Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 12
Orin 112
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: “Oṣù April Jẹ́ Àkókò Láti ‘Ṣiṣẹ́ Kára Ká sì Là Kàkà.’” (Ìpínrọ̀ 1 sí 13) Kí alábòójútó olùṣalága bójú tó o. Fi ọ̀yàyà jíròrò ohun tí a fẹ́ láti ṣàṣeparí lóṣù April. Rọ olúkúlùkù nínú ìjọ láti ṣe ipa tirẹ̀ kọ́wọ́ wa lè tẹ góńgó kíkópa ní kíkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣù yẹn.
Orin 147 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 19
Orin 166
8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
17 min: “Máa Fiyè sí Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run.”a Tọ́ka sí àwọn àwòrán díẹ̀ nínú ìwé tuntun náà tó mú ká túbọ̀ mọrírì àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà.
20 min: “Oṣù April Jẹ́ Àkókò Láti ‘Ṣiṣẹ́ Kára Ká sì Là Kàkà.’” (Ìpínrọ̀ 14 sí 30) Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó o. Àsọyé tó ní àwọn apá tó jẹ́ ìbéèrè àti ìdáhùn. Kí olúkúlùkù ṣe ètò gidi láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ bó bá ti ṣeé ṣe tó lóṣù April. Sọ gbogbo ètò ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tí ẹ ṣe fún oṣù náà. Fún gbogbo àwọn tó bá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ níṣìírí láti ṣe bẹ́ẹ̀, kí o sì sọ pé kí wọ́n gba fọ́ọ̀mù ìforúkọsílẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé.
Orin 188 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 26
Orin 204
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn ará létí pé kò tíì pẹ́ jù láti forúkọ sílẹ̀ fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù April. Fún gbogbo ará níṣìírí pé kí wọ́n ka Bíbélì kíkà fún Ìṣe Ìrántí tí a ṣètò láti April 3 sí 8, bó ṣe wà nínú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2001. Ṣèfilọ̀ ìgbà tí ẹ óò ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tó bọ́ sí àkókò Ìṣe Ìrántí. Kí ẹ má ṣe gbàgbé àsọyé àkànṣe fún gbogbo èèyàn ní Sunday yìí, ìyẹn April 1, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ta Ní Lè Rí Ìgbàlà?” Fún gbogbo akéde níṣìírí láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́jọ́ yẹn, kí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ oṣù April lọ́nà tó dára.
20 min: “Ẹ Jẹ́ Kí Gbogbo Wa Máa Bọlá fún Jèhófà àti fún Ọmọ Rẹ̀.” Kí alàgbà kan sọ àsọyé tó ń fi Ìwé Mímọ́ tani jí yìí. Fún gbogbo akéde níṣìírí láti kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó nínú ìgbòkègbodò àkànṣe tí a wéwèé fún oṣù April, kí wọ́n sì túbọ̀ sapá láti ké sí àwọn èèyàn wá sí Ìṣe Ìrántí.
15 min: Mímúra Bí A Ó Ṣe Fi Ìwé Ìròyìn Wa Lọni. A ó fi Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni lóṣù April. Ṣàtúnyẹ̀wò ojú ìwé 8, ìpínrọ̀ 3 àti 10, nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996. Ṣàlàyé (1) àpilẹ̀kọ, (2) kókó tó yẹ láti sọ̀rọ̀ lé, (3) ìbéèrè tó lè ru ìfẹ́ sókè, àti (4) ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá àkókò mu tí èèyàn lè lò lọ́nà gbígbéṣẹ́ láti fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́ lọni. Sakun láti fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tó bá fìfẹ́ hàn. Parí ọ̀rọ̀ rẹ nípa jíjẹ́ kí á ṣe àṣefihàn kan tí wọ́n múra sílẹ̀ dáadáa nípa bí a ṣe lè ṣe èyí nígbà ìkésíni àkọ́kọ́.
Orin 207 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 2
Orin 220
9 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù March sílẹ̀. Ṣàyẹ̀wò “Àwọn Ohun Tí Kò Yẹ Ká Gbàgbé Nípa Ìṣe Ìrántí.”
18 min: “Ìfẹ́ Ló Ń Mú Ká Wàásù.”b Ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Fi ohun tí ìwé Insight, Apá Kejì, sọ ní ojú ìwé 673, ìpínrọ̀ 1 kún un. Ké sí akéde kan tó ti ń wàásù fún ọ̀pọ̀ ọdún láti ṣàlàyé bí ìfẹ́ tó ní sí Ọlọ́run ṣe ń mú kó máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó. Rọ gbogbo akéde pé kí wọ́n kópa nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí lóṣù April àti ní gbogbo oṣù yòókù lẹ́yìn náà.
18 min: “Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Máa Lọ sí Àwọn Ìpàdé.”c Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996, ìpínrọ̀ 14 sí 16, pèsè àfikún àbá nípa bí a ṣe lè darí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sínú ètò àjọ náà. Fi hàn bí a ṣe lè lo ìwé pẹlẹbẹ Béèrè (ẹ̀kọ́ 5, ìpínrọ̀ 7) àti ìwé Ìmọ̀ (orí 5, ìpínrọ̀ 22) ní ìbẹ̀rẹ̀ láti fún wọ́n níṣìírí láti máa 2wá sí ìpàdé. Láti ṣàpèjúwe èyí, jẹ́ kí á múra àṣefihàn kan sílẹ̀ dáadáa nínú èyí tí akéde kan ti ń fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà fún akẹ́kọ̀ọ́ kan níṣìírí láti ronú jinlẹ̀ lórí wíwá sí ìpàdé.
Orin 47 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.