ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/02 ojú ìwé 2-7
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 9
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 16
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 23
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 30
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 7
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 9/02 ojú ìwé 2-7

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

ÀKÍYÈSÍ: Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yóò ṣètò Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní àwọn oṣù àpéjọ àgbègbè. Kí àwọn ìjọ ṣe àyípadà tó bá yẹ láti fàyè sílẹ̀ fún lílọ sí Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run.” Níbi tó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, ẹ lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó kẹ́yìn kí ẹ tó lọ sí àpéjọ náà láti ṣàtúnsọ àwọn ìmọ̀ràn pàtàkì tí ó wúlò fún ìjọ yín nínú àkìbọnú ti oṣù yìí. Ní oṣù February 2003, a ó ṣètò odindi Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kan láti fi gbé àwọn kókó pàtàkì inú àpéjọ náà yẹ̀ wò. Láti múra sílẹ̀ fún ìjíròrò yẹn, gbogbo wa lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn kókó tá a gbádùn ní àpéjọ, lára ohun tá a sì lè kọ ni àwọn kókó pàtàkì tí àwa fúnra wa fẹ́ fi sílò nínú ìgbésí ayé wa àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Nípa bẹ́ẹ̀, a ó lè ṣàlàyé bí a ti ṣe fi àwọn ìmọ̀ràn wọ̀nyẹn sílò látìgbà tá a ti dé láti àpéjọ náà. Fífetí sí bí ẹnì kìíní kejì ṣe jàǹfààní látinú ìtọ́ni àtàtà tí a rí gbà yóò gbé gbogbo wa ró lápapọ̀.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 9

Orin 209

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ September 15 àti Jí! October 8 lọni. Lo àbá àkọ́kọ́ tó wà ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! October 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, fi hàn bí a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, irú bí “Èmi kò nífẹ̀ẹ́ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 9.

15 min: “A Óò Rí Àkànṣe Ìṣírí Gbà.” Àsọyé. Jẹ́ kí àwọn ará mọyì ìjẹ́pàtàkì lílọ sí àpéjọ àgbègbè. Rọ gbogbo àwọn àwùjọ láti pésẹ̀ fún gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, láti òwúrọ̀ Friday títí di ọ̀sán Sunday.

15 min: ‘Ẹ Máa Lépa Ohun Rere Nígbà Gbogbo.’a Tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì láti tẹ̀ lé àwọn ìṣètò ilé gbígbé tí wọ́n ti ṣe fún àǹfààní wa. Tẹnu mọ́ àwọn ìránnilétí mẹ́rin tó wà ní ìpínrọ̀ 2. Ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí olúkúlùkù wa máa hùwà tó dára.

Orin 115 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 16

Orin 163

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.

15 min: “Bí A Ṣe Lè Rí Ìtẹ́lọ́rùn Nípa Tẹ̀mí Gbà.” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Jíròrò àwọn ìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa fetí sílẹ̀ dáadáa sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè náà. Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì fífi àwọn ohun tá a kẹ́kọ̀ọ́ sílò dípò wíwulẹ̀ gbọ́ ọ sétí lásán. Jíròrò àlàyé tá a ṣe níbẹ̀rẹ̀ ojú ìwé yìí nípa ohun tí a ṣètò láti ṣe nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lóṣù February 2003, nígbà tí a óò ṣàgbéyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì tá a gbádùn ní àpéjọ àgbègbè. Rọ gbogbo àwùjọ láti ṣàkọsílẹ̀. Ké sí àwọn ará díẹ̀ láti sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọdún tó kọjá.

20 min: “Wíwọṣọ àti Mímúra ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.”b Kí alàgbà kan bójú tó o, kí ó máa ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan lẹ́yìn tó bá ti jíròrò rẹ̀. Jẹ́ kí gbogbo àwọn ará mọrírì ìdí tó fi yẹ ká kíyè sára nípa ìwọṣọ àti ìmúra wa ní gbangba.

Orin 169 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 23

Orin 107

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, jẹ́ kí alàgbà kan ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ October 1 lọni, kí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan sì fi hàn bí a ṣe lè fi Jí! October 8 lọni. Lo àbá kejì tó wà ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! October 8 lọni. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, tún gbólóhùn kan tàbí méjì tí wọ́n kọ́kọ́ lò nínú àṣefihàn náà sọ, èyí tó mú kí onílé fẹ́ láti tẹ́tí sí wọn.

