Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2002
Àwọn Ìtọ́ni
Ní ọdún 2002 àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ètò fún dídarí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.
ÀWỌN ÌWÉ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́: A gbé àwọn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ka Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [bi12-YR], Ilé Ìṣọ́ [w-YR], Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun [kl-YR], àti Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé [fy-YR].
Kí á fi orin, àdúrà, àti ọ̀rọ̀ ìkíni ní ṣókí bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà LÁKÒÓKÒ. Kò pọndandan láti mẹ́nu kan nǹkan tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ. Bí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ti ń nasẹ̀ apá kọ̀ọ̀kan, yóò sọ kókó ọ̀rọ̀ tí a ó sọ̀rọ̀ lé lórí. Tẹ̀ lé ìlànà tó wà nísàlẹ̀ yìí:
Ọ̀RỌ̀ ÌTỌ́NI: Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni kó bójú tó èyí, a ó sì gbé e ka Ilé Ìṣọ́. Kí a ṣe iṣẹ́ yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìtọ́ni oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láìsí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ. Ète rẹ̀ kì í ṣe láti wulẹ̀ kárí ibi tí a yàn fúnni, bí kò ṣe láti pe àfiyèsí sí ìsọfúnni tí a ń jíròrò náà nípa bí ó ṣe wúlò to, kí ó sì ṣàlàyé ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn ni kí á lò.
Àwọn arákùnrin tí a yan iṣẹ́ yìí fún ní láti ṣọ́ra láti má ṣe kọjá àkókò tí a fún wọn. Kí a fún wọn ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́ bó bá pọndandan tàbí bí olùbánisọ̀rọ̀ bá béèrè fún un.
ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ KÍKÀ: Ìṣẹ́jú mẹ́fà. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni kó bójú tó o, kí ó sì mú kí àkójọ ọ̀rọ̀ náà bá àwọn ohun tó ń fẹ́ àfiyèsí nínú ìjọ mu lọ́nà tó gbéṣẹ́. Kò pọndandan pé kó lẹ́ṣin ọ̀rọ̀. Èyí kò kàn ní jẹ́ àkópọ̀ lórí ibi tí a yàn fún kíkà. A lè ṣe àkópọ̀ àlàyé aláàbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan, lórí gbogbo orí tí a yàn. Ṣùgbọ́n, olórí ète náà ni láti ran àwùjọ lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí ìsọfúnni náà fi ṣeyebíye fún wa àti bí ó ti ṣeyebíye tó fún wa. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sọ pé kí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lọ sí kíláàsì wọn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KEJÌ: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Èyí jẹ́ Bíbélì kíkà tó wá látinú ibi tí a yàn, arákùnrin ni yóò sì kà á, ì báà jẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ kìíní tàbí ní ìkejì tó jẹ́ àfikún. Ibi tí a yàn pé kí akẹ́kọ̀ọ́ kà sábà máa ń mọ níwọ̀n tí yóò jẹ́ kó lè ṣe àlàyé ṣókí ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó tún lè sọ ìtàn tó yí àwọn ẹsẹ náà ká, ìjẹ́pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ti ẹ̀kọ́ inú rẹ̀, àti bí àwọn ìlànà rẹ̀ ṣe kàn wá. Kí ó ka gbogbo ẹsẹ tí a yàn fún un pátá láìdánudúró lágbede méjì láti ṣàlàyé ohunkóhun. Àmọ́ ṣá o, níbi tí àwọn ẹsẹ tí yóò kà kò bá ti tẹ̀ léra, akẹ́kọ̀ọ́ náà lè sọ ẹsẹ tí yóò ti máa bá Bíbélì kíkà náà lọ.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸTA: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Arábìnrin ni a óò yan èyí fún. Kókó ọ̀rọ̀ fún iṣẹ́ yìí ni a óò gbé karí ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Akẹ́kọ̀ọ́ lè lo ìgbékalẹ̀ èyíkéyìí tó bá bá ìpínlẹ̀ yín mu, àwọn tí yóò sì kópa nínú rẹ̀ lè jókòó tàbí kí wọ́n dúró. Ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ gbà ṣàlàyé ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn fún un, àti ọ̀nà tó gbà ran onílé lọ́wọ́ láti ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ni yóò jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ. Akẹ́kọ̀ọ́ tí a yan iṣẹ́ yìí fún gbọ́dọ̀ mọ̀wéé kà. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò ṣètò fún olùrànlọ́wọ́ kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n akẹ́kọ̀ọ́ lè lo olùrànlọ́wọ́ mìíràn ní àfikún. Ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí a gbà lo Bíbélì ni kí á fún ní àfiyèsí pàtàkì, kì í ṣe ọ̀nà tí a gbà gbé e kalẹ̀.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸRIN: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Kókó ọ̀rọ̀ fún iṣẹ́ yìí ni a óò gbé karí ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. A lè yan Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin fún arákùnrin tàbí arábìnrin. Ní gbogbo ìgbà tí a bá yàn án fún arákùnrin, àsọyé ni kó jẹ́. Bí a bá yàn án fún arábìnrin, kó sọ ọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àlàyé tí a ṣe fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹta. Ní àfikún sí i, bí a bá fi àmì yìí, #, ṣáájú ẹṣin ọ̀rọ̀ fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin, arákùnrin ni kí á yàn án fún.
