ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • od orí 13 ojú ìwé 130-140
  • “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run”
  • A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • BÁ A ṢE LÈ JẸ́ MÍMỌ́ LÓJÚ ỌLỌ́RUN KÁ SÌ MỌ́ NÍWÀ
  • ÌMỌ́TÓTÓ
  • ERÉ ÌTURA ÀTI ERÉ ÌNÀJÚ TÓ BÓJÚ MU
  • ILÉ ÌWÉ
  • IṢẸ́ OÚNJẸ ÒÒJỌ́ ÀTÀWỌN TẸ́ Ẹ JỌ Ń ṢIṢẸ́
  • ÀWA KRISTẸNI WÀ NÍṢỌ̀KAN
  • Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Mọ́ Tónítóní
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Eré Ìnàjú Tó Dára Tó Sì Ń tuni Lára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ṣé Eré Ìtura Tó O Yàn Máa Ṣe Ẹ́ Láǹfààní?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • “Ìwọ Ha Nífẹ̀ẹ́ Mi Ju Ìwọ̀nyí Lọ Bí?”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
od orí 13 ojú ìwé 130-140

ORÍ 13

“Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run”

ÌRÁNṢẸ́ Jèhófà ni wá, a sì ti ya ara wa sí mímọ́ fún un, torí náà gbogbo ohun tá à ń sọ àtèyí tá à ń ṣe ló yẹ kó máa fi ògo fún Jèhófà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa ní ìlànà tó máa tọ́ wa sọ́nà, ó ní: “Bóyá ẹ̀ ń jẹ tàbí ẹ̀ ń mu tàbí ẹ̀ ń ṣe ohunkóhun míì, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 10:31) Lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣe èyí ni pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà, àwọn ìlànà yìí ló sì ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́. (Kól. 3:10) A gbọ́dọ̀ máa fara wé Ọlọ́run torí pé èèyàn mímọ́ ni wá.​—Éfé. 5:1, 2.

2 Kókó yìí ni àpọ́sítélì Pétérù ń pe àfiyèsí àwọn Kristẹni sí nígbà tó sọ pé: “Bí ọmọ tó ń ṣègbọràn, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí tẹ́lẹ̀ torí àìmọ̀kan yín tún máa darí yín, àmọ́ bíi ti Ẹni Mímọ́ tó pè yín, kí ẹ̀yin náà di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín, nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, torí èmi jẹ́ mímọ́.’ ” (1 Pét. 1:14-16) Bí Jèhófà ṣe retí pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ jẹ́ mímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló retí pé káwa Kristẹni jẹ́ mímọ́. Ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ wà láìsí àbààwọ́n, ká má ṣe lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó lè mú wa dẹ́ṣẹ̀, ká má sì fara wé ayé. Èyí fi hàn pé Jèhófà yà wá sọ́tọ̀ ká lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún òun.​—Ẹ́kís. 20:5.

3 Tá a bá fẹ́ máa jẹ́ mímọ́, ó ṣe pàtàkì ká máa tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà, àwọn òfin àti ìlànà yìí sì wà nínú Ìwé Mímọ́. (2 Tím. 3:16) Ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́ ti jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà àti ọ̀nà tó máa ń gbà ṣe àwọn nǹkan, èyí sì ti mú ká sún mọ́ ọn. Ẹ̀kọ́ tá a kọ́ nínú Bíbélì mú ká gbà pé Ìjọba Ọlọ́run ló yẹ ká kọ́kọ́ máa wá, ó sì mú ká rí i pé ó yẹ ká máa fi gbogbo ayé wa ṣe ìfẹ́ Jèhófà. (Mát. 6:33; Róòmù 12:2) Èyí sì gba pé ká gbé ìwà tuntun wọ̀.​—Éfé. 4:22-24.

