ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 9/1 ojú ìwé 19-21
  • Ìwọ́ Ha Lè Mú Ìfòyemọ̀ Dàgbà Sí I Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ́ Ha Lè Mú Ìfòyemọ̀ Dàgbà Sí I Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àìní Ìfòyemọ̀ Israeli
  • Jíjèrè Ìfòyemọ̀ Tẹ̀mí
  • Ìfòyemọ̀ àti Òye-Inú
  • Jẹ́ Kí Ọkàn Àyà Rẹ Fà Sí Ìfòyemọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Jẹ́ Kí Ìfòyemọ̀ Dáàbò Bò ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • “Jèhófà Fúnra Rẹ̀ Ní Ń Fúnni Ní Ọgbọ́n”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ẹ Jẹ́ Onígboyà Kẹ́ Ẹ sì Máa Lo Ìfòyemọ̀ Bíi Ti Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 9/1 ojú ìwé 19-21

Ìwọ́ Ha Lè Mú Ìfòyemọ̀ Dàgbà Sí I Bí?

ÌFÒYEMỌ̀ jẹ́ “agbára tàbí ọgbọ́n èrò-inú nípasẹ̀ èyí tí ó ń fi ìyàtọ̀ hàn láàárín ohun kan àti òmíràn.” Ó tún lè jẹ́ “dídé orí èrò tí ó gbéṣẹ́” tàbí “agbára wíwòye àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín àwọn nǹkan tàbí èrò.” Bẹ́ẹ̀ ni ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Webster’s Universal Dictionary ṣe sọ. Ní kedere, ìfòyemọ̀ jẹ́ ànímọ́ kan tí a níláti ní ìfẹ́-ọkàn sí. Ìníyelórí rẹ̀ ni a rí nínú àwọn ọ̀rọ̀ Solomoni pé: “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọ inú ọkàn-àyà rẹ lọ tí ìmọ̀ fúnra rẹ̀ sì di ohun dídùn fún ọkàn rẹ gan-an, . . . ìfòyemọ̀ fúnra rẹ̀ yóò máa dáàbò bò ọ́, láti dá ọ nídè kúrò ní ọ̀nà búburú.—Owe 2:10-12, NW.

Bẹ́ẹ̀ ni, ìfòyemọ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kọ “ọ̀nà búburú,” tí ó pọ̀ yanturu lónìí. Ó sì tún ń mú ọ̀pọ̀ àǹfààní mìíràn wá. Fún àpẹẹrẹ, àwọn òbí sábà máa ń gbọ́ tí àwọn ọmọ wọn máa ń sọ pé, ‘Kò lè yé yín!’ Pẹ̀lú ìwádìí kékeré, àwọn òbí tí wọ́n ní ìfòyemọ̀ mọ bí àwọn yóò ṣe mú àwọn ọmọ wọn sọ ìmọ̀lára àti àwọn ohun tí ń dà wọ́n láàmú jáde. (Owe 20:5) Ọkọ kan tí ó ní ìfòyemọ̀ yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí aya rẹ̀ yóò sì ní òye-inú nípa èrò àti ìmọ̀lára rẹ̀ dípò kíkánjú dé ìparí-èrò. Aya yóò ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú fún ọkọ rẹ̀. Nípa báyìí, “nípa ọgbọ́n, agboolé kan ni a óò gbé ró, nípa ìfòyemọ̀ yóò sì fi ẹ̀rí ìfìdímúlẹ̀ gbọn-ín-gbọ́n-in hàn.”—Owe 24:3, NW.

Ìfòyemọ̀ ń ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti kápá àwọn àyíká ìpò kan pẹ̀lú àṣeyọrí. Owe 17:27 sọ pé: “Ẹni tí ó ní ìmọ̀, á ṣẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kù: ọlọ́kàn tútù sì ni amòye ènìyàn.” Ẹnì kan tí ó ní ìfòyemọ̀ kì í ṣe olórí gbígbóná, tí ń já lu gbogbo àyíká ipò láìronú. Ó ń fara balẹ̀ sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí àwọn ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àbájáde ṣáájú kí ó tó sọ pé òun ó ṣe ohun kan. (Luku 14:28, 29) Ó tún ń gbádùn ipò ìbátan aláfàáfíà púpọ̀ sí i pẹ̀lú àwọn mìíràn nítorí “ẹnu ọgbọ́n” ni ó sún un láti fara balẹ̀ ṣe àṣàyàn àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Owe 10:19; 12:8, NW) Ṣùgbọ́n, èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ẹnì kan tí ó ní ìfòyemọ̀ ń fi ìrẹ̀lẹ̀ mọ ibi tí ààlà rẹ̀ mọ, ó sì ń wo Ọlọrun fún ìtọ́sọ́nà kì í ṣe ènìyàn. Èyí dùn mọ́ Jehofa nínú, ó sì jẹ́ ìdí mìíràn fún mímú ìfòyemọ̀ dàgbà.—Owe 2:1-9; Jakọbu 4:6.

