ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/01 ojú ìwé 3
  • Máa Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 11/01 ojú ìwé 3

Máa Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ

1 Jésù Kristi pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa wàásù “ìhìn rere ìjọba” náà. (Mát. 24:14) Ọ̀pọ̀ akéde ìhìn rere ló wà tó jẹ́ pé kò tíì pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀, wọ́n sì lè máà fi bẹ́ẹ̀ nírìírí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ṣé ìwọ náà jẹ́ ọ̀kan lára wọn? Báwo lo ṣe lè tẹ̀ síwájú kí o bàa lè ‘ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ yanjú’?—2 Tím. 4:5.

2 Ní Ẹ̀mí Tó Dára: Máa wo iṣẹ́ ìwàásù pé “ìṣúra” ló jẹ́, àǹfààní sì tún ni pẹ̀lú. (2 Kọ́r. 4:7) Nígbà tí a bá kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, a ń fi ìfẹ́, ìdúróṣinṣin àti ìwà títọ́ wa sí Jèhófà hàn. A tún ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àtọkànwá sí aládùúgbò wa. (Lúùkù 10:27) Jésù Kristi, Àwòkọ́ṣe wa, ní ẹ̀mí tó dára nípa iṣẹ́ ìwàásù. Ó láàánú àwọn èèyàn, gbogbo ìgbà ló sì fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Mát. 8:3) Ó yẹ kí o fara wé Jésù Kristi, kí o máa fẹ́ láti kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ yìí bí ìlera àti ipò rẹ bá ṣe gbà ọ́ láyè tó.

3 Borí Ìtìjú: Ó ṣeé ṣe kí ojú máa ti ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ àti àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde ìhìn rere náà. Ṣùgbọ́n a lè borí ìtìjú. Ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ nígbà kan rí nípa ara rẹ̀ pé: “Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀dọ́langba, ojú máa ń tì mí púpọ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ìtìjú yìí fi jẹ́ ohun ìdènà fún mi, pàápàá nígbà tó bá di pé kí n fi ìgbàgbọ́ mi hàn nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà.” Báwo ló ṣe borí ìṣòro yìí? Ó sọ pé: “Kò sígbà kan tí Jèhófà sọ pé kí ẹnikẹ́ni lára wa ṣe nǹkan kan tó mọ̀ pé a kò ní lè ṣe. Ṣùgbọ́n, agbára rẹ̀ ló ń jẹ́ ká lè ṣe ohun tó bá sọ pé ká ṣe. Ohun mìíràn sì ni pé, bí o bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ ní tòótọ́, wọn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ wọn yóò sì tì ọ́ lẹ́yìn.” Dájúdájú, bíbá àwọn akéde tó nírìírí nínú ìjọ ṣiṣẹ́ déédéé jẹ́ ìrànwọ́ ńláǹlà láti borí ìtìjú.

4 Mú Kí Òye Rẹ Nípa Iṣẹ́ Ìwàásù Túbọ̀ Pọ̀ Sí I: Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn máa ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa lápá ibẹ̀ yẹn. Fífi àwọn ohun tí o ń kọ́ nínú àwọn ìpàdé wọ̀nyí sílò lè mú kí o tètè tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ní àwọn ìpàdé wọ̀nyí, a sábà máa ń dábàá pé ká máa ṣe ìdánrawò láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Irú ìdánrawò bẹ́ẹ̀ yóò mú kí ọ̀rọ̀ túbọ̀ yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu, yóò mú kí o túbọ̀ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, yóò sì mú kí o túbọ̀ ní ìgboyà. Bí ó ṣe sábà máa ń rí, bí a bá ṣe jáfáfá tó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, bẹ́ẹ̀ náà la ó ṣe máa gbádùn rẹ̀ tí a ó sì máa ṣàṣeyọrí tó.

5 Gbàdúrà sí Jèhófà: Nígbà tá a bá ti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti borí àwọn ohun tó lè dènà ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí wa, a ní láti gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí. (1 Jòh. 5:14, 15) Ó máa ń fún wa ní agbára tó kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.—2 Kọ́r. 4:7.

6 Dájúdájú, ìtẹ̀síwájú tí o bá ní yóò jẹ́ kí ìdùnnú àti ayọ̀ rẹ máa bá a lọ nísinsìnyí. Yàtọ̀ sí ìyẹn, yóò tún jẹ́ kí o rí àyè nínú ayé tuntun Ọlọ́run, níbi tí wàá ti máa tẹ̀ síwájú títí ayé lábẹ́ Ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́