • Kí Ni Òwò Rẹ Yóò Ná Ọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Òwò Rẹ Yóò Ná Ọ?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fi Owó Sí Àyè Rẹ̀
  • Dúró Ti Àdéhùn Rẹ
  • Jẹ́ Aláìlábòsí
  • Bá Àwọn Onígbàgbọ́ Ẹlẹgbẹ́ Rẹ Lò Lọ́nà Tí Ó Bójúmu
  • Jẹ́ Kí Ìfòyemọ̀ Dáàbò Bò ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Jíjẹ́ Olóòótọ́ Ló Máa Ń Mú Kí Èèyàn Ṣe Àṣeyọrí Tó Tọ́jọ́
    Jí!—2012
  • Àwọn Ohun Tó Mú Kó Ṣòro Láti Jẹ́ Olóòótọ́
    Jí!—2012
  • Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ohun Gbogbo
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 5/1 ojú ìwé 28-31

Kí Ni Òwò Rẹ Yóò Ná Ọ?

AYA ààrẹ orílẹ̀-èdè kan ní South America ni a fẹ̀sùn kàn pé ó ń ná ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún dollar sórí àwọn iṣẹ́ tí a gbé fún àwọn ilé-iṣẹ́ awúrúju tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé rẹ̀ dá sílẹ̀. A fàṣẹ ọba mú olùṣekòkáárí kátàkárà ìṣúra ìdókòwò kan ẹni ọdún 38 ní India tí a sì gba ilé àdágbé aláruru rẹ̀ pẹ̀lú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ 29 lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí ẹ̀sùn tí a fi kàn án pé ó lọ́wọ́ nínú ìwà láìfí tí ó jẹmọ́ ìfowópamọ́ àti kátàkárà ìṣúra ìdókòwò bí $1.6 billion. Ní Philippines, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùgbé erékùṣù ń rí oúnjẹ òòjọ́ wọn nípa ṣíṣe ìbọn ìléwọ́. Ìròyìn fi tó wa létí pé, láti lè máa bá òwò tí ń mówó wọlé yìí lọ, àṣà wọn ni láti máa fún àwọn aláṣẹ ìjọba ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n má baà dásí i.

Bẹ́ẹ̀ni, àbòsí àti èrú nínú òwò wọ́pọ̀ jákèjádò ayé. Lọ́pọ̀ ìgbà ni ó sì ń ná àwọn ènìyàn tí ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀ ní ipò àti ọlá wọn, bákan náà sì ni owó.

Ìwọ ńkọ́? Ṣe oníṣòwò ni ọ́? Tàbí o ha ń gbèrò láti bẹ̀rẹ̀ òwò kan bí? Kí ni yóò ná ọ? Lọ́nà tí kò ṣeé yẹ̀sílẹ̀, jíjẹ́ oníṣòwò yóò ná ọ ní ohun kan. Èyí kò fi dandan burú. Bí ó ti wù kí ó rí, ó bọ́gbọ́n mu láti gbéṣirò lé ohun tí yóò ná ọ ṣáájú kí o tó dáwọ́lé iṣẹ́ òwò kan tàbí kí o tó pinnu nípa ọ̀kan tí a ti dásílẹ̀ tẹ́lẹ̀. (Luku 14:28) Àpótí tí ó wà ní ojú-ìwé 31 fi díẹ̀ nínú ohun tí ń náni tí ìwọ yóò fẹ́ láti gbéyẹ̀wò hàn.

Ó hàn gbangba pé, jíjẹ́ oníṣòwò kò rọrùn. Fún Kristian kan, àwọn ohun àìgbọdọ̀máṣe nípa tẹ̀mí àti ti ìwàrere wà láti gbé yẹ̀wò. Ọwọ́ rẹ ha lè ká ohun tí ń náni kí o sì wàdéédéé nípa tẹ̀mí bí? Àwọn ohun kan tí ń náni ha wà tí ó rékọjá ohun tí o lè faramọ́ níti ìwàrere bí? Àwọn ìlànà díẹ̀ wo ni yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lè pinnu àwọn ohun tí ń náni tí ó ṣeé faramọ́ àti èyí tí kò ṣeé faramọ́?

