Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 14
Orin 3
12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ àti Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: Àpótí Ìbéèrè. Alàgbà ni kí ó bójú tó o.
18 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Àwọn Olùkọ́ni Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọdún 2001.” Akọ̀wé ni kí ó jíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 10 àpilẹ̀kọ inú àkìbọnú yìí lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 31 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 21
Orin 52
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
20 min: Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé Tí Ń Mú Ìdùnnú Wá. Alàgbà ni kí ó sọ àsọyé yìí àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́ August 1, 1997, ojú ìwé 26 sí 29.
15 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Àwọn Olùkọ́ni Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọdún 2001.” Alàgbà ni kí ó jíròrò ìpínrọ̀ 11 sí 15 àpilẹ̀kọ inú àkìbọnú yìí lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ṣíṣètò fún ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ bó bá ti ṣeé ṣe kí ó yá tó láti lè ráyè lọ sí gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọpọ̀ yìí. Gbóríyìn fún gbogbo ìjọ fún fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣètò Society.
Orin 105 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 28
Orin 58
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù May sílẹ̀.
15 min: “Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Lè Mú Àṣeyọrí Wá.” Jíròrò àpilẹ̀kọ yìí pẹ̀lú àwùjọ. Àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wo ni wọ́n ti rí i pé ó gbéṣẹ́ jù lọ ní ìpínlẹ̀ ìjọ? Ìgbà wo ni àwọn akéde máa ń múra àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ lò nínú iṣẹ́ ìsìn pápá sílẹ̀, tí wọ́n sì máa ń fi wọ́n dánra wò? Jẹ́ kí á ṣàṣefihàn ṣókí méjì tàbí mẹ́ta nípa àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ti gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín.
20 min: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ń Sa Agbára.”a Fi àṣefihàn méjì tí a múra dáadáa kún un, kí wọ́n fi hàn bí gbígbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ ní ṣókí ṣe lè darí àfiyèsí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Orin 79 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 4
Orin 100
12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ṣàyẹ̀wò “Ìtara Tó Máa Ń Ru Ọ̀pọ̀ Jù Lọ Sókè.”
15 min: “Kópa Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ Nínú Ìkórè Náà.”b Nígbà tí o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, fi àpẹẹrẹ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ September 15, 1996, ojú ìwé 18, ìpínrọ̀ 10 kún un, kí o sọ ohun tí àwọn kan ń ṣe láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i.
18 min: “A Ti Ṣe Ìpínlẹ̀ Wa Lọ́pọ̀ Ìgbà!”c Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kí ó bójú tó o. (Àwọn ìjọ tí wọ́n ní ìpínlẹ̀ tí wọn kì í sábàá ṣe lè ṣàtúnyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ìwé Ìròyìn Ń Kéde Ìjọba Náà,” tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti April 1998.) Jíròrò ohun tí ẹ lè ṣe nínú ìjọ kí ẹ lè túbọ̀ máa ṣe ìpínlẹ̀ yín kúnnákúnná nígbà tí ẹ bá ń ṣe é. Sọ àwọn ìrírí tó wà nínú ìwé 1997 Yearbook, ojú ìwé 204, àti ti inú Ilé-Ìṣọ́nà, February 15, 1996, ojú ìwé 26. Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì pípa àkọsílẹ̀ ilé dé ilé tó péye mọ́, pípadà lọ sí ibi tí àwọn èèyàn kò ti sí nílé, àti ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò láìfọ̀rọ̀ falẹ̀.
Orin 142 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.