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ BÍBÉLÌ KÍKÀ: A fún olúkúlùkù nínú ìjọ níṣìírí pé kí ẹ máa tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, tó túmọ̀ sí pé ẹ óò máa ka nǹkan bí ojú ewé kan lójúmọ́.
ÀKÍYÈSÍ: Fún àfikún ìsọfúnni àti ìtọ́ni lórí ìmọ̀ràn, ìdíwọ̀n àkókò, àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, àti mímúra àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀, jọ̀wọ́ wo ojú ìwé 3 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996.
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ
Jan. 7 Bíbélì kíkà: Oníwàásù 1 sí 6
Orin 59
No. 1: “Bẹru Ọlọrun Tootọ naa Ki O Sì Pa Awọn Òfin-Àṣẹ Rẹ̀ Mọ́”—Apá Kìíní (w87-YR 9/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1)
No. 2: Oníwàásù 4:1-16.
No. 3: Ọlọ́run Fẹ́ Kí O Ní Ọjọ́ Ọ̀la Aláyọ̀ (kl-YR ojú ìwé 6 àti 7 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: #Ìdílé Wà Nínú Ìṣòro (fy-YR ojú ìwé 1 sí 9 ìpínrọ̀ 1 sí 14)
Jan. 14 Bíbélì kíkà: Oníwàásù 7 sí 12
Orin 25
No. 1: “Bẹru Ọlọrun Tootọ naa Ki O Sì Pa Awọn Òfin-Àṣẹ Rẹ̀ Mọ́”—Apá Kejì (w87-YR 9/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2 sí 20)
No. 2: Oníwàásù 8:1-17.
No. 3: Ìyè Àìnípẹ̀kun Nínú Párádísè Kì Í Ṣe Àlá Kan Lásán (kl-YR ojú ìwé 7 sí 9 ìpínrọ̀ 6 sí 10)
No. 4: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 10 sí 12 ìpínrọ̀ 15 sí 23)
Jan. 21 Bíbélì kíkà: Orin Sólómọ́nì 1 sí 8
Orin 11
No. 1: Ìfẹ́ Tòótọ́ Máa Ń Yọ Ayọ̀ Ìṣẹ́gun (w87-YR 11/15 ojú ìwé 24 àti 25)
No. 2: Orin Sólómọ́nì 5:1-16.
No. 3: Bí Ìgbésí Ayé Yóò Ṣe Rí Nínú Párádísè (kl-YR ojú ìwé 9 àti 10 ìpínrọ̀ 11 sí 16)
No. 4: #Ǹjẹ́ O Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó? (fy-YR ojú ìwé 13 sí 15 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
Jan. 28 Bíbélì kíkà: Aísáyà 1 sí 6
Orin 204
No. 1: Ayọ̀ Yíyọ̀ Fáwọn Tí Ń Rìn Nínú Ìmọ́lẹ̀ (w01-YR 3/1 ojú ìwé 12 sí 17)
No. 2: Aísáyà 2:1-17.
No. 3: Ìdí Tí Ìmọ̀ Ọlọ́run Fi Ṣe Pàtàkì (kl-YR ojú ìwé 10 àti 11 ìpínrọ̀ 17 sí 19)
No. 4: Ìdí Tó Fi Yẹ Kí O Mọ Ara Rẹ Kí O sì Jẹ́ kí Ohun Tí Ò Ń Retí Bọ́gbọ́n Mu (fy-YR ojú ìwé 16 sí 18 ìpínrọ̀ 7 sí 10)
Feb. 4 Bíbélì kíkà: Aísáyà 7 sí 11
Orin 89
No. 1: Kòṣeémánìí Lètò Àjọ Jèhófà (w00-YR 1/1 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: Aísáyà 8:1-22.
No. 3: Ìwé Náà Tí Ó Ṣí Ìmọ̀ Ọlọ́run Payá (kl-YR ojú ìwé 12 àti 13 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 4: #Àwọn Ànímọ́ Tí Ó Yẹ Kí O Wò Lára Ẹni Tí O Máa Fẹ́ (fy-YR ojú ìwé 20 sí 22 ìpínrọ̀ 11 sí 15)
Feb. 11 Bíbélì kíkà: Aísáyà 12 sí 19
Orin 177
No. 1: Ojú Wo Lo Fi Ń Wo Ara Rẹ? (w00-YR 1/15 ojú ìwé 20 sí 22)
No. 2: Aísáyà 17:1-14.