Fi Owó Sí Àyè Rẹ̀

A nílò owó láti lè máa bá òwò lọ, a sì ní ìrètí pé òwò yóò mú owó tí ó tó wọlé láti lè gbọ́ bùkátà ìdílé ẹni. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn góńgó tí ó níí ṣe pẹ̀lú owó ni a lè tètè fèrúyípo. Ìwọra lè wọnú ọ̀ràn náà. Fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, gbogbo nǹkan ni a óò fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn tí ọ̀ràn owó bá ti wọ̀ ọ́. Síbẹ̀, ọ̀kan lára àwọn òǹkọ̀wé ìwé Owe nínú Bibeli, Aguri, fi ojú-ìwòye tí ó wàdéédéé hàn nígbà tí ó wí pé: “Máṣe fún mi ní òṣì, máṣe fún mi ní ọrọ̀; fi oúnjẹ tí ó tó fún mi bọ́ mi.” (Owe 30:8) Ó mọ ìníyelórí níní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun ìgbẹ́mìíró tí ó tó—òun kò ní “ẹ̀mí níní owó tabua,” bí àwọn kan tí máa ń sọ bí ó bá di ọ̀ràn òwò.

Ṣùgbọ́n, ìwọra lè mú kí ẹnì kan gbàgbé ìlànà yìí nígbà tí ohun tí a sábà máa ń pè ní àǹfààní aásìkí bá yọjú. Òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ní orílẹ̀-èdè kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ròyìn irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Ilé-iṣẹ́ kan tí ó ń fẹ́ owó ìdókòwò fúnni ní èrò náà pé àwọn olùdókòwò lè sọ owó wọn di ìlọ́po méjì ní kíákíá, bóyá láàárín oṣù díẹ̀. Àǹfààní owó bìrìbìrì yìí sún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti dókòwò. Òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò náà sọ pé: “Wọ́n háragàgà láti kó wọ̀ ọ́. Wọn kò ṣe ìwádìí dáradára, wọ́n sì yáwó [láti dókòwò].”

Ní ìyàtọ̀ gédégédé, àwọn ẹni méjì kan lọ láti wádìí ọ́fíìsì ilé-iṣẹ́ náà ṣáájú kí wọ́n tó dókòwò. A dù wọ́n ní àǹfààní náà láti rí àwọn ohun-èlò tí a fi ń ṣe àwọn nǹkan. Èyí mú kí wọ́n máa ṣiyèméjì nípa irú orúkọ tí ilé-iṣẹ́ náà ní. Èyí yọrí sí ààbò fún wọn, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé láàárín ọ̀sẹ̀ mélòókan, a túdìí àṣírí ohun tí ó jọ bí èrú tí a pètepèrò, a sì fàṣẹ ọba mú àwọn ènìyàn tí ọ̀ràn náà kàn. Ìwọ ro ohun tí èyí ná àwọn wọnnì tí kò kọ́kọ́ wádìí. Kì í ṣe owó nìkan ni wọ́n pàdánù ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rẹ́ pàápàá tí wọ́n yá wọn lówó ṣùgbọ́n tí wọn kò lè san án padà nígbà tí ìpètepèrò náà dojúdé. Nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn owó, ẹ wo bí ó ti bọ́gbọ́n mu tó láti fi ìlànà Owe 22:3 sílò pé: “Ọlọgbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó sì pa ara rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n àwọn òpè a kọjá, a sì jẹ wọ́n níyà”!

Dúró Ti Àdéhùn Rẹ

Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé òwò náà kò mú èrè wá bí a ṣe retí ńkọ́? Orin Dafidi 15:4 gbóríyìn fún ẹnì kan tí ó dúró ti àdéhùn rẹ̀ àní bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kò bá tilẹ̀ mú èrè kankan wá fún un: “Ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀, tí kò sì yípadà.” Ó máa ń rọrùn láti dúró ti àdéhùn ẹni nígbà tí nǹkan bá ń lọ geere. Ṣùgbọ́n ó máa ń di ìdánwò ìwàtítọ́ nígbà tí kò bá lè mú èrè kankan wá fúnni níti ìṣúnná owó.