BÁ A ṢE LÈ JẸ́ MÍMỌ́ LÓJÚ ỌLỌ́RUN KÁ SÌ MỌ́ NÍWÀ

4 Gbogbo ìgbà kọ́ ló máa ń rọrùn láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. Sátánì Èṣù tó jẹ́ elénìní wa ń wá bó ṣe máa mú wa kẹ̀yìn sí òtítọ́. Ayé Èṣù yìí àti ara àìpé máa ń mú kí nǹkan nira fún wa nígbà míì. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ máa gbógun ti àwọn nǹkan yìí tá a bá fẹ́ máa ṣe ohun tó bá ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa mu. Ìwé Mímọ́ sọ pé ká má ṣe jẹ́ kó yà wá lẹ́nu tí àwọn èèyàn bá ta kò wá tàbí tí àdánwò bá dé bá wa. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé a máa jìyà nítorí òdodo. (2 Tím. 3:12) A ṣì lè láyọ̀ tá a bá wà nínú ìṣòro, torí a mọ̀ pé àwọn ìṣòro yẹn jẹ́ ẹ̀rí pé à ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.​—1 Pét. 3:14-16; 4:12, 14-16.

5 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, ó kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀. Jésù kò gbà kí Sátánì mú òun dẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ káwọn nǹkan ayé máa dá òun lọ́rùn. (Mát. 4:1-11; Jòh. 6:15) Jésù ò tiẹ̀ fìgbà kan rí ronú pé kí òun ṣe ohun tí kò tọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ayé kórìíra rẹ̀ nítorí pé ó ń hùwà òdodo, ó rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. Nígbà tí àkókò ikú rẹ̀ ń sún mọ́, ó kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ayé máa kórìíra àwọn náà. Látìgbà yẹn làwọn èèyàn ti ń pọ́n àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lójú, àmọ́ wọ́n lo ìgboyà torí wọ́n mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ti ṣẹ́gun ayé.​—Jòh. 15:19; 16:33; 17:16.

6 Tí a ò bá fẹ́ jẹ́ apá kan ayé, àfi ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà bíi ti Ọ̀gá wa. Yàtọ̀ sí pé a ò ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú àti rògbòdìyàn ìlú, a ò tún gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí àwọn ìwà ìbàjẹ́ tó kún ayé yìí. Ọwọ́ pàtàkì la fi mú ìmọ̀ràn tó wà nínú Jémíìsì 1:21, pé: “Ẹ mú gbogbo èérí àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìwà burúkú kúrò, kí ìwà tútù yín sì mú kí ọ̀rọ̀ tó lè gbà yín là fìdí múlẹ̀ nínú yín.” Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń lọ sípàdé, ‘ọ̀rọ̀ òtítọ́ á fìdí múlẹ̀’ lọ́kàn wa, á sì máa darí èrò wa, ìyẹn ò ní jẹ́ kí ọkàn wa fà sì àwọn nǹkan ayé. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jémíìsì sọ pé: “Ṣé ẹ ò mọ̀ pé bíbá ayé ṣọ̀rẹ́ ń sọni di ọ̀tá Ọlọ́run ni? Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” (Jém. 4:4) Abájọ tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú gan-an pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà ká má sì dà pọ̀ mọ́ ayé.

7 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe lọ́wọ́ nínú ìwà tó ń tini lójú àti ìṣekúṣe. Ó ní: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan ìṣekúṣe àti ìwà àìmọ́ èyíkéyìí tàbí ojúkòkòrò láàárín yín, bí ó ṣe yẹ àwọn èèyàn mímọ́.” (Éfé. 5:3) Nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba èròkerò, àwọn ohun tó ń tini lójú tàbí èyí tó ń tàbùkù ẹni, ó sì dájú pé a ò ní gbà kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ yọ́ wọnú ìjíròrò wa. Nípa bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà òdodo Jèhófà, àwọn ìlànà mímọ́ rẹ̀ yìí la sì ń tẹ̀ lé.