Àìní Ìfòyemọ̀ Israeli

Ewu kíkọ̀ láti lo ìfòyemọ̀ ni a rí nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìtàn Israeli ìgbàanì. Ní bíbojú wo ẹ̀yìn sí àsìkò náà, onipsalmu tí a mí sí náà sọ pé: “Iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé àwọn bàbá wa ní Egipti; wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ; ṣùgbọ́n wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi òkun, àní níbi Òkun Pupa.”—Orin Dafidi 106:7.

Nígbà tí Mose ṣáájú Israeli kúrò ní Egipti, Jehofa ti fi àgbára rẹ̀ àti ìmúratán rẹ̀ hàn láti sọ àwọn ènìyàn rẹ̀ dòmìnira nípa fífi ìyọnu mẹ́wàá bẹ alágbára ayé yẹn wò. Lẹ́yìn tí Farao ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Israeli lọ, Mose darí wọn lọ sí bèbè Òkun Pupa. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ ogun Egipti kó tì wọ́n ní lílépa wọn. Ó dàbí ẹni pé àwọn ọmọ Israeli ti wọ páńpẹ́ àti pé òmìnira wọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí kì yóò wà pẹ́. Nítorí náà, àkọsílẹ̀ Bibeli sọ pé: “Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi: àwọn ọmọ Israeli sì kígbe pe OLUWA.” Wọ́n sì kọjú sí Mose, ní sísọ pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀, láti mú wa jáde ti Egipti wá? . . . Ó sá sàn fún wa láti máa sin àwọn ará Egipti, jù kí àwa kú ní aginjù lọ.”—Eksodu 14:10-12.

Ìbẹ̀rù wọn lè dàbí ohun tí ó bọ́gbọ́n mu títí di ìgbà tí a bá tó rántí pé wọ́n ti rí àṣefihàn títayọ lọ́lá mẹ́wàá ní ti agbára Jehofa. Wọ́n fúnra wọn mọ ohun tí Mose yóò rán wọn létí rẹ̀ ní nǹkan bí 40 ọdún lẹ́yìn náà: “OLUWA . . . mú wa láti Egipti jáde wá pẹ̀lú ọwọ́ agbára, àti apá nínà, àti pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá, àti pẹ̀lú iṣẹ́-àmì, àti pẹ̀lú ìṣẹ́-ìyanu.” (Deuteronomi 26:8) Nípa báyìí, gẹ́gẹ́ bí onipsalmu náà ti kọ̀wé rẹ̀, nígbà tí àwọn ọmọ Israeli kọ ẹ̀yìn sí ìdarísọ́nà Mose, “wọn kò fi òye-inú kankan hàn.” (NW) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jehofa, ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, borí agbo ọmọ ogun Egipti pẹ̀lú ìyàlẹ́nu ńláǹlà.—Eksodu 14:19-31.

Lọ́nà tí ó jọra, ìgbàgbọ́ wa ni a lè tì síhìn-ín sọ́hùn-ún bí a bá ń ṣiyèméjì tàbí tí a kò dórí ìpinnu kan pàtó. Ìfòyemọ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye bí nǹkan ṣe yẹ kí ó rí gan-an ní gbogbo ìgbà, ní rírántí bí Jehofa ti ga ju ẹnikẹ́ni yòówù tí ó lè máa ṣàtakò sí wa lọ tó. Ìfòyemọ̀ yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti fi ohun tí Jehofa ti ṣe fún wa sọ́kàn. Yóò ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe gbàgbé òkodoro òtítọ́ náà láé pé òun ni Ẹni náà tí ń “dá gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ẹ sí.”—Orin Dafidi 145:18-20.