Rántí àpẹẹrẹ kan nínú Bibeli ní àkókò Joṣua. Àwọn ará Gibeoni dọ́gbọ́n darí àwọn ọ̀ràn kí ó baà lè jẹ́ pé àwọn olórí ìjọ ní Israeli yóò dá májẹ̀mú pẹ̀lú wọn kí wọ́n má sì ṣe pa wọ́n run. Níti gidi, wọ́n jẹ́ apákan orílẹ̀-èdè kan tí a kà sí àwọn tí ń dáyàfo Israeli. Nígbà tí a túdìí arúmọjẹ náà, “àwọn ọmọ Israeli kò pa wọ́n, nítorí tí àwọn olórí ìjọ àwọn ènìyàn ti fi OLUWA, Ọlọrun Israeli búra fún wọn.” (Joṣua 9:18) Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ àwùjọ yìí wá láti agbègbè ìpínlẹ̀ àwọn ọ̀tá, àwọn olórí ìjọ náà rí i pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e fi hàn pé èyí dùn mọ́ Jehofa nínú.—Joṣua 10:6-11.

Ìwọ yóò ha dúró ti àdéhùn òwò rẹ àti iṣẹ́ tí o gbà àní bí àwọn nǹkan kò bá lọ bí o ṣe retí bí?a Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí o túbọ̀ dàbí Jehofa, ẹni tí ó máa ń fìgbà gbogbo dúró ti àdéhùn rẹ̀.—Isaiah 55:11.

Jẹ́ Aláìlábòsí

Nínú òwò òde-òní àìlábòsí dàbí ẹranko tí a ti wu léwu, bí kò bá tilẹ̀ jẹ́ èyí tí ó ti parẹ́. Àwọn mìíràn tí wọ́n wà nínú òwò tí ó farajọ tìrẹ lè lo ọ̀nà àbòsí láti mú kí owó tí ń wọlé fún wọn pọ̀ síi. Wọ́n lè jẹ́ alábòsí nínú ìpolówó-ọjà. Wọ́n lè jí orúkọ ilé-iṣẹ́ mìíràn kí wọ́n sì lẹ̀ ẹ́ mọ́ ara ọjà wọn. Tàbí kí wọ́n gbé ọjà bàrúùfù kalẹ̀ bí èyí tí ó jẹ́ ojúlówó. Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọ̀nà àbòsí. Gẹ́gẹ́ bí Asafu ṣe sọ àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí “aláìwà-bí-Ọlọ́run” àwọn ẹni tí wọ́n ‘ti mú kí ọrọ̀ wọn pọ̀ síi.’—Orin Dafidi 73:12.

Ìwọ, gẹ́gẹ́ bí Kristian, yóò ha gba ọ̀nà tí kò bófinmu bí? Tàbí ìwọ yóò jẹ́ kí a ṣamọ̀nà rẹ̀ nípa ìlànà Bibeli, irú bí: “Awa kò ṣe àìtọ́ sí ẹni kankan, awa kò sọ ẹni kankan di ìbàjẹ́, awa kò yan ẹni kankan jẹ”; “awa ti kọ awọn ohun má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ tí ń tinilójú sílẹ̀ ní àkọ̀tán, a kò rin ìrìn àlùmọ̀kọ́rọ́yí”; “ìwọ̀n mìíràn, àti òṣùwọ̀n mìíràn, ìríra ni lójú Oluwa; ìwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì dára”? (2 Korinti 4:2; 7:2; Owe 20:23) Rántí pé, olùpilẹ̀ṣẹ̀ àbòsí kì í ṣe ẹlòmíràn bíkòṣe Satani Èṣù, “baba irọ́.”—Johannu 8:44.

