APÁ 8
Eré Ìtura
Báwo lo ṣe máa ń fàwọn nǹkan wọ̀nyí gbádùn ara ẹ tó: eré ìdárayá, orin, fíìmù, tẹlifíṣọ̀n àti eré orí kọ̀ǹpútà?
□ Bóyá ni
□ Ẹ̀ẹ̀kan lóòjọ́
□ Ìgbà díẹ̀ lóòjọ́
Ta ni tàbí kí ló máa ń nípa tó pọ̀ jù lọ lórí irú eré ìtura tó o yàn láàyò?
□ Àwọn ojúgbà ẹ
□ Dádì tàbí mọ́mì ẹ
□ Ìpolówó ọjà
Lóde òní, eré ìtura tíwọ àtàwọn ojúgbà ẹ lè yan èyí tẹ́ ẹ fẹ́ nínú ẹ̀ pọ̀ ju tàtijọ́ lọ. Àmọ́, àkókò tẹ́ ẹ ní láti fi ṣe àwọn eré ìtura náà ò tó nǹkan. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, irú eré ìtura tẹ́ ẹ bá yàn lè nípa lórí èrò àti ìwà yín. Torí náà, ìwọ̀n àkókò wo ló bójú mu pé kéèyàn fi máa ṣeré ìtura? Báwo lo sì ṣe lè pinnu irú eré ìtura tó o máa yàn? Orí 30 sí 33 nínú ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fojú pàtàkì wo irú eré ìtura tó o bá yàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 244, 245]