ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/95 ojú ìwé 5-6
  • Fi Tọkàntọkàn Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Tọkàntọkàn Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
km 9/95 ojú ìwé 5-6

Fi Tọkàntọkàn Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá

1 Jíjẹ́ ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń jẹyọ láti inú níní ìmọrírì tí ó jinlẹ̀ fún Jehofa àti gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún wa. (2 Sam. 22:2, 3) Kíkáàánú lórí ipò tí aráyé tí a sọ di àjèjì sí Ọlọrun wà, yẹ kí ó sún wa láti lo gbogbo okun wa nínú iṣẹ́ ìsìn náà. (Matt. 9:36; 2 Kor. 5:14, 15) Bí a bá ṣe yara wa sọ́tọ̀ pátápátá fún Jehofa tó, àti bí a bá ṣe ń ṣàníyàn tó nípa àwọn ènìyàn, bẹ́ẹ̀ náà ni a óò máa sún wa tó láti fi tìtaratìtara ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. (Matt. 22:27-39) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yóò wá di ìṣúra tí kò ṣeé díyelé. (2 Kor. 4:7) Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè mú irú ìmọrírì fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ bẹ́ẹ̀ dàgbà?

2 Àwọn Kọ́kọ́rọ́ fún Mímú Ìmọrírì Dàgbà: Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ìjọ, ní àfikún sí àṣàrò tí a fi tàdúràtàdúrà ṣe, ń ṣèrànwọ́ fún wa láti mú ipò ìbátan ti ara ẹni pẹ̀lú Jehofa dàgbà. A bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ẹwà àwọn ànímọ́ àti ìwà rẹ̀, a sì wá mú ìmọrírì àtọkànwá dàgbà fún adùn ẹwà Ọlọrun wa onínúure àti àwọn ìṣètò rẹ̀ fún ìjọsìn tòótọ́. (Orin Da. 27:4) Nígbà tí a bá kọ́ nípa ẹwà ìyìn ológo Jehofa àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀, a ń sún wa láti polongo ìtóbilọ́lá rẹ̀, a sì ń fi taápọntaápọn wá àwọn ọ̀nà láti gbà tan ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kálẹ̀. (Orin Da. 145:5-7; Luku 6:45) Síwájú sí i, ṣíṣàgbéyẹ̀wò pẹ́kípẹ́kí àti ríronú nípa àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun tí wọ́n fi tọkàntọkàn sìn, lè mú ìmọrírì wa lágbára sí i. Jeremiah, Jesu, àti aposteli Paulu wà lára wọn.—Jer. 20:9; Joh. 4:34; 1 Tim. 1:12, 13, 17.

3 Ìmúrasílẹ̀ Máa Ń Ru Ìtara Ọkàn Sókè: Iṣẹ́ ìsìn tọkàntọkàn wa ń béèrè fún mímú ìtara ọkàn dàgbà. Ìmúrasílẹ̀ ṣe kókó láti lè ṣe èyí. Èyí jẹ́ nítorí pé ìmúrasílẹ̀ máa ń ru ìtara ọkàn sókè. Ó rọrùn láti nítara nínú ìgbòkègbodò kan tí a gbádùn, lọ́pọ̀ ìgbà, ènìyàn máa ń gbádùn ṣíṣe ohun kan tí ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀. Báwo, nígbà náà, ni a ṣe lè múra sílẹ̀ dáradára láti baà lè mú ìtara ọkàn dàgbà fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí a baà lè di òṣìṣẹ́ tí ó jáfáfá, kí a sì ká ìtẹ́lọ́rùn onídùnnú?—Joh. 2:17.

4 Ó máa ń ṣàǹfààní láti lo àkókò díẹ̀ ní wíwá àwọn kókó ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ kan pàtó nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò gbé jáde lákànṣe. Ẹ ní àwọn àkókò ìdánrawò. Ṣíṣe èyí papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan lè ṣèrànwọ́. Ìwé Reasoning jẹ́ irin iṣẹ́ ṣíṣeyebíye kan ní mímúra sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Fún àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan tí a bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé bá fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí Musulumi, kí ni a lè sọ? Akéde kan tí ó ti múra sílẹ̀ dáradára lè sọ pé: “Ìyẹn dára. Mo ti ka ohun kan nípa díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn yín nínú ìwé ọwọ́ mi yìí. [Ṣí ìwé Reasoning sí ojú ìwé 23.] Ó sọ pé ẹ gbàgbọ́ pé Jesu jẹ́ wòlíì kan, ṣùgbọ́n pé Muhammadu ni wòlíì tí ó kẹ́yìn, tí ó sì ṣe pàtàkì jù lọ. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] O ha gbàgbọ́ pẹ̀lú pé Mose jẹ́ wòlíì òtítọ́? [Jẹ́ kí ó fèsì, bóyá ní dídáhùn bẹ́ẹ̀ ni.] Mo ha lè fi ohun tí Mose kọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nípa orúkọ Rẹ̀ hàn ọ́ nínú àwọn Àkọsílẹ̀ Mímọ́ bí?” Lẹ́yìn náà, o lè ka Eksodu 6:3. O lè bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ alárinrin lọ́nà yìí.

