Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
1 “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) Ẹ̀yin òbí, bí ẹ kò bá fẹ́ kí àwọn ọmọ yín “yà kúrò nínú” ọ̀nà òtítọ́, ìgbà wo ló yẹ kí ẹ bẹ̀rẹ̀ irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀? Ní kùtùkùtù ìgbésí ayé wọn ní!
2 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé “láti ìgbà ọmọdé jòjòló” ni Tímótì ti bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìmọ̀ tẹ̀mí, ó ṣe kedere pé láti ìgbà ọmọ ọwọ́ ló ní lọ́kàn. (2 Tím. 3:14, 15) Àbáyọrí èyí ni pé, Tímótì dàgbà di ẹni tẹ̀mí tó tayọ lọ́lá. (Fílí. 2:19-22) Ẹ̀yin òbí, “láti ìgbà ọmọdé jòjòló” ló yẹ kí ẹ̀yin náà ti bẹ̀rẹ̀ kí ẹ lè fún àwọn ọmọ yín ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n nílò láti lè ‘dàgbà síhà ọ̀dọ̀ Jèhófà.’—1 Sám. 2:21.
3 Pèsè Omi Tí Wọ́n Nílò Láti Dàgbà: Bí àwọn igi kéékèèké ṣe nílò ìpèsè omi déédéé láti dàgbà di igi tó gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, bákan náà ló ṣe yẹ ká máa bomi òtítọ́ Bíbélì rin àwọn ọmọdé, láìka ọjọ́ orí wọn sí, kí wọ́n lè dàgbà di ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó dàgbà dénú. Ọ̀nà tó dára jù láti kọ́ àwọn ọmọ ní òtítọ́ ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́ ni nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé tí a ń ṣe déédéé. Ṣùgbọ́n, kí ẹ̀yin òbí mọ̀ pé ó ní bí àkókò tí ọmọ kọ̀ọ̀kan fi lè pọkàn pọ̀ ṣe gùn mọ. Bó bá jẹ́ àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, fífún wọn ní ìtọ́ni láàárín àkókò kúkúrú, àmọ́ tó jẹ́ lóòrèkóòrè yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ gbéṣẹ́ ju lílo àkókò tó gùn jàn-ànràn jan-anran lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.—Diu. 11:18, 19.
4 Má ṣe fojú kéré agbára tí àwọn ọmọ rẹ ní láti kẹ́kọ̀ọ́ láé. Sọ ìtàn àwọn èèyàn inú Bíbélì fún wọn. Jẹ́ kí wọ́n ya àwọn àwòrán nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì tàbí kí wọ́n fi wọ́n ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́. Lo àwọn fídíò àti kásẹ́ẹ̀tì àfetígbọ́ wa dáadáa, títí kan àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé bá ọjọ́ orí àti agbára tí àwọn ọmọ rẹ ní láti kẹ́kọ̀ọ́ mu. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbọ́dọ̀ rọrùn kó sì jẹ́ níwọ̀nba; ṣùgbọ́n bí ọmọ kan bá ṣe ń dàgbà, ó yẹ kí ìdálẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ máa gbòòrò sí i kó sì máa tẹ̀ síwájú. Jẹ́ kí ìtọ́ni Bíbélì tani jí kó sì jẹ́ ní onírúurú. Bí o bá fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ “ní ìyánhànhàn” fún Ọ̀rọ̀ náà, àfi kó o jẹ́ kó lárinrin bó o bá ti lè ṣe é tó.—1 Pét. 2:2.
5 Jẹ́ Kí Wọ́n Máa Kópa Nínú Àwọn Ìgbòkègbodò Ìjọ: Gbé àwọn ohun tí àwọn ọmọ rẹ á máa lépa síwájú wọn kí wọ́n lè kópa kíkún nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ. Kí ló lè jẹ́ ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n á máa lépa? Àwọn òbí kan tí wọ́n ní àwọn ọmọ kékeré méjì sọ pé: “Àwọn ọmọ méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti máa jókòó jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.” Lẹ́yìn náà, ràn àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti dáhùn lọ́rọ̀ ara wọn láwọn ìpàdé, kí o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa lépa àtiforúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, àwọn ohun tó dára tí wọ́n lè máa lépa ni fífi ìwé àṣàrò kúkúrú lọni lẹ́nu ọ̀nà, kíka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, fífi ìwé ìròyìn lọni, àti jíjíròrò pẹ̀lú àwọn onílé lọ́nà tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn.
6 Fi Àpẹẹrẹ Onítara Lélẹ̀: Ṣé àwọn ọmọ rẹ máa ń gbọ́ kí o máa sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, kí o sì máa gbàdúrà sí i lójoojúmọ́? Ṣé wọ́n ń rí i pé o máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, o máa ń lọ sí ìpàdé, o máa ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá tí o sì máa ń ní ìdùnnú nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run? (Sm. 40:8) Ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n rí i pé ò ń ṣe bẹ́ẹ̀ kí ẹ sì jọ máa ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí pa pọ̀. Ọmọbìnrin kan tó ti dàgbà sọ nípa ìyá rẹ̀, ẹni tó ti tọ́ ọmọ mẹ́fà dàgbà láti di Ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ pé: “Ohun tí ó wú wa lórí jù lọ ni àpẹẹrẹ Màmá fúnra rẹ̀—ó gbéṣẹ́ ju ọ̀rọ̀ ẹnu lọ.” Òbí ọlọ́mọ mẹ́rin kan sọ pé: “‘Jèhófà ní àkọ́kọ́’ kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe gbólóhùn ṣákálá, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé wa.”
7 Ẹ̀yin òbí, ẹ tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ ní kùtùkùtù ìgbésí ayé wọn, kí ẹ kọ́ wọn ní òtítọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ẹ jẹ́ kí wọ́n ní ohun tí wọ́n á máa lépa, kí ẹ sì pèsè àpẹẹrẹ tó dára jù lọ fún wọn. Ẹ óò láyọ̀ pé ẹ ṣe bẹ́ẹ̀!