No. 3: Ohun Tí Bíbélì Ṣí Payá Nípa Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 13 sí 15 ìpínrọ̀ 7 sí 9)
No. 4: Àwọn Ohun Tó Yẹ Kí O Gbé Yẹ̀ Wò Kí O Tó Jẹ́ Ẹ̀jẹ́ Tó Wà Pẹ́ Títí (fy-YR ojú ìwé 22 sí 24 ìpínrọ̀ 16 sí 19)
Feb. 18 Bíbélì kíkà: Aísáyà 20 sí 26
Orin 225
No. 1: Ní Ìbárẹ́ Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Jèhófà (w00-YR 1/15 ojú ìwé 23 sí 26)
No. 2: Aísáyà 22:1-19.
No. 3: Ìdí Tí O Fi Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Bíbélì (kl-YR ojú ìwé 15 àti 16 ìpínrọ̀ 10 sí 13)
No. 4: #Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́sọ́nà Yín Lọ́lá Kí Ẹ sì Wò Ré Kọjá Ọjọ́ Ìgbéyàwó (fy-YR ojú ìwé 24 sí 26 ìpínrọ̀ 20 sí 23)
Feb. 25 Bíbélì kíkà: Aísáyà 27 sí 31
Orin 192
No. 1: Onínúnibíni Rí Ìmọ́lẹ̀ Ńlá (w00-YR 1/15 ojú ìwé 27 sí 29)
No. 2: Aísáyà 29:1-14.
No. 3: Bíbélì Péye, Ó sì Ṣeé Fọkàn Tẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 14 àti 15)
No. 4: Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Lè Ṣèrànwọ́ fún Ọ Láti Múra Sílẹ̀ fún Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí (fy-YR àpótí àtúnyẹ̀wò lójú ìwé 26)
Mar. 4 Bíbélì kíkà: Aísáyà 32 sí 37
Orin 98
No. 1: Ìforítì Ní Ń Múni Ṣàṣeyọrí (w00-YR 2/1 ojú ìwé 4 sí 6)
No. 2: Aísáyà 33:1-16.
No. 3: Bíbélì Jẹ́ Ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 17 àti 18 ìpínrọ̀ 16 sí 18)
No. 4: #Kọ́kọ́rọ́ Àkọ́kọ́ sí Ìgbéyàwó Wíwà Pẹ́ Títí (fy-YR ojú ìwé 27 sí 29 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
Mar. 11 Bíbélì kíkà: Aísáyà 38 sí 42
Orin 132
No. 1: Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Látọ̀dọ̀ Ìyá Kan (w00-YR 2/1 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: Aísáyà 42:1-16.
No. 3: Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Jésù (kl-YR ojú ìwé 19 sí 21 ìpínrọ̀ 19 àti 20)
No. 4: Kọ́kọ́rọ́ Kejì sí Ìgbéyàwó Wíwà Pẹ́ Títí (fy-YR ojú ìwé 30 àti 31 ìpínrọ̀ 7 sí 10)
Mar. 18 Bíbélì kíkà: Aísáyà 43 sí 47
Orin 160
No. 1: Sá Kúrò Lágbègbè Eléwu (w00-YR 2/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Aísáyà 44:6-20.
No. 3: Máa Yán Hànhàn fún Ìmọ̀ Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 21 àti 22 ìpínrọ̀ 21 sí 23)
No. 4: #Ọkùnrin Gbọ́dọ̀ Lo Ipò Orí Rẹ̀ Bíi ti Kristi (fy-YR ojú ìwé 31 sí 33 ìpínrọ̀ 11 sí 15)
Mar. 25 Bíbélì kíkà: Aísáyà 48 sí 52
Orin 161
No. 1: Agbára Àdúrà (w00-YR 3/1 ojú ìwé 3 àti 4)
No. 2: Aísáyà 49:1-13.
No. 3: Ọlọ́run Tòótọ́ Náà àti Orúkọ Rẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 23 àti 24 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: Ọ̀nà Tí Aya Yóò Gbà Jẹ́ Àṣekún fún Ọkọ Rẹ̀ (fy-YR ojú ìwé 34 àti 35 ìpínrọ̀ 16 sí 19)
Apr. 1 Bíbélì kíkà: Aísáyà 53 sí 59
Orin 210
No. 1: Fífi Ọkàn Tá A Ti Múra Sílẹ̀ Wá Jèhófà (w00-YR 3/1 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Aísáyà 54:1-17.
