ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/00 ojú ìwé 5-6
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 8/00 ojú ìwé 5-6

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run

Àtúnyẹ̀wò láìṣí ìwé wò fún àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún àwọn ọ̀sẹ̀ May 1 sí August 21, 2000. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.

[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́ka tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]

Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:

1. Èsì tí Gídéónì fún àwọn ọkùnrin Éfúráímù nítorí bí wọ́n ṣe sọ̀rọ̀ sí i lọ́nà àìtọ́ fi ìwà tútù àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní hàn, èyí sì mú kó yí àríwísí tí wọ́n ń ṣe lọ́nà àìtọ́ padà, kí àlàáfíà sì wà. (Oníd. 8:1-3) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]

2. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mánóà sọ pé “àwa ti rí Ọlọ́run,” ní ti gidi, ẹni tó sọ ara rẹ̀ di ènìyàn, tó ń gbẹnu sọ fún Ọlọ́run, ni òun àti aya rẹ̀ rí, wọn ò rí Jèhófà fúnra rẹ̀. (Oníd. 13:22) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 5/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 3.]

3. Ìwé Àwọn Onídàájọ́ ń mú kó túbọ̀ dáni lójú pé Jèhófà jẹ́ atóbilọ́lá Olùdáǹdè fún àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀. [w85-YR 1/1 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 3]

4. Rúùtù jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, láti ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. [w85-YR 3/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 1]

5. Ìwé Àwọn Onídàájọ́ 21:25 sọ̀rọ̀ nípa àkókò kan tí Jèhófà fi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀ láìsí ìtọ́sọ́nà kankan bó tií wù ó mọ. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 6/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 16.]

6. Àwòrán àwọn kérúbù tó wà lórí àpótí májẹ̀mú fi hàn pé Jèhófà wà níbẹ̀, ẹni tí a sọ pé ó “ń jókòó lórí [tàbí, “láàárín”] àwọn kérúbù.” (1 Sám. 4:4, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, New World Translation Reference Bible) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w81-YR 5/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1.]

7. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù jẹ ẹ̀jẹ̀ nígbà tí wọ́n wà ní ipò ìgbékútà, tí a kò sì fìyà jẹ wọ́n, èyí fi hàn pé ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ lè wà tí ẹnì kan fi lè ṣàìka òfin Ọlọ́run sí fún ìgbà díẹ̀ láti lè dáàbò bo ìwàláàyè rẹ̀. (1 Sám. 14:24-35) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w94-YR 4/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 7 sí 9.]

8. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan máa ń ronú pé ọ̀rọ̀ náà, “yí lérò padà,” ní í ṣe pẹ̀lú ọgbọ́n àrékendá tàbí ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, a lè lò ó ní èrò rere láti túmọ̀ sí láti lo ìfèròwérò tó gbéṣẹ́, tó sì bọ́gbọ́n mu láti mú kí ẹnì kan gbà gbọ́ dájú, kí èrò inú ẹni náà sì yí padà. (2 Tím. 3:14, 15) [w98-YR 5/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 4]

9. “Àpò ìwàláàyè” ń tọ́ka sí ààbò àti ìpamọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí yóò ṣe Dáfídì láǹfààní bó bá yẹra fún jíjẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ lójú Ọlọ́run. (1 Sám. 25:29) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 6/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 3.]

10. Májẹ̀mú Ìjọba Dáfídì, tí 2 Sámúẹ́lì 7:16 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, fi hàn pé ìlà ìdílé ti Irú Ọmọ náà ni yóò mú Mèsáyà jáde, èyí sì jẹ́ ìdánilójú lọ́nà òfin pé ẹnì kan láti ìlà ìdílé Dáfídì ni yóò wá láti ṣàkóso “fún àkókò tí ó lọ kánrin.” [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 2/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 21 àti 22.]

Dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:

11. Ìdánilójú wo ni Sáàmù 34:18 fúnni? [w98-YR 4/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3]

12. Fífún tí wọ́n fún Jósẹ́fù ní àpèlé náà, Bánábà, fi kí ni hàn? (Ìṣe 4:36) [w98-YR 4/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 3, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, New World Translation Reference Bible]

13. Èé ṣe tí àkọsílẹ̀ Bíbélì fi sọ pé Élì ń bá a nìṣó láti bọlá fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ju bó ṣe bọlá fún Jèhófà? (1 Sám. 2:12, 22-24, 29) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 9/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 14.]

14. Kí ló fún Rúùtù ní àǹfààní láti wá mọ Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà, àti àwọn ènìyàn tí ń jọ́sìn rẹ̀? [w85-YR 3/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 2]

15. Ní ìbámu pẹ̀lú 1 Sámúẹ́lì 1:1-7, àpẹẹrẹ títayọ wo ni ìdílé Sámúẹ́lì fi lélẹ̀? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w98-YR 3/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 12.]

16. Lọ́nà wo la fi lè sọ pé ‘agbára ọrọ̀ ń tanni jẹ’? (Mát. 13:22) [w98-YR 5/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1]

17. Báwo ni Jónátánì tó dàgbà ju Dáfídì lọ ṣe fi hàn pé òún tẹ́wọ́ gba Dáfídì, ẹni àmì òróró Jèhófà, kí ni èyí sì dúró fún lónìí? (1 Sám. 18:1, 3, 4) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 1/1 ojú ìwé 24 àti 26 ìpínrọ̀ 4 àti 13.]

18. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù jẹ́ “aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán,” báwo ni ìwé Jóòbù ṣe fi hàn pé èyí kò túmọ̀ sí pé ó jẹ́ ẹni pípé? (Jóòbù 1:8) [w98-YR 5/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1]

19. Kí ni gbólóhùn náà, “ẹ tiraka tokuntokun,” túmọ̀ sí? (Lúùkù 13:24) [w98-YR 6/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1, 4]

20. Bí a ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ̀kọ́ ńláǹlà wo ló yẹ ká máa fi sọ́kàn, bí a ṣe ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní 2 Sámúẹ́lì 12:26-28? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w93-YR 12/1 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 19.]

Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tó yẹ kó wà ní àlàfo inú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:

21. Àkọsílẹ̀ Àwọn Onídàájọ́ 16:1-21 kọ́ wa pé a gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra nígbà gbogbo fún __________________________ láti ọ̀dọ̀ __________________________. [w85-YR 1/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 5 àti ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 1]

22. Ìwé Sámúẹ́lì méjèèjì ṣàlàyé nípa òpin sànmánì __________________________ àti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso __________________________ Ísírẹ́lì. [w85-YR 1/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 3]

23. Orúkọ àtọ̀runwá náà, Jèhófà, túmọ̀ sí “__________________________,” ó sì túmọ̀ sí pé Jèhófà lè ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́, tó yẹ kó ṣe láti lè mú __________________________ rẹ̀ ṣẹ. [w98-YR 5/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 3]

24. __________________________ náà, tí í ṣe “Ọmọ Dáfídì,” ni a bí ní __________________________. [w85-YR 1/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 3]

25. Àkàwé Jésù nípa ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere fi hàn pé ẹni tí ó dúró ṣánṣán ní tòótọ́ ni ẹni tí kì í ṣe pé ó ń pa __________________________ Ọlọ́run mọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń fara wé __________________________ rẹ̀. (Lúùkù 10:29-37) [w98-YR 7/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2]

Mú ìdáhùn tó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:

26. Nígbà tí (Rúùtù; Náómì; Ópà), ní àǹfààní láti sin Ọlọ́run tòótọ́, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run, ó fi tọkàntọkàn gbá àǹfààní yẹn mú. [w85-YR 3/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 1]

27. Dídé (Sámúẹ́lì; Dáfídì; Sọ́ọ̀lù) ládé gẹ́gẹ́ bí ọba fòpin sí sànmánì ìṣàkóso àwọn onídàájọ́ Ísírẹ́lì, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tó fi ṣẹ́gun (àwọn ará Ámónì; àwọn ọmọ Móábù; àwọn Filísínì) pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. (1 Sám. 11:6, 11) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 12/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 1.]

28. (Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù; bàbá Tímótì; ìyá Tímótì àti ìyá ìyá rẹ̀) ló mú ipò iwájú nínú kíkọ́ ọ ní “ìwé mímọ́” débi tó fi lè di míṣọ́nnárì àti alábòójútó dídáńgájíá. (2 Tím. 3:14, 15; Fílí. 2:19-22) [w98-YR 5/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 5]

29. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, sùúrù, ìfaradà, àti ìgbáralé Jèhófà tí (Dáfídì; Sámúẹ́lì; Jónátánì) ní ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nílò lọ́jọ́ orí yòówù kí wọ́n jẹ́. [w85-YR 1/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 2]

30. Ibi tí Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run wà lókè ọ̀run ni a ń pè ní (“Òkè Síónì;” “Jerúsálẹ́mù ti òkè;” “Jerúsálẹ́mù Tuntun”). [w85-YR 1/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2]

So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí mọ́ èyí tó bá a mu lára àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí:

Oníd. 11:30, 31; 1 Sám. 15:22; 30:24, 25; 2 Ọba 6:15-17; Ják. 5:11

31. Jèhófà mú un dáni lójú pé òun yóò lo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run òun láti dáàbò bo àwọn èèyàn òun bí òun ṣe fẹ́. [w98-YR 4/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 5]

32. Àwọn alábòójútó nínú ìjọ ní ẹrù iṣẹ́ láti mú àdéhùn wọn ṣẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè dunni, ó sì lè náni ní ohun púpọ̀ nígbà mìíràn. [w99-YR 9/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 3 àti 4]

33. Pípa ìwà títọ́ mọ́ lábẹ́ àdánwò máa ń yọrí sí èrè ńláǹlà látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run. [w98-YR 5/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 4]

34. Ojúlówó ìfẹ́ fún Ọlọ́run ju wíwulẹ̀ ṣèrúbọ lásán lọ, ó ń béèrè ṣíṣègbọràn sí àwọn ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 6/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1.]

35. Jèhófà máa ń fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún àwọn tí ń sìn ní ipò ìṣètìlẹ́yìn nínú ètò àjọ rẹ̀ lónìí. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo g88-YR 1/8 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 4.]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́