ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/01 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 9
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 16
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 23
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 30
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 7
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 4/01 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 9

Orin 93

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Kéde iye àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí ní ìjọ yín. Sọ pé kí àwùjọ sọ àwọn gbólóhùn onímọrírì tí àwọn tó wá fún ìgbà àkọ́kọ́ sọ. Fún olúkúlùkù níṣìírí pé kí wọ́n wo fídíò The Bible—Its Power in Your Life láti múra sílẹ̀ fún ìjíròrò tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ April 23.

30 min: “Ètò Mímú Kí Ìpínkiri Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Rọrùn Tí A Ṣe.” Kí alàgbà tó tóótun bá àwùjọ jíròrò ohun tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà. Tọ́ka sí lẹ́tà tí a kọ sí gbogbo ìjọ ní September 21, 1999. Lẹ́yìn náà, kí o jẹ́ kí akéde kan tó jẹ́ onírìírí, tó múra sílẹ̀ dáadáa ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè lo ohun tí a gbọ́ nínú ọ̀rọ̀ yìí nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Akéde náà bá onílé jíròrò kókó ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ kan nípa lílo ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tí a óò fi lọni nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lópin ọ̀sẹ̀ yìí. Bí akéde náà ṣe pe àfiyèsí sí kókó kan pàtó nínú ìwé ìròyìn ọ̀hún, onílé sọ pé: “Èyí mà dára o.” Akéde náà wá sọ pé: “Màá láyọ̀ láti fi ìwé ìròyìn yìí sílẹ̀ fún ọ kí o lè gbádùn kíka àpilẹ̀kọ yìí àti gbogbo àwọn yòókù tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí.” Onílé wá béèrè pé: “Èló ni?” Akéde náà dáhùn pé: “Bí o bá máa kà á, kò sí iye owó tí a ń dá lé e. O lè rí i lójú ìwé tí ọ̀rọ̀ àwọn tó ṣèwé yìí jáde wà pé ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ara iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé àti pé ọrẹ àtinúwá la fi ń tì í lẹ́yìn. [Tọ́ka sí gbólóhùn tó wà ní ojú ìwé 5 nínú Jí! tàbí sí ọwọ́ ìsàlẹ̀ lápá òsì ojú ìwé 2 nínú Ilé Ìṣọ́.] Mo wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ju mílíọ̀nù mẹ́fà tí wọ́n yọ̀ǹda àkókò àti ohun ìní wọn láti ṣe iṣẹ́ tó ṣe kókó yìí ní ilẹ̀ tó ju igba àti ọgbọ̀n [230] lọ. Bí o ba fẹ́ láti fi ọrẹ díẹ̀ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ yìí, inú wa á dùn sí i.” Onílé fi ọrẹ ṣètìlẹyìn, ó sì fi owó ọ̀hún sínú àpò ìwé tó wà fún iṣẹ́ kárí ayé náà. Akéde dúpẹ́ fún ìtìlẹyìn tí onílé ṣe, ó sì sọ pé òun á tún mú àwọn ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn tí ń bọ̀ wá. Nínú àṣefihàn ṣókí kejì, fi hàn bí akéde kò ṣe fi ìtẹ̀jáde sílẹ̀ nítorí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé onílé náà ṣe tán láti sọ̀rọ̀, kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn Ìjọba náà. Nínú àṣefihàn ṣókí kẹta, fi hàn bí a ṣe lè fi ìwé àṣàrò kúkúrú sílẹ̀ fún ẹnì kan tó fi ojúlówó ìfẹ́ hàn ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ọwọ́ rẹ̀ dí gidigidi lákòókò yẹn, tó sì dà bíi pé kò ní bá a mu lákòókò yẹn láti ṣàlàyé bí a ṣe ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ tí a ń ṣe kárí ayé. Akéde ṣèlérí láti padà wá ní àkókò mìíràn tí yóò túbọ̀ rọrùn. Nígbà tó tún padà wá, yóò sakun láti pinnu bóyá onílé náà nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ wa ní ti gidi, bó bá sì rí bẹ́ẹ̀, yóò ṣàlàyé bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ṣe jẹ́ àti bí a ṣe ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ọ̀hún.

