Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A óò sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, a lè fi ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn lọni. Fi ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí o ní in lọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. June: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Pọkàn pọ̀ sórí bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
◼ Kí àwọn akéde tí wọ́n fẹ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April wéwèé nísinsìnyí, kí wọ́n sì tètè forúkọ sílẹ̀. Èyí á ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ètò tó yẹ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kí wọ́n sì ní àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́. Kí a kéde orúkọ gbogbo àwọn táa fọwọ́ sí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún ìjọ.
◼ A ó ṣe Ìṣe Ìrántí ní Sunday, April 8, 2001. Kò sí ìpàdé mìíràn tí a óò ṣe lọ́jọ́ yẹn yàtọ̀ sí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Àwọn alàgbà lè ṣe ètò tó bá yẹ láti lè ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ní àkókò mìíràn.