No. 3: Ìdí Tí Ó Fi Yẹ Kí O Lo Orúkọ Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 24 àti 25 ìpínrọ̀ 6 sí 8)
No. 4: #Ohun Tí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán Túmọ̀ sí Gan-an (fy-YR ojú ìwé 35 sí 38 ìpínrọ̀ 20 sí 26)
Apr. 8 Bíbélì kíkà: Aísáyà 60 sí 66
Orin 111
No. 1: Ìgbàlà Fáwọn Tó Yan Ìmọ́lẹ̀ (w01-YR 3/1 ojú ìwé 17 sí 22)
No. 2: Aísáyà 61:1-11.
No. 3: Bí Jèhófà Ṣe Sọ Orúkọ Rẹ̀ Di Ńlá (kl-YR ojú ìwé 25 sí 27 ìpínrọ̀ 9 sí 13)
No. 4: Àwọn Ìlànà Bíbélì Tí Ó Lè Ṣèrànwọ́ fún Ọ Láti Gbádùn Ìgbéyàwó Aláyọ̀, Tí Ó Wà Pẹ́ Títí (fy-YR àpótí àtúnyẹ̀wò lójú ìwé 38)
Apr. 15 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 1 sí 4
Orin 70
No. 1: Jeremáyà—Aláìgbajúmọ̀ Wòlíì Àwọn Ìdájọ́ Ọlọ́run (w88-YR 4/1 ojú ìwé 10 sí 15)
No. 2: Jeremáyà 2:4-19.
No. 3: Àwọn Ànímọ́ Ọlọ́run Tòótọ́ Náà (kl-YR ojú ìwé 27 àti 28 ìpínrọ̀ 14 sí 16)
No. 4: #Ṣe Bí O Ti Mọ (fy-YR ojú ìwé 39 sí 41 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
Apr. 22 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 5 sí 8
Orin 205
No. 1: Ìdí Tí Aráyé Fi Nílò Olùrànlọ́wọ́ (w00-YR 3/15 ojú ìwé 3 àti 4)
No. 2: Jeremáyà 7:1-20.
No. 3: Jèhófà Ọlọ́run Jẹ́ Aláàánú àti Olóore Ọ̀fẹ́ (kl-YR ojú ìwé 28 àti 29 ìpínrọ̀ 17 sí 19)
No. 4: Títọ́jú Agboolé Jẹ́ Ojúṣe Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 42 sí 44 ìpínrọ̀ 7 sí 11)
Apr. 29 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Bíbélì kíkà: Jeremáyà 9 sí 13
Orin 46
May 6 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 14 sí 18
Orin 224
No. 1: Bí Jésù Kristi Ṣe Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ (w00-YR 3/15 ojú ìwé 5 sí 9)
No. 2: Jeremáyà 17:1-18.
No. 3: Jèhófà Lọ́ra Láti Bínú, Kì Í Ṣe Ojúsàájú, Ó sì Jẹ́ Olódodo (kl-YR ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 20 àti 21)
No. 4: #Ìdí Tí Jèhófà Fi Béèrè Pé Ká Mọ́ Tónítóní (fy-YR ojú ìwé 45 sí 49 ìpínrọ̀ 12 sí 20)
May 13 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 19 sí 23
Orin 73
No. 1: Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà—Ànímọ́ Tó Ń Gbé Àlàáfíà Lárugẹ (w00-YR 3/15 ojú ìwé 21 sí 24)
No. 2: Jeremáyà 19:1-15.
No. 3: Ọ̀kan Ṣoṣo ni Jèhófà Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 30 àti 31 ìpínrọ̀ 22 àti 23)
No. 4: Ohun Tí Gbígbóríyìn Fúnni Látọkànwá àti Ìmoore Lè Ṣe fún Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 49 àti 50 ìpínrọ̀ 21 àti 22)
May 20 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 24 sí 28
Orin 140
No. 1: Ọkùnrin Àwòfiṣàpẹẹrẹ Kan Tó Tẹ́wọ́ Gba Ìbáwí (w00-YR 3/15 ojú ìwé 25 sí 28)
No. 2: Jeremáyà 25:1-14.
No. 3: Jésù Kristi ni Kọ́kọ́rọ́ Náà sí Ìmọ̀ Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 32 àti 33 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 4: #Èrò Bíbélì Nípa Àwọn Ọmọ àti Ojúṣe Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 51 àti 52 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
May 27 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 29 sí 31
Orin 42
No. 1: Báwo Lẹ̀mí Ọlọ́run Ṣe Ń Ṣiṣẹ́ Lónìí? (w00-YR 4/1 ojú ìwé 8 sí 11)
No. 2: Jeremáyà 30:1-16.
No. 3: Mèsáyà Tí A Ṣèlérí Náà (kl-YR ojú ìwé 33 ìpínrọ̀ 4 àti 5)
No. 4: Ohun Tí Ó Túmọ̀ sí Láti Pèsè Ohun Tí Ọmọ Nílò (fy-YR ojú ìwé 53 sí 55 ìpínrọ̀ 6 sí 9)
June 3 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 32 sí 35
Orin 85
No. 1: Rí Ìtùnú Nínú Okun Jèhófà (w00-YR 4/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Jeremáyà 34:1-16.
