Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù November: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí àwọn èèyàn bá ti ní ìwọ̀nyí tẹ́lẹ̀, a lè fi ìtẹ̀jáde mìíràn tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ ju tàwọn tá a dárúkọ yìí lọ̀ wọ́n. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. A lè fi Iwe Itan Bibeli Mi tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni bí àfidípò. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ìjọ bá ní, tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1987. February: Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀, tàbí ìwé olójú ewé 192 mìíràn tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ ju èyí tá a dárúkọ yìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní December 1, tàbí bó bá ṣe lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tó tẹ̀ lé e.
◼ Kì í ṣe ọ́fíìsì ẹ̀ka ló ń kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò fún ìfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ìjọ lóṣooṣù ránṣẹ́ sí ọ́fíìsì ẹ̀ka, kí olúkúlùkù ẹni tó bá fẹ́ láti gba ìwé tirẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rántí pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tó jẹ́ ìbéèrè àkànṣe.