Àwọn kan lè lòdì sí èyí kí wọ́n sì sọ pé: ‘Ó ṣòro láti máa bá òwò nìṣó láìjẹ́ pé ẹnì kan lo ọ̀nà àbòsí bí àwọn mìíràn ti ń ṣe.’ Níhìn-ín ni àwọn Kristian ti lè fi ìgbàgbọ́ nínú Jehofa hàn. A ń dán àìlábòsí wò nígbà tí ó bá náni ní nǹkan. Láti sọ pé ẹnì kan kò lè rí bá-ti-ṣé láìjẹ́ pé ó hùwà àbòsí túmọ̀ sí sísọ pé Ọlọrun kò bìkítà nípa àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹnì kan tí ó bá ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ nínú Jehofa ń mọ̀ pé Ọlọrun lè pèsè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè èyíkéyìí àti ní irú ipò-ọ̀ràn yòówù kí ó jẹ́. (Heberu 13:5) Lóòótọ́, ẹnì kan lè níláti ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí kò tó tí ń wọlé ju èyí tí àwọn alábòsí lè ní lọ, ṣùgbọ́n iye owó yìí kò ha tó láti san fún ìbùkún Ọlọrun bí?

Rántí pé, àbòsí dàbí ohun kan tí a jù, tí yóò tún ta padà lọ bá ẹni tí ó jù ú. Bí a bá rí i pé oníṣòwò kan jẹ́ alábòsí, ìgbà gbogbo ni àwọn oníbàárà àti akọ́jà-fúnni yóò máa pa á tì. Ó lè lù wọ́n ní jìbìtì lẹ́ẹ̀kan, ṣùgbọ́n àṣemọ nìyẹn. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, oníṣòwò kan tí ó jẹ́ aláìlábòsí sábà máa ń jèrè ọ̀wọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Ṣọ́ra kí èrò òdì má ṣe nípa ìdarí lórí rẹ, ‘Gbogbo ènìyàn ni ń ṣe é, nítorí náà ó dára.’ Ìlànà Bibeli ni pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ tọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́yìn láti ṣe ibi.”—Eksodu 23:2.

Bí ó bá jẹ́ pé alábàádòwòpọ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́ kì í ṣe Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ tí kì í sì í fi ìgbà gbogbo kọbiara sí ìlànà Bibeli ńkọ́. Yóò ha bójúmu láti lo èyí gẹ́gẹ́ bí àwáwí láti yẹ ẹrù-iṣẹ́ tìrẹ sílẹ̀ nígbà tí ó bá ṣe ohun kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu? Rántí àwọn àpẹẹrẹ Adamu àti Saulu. Dípò yíyẹra fún ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n juwọ́sílẹ̀ fún ìkìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn wọ́n sì wá di ẹ̀bi rẹ̀ ru àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn. Ẹ wo iye gíga tí wọ́n san!—Genesisi 3:12, 17-19; 1 Samueli 15:20-26.

Bá Àwọn Onígbàgbọ́ Ẹlẹgbẹ́ Rẹ Lò Lọ́nà Tí Ó Bójúmu

Àwọn ohun tí ń náni tí a níláti gbéyẹ̀wò ha wà nígbà tí a bá ń kówọ inú òwò pẹ̀lú ẹlẹ́gbẹ́ ẹni tí a jùmọ̀ ń jọ́sìn Jehofa bí? Nígbà tí wòlíì Jeremiah ra pápá kan ní ìlú rẹ̀ Anatoti lọ́wọ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun kò wulẹ̀ fún un ní owó náà kí ó sì bọ̀ ọ́ lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wí pé: “Mo sì kọ ọ́ sínú ìwé, mo sì dì í, mo sì pe àwọn ẹlẹ́rìí sí i, mo sì wọn owó náà nínú òṣùwọ̀n.” (Jeremiah 32:10) Ṣíṣe irú àdéhùn alákọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè dènà èdè-àìyedè tí ó lè dìde lẹ́yìn-ọ̀la bí àyíká ipò bá yípadà.