No. 3: Ìlà Ìdílé Jésù Fi Í Hàn Pé Òun ni Mèsáyà (kl-YR ojú ìwé 33 ìpínrọ̀ 6)
No. 4: #Gbin Òtítọ́ Sínú Ọmọ Rẹ (fy-YR ojú ìwé 55 sí 57 ìpínrọ̀ 10 sí 15)
June 10 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 36 sí 40
Orin 159
No. 1: Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Àwọn Oníwà Ipa Lo Fi Ń Wò Wọ́n? (w00-YR 4/15 ojú ìwé 26 sí 29)
No. 2: Jeremáyà 37:1-17.
No. 3: Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ní Ìmúṣẹ Fi Jésù Hàn Pé Òun ni Mèsáyà (kl-YR ojú ìwé 34 sí 36 ìpínrọ̀ 7 àti 8)
No. 4: Fi Ọ̀nà Jèhófà Kọ́ Ọmọ Rẹ (fy-YR ojú ìwé 58 àti 59 ìpínrọ̀ 16 sí 19)
June 17 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 41 sí 45
Orin 26
No. 1: “Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọkàn-Àyà Rẹ” (w00-YR 5/15 ojú ìwé 20 sí 24)
No. 2: Jeremáyà 41:1-15.
No. 3: Ẹ̀rí Síwájú Sí I Pé Jésù ni Mèsáyà (kl-YR ojú ìwé 36 ìpínrọ̀ 9)
No. 4: #Ìbáwí Lónírúurú Ṣe Pàtàkì (fy-YR ojú ìwé 59 àti 60 ìpínrọ̀ 20 sí 23)
June 24 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 46 sí 49
Orin 15
No. 1: Ìwàláàyè Pípé Kì Í Màá Ṣe Àlá Lásán! (w00-YR 6/15 ojú ìwé 5 sí 7)
No. 2: Jeremáyà 49:1-13.
No. 3: Jèhófà Jẹ́rìí Nípa Ọmọ Rẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 38 ìpínrọ̀ 10 àti 11)
No. 4: Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Ìpalára (fy-YR ojú ìwé 61 sí 63 ìpínrọ̀ 24 sí 28)
July 1 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 50 sí 52
Orin 100
No. 1: Àwọn Ìdájọ́ Ọlọ́run ni A Gbọ́dọ̀ Polongo (w88-YR 4/1 ojú ìwé 21 sí 26)
No. 2: Jeremáyà 50:1-16.
No. 3: Wíwàláàyè Jésù Ṣáájú Dídi Ẹ̀dá Ènìyàn (kl-YR ojú ìwé 39 ìpínrọ̀ 12 sí 14)
No. 4: Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Mú Kí Ọ̀nà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Ṣí Sílẹ̀ (fy-YR ojú ìwé 64 sí 66 ìpínrọ̀ 1 sí 7)
July 8 Bíbélì kíkà: Ìdárò 1 àti 2
Orin 8
No. 1: Jèhófà Ń Fúnni ní Ìrètí Láàárín Ìkárísọ (w88-YR 9/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 5)
No. 2: Ìdárò 1:1-14.
No. 3: Ipa Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Jésù Lórí Ilẹ̀ Ayé (kl-YR ojú ìwé 40 ìpínrọ̀ 15 sí 17)
No. 4: Fi Ìwà Rere àti Àwọn Ohun Tẹ̀mí Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ (fy-YR ojú ìwé 67 sí 70 ìpínrọ̀ 8 sí 14)
July 15 Bíbélì kíkà: Ìdárò 3 sí 5
Orin 145
No. 1: Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó Wà Nínú Ìwé Ìdárò (w88-YR 9/1 àpótí ojú ìwé 27)
No. 2: Ìdárò 3:1-30.
No. 3: Jésù Wà Láàyè, Ó sì Ń Jọba (kl-YR ojú ìwé 41 àti 42 ìpínrọ̀ 18 sí 20)
No. 4: Ìdí Tí Ìbáwí àti Ọ̀wọ̀ Fi Ṣe Pàtàkì (fy-YR ojú ìwé 71 àti 72 ìpínrọ̀ 15 sí 18)
July 22 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 1 sí 6
Orin 94
No. 1: Fetí Sílẹ̀—Ẹ̀ṣọ́ Jèhófà Ń Sọ̀rọ̀! (w88-YR 9/15 ojú ìwé 10 sí 15)
No. 2: Ìsíkíẹ́lì 4:1-17.
