Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, a lè fi ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn lọni. November: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí àwọn èèyàn bá ti ní ìwọ̀nyí tẹ́lẹ̀, a lè fi ìtẹ̀jáde mìíràn tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ lọ̀ wọ́n. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. A lè fi Iwe Itan Bibeli Mi tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni bí àfidípò. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ìjọ bá ní, tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1987.
◼ “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2002” ni àkìbọnú tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí, kí ẹ tọ́jú rẹ̀ kí ẹ lè rí i lò jálẹ̀ ọdún 2002.
◼ Bí àwọn àkókò tí ìjọ yín máa ń ṣe ìpàdé yóò bá yí padà ní January 1, kí akọ̀wé ìjọ fi ìyípadà náà tó ọ́fíìsì ẹ̀ka létí nípa fífi fọ́ọ̀mù Congregation Meeting Information and Handbill Request (S-5) ránṣẹ́ sí ọ́fíìsì ẹ̀ka. Bí ẹ bá ń fẹ́ ìwé ìléwọ́ tuntun, ẹ lè fi fọ́ọ̀mù ọ̀hún kan náà béèrè fún un. Kí ẹ rí i dájú pé ẹ kọ̀wé béèrè fún ìwé ìléwọ́ ní ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ, ó kéré tán, ṣáájú àkókò tí ẹ fẹ́ kó tẹ̀ yín lọ́wọ́.