Ṣùgbọ́n kí ni bí Kristian arákùnrin kan bá dàbí ẹni pé ó hùwà sí ọ lọ́nà tí kò tọ́ nínú òwò? O ha níláti mú un lọ sí ilé-ẹjọ́ bí? Bibeli ṣe kedere lórí èyí. Paulu béèrè pé: “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni ninu yín tí ó ní ẹjọ́ lòdì sí ẹni kejì ha gbójúgbóyà lati lọ sí kóòtù níwájú awọn aláìṣòdodo ènìyàn, tí kì í sì í ṣe níwájú awọn ẹni mímọ́?” Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a kò yanjú ìṣòro kan lọ́nà tí ó tẹ́nilọ́rùn lójú-ẹsẹ̀ ńkọ́? Paulu fikún un pé: “Gbogbo-ẹ̀ gbògbò-ẹ̀ ó túmọ̀ sí ìpaláyò fún yín pé ẹ̀yin ń pe ara yín lẹ́jọ́ lẹ́nìkínní kejì. Èéṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a ṣe àìtọ́ sí ẹ̀yin fúnra yín? Èéṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a lu ẹ̀yin fúnra yín ní jìbìtì?” Ìwọ rò ó wò ná irú àbàwọ́n burúkú tí yóò kó bá ètò-àjọ Kristian bí àwọn ará-ìta bá gbọ́ tí àwọn Kristian tòótọ́ ń fi ìjà pẹẹ́ta ní kóòtù! Ó ha lè jẹ́ pé nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ìfẹ́ owó ti wá lágbára ju ìfẹ́ fún arákùnrin lọ bí? Tàbí ó ha lè jẹ́ pé a ti kó èérí bá ọlá ẹnì kan tí gbígbẹ̀san sì ti wá gba ipò àkọ́kọ́ nínú ọkàn rẹ̀ bí? Ìmọ̀ràn Paulu fi hàn pé nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ yóò sàn jù láti jìyà òfò ju láti lọ sí kóòtù lọ.—1 Korinti 6:1, 7; Romu 12:17-21.

Àmọ́ ṣáá o, ọ̀nà tí ó bà Ìwé Mímọ́ mu wà láti yanjú irú aáwọ̀ bẹ́ẹ̀ láàárín ìjọ. (Matteu 5:37; 18:15-17) Ní ríran àwọn arákùnrin tí ọ̀ràn náà kàn lọ́wọ́ láti tẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ tí a dámọ̀ràn, àwọn Kristian alábòójútó lè fún gbogbo àwọn tí ọ̀ràn kàn ní ìmọ̀ràn tí ó lè rannilọ́wọ́. Ó lè dàbí ohun tí ó rọrùn nígbà tí irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ bá ń lọ lọ́wọ́ láti fohùnsọ̀kan pẹ̀lú ìlànà Bibeli, ṣùgbọ́n lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ìwọ yóò ha fi hàn níti gidi pé o tẹ́tísílẹ̀ nípa fífi àwọn ìmọ̀ràn tí a fúnni sílò bí? Ìfẹ́ fún Ọlọrun àti fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa yóò sún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Láìsí iyèméjì, jíjẹ́ oníṣòwò yóò ná ọ ní ohun kan. Ìrètí wa ni pé, iye tí ó mọníwọ̀n ni ìwọ yóò san. Nígbà tí o bá dojúkọ ṣíṣe ìpinnu tàbí ipò èyíkéyìí tí ó lè gbé ìbéèrè dìde, fi í sọ́kàn pé àwọn ohun púpọ̀ wà nínú ìgbésí-ayé tí ó níyelórí fíìfíì ju owó lọ. Nípa fífi owó sí àyè rẹ̀, dídúró ti àdéhùn ẹni, jíjẹ́ aláìlábòsí, àti bíbá àwọn alábàádòwòpọ̀ lò lọ́nà ti Kristian, a lè rí i dájú pé òwò kan kò náni ní àkókò àti owó púpọ̀ síi ju bí ó ṣe yẹ lọ, tí ó sì tún jẹ́ pé a lè máa bá ọ̀rẹ́ wa nìṣó, kí a pa ẹ̀rí-ọkàn rere, àti ipò-ìbátan àtàtà mọ́ pẹ̀lú Jehofa.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àpẹẹrẹ òde-oní nípa dídúró ti ọ̀rọ̀ ẹni nínú òwò, wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Ọ̀rọ̀ Mi Ìdè Mi” nínú Ji! ti April 22, 1989, ojú-ìwé 14 sí 16.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn Ohun Tí Òwò Rẹ Lè Ná Ọ

