“Máa Bá Ọ̀rọ̀ Rẹ Lọ!”
NÍLÙÚ Nezlobnaya, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ń kọ́ ẹ̀kọ́ lítíréṣọ̀ ní kíláàsì, àwọn ìwé tí òǹṣèwé ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mikhail Bulgakov kọ ni wọ́n sì ń lò. Ọ̀kan lára àwọn ìwé náà tó jẹ́ ìwé ìtàn àròsọ sọ ohun tí kò dára rárá nípa Jésù Kristi, àmọ́ ó pe Sátánì ní akọni. Lẹ́yìn tí ìjíròrò inú kíláàsì náà parí, olùkọ́ wọn tó jẹ́ obìnrin ṣe ìdánwò kan tó dá lórí ìwé náà fáwọn ọmọ kíláàsì náà. Àmọ́, ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tó ń jẹ́ Andrey, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún tó sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún olùkọ́ wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé òun kò ní lè ṣe ìdánwò náà nítorí pé ẹ̀rí ọkàn òun kò gba òun láyè láti kẹ́kọ̀ọ́ irú ìwé bẹ́ẹ̀. Ó ní kí olùkọ́ náà jẹ́ kóun kọ ọ̀rọ̀ nípa Jésù Kristi kóun lè sọ èrò òun nípa rẹ̀. Olùkọ́ náà sì gbà.
Nínú ohun tí Andrey kọ, ó ṣàlàyé pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun máa ń gba èrò àwọn mìíràn yẹ̀ wò, òun ti rí i pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti mọ̀ nípa Jésù ni pé kéèyàn ka ọ̀kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere inú Bíbélì. Ó ní bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, “wàá mọ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ báwọn tó fojú rí i ṣe kọ ọ́ sílẹ̀.” Andrey fi kún un pé: “Ìṣòro mìíràn tún ni irú ẹni tí ìwé yẹn sọ pé Sátánì jẹ́. Kíka ìwé tó pe Sátánì ní akọni lè múnú àwọn kan dùn, àmọ́ kò múnú mi dùn.” Ó ṣàlàyé pé ẹ̀dá ẹ̀mí tó burú gan-an ni Sátánì, pé ó yí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì lẹni tó ń fa ibi, ìpọ́njú àti ìnira bá gbogbo èèyàn. Andrey kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Mi ò gbà pé kíka ìwé ìtàn àròsọ yìí yóò ṣe mí láǹfààní. Kì í ṣe pé mo kórìíra Bulgakov o. Àmọ́ ní tèmi, Bíbélì ni màá kà láti mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa Jésù Kristi.”
Inú olùkọ́ Andrey dùn sí ohun tí Andrey kọ yìí débi pé, ó tún ní kó lọ kọ ọ̀rọ̀ mìíràn nípa Jésù Kristi kó sì wàá kà á fáwọn ọmọ Kíláàsì rẹ̀. Andrey sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, tí wọ́n tún ṣe ẹ̀kọ́ lítíréṣọ̀, Andrey ka ọ̀rọ̀ tó ti kó jọ náà níwájú gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀. Ó ṣàlàyé ìdí tóun fi gbà pé Jésù lẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ tó tíì gbé ayé rí. Lẹ́yìn náà, ó wá ka orí kan tó sọ nípa ikú Jésù nínú ìwé Mátíù tó wà nínú Bíbélì. Nítorí pé àkókò tí wọ́n fún Andrey láti ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti fẹ́ pé, ó fẹ́ parí rẹ̀ síbẹ̀, àmọ́ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ sọ fún un pé: “Máa Bá Ọ̀rọ̀ Rẹ Lọ! Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?” Ló bá ń ka àkọsílẹ̀ Mátíù nípa àjíǹde Jésù nìṣó.
Nígbà tí Andrey parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ béèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè nípa Jésù àti nípa Jèhófà lọ́wọ́ rẹ̀. Andrey sọ pé: “Mo ti gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún mi lọ́gbọ́n, ó sì dáhùn àdúrà mi. Gbogbo ìbéèrè wọn ni mo dáhùn!” Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe tán, Andrey fún olùkọ́ rẹ̀ ní ẹ̀dà kan ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí,a tayọ̀tayọ̀ ni olùkọ́ náà sì fi tẹ́wọ́ gbà á. Andrey sọ pé: “Máàkì tó fún mi nítorí ọ̀rọ̀ tí mo sọ yẹn pọ̀ gan-an, ó sì yìn mí pé ohun tí mo gbà gbọ́ dá mi lójú, mi ò sì jẹ́ kójú tì mí láti sọ ọ́. Ó tún sọ pé òun fara mọ́ díẹ̀ lára àwọn ohun tí mo gbà gbọ́ yẹn.”
Inú Andrey dùn gan-an pé òun tẹ̀ lé ohun tí ẹ̀rí ọkàn òun tóun ti fi Bíbélì kọ́ sọ nítoríi pé òun kò ka ìwé tó ń tàbùkù Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. Kì í ṣe pé ìpinnu yìí jẹ́ kó bọ́ lọ́wọ́ dídẹni tó ń ní èrò tó ta ko Ìwé Mímọ́ nìkan ni, ó tún jẹ́ kó ní àǹfààní ńlá láti sọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì gan-an nínú Bíbélì fún àwọn mìíràn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.