20 min: “Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Yin Jèhófà Lógo.”c

15 min: Dídúró Ṣinṣin Lórí Òtítọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀dọ́ akéde kan tàbí méjì lẹ́nu wò tí wọ́n ti wọlé padà sí ilé ẹ̀kọ́, tí wọ́n wá rí i pé ó yẹ kí àwọn dín bí àwọn ṣe ń ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí kù. Báwo ni wọ́n ṣe múra sílẹ̀ láti kojú àwọn ìpèníjà àtàwọn ohun tó ń fani mọ́ra, irú bí àwọn ayẹyẹ tó ń gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lárugẹ, lílọ síbi ijó àti àpérò ilé ẹ̀kọ́, ṣíṣe àwọn eré ìdárayá ilé ẹ̀kọ́, àtàwọn ìwà àìmọ́ mìíràn gbogbo? Sọ pé kí wọ́n tún ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń múra sílẹ̀ láti jẹ́rìí ní ilé ẹ̀kọ́.

Orin 171 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 30

Orin 116

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù September sílẹ̀.

10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

15 min: Kí Ló Mú Káwọn Ìwé Ìròyìn Wa Jẹ́ Àkànṣe? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ní oṣù October, a ó fi Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Jíròrò àwọn ìdí tí àwọn ìwé ìròyìn wa fi jẹ́ àkànṣe: (1) Wọ́n ń gbé orúkọ Jèhófà ga. (2) Wọ́n ń fúnni níṣìírí láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù. (3) Wọ́n ń polongo Ìjọba Ọlọ́run. (4) Wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn rí i kedere pé ohun tí Bíbélì bá sọ labẹ gé. (5) Wọ́n ń ṣàlàyé bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń nímùúṣẹ. (6) Wọ́n ń ṣàlàyé ohun tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé túmọ̀ sí ní ti gidi. (7) Wọ́n ń fi bí a ṣe lè kápá àwọn ìṣòro òde òní hàn. (8) Gbogbo èèyàn lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan ló máa ń fẹ́ láti kà wọ́n. (9) Wọn kì í dá sí ọ̀ràn ìṣèlú. Ṣe àwọn àṣefihàn kúkúrú méjì, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn fi hàn bí a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú èyíkéyìí lára àwọn kókó wọ̀nyí.

15 min: “Máa Náání Àwọn Ohun Ìní Ètò Àjọ Ọlọ́run.”d Kí alàgbà kan bójú tó o. Ṣe àlàyé síwájú sí i nípa àwọn àkíyèsí tí a ti ṣe nípa bí àwọn ará ṣe ń lo àwọn ìtẹ̀jáde wa, àti ohun tí gbogbo wa lè ṣe láti fi ọgbọ́n lò wọ́n. Rọ̀ wọ́n láti dín iye àwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n máa ń béèrè fún kù sí kìkì àwọn tí wọ́n dìídì nílò. Kí gbogbo wa rántí pé a láǹfààní láti fowó ṣètọrẹ láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé.—Wo àpilẹ̀kọ náà, “Máa Ṣàjọpín Nǹkan Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn Gẹ́gẹ́ Bí Wọ́n Ṣe Nílò Rẹ̀,” tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 2000, ojú ìwé 3.

Orin 21 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 7

Orin 129

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: Báwo La Ṣe Ṣe sí Lọ́dún Tó Kọjá? Àsọyé tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn yóò sọ. Mẹ́nu kan díẹ̀ lára ibi tí a ti ṣe dáradára nínú ìròyìn ìjọ fún ọdún iṣẹ́ ìsìn 2002. Gbóríyìn fún gbogbo àwọn ará fún àwọn ohun rere tí ìjọ ti ṣe. Pe àfiyèsí sí àwọn ìsapá tí ìjọ ṣe ní ti wíwá sí ìpàdé, ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, kí o sì sọ àwọn ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tó lè ṣèrànwọ́ fún gbogbo wa láti túbọ̀ tẹ̀ síwájú. Kí a gbé àwọn góńgó tí ọwọ́ wa lè tẹ̀ kalẹ̀ fún ọdún tó ń bọ̀.

20 min: “Yẹra fún Lílépa ‘Àwọn Ohun Tí Kò Ní Láárí.’”e Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 4, fi àlàyé kún un látinú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1999, ìpínrọ̀ 30 sí 32. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, fi àlàyé kún un látinú àpótí tó wà nínú Ilé-ìṣọ́nà October 1, 1994, ojú ìwé 8. Tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 6, ka ìpínrọ̀ 18 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1999.

Orin 105 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́