No. 3: Ìjọsìn Tí Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà (kl-YR ojú ìwé 43 sí 45 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: Kọ́ Àwọn Ọmọ ní Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Iṣẹ́ àti Eré (fy-YR ojú ìwé 72 sí 75 ìpínrọ̀ 19 sí 25)
July 29 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 7 sí 12
Orin 221
No. 1: Jàǹfààní Látinú Àwọn Àpẹẹrẹ Rere (w00-YR 7/1 ojú ìwé 19 sí 21)
No. 2: Ìsíkíẹ́lì 10:1-19.
No. 3: Ṣíṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 46 àti 47 ìpínrọ̀ 6 sí 10)
No. 4: Ọlọ̀tẹ̀ Ọmọ àti Àwọn Ohun Tó Ń Fà Á (fy-YR ojú ìwé 76 sí 79 ìpínrọ̀ 1 sí 8)
Aug. 5 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 13 sí 16
Orin 106
No. 1: O Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nínú Ayé Oníṣekúṣe (w00-YR 7/15 ojú ìwé 28 sí 31)
No. 2: Ìsíkíẹ́lì 13:1-16.
No. 3: Jọ́sìn Ọlọ́run ní Ọ̀nà Rẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 47 àti 48 ìpínrọ̀ 11 sí 13)
No. 4: #Má Ṣe Gbọ̀jẹ̀gẹ́ Má sì Le Koko Jù (fy-YR ojú ìwé 80 àti 81 ìpínrọ̀ 9 sí 13)
Aug. 12 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 17 sí 20
Orin 214
No. 1: Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Bọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ? (w00-YR 8/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Ìsíkíẹ́lì 17:1-18.
No. 3: Ṣọ́ra fún Mímú Ọlọ́run Bínú (kl-YR ojú ìwé 49 àti 50 ìpínrọ̀ 14 sí 17)
No. 4: Pípèsè Àwọn Ohun Pàtàkì Tí Ọmọ Nílò Lè Dènà Ọ̀tẹ̀ (fy-YR ojú ìwé 82 sí 84 ìpínrọ̀ 14 sí 18)
Aug. 19 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 21 sí 23
Orin 86
No. 1: Báwo Lo Ṣe Ń Yanjú Aáwọ̀? (w00-YR 8/15 ojú ìwé 23 sí 25)
No. 2: Ìsíkíẹ́lì 22:1-16.
No. 3: Pa Àwọn Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Gíga Ọlọ́run Mọ́ (kl-YR ojú ìwé 50 àti 51 ìpínrọ̀ 18 àti 19)
No. 4: #Àwọn Ọ̀nà Tí A Lè Gbà Ran Ọmọ Tó Ṣàṣìṣe Lọ́wọ́ (fy-YR ojú ìwé 85 sí 87 ìpínrọ̀ 19 sí 23)
Aug. 26 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 24 sí 28
Orin 18
Sept. 2 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 29 sí 32
Orin 40
No. 1: Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Ní Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ? (w00-YR 9/15 ojú ìwé 21 sí 24)
No. 2: Ìsíkíẹ́lì 30:1-19.
No. 3: Jọ́sìn Jèhófà Tọkàntọkàn (kl-YR ojú ìwé 51 àti 52 ìpínrọ̀ 20 sí 22)
No. 4: #Bíbá Ọlọ̀tẹ̀ Paraku Lò (fy-YR ojú ìwé 87 sí 89 ìpínrọ̀ 24 sí 27)
Sept. 9 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 33 sí 36
Orin 49
No. 1: Bí O Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run (w00-YR 10/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Ìsíkíẹ́lì 33:1-16.
No. 3: A Kò Dá Èèyàn Láti Máa Kú (kl-YR ojú ìwé 53 sí 55 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 4: Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Àwọn Ìdarí Apanirun (fy-YR ojú ìwé 90 sí 92 ìpínrọ̀ 1 sí 7)
Sept. 16 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 37 sí 40
Orin 34
No. 1: Kí Lo Fi Ń Díwọ̀n Àṣeyọrí? (w00-YR 11/1 ojú ìwé 18 sí 21)
No. 2: Ìsíkíẹ́lì 39:1-16.
No. 3: Ìdìmọ̀lù Ibi Kan (kl-YR ojú ìwé 55 àti 56 ìpínrọ̀ 4 sí 7)
No. 4: #Èrò Ọlọ́run Nípa Ìbálòpọ̀ (fy-YR ojú ìwé 92 sí 94 ìpínrọ̀ 8 sí 13)
Sept. 23 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 41 sí 45
Orin 50
No. 1: Fi Ẹ̀mí Ìmúratán Sin Ọlọ́run (w00-YR 11/15 ojú ìwé 21 sí 23)
No. 2: Ìsíkíẹ́lì 42:1-20.