5 Pẹ̀lú ìmúrasílẹ̀ àti ìdánrawò díẹ̀, a lè lo apá ti a pè ní “Conversation Stoppers” (Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí Ń Bẹ́gi Dínà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀), tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé Reasoning, láti ràn wá lọ́wọ́ láti róhun fèsì fún àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí onísìn kan.

6 Ìwé Reasoning tún ní ẹ̀ka tí ó dára kan lórí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀. A lè fẹ́ láti mú ìgbékalẹ̀ wa bá ipò náà mu. Ẹ̀ka kan wà, “If Somebody Says” (Bí Ẹnì Kan Bá Sọ Pé), ní òpin ọ̀pọ̀ lára àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé Reasoning, tí ó pèsè àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó ṣe tààràtà ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tàbí àtakò pàtó kan, tí ó tan mọ́ kókó ẹ̀kọ́ náà. Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo àkójọpọ̀ àtàtà yìí ṣeyebíye, kìkì dé ìwọ̀n tí a bá lò ó dé nínú ìmúrasílẹ̀ wa.

7 Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Tẹ̀ Síwájú: Jíjẹ́ ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá wa ń béèrè pé kí a fi kún ìtẹ̀síwájú àwọn ẹlòmíràn. A lè ṣe èyí nípa fífún àwọn ẹlòmíràn ní ìrànlọ́wọ́ àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n nílò. Ìbátan tí ó wà láàárín arákùnrin tí ó dàgbà náà, Paulu, àti ọ̀dọ́ olùfọkànsìn náà, Timoteu, pèsè àpẹẹrẹ àtàtà ti dídánilẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ ìsìn. (1 Kor. 4:17; 2 Tim. 2:1) Nínú ìjọ lónìí, àìní fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ túbọ̀ ń ṣe kedere sí i, nígbà tí a bá mọ̀ pé àwọn akéde, tí wọ́n fi nǹkan bí 40,000 lé sí i ju ti ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, ni wọ́n wà ní Nigeria nísinsìnyí. Ó ṣeé ṣe dáradára pé èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn wọ̀nyí ni yóò jàǹfààní láti inú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn akéde onírìírí bá lè fi fúnni. Arábìnrin kan, tí ń lo wákàtí kan tàbí méjì lóṣù nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, kọ́ láti sọ̀rọ̀ lọ́nà jíjá geerege ní ẹnu ọ̀nà, nígbà tí akéde onírìírí kan ràn án lọ́wọ́. Ìlọ́tìkọ̀ rẹ̀ àtijọ́ láti ṣàjọpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pòórá, ó sì di akéde ìhìnrere onítara. Nísinsìnyí, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ògbóṣáṣá kan, ó ronú padà sẹ́yìn, ó sì sọ pé: “Ohun kan ṣoṣo tí mo nílò ni kí a kọ́ mi ní ohun tí n óò sọ, àti láti ìgbà náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.”

8 Bí ìwọ bá jẹ́ alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, aṣáájú ọ̀nà, tàbí akéde onírìírí kan, báwo ni ìwọ ṣe lè fi kún ìtẹ̀síwájú àwọn ẹlòmíràn? Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ yóò jẹ́ láti fi tó olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ létí pé ìwọ yóò fẹ́ láti ṣèrànlọ́wọ́ fún akéde mìíràn. Ṣùgbọ́n ìwọ gbọ́dọ̀ wà létòlétò, kí o sì múra sílẹ̀. Ẹ ṣètò àkókò kan pàtó láti jọ ṣiṣẹ́ papọ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ lè máa ṣojo tàbí kí ó máà dá ara rẹ̀ lójú, ṣùgbọ́n òun yóò mọrírì pé ẹnì kan tí ó lè ran òun lọ́wọ́, nígbà tí àìní bá dìde, ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òun.—Oniwasu 4:9.

9 Bí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń tẹ̀ síwájú, jíròrò pẹ̀lú akéde tí kò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí náà nípa bí a ti ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí ó fìfẹ́ hàn. Èyí ní fífi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ nígbà ìkésíni àkọ́kọ́ nípa fífi onílé náà sílẹ̀ pẹ̀lú ìbéèrè kan tí ìwọ yóò dáhùn nígbà tí o bá padà lọ nínú. Rí i dájú pé o ran akéde tí kò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí náà lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀, kí o sì tẹ̀ lé e lọ ṣe ìkésíni náà lẹ́yìn náà. Bí ó bá yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́, tí òye akéde náà kò sì tí ì dá a lójú tó, akéde tí ó túbọ̀ nírìírí lè fẹ́ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fún àwọn ìgbà díẹ̀, títí tí akéde titun náà yóò fi tóótun láti máa bá a lọ.

