Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Jan. 15
“Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lo ère nínú ìjọsìn wọn. Ǹjẹ́ o rò pé irú àwọn nǹkan aláìlẹ́mìí bẹ́ẹ̀ lágbára láti gbà wá là? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jọ̀wọ́ kíyè sí ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe fún wa. [Ka Ìṣípayá 21:3, 4.] Àfi Ọlọ́run gidi kan ló lè gbé irú èyí ṣe. Ìwé ìròyìn yìí sọ ẹni tí ó jẹ́ àti bí a ṣe lè jàǹfààní bí a bá gbẹ́kẹ̀ lé e.”
Jí! Jan. 8
“A lè má fi bẹ́ẹ̀ ka ọ̀rọ̀ ilé gbígbé sí nítorí a ní ibi tí a ń gbé. Síbẹ̀, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn olùwá-ibi-ìsádi kárí ayé ni wọ́n kàn ń rìn kiri láìmọ ohun tí wọ́n lè ṣe, tí wọn kò sì ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tí wọ́n ń fẹ́. Ìwé ìròyìn Jí! yìí ṣàlàyé ìdí tí ìṣòro yìí fi wà, ó tún sọ nípa ìlérí Bíbélì pé ìgbà kan ń bọ̀ tí olúkúlùkù yóò ní ilé tirẹ̀.”
Ilé Ìṣọ́ Feb. 1
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ń ṣàníyàn nípa bí àyíká wa ṣe ń bà jẹ́. Àmọ́, ṣé o tiẹ̀ ti ronú rí nípa bí èrò inú wa ṣe lè dìbàjẹ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì pé ká wà ní mímọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí àti nípa tara. [Ka 2 Kọ́ríńtì 7:1.] Ó dá mi lójú pé wàá rí i pé ìsọfúnni yìí wúlò ó sì lè ṣèrànwọ́.”
Jí! Feb. 8
“Ó dájú pé o ti rí ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó tó bẹ̀rẹ̀ dáadáa, tó jẹ́ pé láìtọ́jọ́ wọn fọ́ yángá. Inú mi á dùn láti fi ẹ̀dà Jí! yìí sílẹ̀ fún ọ, ó ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ìgbéyàwó ẹni ṣe lè tọ́jọ́ tí yóò sì láyọ̀.”