Orin 72 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 16

Orin 145

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Òpin ọ̀sẹ̀ méjì péré ló ṣẹ́ kù nínú oṣù April, nítorí náà, fún gbogbo akéde níṣìírí láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ kí oṣù tó parí.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Sísọ̀rọ̀ Lọ́nà Tó Rọrùn Tó sì Yéni Ló Dára Jù Lọ.”a Fí àlàyé kún un látinú àpilẹ̀kọ náà, “Tètè Sọ Ohun Tóo Ní Í Sọ!” nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 1999, ojú ìwé 4. Ṣàṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ ṣókí kan tàbí méjì tó rọrùn.

Orin 146 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 23

Orin 163

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: “Kí Ló Yẹ Ká Gbé Ìwéwèé Wa Kà?” Àsọyé. Fi àwọn kókó tó bá a mu kún un látinú Ilé Ìṣọ́, November 1, 2000, ojú ìwé 18 sí 21.

25 min: “Àwọn Ohun Tí Fídíò The Bible—Its Power in Your Life Ń Tẹ̀ Mọ́ni Lọ́kàn.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Èé ṣe tí o kò fi ṣiṣẹ́ lórí àlàyé tí a ṣe nínú ìrírí tí a sọ nínú ìwé 1997 Yearbook, ojú ìwé 54, ìpínrọ̀ 1, nípa bí a ṣe lè lo àwọn fídíò Society lọ́nà rere? Ní oṣù June, a óò wo fídíò náà, Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault. Ní àfirọ́pò, jíròrò “Bíbélì Ha Fi Ìgbàgbọ́ Nínú Àyànmọ́ Kọ́ni Bí?” Àsọyé tí alàgbà kan sọ, tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, September 1, 1996, ojú ìwé 4 sí 7.

Orin 202 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 30

Orin 215

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù April sílẹ̀. Kí àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ béèrè ti olúkúlùkù tó wà nínú àwùjọ wọn kí a lè ṣàkójọ gbogbo ìròyìn ní May 6.

15 min: “Jẹ́rìí Gẹ́gẹ́ Bí Aládùúgbò Rere.”b Mẹ́nu kan àwọn àfikún ọ̀nà tí a lè gbà fi ìwà wa jẹ́rìí.—Wo Ilé Ìṣọ́, November 1, 1997, ojú ìwé 18, ìpínrọ̀ 16.

20 min: Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́. Àsọyé àti àwọn ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn darí. Ṣàtúnyẹ̀wò ètò Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1998, ojú ìwé 8. Sọ àwọn nǹkan tó ń gbéni ró tí a ti ṣe nínú ìjọ. Fọ̀rọ̀ wá aṣáájú ọ̀nà kan lẹ́nu wò, tó ti ran ẹlòmíràn lọ́wọ́, àti akéde kan tí a ti ràn lọ́wọ́. Fi hàn bí àwọn méjèèjì ṣe jèrè látinú jíjùmọ̀ ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Rọ àwọn mìíràn láti wá jàǹfààní ìpèsè yìí láwọn oṣù tó ń bọ̀.

Orin 216 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 7

Orin 84

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run Ohun Gbogbo Ṣeé Ṣe.”c Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ìwé Proclaimers sọ ní ojú ìwé 443, kí o sọ bí iṣẹ́ ìwàásù táa ṣe lọ́dún 1935 ṣe gbòòrò tó bí a bá fi wéra pẹ̀lú ìròyìn ti inú ìwé Yearbook lọ́ọ́lọ́ọ́. Tọ́ka sí bí ìmúgbòòrò ńláǹlà yìí ṣe fìgbà kan rí dà bíi pé kò ní ṣeé ṣe.

20 min: “Jẹ́ Kí ‘Ọwọ́ Rẹ Dí Jọjọ’ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ.”d Ké sí akéde méjì tàbí mẹ́ta láti sọ ìrírí tí wọ́n ní nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí a ṣe dámọ̀ràn ní ìpínrọ̀ 3 sí 5.

Orin 80 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́