No. 3: Ọ̀nà Tí Sátánì Gbà Gbé Rìkíṣí Rẹ̀ Kalẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 56 sí 58 ìpínrọ̀ 8 sí 12)
No. 4: Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Yan Ọ̀rẹ́ Tó Dára (fy-YR ojú ìwé 95 àti 96 ìpínrọ̀ 14 sí 18)
Sept. 30 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 46 sí 48
Orin 112
No. 1: ‘Wọn Yóò Ní Láti Mọ̀ Pé Èmi ni Jèhófà’ (w88-YR 9/15 ojú ìwé 22 sí 27)
No. 2: Ìsíkíẹ́lì 46:1-15.
No. 3: Bí Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú Ṣe Gbilẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 58 àti 59 ìpínrọ̀ 13 sí 15)
No. 4: #Yíyan Eré Ìnàjú Tó Gbámúṣé fún Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 97 sí 102 ìpínrọ̀ 19 sí 27)
Oct. 7 Bíbélì kíkà: Dáníẹ́lì 1 sí 4
Orin 10
No. 1: Máa Fiyè sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run fún Ọjọ́ Wa (w00-YR 5/15 ojú ìwé 10 sí 14)
No. 2: Dáníẹ́lì 1:1-17.
No. 3: Ṣọ́ra fún Àwọn Ọgbọ́n Ẹ̀wẹ́ Sátánì (kl-YR ojú ìwé 59 àti 60 ìpínrọ̀ 16 sí 18)
No. 4: Ìjìnlẹ̀ Òye Ìwé Mímọ́ fún Àwọn Ìdílé Olóbìí Kan (fy-YR ojú ìwé 103 sí 105 ìpínrọ̀ 1 sí 8)
Oct. 14 Bíbélì kíkà: Dáníẹ́lì 5 sí 8
Orin 191
No. 1: Ṣe Gbogbo Ìgbà Ló Yẹ Kí O Gba Ohun Tí Àwọn “Ọlọgbọ́n” Èèyàn Sọ Gbọ́? (w00-YR 12/1 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Dáníẹ́lì 5:1-16.
No. 3: Ní Ìgbàgbọ́ Kí O sì Múra Sílẹ̀ De Àtakò (kl-YR ojú ìwé 60 àti 61 ìpínrọ̀ 19 sí 21)
No. 4: Ìṣòro Tí Òbí Anìkàntọ́mọ Máa Ń Dojú Kọ Láti Gbọ́ Bùkátà (fy-YR ojú ìwé 105 sí 107 ìpínrọ̀ 9 sí 12)
Oct. 21 Bíbélì kíkà: Dáníẹ́lì 9 sí 12
Orin 108
No. 1: Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run! (w00-YR 5/15 ojú ìwé 15 sí 19)
No. 2: Dáníẹ́lì 10:1-21.
No. 3: Ohun Tí Ọlọ́run Ti Ṣe Láti Gba Aráyé Là (kl-YR ojú ìwé 62 àti 63 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: Pípèsè Ìbáwí Nínú Ilé Olóbìí Kan (fy-YR ojú ìwé 107 sí 109 ìpínrọ̀ 13 sí 17)
Oct. 28 Bíbélì kíkà: Hóséà 1 sí 14
Orin 23
No. 1: Jèhófà Ọlọ́run Wa Jẹ́ Aláàánú (w89-YR 3/1 ojú ìwé 14 àti 15)
No. 2: Hóséà 4:1-19.
No. 3: Ìdí Tí Mèsáyà Yóò Fi Kú (kl-YR ojú ìwé 63 sí 65 ìpínrọ̀ 6 sí 11)
No. 4: Ṣíṣẹ́gun Ìnìkanwà (fy-YR ojú ìwé 110 sí 113 ìpínrọ̀ 18 sí 22)
Nov. 4 Bíbélì kíkà: Jóẹ́lì 1 sí 3
Orin 166
No. 1: Ké Pe Orúkọ Jèhófà Kí O sì Rí Ìgbàlà! (w89-YR 3/15 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: Jóẹ́lì 1:1-20.
No. 3: Bí A Ṣe San Ìràpadà Náà (kl-YR ojú ìwé 65 sí 68 ìpínrọ̀ 12 sí 16)
No. 4: #Bí A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Ìdílé Olóbìí Kan (fy-YR ojú ìwé 113 sí 115 ìpínrọ̀ 23 sí 27)
Nov. 11 Bíbélì kíkà: Ámósì 1 sí 9
Orin 80
No. 1: Ìparun Orílẹ̀-Èdè Kan (w89-YR 4/1 ojú ìwé 22 àti 23)
No. 2: Ámósì 1:1-15.