ÌMỌ́TÓTÓ

8 Àwa Kristẹni mọ̀ pé yàtọ̀ sí pé ká jẹ́ mímọ́ nínú ìjọsìn àti ìwà wa, ó tún yẹ ká máa mọ́ tónítóní. Ọlọ́run mímọ́ pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé àgọ́ wọn gbọ́dọ̀ máa wà ní mímọ́ tónítóní. Àwa náà gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní kí Jèhófà “má bàa rí ohunkóhun tí kò bójú mu” lọ́dọ̀ wa.​—Diu. 23:14.

9 Nínú Bíbélì, ìjẹ́mímọ́ àti ìmọ́tótó wọnú ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, . . . ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí, kí a jẹ́ mímọ́ pátápátá nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́r. 7:1) Nítorí náà, ó yẹ kí àwa Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa wẹ̀ déédéé ká sì máa fọ aṣọ wa, ká lè máa wà ní mímọ́ tónítóní. Lóòótọ́ ipò nǹkan lórílẹ̀-èdè kan lè yàtọ̀ sí ti ibòmíì, síbẹ̀ àá ṣì rí ọṣẹ àti omi tá a lè máa fi wẹ̀, tá a sì tún lè fi wẹ àwọn ọmọ wa.

10 Nítorí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe, àwọn èèyàn mọ̀ wá dáadáa ládùúgbò tá à ń gbé. Tá a bá ń jẹ́ kí ilé wa àti àyíká wa mọ́ tónítóní tó sì wà létòlétò, ìwàásù ló máa jẹ́ fáwọn aládùúgbò wa. Gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé ló sì yẹ kó máa kọ́wọ́ tì í. Ó yẹ kí àwọn arákùnrin máa múpò iwájú ní mímú kí ilé wọn àti àyíká wọn wà ní mímọ́ tónítóní ní gbogbo ìgbà, torí pé bí inú ilé àti àyíká ilé bá mọ́, àwọn èèyàn máa sọ ohun tó dáa nípa wa. Tí àwọn baálé ilé bá ń rí sí ìmọ́tótó ilé, tí wọ́n sì tún ń múpò iwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run, èyí á fi hàn pé wọ́n ń bójú tó ìdílé wọn dáadáa. (1 Tím. 3:4, 12) Àwọn arábìnrin pẹ̀lú ní àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n bójú tó, pàápàá nínú ilé. (Títù 2:4, 5) Tá a bá kọ́ àwọn ọmọ dáadáa, wọ́n á lè máa túnra ṣe, wọ́n á sì máa mú kí yàrá wọn wà ní mímọ́ tónítóní. Nípa báyìí, á mọ́ gbogbo ìdílé lára láti máa ṣe nǹkan lọ́nà tó máa bá ìmọ́tótó inú ayé tuntun mu, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.

11 Àwọn kan lára àwọn èèyàn Jèhófà òde òní ní ohun ìrìnnà tí wọ́n ń gbé lọ sípàdé. Láwọn agbègbè kan, iṣẹ́ ìwàásù ò ṣeé ṣe láìsí mọ́tò. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ọkọ̀ yẹn gbọ́dọ̀ máa wà ní mímọ́ tónítóní, kó sì máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Ó yẹ kí ilé wa àti ohun ìrìnnà wa máa fi hàn pé a jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn Jèhófà tó wà ní mímọ́. Ó yẹ kí báàgì òde ẹ̀rí wa àti Bíbélì wa náà dùn ún wò, kó sì buyì kún Jèhófà.