Jíjèrè Ìfòyemọ̀ Tẹ̀mí

Ìfòyemọ̀ kì í dédé wá pẹ̀lú ọjọ́-orí. A gbọ́dọ̀ mú un dàgbà. Ọlọgbọ́n Ọba Solomoni, tí a mọ̀ kárí-ayé nítorí ìfòyemọ̀ rẹ̀, sọ pé: “Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó wá ọgbọ́n rí, àti ọkùnrin náà tí ó gba òye. Nítorí tí owó rẹ̀ ju owó fàdákà lọ, èrè rẹ̀ sì ju ti wúrà dáradára lọ.” (Owe 3:13, 14) Ibo ni Solomoni ti rí ìfòyemọ̀ rẹ̀? Láti ọ̀dọ̀ Jehofa. Nígbà tí Jehofa béèrè ìbùkún tí Solomoni fẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, Solomoni dáhùn pé: “Kí ìwọ fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọkàn-àyà ìgbọràn láti ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ, láti fòye mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú.” (1 Awọn Ọba 3:9, NW) Bẹ́ẹ̀ ni, Solomoni yíjú sí Jehofa gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀. Ó béèrè fún ìfòyemọ̀, Jehofa sì fi fún un dé ìwọ̀n àyè tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? “Ọgbọ́n Solomoni sì borí ọgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ [Ìlà-Oòrùn], àti gbogbo ọgbọ́n Egipti.”—1 Awọn Ọba 4:30.

Ìrírí Solomoni fi ibi tí ó yẹ kí a lọ hàn wá nínú wíwá ìfòyemọ̀ kiri. Gẹ́gẹ́ bí Solomoni, a níláti yíjú sí ọ̀dọ̀ Jehofa. Báwo? Tóò, Jehofa ti pèsè Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, tí ó ń fún wa ní òye-inú sínú èrò rẹ̀. Nígbà tí a bá ń ka Bibeli, a ń walẹ̀ lọ sínú orísun ìmọ̀ tí ó ṣeyebíye tí yóò pèsè àwọn ìpìlẹ̀ fún ìfòyemọ̀ nípa tẹ̀mí. A níláti ṣàṣàrò lórí àwọn ìsọfúnni tí a bá kójọ láti inú Bibeli kíkà wa. Lẹ́yìn náà, a lè ló ó láti ṣe àwọn ìpinnu tí ó tọ́. Láìpẹ́, agbára ìwòye wa ni a óò mú dàgbà débi pé a óò “dàgbà di géńdé ninu agbára òye,” tí a fi lè “fi ìyàtọ̀ sáàárín [tàbí, fòye mọ ìyàtọ̀ láàárín] ohun tí ó tọ́ ati ohun tí kò tọ́.”—1 Korinti 14:20; Heberu 5:14; fiwé 1 Korinti 2:10.

Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni nínú, a ṣì lè jàǹfààní láti inú ìfòyemọ̀ tí Jehofa fún Solomoni. Báwo? Solomoni di ìjìmì nínú sísọ̀rọ̀ ọgbọ́n ní ọ̀nà òwe, èyí tí ó jẹ́ àkójọpọ̀ ọgbọ́n àtọ̀runwá tí a mí sí ní ti gàsíkíá. Ọ̀pọ̀ àwọn àṣàyàn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni a pamọ́ sínú iwé Owe nínú Bibeli. Kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé yẹn ń ràn wá lọ́wọ́ láti jàǹfààní láti inú ìfòyemọ̀ Solomoni kí a sì mú ìfòyemọ̀ dàgbà fúnra wa.

Láti ràn wá lọ́wọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wa, a lè lo àwọn ìrànlọ́wọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, irú bí ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! Fún èyí tí ó lé ní 116 ọdún, ni Ilé-Ìṣọ́nà ti ń kéde Ìjọba Jehofa fún àwọn aláìlábòsí-ọkàn. Ìwé ìròyìn Jí! àti àwọn èyí tí ó ṣáájú rẹ̀ ti ń sọ̀rọ̀ lórí ipò ayé bẹ̀rẹ̀ láti 1919 wá. Àwọn ìwé ìròyìn méjì wọ̀nyí ń yẹ àwọn òtítọ́ Bibeli wò, wọ́n sì ń pèsè ìlàlóye nípa tẹ̀mí lọ́nà tí ń tẹ̀ síwájú tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti fòye mọ àwọn àṣìṣe, bóyá tí Kristẹndọm ń fi kọ́ni tàbí tí a ń rí nínú ọ̀nà ìrònú wa.—Owe 4:18.

