ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/01 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 11
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 18
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 25
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 2
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 6/01 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 11

Orin 178

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún gbogbo ìjọ níṣìírí pé kí wọ́n wo fídíò Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault ní ìmúrasílẹ̀ fún ìjíròrò tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ June 18.

15 min: “Ẹ Máa Bá A Lọ Ní ‘Ṣíṣe Ohun Tí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀.’” Kí alàgbà kan sọ àsọyé tí a gbé karí Ìwé Mímọ́ yìí lọ́nà tí ń fúnni níṣìírí.

20 min: “Dé Inú Ọkàn Akẹ́kọ̀ọ́ Rẹ.”a Fi àwọn àbá tó ṣeé mú lò kún un nípa bí a ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti mú kí ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ fún Jèhófà àti Jésù gbèrú nínú ọkàn wọn. Ló àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 1999, ojú ìwé 14, ìpínrọ̀ 18 sí 20.

Orin 184 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 18

Orin 194

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.

10 min: Dídáhùn sí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí Ó Lè Bẹ́gi Dínà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàtúnyẹ̀wò “Àlàyé” nínú ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 7 àti 8. Láti ojú ìwé 8 sí 12, yan àwọn àtakò tí ẹ máa ń bá pàdé ní ìpínlẹ̀ yín. Sọ pé kí àwùjọ ṣàlàyé irú ìdáhùn tó ṣiṣẹ́ fún wọn dáadáa àti ìdí tó fi ṣiṣẹ́.

30 min: “Mo Dúró Gbọn-in! Mo Dúró Gbọn-in! Mo Dúró Gbọn-in!” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ lórí fídíò Stand Firm, nípa lílo àwọn ìbéèrè tó wà ní ìpínrọ̀ 2. Lẹ́yìn náà, jíròrò ìpínrọ̀ 3 àti 4. Fi ìrírí tó wà nínú Jí! November 22, 1999, Gẹ̀ẹ́sì, ojú ìwé 31 parí ọ̀rọ̀ rẹ. Ní oṣù August, a óò ṣàyẹ̀wò fídíò náà, The New World Society in Action. Ní àfidípò, jíròrò “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Àwọn Onígboyà Lójú Ewu Nazi.” Kí alàgbà sọ àsọyé yìí tí a gbé karí Jí! July 8, 1998, ojú ìwé 10 sí 14.

Orin 197 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 25

Orin 2

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ṣàyẹ̀wò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù July àti August. Ṣàlàyé ìwé pẹlẹbẹ méjì tó wà lọ́wọ́ nínú ìjọ. Jẹ́ kí á ṣe àṣefihàn méjì táa múra dáadáa nípa bí a ṣe lè fi wọ́n lọni nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Láti mọ àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a dábàá, wo ojú ìwé tó kẹ́yìn nínú àwọn ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù July àti August 1995 àti ti àwọn oṣù kan náà yẹn nínú ọdún 1996 àti ọdún 1997.

17 min: “Wà Lójúfò Láti Wá Àwọn Adití Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Yín Rí.”b Bí àkọsílẹ̀ nípa iye àwọn adití tó wà ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín bá wà, sọ iye wọn. Sọ ìrírí tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 1998, ojú ìwé 3, ìpínrọ̀ 6.

13 min: “Báwo La Ṣe Lè Pèsè Àwọn Àfikún Gbọ̀ngàn Ìjọba Tí A Nílò?”c (Ìpínrọ̀ 1 sí 10) Ka ìpínrọ̀ 4 kí o sì jíròrò ṣókí nípa ohun tí ẹ nílò nínú ìjọ yín láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ́ ẹ̀rí rere ládùúgbò yín. (1 Kọ́r. 10:31) Ka ìpínrọ̀ 9 kí o sì mẹ́nu kàn án pé lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, ìjíròrò apá tó ṣẹ́ kù nínú àkìbọnú yìí yóò ṣàlàyé àǹfààní tuntun kan tó túbọ̀ gbòòrò sí i láti kópa nínú kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Orin 29 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 2

Orin 5

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù June sílẹ̀.

10 min: Àpótí Ìbéèrè. Alàgbà ni kí ó sọ àsọyé yìí.

15 min: Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Jẹ́ Ọlọgbọ́n Nínú Yíyan Iṣẹ́ Ìgbésí Ayé Yín. Èyí ni àkọ́kọ́ nínú apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn mẹ́ta tí yóò jíròrò àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́. Àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan ń lépa iṣẹ́ ìgbésí ayé nípa lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga, tí èyí sì wá ń ní ipa tí kò dára lórí ipò tẹ̀mí wọn. Apá yìí yóò jẹ́ ìjíròrò láàárín òbí méjì àti ọmọ wọn ọkùnrin tàbí obìnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́langba. Ńṣe ni ọ̀dọ́ náà wà ní ipò kan tí ó ní láti ṣe ìpinnu ńláǹlà nípa àwọn ìlépa ọjọ́ ọ̀la. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lè fẹ́ lépa owó, ipò iyì, tàbí adùn ìgbésí ayé, ìdílé náà ṣàyẹ̀wò Bíbélì láti mọ ohun tí ó dámọ̀ràn. (Wo ìwé Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè, ojú ewé 174 àti 175; Ilé Ìṣọ́, August 15, 1997, ojú ìwé 21, àti September 1, 1999, ojú ìwé 19 sí 21, ìpínrọ̀ 1 sí 3 àti 5 àti 6.) Ọ̀dọ́ náà gbà pé ó bọ́gbọ́n mu láti lépa ọ̀nà ìgbésí ayé tí yóò ràn òun lọ́wọ́ láti lè jẹ́ kí ọwọ́ òun tẹ àwọn góńgó ìṣàkóso Ọlọ́run láti lè mú kí ire Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú.

15 min: “Báwo La Ṣe Lè Pèsè Àwọn Àfikún Gbọ̀ngàn Ìjọba Tí A Nílò?”d (Ìpínrọ̀ 11 sí 21) Ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti òṣìṣẹ́ tí ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí a ń pèsè fún olùyọ̀ǹda ara ẹni àti òṣìṣẹ́ yìí jọ ara wọn, a kò ka àwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn fún ìgbà díẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí ẹni tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún àyàfi tó bá jẹ́ pé wọ́n ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bí wọ́n bá jẹ́ aṣáájú ọ̀nà báyìí, a lè fún wọn ní wákàtí ní àfidípò fún àwọn wákàtí tí wọ́n lò lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n á fi lè ní àádọ́rin wákàtí lóṣù. Àwọn tó bá tóótun fún iṣẹ́ ìsìn yìí lè rí fọ́ọ̀mù tí a fi ń yọ̀ǹda ara ẹni fún iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ìyẹn, fọ́ọ̀mù Application for Kingdom Hall Construction Volunteer Program (A-25) gbà lọ́dọ̀ alábòójútó olùṣalága. Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ló ń fún àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó bá tóótun ní fọ́ọ̀mù tí wọ́n fi ń di òṣìṣẹ́ tí ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn fọ́ọ̀mù Application for Kingdom Hall Construction Servant (A-12). Ka ìpínrọ̀ 20 àti Fílípì 2:2-4. Ṣàlàyé bí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a ń kọ́ lọ́nà tó rọrùn tó sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì yóò ṣe mú kí iṣẹ́ ìkọ́lé yára kánkán. Fi kíka ìpínrọ̀ 21 parí ọ̀rọ̀ rẹ.

Orin 32 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́