12 Ìlànà Ọlọ́run ló yẹ kó máa darí wa tá a bá ń yan irú aṣọ tá a máa wọ̀ àti bá a ṣe máa múra. A ò ní fẹ́ múra wúruwùru tàbí ká wọṣọ lọ́nà kan ṣá lọ síwájú gbajúmọ̀ èèyàn kan. Ǹjẹ́ kò yẹ ká ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ tá a bá ń ṣojú fún Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti lórí pèpéle? Tá a bá ṣe múra àti irú aṣọ tá a wọ̀ lè mú káwọn èèyàn fojú tí kò dáa wo ìjọsìn Jèhófà, ó sì lè mú kí wọ́n fojú tó dáa wò ó. Kò ní dáa rárá tá a bá múra lọ́nà tí kò bójú mu tàbí lọ́nà tí kò gba tàwọn ẹlòmíì rò. (Míkà 6:8; 1 Kọ́r. 10:31-33; 1 Tím. 2:9, 10) Torí náà, tá a bá ń múra àtilọ sóde ẹ̀rí tàbí àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká tàbí ti agbègbè, ẹ jẹ́ ká máa rántí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìmọ́tótó àti ìmúra tó bójú mu. Ká máa ní in lọ́kàn nígbà gbogbo pé a fẹ́ bọlá fún Jèhófà, a sì fẹ́ fògo fún un.

Ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá, a sì ti ya ara wa sí mímọ́ fún un, torí náà gbogbo ohun tá à ń sọ àtèyí tá à ń ṣe ló yẹ kó máa fi ògo fún Jèhófà

13 Ìlànà kan náà yìí la gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn tá a bá ń ṣèbẹ̀wò sí orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Ká rántí pé “Ilé Ọlọ́run” ni Bẹ́tẹ́lì túmọ̀ sí. Torí náà, ó yẹ kí ìmúra àti ìwà wa rí bí i pé a wà nípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

14 Kódà nígbà tá a bá ń gbafẹ́, ó yẹ ká kíyè sí irú aṣọ tá à ń wọ̀ àti bá a ṣe ń múra. Ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ aṣọ tí mo wọ̀ àti ìmúra mi lè mú kí ojú tì mí láti wàásù fáwọn èèyàn?’

ERÉ ÌTURA ÀTI ERÉ ÌNÀJÚ TÓ BÓJÚ MU

15 Gbogbo wa la mọ̀ pé ara ń fẹ́ ìsinmi, béèyàn bá sì ṣiṣẹ́ ó yẹ kó lásìkò ìgbádùn, kó lè ní ìlera tó jí pépé. Ìgbà kan wà tí Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ síbi tó dá, kí wọ́n lè “sinmi díẹ̀.” (Máàkù 6:31) Tá a bá sinmi, tá a ṣeré ìtura tàbí eré ìnàjú tó bójú mu, ìyẹn á mú kí ara tù wá dáadáa. Á jẹ́ kára wa túbọ̀ jí pépé ká lè máa bá iṣẹ́ wa lọ.

16 Onírúurú eré ìtura ló wà lóde òní, ìdí nìyẹn tó fi yẹ káwa Kristẹni ṣọ́ra tá a bá fẹ́ yan èyí tá a fẹ́ ṣe, ká jẹ́ kí ìlànà Ọlọ́run darí wa. Òótọ́ ni pé eré ìtura dáa, àmọ́ òun kọ́ ló ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé. Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ fún wa pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn èèyàn “á fẹ́ràn ìgbádùn dípò Ọlọ́run.” (2 Tím. 3:1, 4) Ọ̀pọ̀ ohun táwọn èèyàn ń pè ní eré ìtura àti eré ìnàjú lóde òní ni ò bójú mu fáwọn tó fẹ́ máa tẹ̀ lé ìlànà òdodo Jèhófà.