Ìrànlọ́wọ́ mìíràn nínú mímú ìfòyemọ̀ dàgbà ni ìkẹ́gbẹ́pọ̀ rere. Ọ̀kan lára àwọn òwe Ọba Solomoni sọ pé: “Ẹni tí ó ń bá ọlọgbọ́n rìn yóò gbọ́n; ṣùgbọ́n ẹ̀gbẹ́ àwọn aṣiwèrè ni yóò ṣègbé.” (Owe 13:20) Ohun ìtìjú ni ó jẹ́ pé Rehoboamu ọmọkùnrin Ọba Solomoni kò rántí òwe yìí ní apá pàtàkì ìgbésí-ayé rẹ̀. Lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀, àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá ti àríwá orílẹ̀-èdè Israeli wá bá a láti béèrè pé kí ó dín ẹrù-ìnira wọn kù. Lákọ̀ọ́kọ́, Rehoboamu fọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbà-àgbà, àwọn wọ̀nyí sì fi ìfòyemọ̀ hàn nígbà tí wọ́n fún un ní ìṣírí láti fetí sílẹ̀ sí àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin. Àwọn wọ̀nyí fi àìní ìrírí àti àìní ìfòyemọ̀ hàn, nípa fífún Rehoboamu ní ìṣírí láti halẹ̀ mọ àwọn ọmọ Israeli. Rehoboamu gbọ́ ti àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Israeli ṣọ̀tẹ̀, Rehoboamu sì pàdánù apá tí ó pọ nínú ìjọba rẹ̀.—1 Awọn Ọba 12:1-17.

Apá pàtàkì kan nínú mímú ìfòyemọ̀ dàgbà ni wíwá ìrànwọ́ ẹ̀mí mímọ́. Ní ṣíṣe àyẹ̀wò ìbálò Jehofa pẹ̀lú àwọn ọmọ Israeli lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ wọn ní oko-òǹdè ti Egipti, akọ̀wé Bibeli náà Nehemiah sọ pé: “Ẹ̀mí rere rẹ ni ìwọ fún wọn láti sọ wọ́n di olùmòyemèrò.” (Nehemiah 9:20, NW) Ẹmí Jehofa tún lè ṣèrànwọ́ láti sọ wá di olùmòyemèrò. Bí o ti ń gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ Jehofa láti fún ọ ní ìfòyemọ̀, fi ìgbọ́kànlé gbàdúrà nítorí pé Jehofa “a máa fifún gbogbo ènìyàn pẹlu ìwà-ọ̀làwọ́ ati láìsí gíganni.”—Jakọbu 1:5; Matteu 7:7-11; 21:22.

Ìfòyemọ̀ àti Òye-Inú

Aposteli Paulu fi ìfòyemọ̀ hàn nígbà tí ó ń wàásù òtítọ́ náà fún gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè. Fún àpẹẹrẹ, ní ìgbà kan, nígbà tí ó wà ní Ateni, ó ‘ń kọjá lọ ó sì ń fẹ̀sọ̀ kíyèsí’ àwọn ohun tí wọ́n ń júbà fún. Àwọn òrìṣà ni ó yí Paulu ká, ẹmí rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í bínú. Nísinsìnyí ó níláti ṣe ìpinnu kan. Ó ha níláti tẹ̀ lé ọ̀nà aláìléwu kí ó sì dákẹ́ bí? Àbí ó ha níláti kan ojú abẹ níkòó nípa ìbọ̀rìṣà tí ó rí gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra tí ó gbalé-gbòde, àní pàápàá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè léwu?

Paulu fi ìmòye hùwà. Ó ti tajú kán rí pẹpẹ kan tí ó ní àkọlé náà: “Sí Ọlọrun Àìmọ̀.” Pẹ̀lú ọgbọ́n, Paulu jẹ́wọ́ ìfọkànsìn wọn sí àwọn òrìṣà, ó sì lo pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti nasẹ̀ kókó ọ̀rọ̀ náà nípa “Ọlọrun naa tí ó ṣe ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jehofa ni Ọlọrun tí wọn kò mọ̀ nípa rẹ̀! Nípa báyìí Paulu ṣàkíyèsí ìmọ̀lára wọn lórí ọ̀ràn náà, ó sì ṣeé ṣe fún un láti fún wọn ní ìwàásù tí ó kàmàmà. Pẹ̀lú ìyọrísí wo ni? Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn, títí kan “Dionisiu, adájọ́ kan ní kóòtù Areopagu, ati obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Damari, ati awọn mìíràn ní àfikún sí wọn” tẹ́wọ́ gba òtítọ́. (Ìṣe 17:16-34) Ẹ wo irú àpẹẹrẹ tí Paulu jẹ́ ní ti ìfòyemọ̀!

Láìsí iyàn jíjà, ìfòyemọ̀ kì í wá pẹ̀lú ìrọ̀rùn tàbí lọ́nà àbínibí. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú sùúrù, àdúrà, ìsapá aláápọn, ìkẹ́gbẹ́pọ̀ ọlọ́gbọ́n, ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìṣàṣàrò lórí Bibeli, àti ìgbáralé ẹmí mímọ́ Jehofa, ìwọ̀ pẹ̀lú lè mú un dàgbà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́