10 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àti Góńgó: Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kì í ṣe iṣẹ́ kan lásánlàsàn tàbí ti àkọsẹ̀bá nínú ìgbésí ayé wa. Láti lè ṣètò iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ́nà tí ó gbéṣẹ́, a gbọ́dọ̀ ya àkókò sọ́tọ̀ fún onírúurú ẹ̀ka rẹ̀, kí a má sì fi ọ̀ràn náà sílẹ̀ bẹ́ẹ̀. (Efe. 5:15, 16) Ó máa ń ṣèrànwọ́ láti gbé góńgó wákàtí tí o máa lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní oṣù kọ̀ọ̀kan kalẹ̀. Èyí yóò béèrè pé kí o ṣètò àwọn àlámọ̀rí rẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìṣètò ìwéwèé kan. Àwọn òbí Kristian ní láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ṣètò àkókò fún kíkópa nínú onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá déédéé.—Deut. 6:7: Owe 22:6.

11 Fún àpẹẹrẹ, o ha ní ìpèsè àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tí ó pọ̀ tó bí? O ha máa ń ní ìpèsè àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́, wọ́n ha sì bójú mu bí? O ha máa ń lo àkọsílẹ̀ ilé dé ilé dáradára, ní lílo ọ̀kan láti ṣàkọsílẹ̀ orúkọ àwọn tí wọ́n fi ìfẹ́ hàn àti òmíràn láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn wọnnì tí kò sí nílé?

12 Ó Ń Béèrè Ìsapá Ara Ẹni: Bí ẹ ṣe ń gbádùn àwọn àǹfààní tí Ọlọrun ń fi fúnni tó ń sinmi púpọ̀púpọ̀ lórí ìsapá yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti ṣe ìfẹ́ Ọlọrun. Ní ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, Paulu kọ̀wé pé: “Ẹni kọ̀ọ̀kan yoo gba èrè-ẹ̀san tirẹ̀ ní ìbámu pẹlu òpò tirẹ̀.” (1 Kor. 3:8, NW) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ní ìpín kíkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà bí agbára wa bá ti tó. Aposteli Paulu ní èrè-ẹ̀san ara ẹni ti ríran ọ̀pọ̀ ènìyàn, àní gbogbo ìjọ pàápàá, lọ́wọ́ láti wá mọ Ọlọrun. Ẹ wo irú ìdùnnú tí òun nímọ̀lára rẹ̀ ní wíwo ìdúróṣinṣin wọn nínú ìgbàgbọ́! (1 Tessa. 2:19, 20) Ó ṣeé ṣe kí ipò rẹ má yọ̀ǹda fún ọ láti fi ara rẹ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bíi ti Paulu. Síbẹ̀, kò ha ní jẹ́ ìbùkún jìngbìnnì láti ran ẹnì kan, tàbí ìdílé àwọn ẹni bí àgùtàn pàápàá, lọ́wọ́ láti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin ní ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè? Ẹ wo irú ìsúnniṣe tí èyí jẹ́ láti ṣiṣẹ́ kára nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé, kí a sì fi ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kín in lẹ́yìn!

13 Àwọn Àǹfààní Síwájú Sí I: Àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tọkàntọkàn kan tí a kò lè díye lé ni pé, gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ kan, ẹnì kan túbọ̀ ń sún mọ́ Jehofa àti Jesu Kristi pẹ́kípẹ́kí sí i. (Matt. 11:29, 30: 1 Kor. 3:9) Wo irú ìdùnnú tí ó jẹ́ láti nímọ̀lára pé ẹ̀mí Ọlọrun ń ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà! (Matt. 10:20; Joh. 14:26) Síwájú sí i, fífi taápọntaápọn ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ, ń mú kí ìsopọ̀ ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan wa túbọ̀ lágbára sí i.

14 A kò lè gbádùn àwọn àǹfààní kíkún láti ọ̀dọ̀ Jehofa láìjẹ́ pé a fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú ètò àjọ tí òun ń lò láti ṣàṣeparí ìfẹ́ inú rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. (Fi wé 2 Àwọn Ọba 10:15.) Nígbà tí a bá fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé ìtọ́ni tí a ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ aṣojú tí Ọlọrun ń lò, tí a tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí, tí a sì fi ara wa fún àwọn ìgbòkègbodò ìjọ, a ń dáàbò bo wá nípa tẹ̀mí lọ́wọ́ àwọn àrékérekè Satani. A ń mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti ní ìpín tí ó túbọ̀ ń mú èso jáde sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.

15 Jehofa ń fẹ́ kí a ṣe ara wa ní àǹfààní nípa ṣíṣègbọràn sí òun. (Isa. 48:17) Síwájú sí i, àwọn ìbùkún iṣẹ́ ìsìn tí a ṣe tọkàntọkàn gbòòrò dé ọ̀dọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n ń fetí sílẹ̀ sí wa. (1 Tim. 4:15, 16) Jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé, bí o ti ń fi taápọntaápọn fi ara rẹ fún iṣẹ́ tí ó wà lọ́wọ́, Jehofa ń ṣàkíyèsí èyí, ìwọ yóò sì “gba èrè-ẹ̀san yíyẹ ti ogún naa,” ìyè àìnípẹ̀kun.—Kol. 3:23, 24, NW.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́