17 Àwọn Kristẹni tó wà láyé lẹ́yìn ikú Jésù kì í lọ sáwọn ibi ìkórajọ tí kò bójú mu tó kún inú ayé onífàájì tí wọ́n ń gbé nígbà náà lọ́hùn-ún. Ní pápá ìwòran àwọn ará Róòmù, eré ìnàjú tí àwọn èèyàn ti ń jẹ̀rora ni wọ́n fi máa ń dá àwọn èèyàn lára yá. Wọ́n kúndùn àwọn eré ìnàjú tó ní ìwà ipá nínú, èyí tí ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀ ti ń ṣàn, àtèyí tí wọ́n ti ń ṣèṣekúṣe, àmọ́ àwọn Kristẹni ìgbà yẹn kì í bá wọn wo ìwòkuwò bẹ́ẹ̀. Irú ìwà ìbàjẹ́ kan náà ló kún inú èyí tó pọ̀ jù lára eré ìnàjú táwọn èèyàn ń gbádùn lóde òní. A gbọ́dọ̀ “máa ṣọ́ra lójú méjèèjì” bá a ṣe ń rìn, ká yẹra pátápátá fáwọn eré ìnàjú tó ń sọni di oníwà ìbàjẹ́. (Éfé. 5:15, 16; Sm. 11:5) Kódà, ká tiẹ̀ ní eré ìnàjú ọ̀hún ò burú, irú àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ àtàwọn nǹkan míì tó wà níbẹ̀ lè mú kó léwu.​—1 Pét. 4:1-4.

18 Oríṣiríṣi eré ìtura àti eré ìnàjú tó bójú mu wà táwa Kristẹni lè ṣe. Ọ̀pọ̀ ló ti jàǹfààní torí pé wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ àtàwọn àbá tó wúlò tó wà nínú ìtẹ̀jáde wa.

19 Nígbà míì, ẹnì kan lè pe àwọn ìdílé Kristẹni mélòó kan sílé rẹ̀. Nígbà míì sì rèé, wọ́n lè pe àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin kan síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó tàbí sí irú àpèjẹ míì bẹ́ẹ̀. (Jòh. 2:2) Ó yẹ káwọn tó bá ṣètò ìkórajọ náà mọ̀ pé àwọn làwọn máa dáhùn fún ohun tó bá ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Gbogbo wa la mọ̀ pé ó yẹ ká túbọ̀ kíyè sára tí èrò bá ti pọ̀ jù níbi ìkórajọ kan. Nígbà tí ara tu àwọn kan níbi irú ìkórajọ bẹ́ẹ̀, wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwà tí kò yẹ Kristẹni, wọ́n ṣàṣejù nídìí oúnjẹ àti ọtí, wọ́n sì tún dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì tó burú jáì. Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, àwọn Kristẹni tó gbọ́n ti rí i pé ohun tó dáa jù ni pé kí àwọn má pe èrò tó pọ̀, káwọn má sì jẹ́ kí irú ìkórajọ bẹ́ẹ̀ pẹ́. Tí ọtí líle bá máa wà níbẹ̀, ó yẹ kó mọ níwọ̀nba. (Fílí. 4:5) Tá a bá ṣe gbogbo ohun tó yẹ ká ṣe láti rí i pé ìkórajọ wa jẹ́ èyí tó bójú mu, tó sì ń tuni lára nípa tẹ̀mí, a ò ní ka oúnjẹ àti ohun mímu sí bàbàrà.

20 Kò sóhun tó burú nínú ká kó àwọn èèyàn lẹ́nu jọ. (1 Pét. 4:9) Tá a bá ń pe àwọn ará wá sílé wa ká lè jọ jẹun tàbí ká jọ wá nǹkan panu, ká lè jọ najú tàbí ká jọ ṣeré, ká máa rántí pé àwọn kan wà tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán fún. (Lúùkù 14:12-14) Tá a bá wà lára àwọn tí wọ́n pè síbi àpèjẹ bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn tó wà nínú Máàkù 12:31 ló yẹ ká tẹ̀ lé. Ó sì dáa ká máa dúpẹ́ oore táwọn èèyàn ṣe fún wa.

