ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/01 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 8/01 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù August àti September: Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. (Bí èyí kò bá sí, a lè fi ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ lọni.) October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, a lè fi ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn lọni. November: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí àwọn èèyàn bá ti ní ìwọ̀nyí tẹ́lẹ̀, a lè fi ìtẹ̀jáde mìíràn tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ lọ̀ wọ́n.

◼ Nínú ìfilọ̀ táa ṣe nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù June 2001, nípa ìtẹ̀jáde tó wà fáwọn afọ́jú, a sọ ohun tó tẹ̀ lé e yìí nípa ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa pé: “(ìwé mẹ́rin; kìkì àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi ló wà fún).” Bó ṣe yẹ kó kà nìyí: “(ìwé mẹ́rin; àwọn akéde nìkan ló wà fún).”

◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní September 1, tàbí bó bá ṣe lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tó tẹ̀ lé e.

◼ A ń kó àwọn fọ́ọ̀mù tí ó tó láti lò ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2002 ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fọgbọ́n lo àwọn fọ́ọ̀mù wọ̀nyí. Ète tí a torí rẹ̀ ṣe wọ́n nìkan ni kí ẹ lò wọ́n fún.

◼ Bẹ̀rẹ̀ látọdún yìí, àwọn aṣáájú ọ̀nà tí kò bá pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ó kéré tán ní September 1 ọdún tí wọ́n fẹ́ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà kò ní tóótun láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà. A lè fàyè gba irú ẹni bẹ́ẹ̀ bó bá jẹ́ pé òbí ẹni tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tí kò tíì tójúúbọ náà tóótun láti lọ sí kíláàsì kan náà.

◼ Ní August 31, 2001 tàbí kó ṣáà má jìnnà sí ọjọ́ yẹn rárá, kí ẹ ṣírò gbogbo iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ bí a ti ń ṣe lọ́dọọdún. Ìṣirò yìí jọ èyí tí ẹni tó ń ṣe kòkáárí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe lóṣooṣù nípa kíka iye àwọn ìwé náà, kí ẹ sì kọ àròpọ̀ iye wọn sórí fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18). Àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tí ó wà lọ́wọ́ ni ẹ lè mọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìròyìn ní ìjọ kọ̀ọ̀kan tí ẹ jọ ń gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ pọ̀. Olúkúlùkù ìjọ tí ń ṣe kòkáárí yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18) mẹ́ta. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà àkọ́kọ́ ránṣẹ́ sí Society, ó pẹ́ tán ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta gẹ́gẹ́ bí èyí tí ẹ óò kọ nǹkan sí. Kí akọ̀wé ìjọ tí ń ṣe kòkáárí bójú tó ìṣirò náà. Akọ̀wé àti alábòójútó olùṣalága ìjọ tí ń ṣe kòkáárí ni kó fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti August 27, 2001, sí September 1, 2001, Society yóò ṣírò gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lọ́wọ́ ní Bẹ́tẹ́lì Igieduma. Nítorí ìṣirò tí a fẹ́ ṣe yìí, a kò ní ṣiṣẹ́ lórí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ béèrè pé kí a fi ránṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní lè rí wọn kó ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́