No. 3: Ìwọ àti Ìràpadà Kristi (kl-YR ojú ìwé 68 àti 69 ìpínrọ̀ 17 sí 20)
No. 4: #Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Níní Èrò Ọlọ́run Nígbà Tí A Bá Kojú Àìsàn (fy-YR ojú ìwé 116 sí 119 ìpínrọ̀ 1 sí 9)
Nov. 18 Bíbélì kíkà: Ọbadáyà 1 sí Jónà 4
Orin 96
No. 1: Àwọn Ìkìlọ̀ Àtọ̀runwá Tí Ó Kàn Ọ́ (w89-YR 4/15 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: Ọbadáyà 1:1-16.
No. 3: Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fa Ìyà Tó Ń Jẹ Àwọn Èèyàn? (kl-YR ojú ìwé 70 sí 72 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: Ìwúlò Ẹ̀mí Tí Ń Woni Sàn (fy-YR ojú ìwé 120 àti 121 ìpínrọ̀ 10 sí 13)
Nov. 25 Bíbélì kíkà: Míkà 1 sí 7
Orin 138
No. 1: A Gbé Ìdájọ́ Òdodo àti Orúkọ Jèhófà Ga (w89-YR 5/1 ojú ìwé 14 àti 15)
No. 2: Míkà 1:1-16.
No. 3: Ìbẹ̀rẹ̀ Pípé Kan àti Ìpèníjà Onínú Burúkú (kl-YR ojú ìwé 72 àti 73 ìpínrọ̀ 6 sí 10)
No. 4: Gbé Àwọn Ohun Àkọ́múṣe Kalẹ̀ Kí O sì Ran Àwọn Ọmọ Lọ́wọ́ Láti Kojú Àmódi Nínú Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 122 àti 123 ìpínrọ̀ 14 sí 18)
Dec. 2 Bíbélì kíkà: Náhúmù 1 sí Hábákúkù 3
Orin 137
No. 1: Ìgbàlà Ṣeé Ṣe Nígbà Tí Ọlọ́run Bá Gbẹ̀san (w89-YR 5/15 ojú ìwé 24 àti 25)
No. 2: Náhúmù 3:1-19.
No. 3: Àwọn Ọ̀ràn Àríyànjiyàn Náà Gan-an àti Ọ̀nà Tí Jèhófà Yóò Gbà Yanjú Wọn (kl-YR ojú ìwé 74 sí 76 ìpínrọ̀ 11 sí 15)
No. 4: #Ojú Tí Ó Yẹ Kí Á Fi Wo Ìtọ́jú Ìṣègùn (fy-YR ojú ìwé 124 sí 127 ìpínrọ̀ 19 sí 23)
Dec. 9 Bíbélì kíkà: Sefanáyà 1 sí Hágáì 2
Orin 146
No. 1: Wá Jèhófà Kí O sì Sìn Ín Tọkàntọkàn (w89-YR 6/1 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: Sefanáyà 2:1-15.
No. 3: Ẹ̀rí Tí Fífàyè Tí Ọlọ́run Fàyè Gbà Ìwà Ibi Fi Hàn (kl-YR ojú ìwé 76 àti 77 ìpínrọ̀ 16 sí 19)
No. 4: Báwo Ni Aya Kan Tó Jẹ́ Onígbàgbọ́ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Jọba Nínú Agboolé Tí Wọn Kò Ti Jẹ́ Ẹlẹ́sìn Kan Náà? (fy-YR ojú ìwé 128 sí 132 ìpínrọ̀ 1 sí 9)
Dec. 16 Bíbélì kíkà: Sekaráyà 1 sí 8
Orin 1
No. 1: Jèhófà Ru Ẹ̀mí Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Sókè (w89-YR 6/15 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: Sekaráyà 6:1-15.
No. 3: Ìhà Ọ̀dọ̀ Ta Lo Wà? (kl-YR ojú ìwé 78 àti 79 ìpínrọ̀ 20 sí 23)
No. 4: #Báwo Ni Ọkọ Kan Tó Jẹ́ Onígbàgbọ́ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Jọba Nínú Agboolé Tí Wọn Kò Ti Jẹ́ Ẹlẹ́sìn Kan Náà? (fy-YR ojú ìwé 132 ìpínrọ̀ 10 àti 11)
Dec. 23 Bíbélì kíkà: Sekaráyà 9 sí 14
Orin 176
No. 1: Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó Wà Nínú Ìwé Sekaráyà (w89-YR 6/15 àpótí ojú ìwé 31)
No. 2: Sekaráyà 9:1-17.
No. 3: Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Èèyàn Wa Tí Wọ́n Ti Kú? (kl-YR ojú ìwé 80 sí 82 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 4: Fífi Ìwé Mímọ́ Kọ́ Àwọn Ọmọ Nínú Agboolé Tí Wọn Kò Ti Jẹ́ Ẹlẹ́sìn Kan Náà (fy-YR ojú ìwé 133 àti 134 ìpínrọ̀ 12 sí 15)
Dec. 30 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Bíbélì kíkà: Málákì 1 sí 4
Orin 118