21 Inú àwa Kristẹni máa ń dùn nítorí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run fún wa, inú wa sì máa ń dùn pé a lè ‘máa jẹ, ká máa mu, ká sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára wa.’ (Oníw. 3:12, 13) Tá a bá “ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run,” ọkàn ẹni tó pe àwọn èèyàn àtàwọn tó wá síbẹ̀ á balẹ̀ nígbàkigbà tí wọ́n bá rántí ìkórajọ náà, ara sì máa tu gbogbo wa torí a ti ṣohun tí Ọlọ́run fẹ́.

ILÉ ÌWÉ

22 Àwọn ọmọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kàwé tó mọ níwọ̀n, ó sì máa ń wúlò fún wọn. Ohun tó wà lọ́kàn wọn bí wọ́n ṣe ń lọ síléèwé ni pé kí wọ́n mọ̀ ọ́n kọ, kí wọ́n sì mọ̀ ọ́n kà. Àwọn iṣẹ́ míì tí wọ́n bá kọ́ níléèwé lè wúlò fún wọn bí wọ́n ṣe ń lé àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Lásìkò tí wọ́n fi ń lọ síléèwé, ó yẹ kí wọ́n ‘rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá,’ èyí gba pé kí wọ́n sapá láti fi ìjọsìn Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́.​—Oníw. 12:1.

23 Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́ tó ń lọ síléèwé, ṣọ́ra kó má di pé ò ń ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ Jèhófà. (2 Tím. 3:1, 2) Ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe láti yẹra fún ìwà àwọn èèyàn ayé torí Jèhófà ti fún wa láwọn ohun tó ń dáàbò bò wá. (Sm. 23:4; 91:1, 2) Torí náà, rí i pé ò ń lo àwọn ohun tí Jèhófà ti pèsè, káyé má bàa kéèràn ràn ẹ́.​—Sm. 23:5.

24 Ohun tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí máa ń ṣe kí wọ́n má bàa kẹ́gbẹ́ búburú ni pé wọn kì í lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò míì táwọn ọmọléèwé máa ń ṣe. Àwọn olùkọ́ àtàwọn ọmọ kíláàsì rẹ lè má fi bẹ́ẹ̀ lóye ìdí tí o kò fi dara pọ̀ mọ́ wọn. Àmọ́, bó o ṣe máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù. Tó o bá sì fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, á dáa kó o jẹ́ kí ìlànà Ìwé Mímọ́ darí ẹ̀rí ọkàn rẹ kó o sì pinnu pé o ò ní lọ́wọ́ nínú ìdíje, o ò sì ní wà lára àwọn tó ń gbé orílẹ̀-èdè wọn lárugẹ. (Gál. 5:19, 26) Tí ẹ̀yin ọ̀dọ́ bá ń fetí sí ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ táwọn òbí yín fi ń kọ́ yín, tẹ́ ẹ sì ń bá àwọn ará nínú ìjọ kẹ́gbẹ́, á rọrùn fún yín láti máa tẹ̀ lé ìlànà òdodo Jèhófà.

IṢẸ́ OÚNJẸ ÒÒJỌ́ ÀTÀWỌN TẸ́ Ẹ JỌ Ń ṢIṢẸ́

25 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ojúṣe àwọn olórí ìdílé ni láti máa bójú tó ìdílé wọn. (1 Tím. 5:8) Síbẹ̀, torí pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n, wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ló ṣe pàtàkì jù, bí kò ṣe ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 6:33; Róòmù 11:13) Bí wọ́n ṣe ń fọkàn sin Ọlọ́run, tí wọ́n jẹ́ kí oúnjẹ àti aṣọ tí wọ́n ní tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn ò ní máa ṣàníyàn, wọn ò sì ní kó sínú ìdẹwò kíkó ohun ìní jọ.​—1 Tím. 6:6-10.