Àkókò: Ṣíṣe òwò ara-ẹni sábà máa ń gba àkókò púpọ̀ ju ṣíṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ kan. Èyí yóò ha da ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ rú, tí yóò sì fi àkókò tí kò tó sílẹ̀ fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí tí ó ṣe pàtàkì bí? Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ìwọ yóò ha lè ṣètò àlámọ̀rí rẹ láti lo àkókò púpọ̀ síi ní ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn dára. Ṣùgbọ́n ṣọ́ra o! Èyí rọrùn láti sọ ju láti ṣe lọ.

Owó: Owó ni a fi ń peéná owó. Owó-ìdókòwò wo ni òwò rẹ ń fẹ́? Ó ha ti ní owó náà bí? Tàbí ìwọ ha níláti lọ yá a ni? Agbára rẹ ha lè gbé pípàdánù owó díẹ̀ bí? Tàbí ìnáwó náà yóò ha pọ̀ ju ohun tí agbára rẹ lè gbé lọ bí nǹkan kò bá lọ bí o ṣe retí?

Àwọn Ọ̀rẹ́: Nítorí àwọn ìṣòro tí ń dìde nínú iṣẹ́ ojoojúmọ́, ọ̀pọ̀ òwò àwọn olùṣekòkáárí òwò ti mú kí wọ́n pàdánù àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe láti ní àwọn ọ̀rẹ̀, ṣíṣeéṣe pé kí a ya ipò-ìbátan nípa jẹ́ gidi gan-an. Bí ó bá jẹ́ pé àwọn Kristian arákùnrin wa ni àwọn ọ̀rẹ́ wọ̀nyí ńkọ́?

Ẹ̀rí-Ọkàn Rere: Ọwọ́ tí gbogbogbòò fi ń mú òwò nínú ayé lónìí ni “Bó o ba o pa á, bó ò ba o bù ú lẹ́sẹ̀” tàbí “Báwo ni mo ṣe lè rí ìjẹ tèmi?” Iye tí ó lé ní ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwádìí kan tí a ṣe ní ilẹ̀ Europe sọ pé ètò-ìlànà-ìwàhíhù kò rí ọwọ́ mú nínú ọ̀ràn òwò. Abájọ tí jìbìtì, àbòsí, àti àwọn òwò tí ó lè gbé ìbéèrè dìde fi di ohun tí ó wọ́pọ̀. A óò ha dán ọ wò láti ṣe bí àwọn mìíràn ti ń ṣe bí?

Ipò-Ìbátan Rẹ Pẹ̀lú Jehofa: Ìgbésẹ̀ èyíkéyìí nínú òwò tí ó bá lòdì sí àwọn òfin àti ìlànà Ọlọrun, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wọ́pọ̀ nínú àlámọ̀rí òwò, yóò ba ipò-ìbátan ẹnì kan pẹ̀lú Olùṣẹ̀dá rẹ jẹ́. Èyí lè ná an ní ìfojúsọ́nà rẹ̀ fún ìyè ayérayé. Èyí kò ha ní jẹ́ iye tí ó ga jù fún Kristian adúróṣinṣin kan láti san bí, láìka ohun tí àǹfààní nípa ti ara náà lè jẹ́ sí?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Èwo ni yóò ṣèrànwọ́ láti dènà èdè-àìyedè ẹ̀yìnwá-ọ̀la? Ìfìbọra-ẹni-lọ́wọ́ ṣàdéhùn tàbí àdéhùn alákọsílẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́