26 Ó yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni tá à ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ máa fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sọ́kàn. Tá a bá fẹ́ máa fòótọ́ inú wá jíjẹ mímu àtàwọn nǹkan míì, a ò ní máa lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó ta ko òfin Ọlọ́run tàbí òfin ìjọba. (Róòmù 13:1, 2; 1 Kọ́r. 6:9, 10) Ká máa rántí pé ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́. Torí pé ọmọ ogun Kristi ni wá, a kì í lọ́wọ́ nínú òwò tàbí iṣẹ́ tó lè mú wa rú òfin Ọlọ́run, tó lè mú wa dá sí ọ̀rọ̀ ogun àti òṣèlú tàbí tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. (Àìsá. 2:4; 2 Tím. 2:4) A kì í sì í dòwò pọ̀ pẹ̀lú ìsìn tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run, ìyẹn “Bábílónì Ńlá.”​—Ìfi. 18:2, 4; 2 Kọ́r. 6:14-17.

27 Tá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà òdodo Ọlọ́run, a ò ní máa polówó ọjà, iṣẹ́ wa tàbí àwọn nǹkan míì láwọn ibi tá a ti ń jọ́sìn Jèhófà. Ìdí pàtàkì tá a fi ń pé jọ láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti ti agbègbè ni pé ká lè jọ́sìn Jèhófà. À ń kóra jọ ká lè kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì “jọ fún ara wa ní ìṣírí.” (Róòmù 1:11, 12; Héb. 10:24, 25) Ká rí i pé àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn nìkan là ń ṣe làwọn ìpàdé náà.

ÀWA KRISTẸNI WÀ NÍṢỌ̀KAN

28 Ìlànà òdodo Jèhófà tún jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa “pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.” (Éfé. 4:1-3) Dípò ká máa tẹ́ ara wa nìkan lọ́rùn, ohun tó máa ṣe àwọn ẹlòmíì láǹfààní ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ń ṣe. (1 Tẹs. 5:15) Ó dájú pé báwọn ará ṣe ń ṣe nínú ìjọ yín náà nìyẹn. Ìlànà òdodo kan náà ni gbogbo wa ń tẹ̀ lé láìka ẹ̀yà tá a jẹ́, orílẹ̀-èdè wa, ipò wa láwùjọ, bá a ṣe rí já jẹ tó tàbí bá a ṣe kàwé tó sí. Kódà àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ti kíyè sí pé ìṣọ̀kan àwa èèyàn Jèhófà ṣàrà ọ̀tọ̀.​—1 Pét. 2:12.

29 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún tẹnu mọ́ ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa wà níṣọ̀kan nígbà tó sọ pé: “Ara kan ló wà àti ẹ̀mí kan, bó ṣe jẹ́ pé ìrètí kan ṣoṣo la pè yín sí; Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìbatisí kan; Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo èèyàn, tó wà lórí ohun gbogbo, tó ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ohun gbogbo àti nínú ohun gbogbo.” (Éfé. 4:4-6) Èyí gba pé ká jọ gba ohun kan náà gbọ́, tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ inú Bíbélì, títí kan àwọn ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀, torí pé a gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ wa. Ká sòótọ́, Jèhófà ti fún àwa èèyàn rẹ̀ ní èdè mímọ́ ti òtítọ́, èyí sì ń jẹ́ ká lè máa sin Jèhófà níṣọ̀kan.​—Sef. 3:9.

30 Ara tu gbogbo àwa tá à ń sin Jèhófà torí pé àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ Kristẹni. Ìlérí tí Jèhófà ṣe ti ṣẹ sí wa lára pé: “Màá mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan, bí àgùntàn ní ilé ẹran.” (Míkà 2:12) Ó yẹ ká máa fi àwọn ìlànà òdodo Jèhófà ṣèwàhù kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ààrín wa lè máa gbilẹ̀ sí i.

31 A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà pè wá sínú ìjọ rẹ̀ mímọ́! Ohun yòówù ká yááfì torí ká lè jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bá a ṣe ń mú kí àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ dán mọ́rán, àá máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo rẹ̀, àá sì máa rọ àwọn míì láti ṣe bẹ́ẹ̀.​—2 Kọ́r. 3:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́