Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àtúnyẹ̀wò tá a máa ṣe láìṣíwèéwò lórí àwọn ẹ̀kọ́ tá a ti kọ́ nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run láwọn ọ̀sẹ̀ September 2 sí December 23, 2002. Lo abala bébà ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Ìwádìí tìrẹ fúnra rẹ ni àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn ní gbogbo àwọn ibi tá a ti tọ́ka sí Ilé Ìṣọ́.]
Dáhùn Bẹ́ẹ̀ ni tàbí Bẹ́ẹ̀ kọ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
1. Ṣíṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ Jèhófà jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì kan láti sún mọ́ ọn. (Sm. 143:5) [w00-YR 10/15 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 6]
2. Síso igi méjì pọ̀, èyí tá a mẹ́nu kàn nínú Ìsíkíẹ́lì 37:15-24, ní aláfijọ òde òní, ni ti pé, lọ́dún 1919, àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ ni a mú ṣọ̀kan lábẹ́ Kristi, “ọba [wọn] kan ṣoṣo” àti “olùṣọ́ àgùntàn [wọn] kan ṣoṣo.” [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 9/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 13.]
3. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ Bíbélì sọ pé kò sí ohun tó ń jẹ́ ìwé Dáníẹ́lì nínú ìtàn, àwárí àwọn awalẹ̀pìtàn bí ọdún ṣe ń gorí ọdún ti pa wọ́n lẹ́nu mọ́ pátápátá. [w00-YR 5/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 12]
4. Nígbà tá a bá gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́nu ẹnì kan tó jọ pé kò ṣeé jà níyàn tàbí ẹnì kan tó sọ pé òún ní ìmọ̀ jù wá lọ, kò sí ìdí kankan tó fi yẹ ká kọ ọ̀rọ̀ náà pé kì í ṣòótọ́. [w00-YR 12/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 7 àti 8]
5. Jèhófà kì í fi àánú hàn sí àwọn tó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo. [w89-YR 3/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 5 àti 6]
6. Nígbà tí Ọlọ́run pe Ámósì láti ṣe iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo èèyàn, olùtọ́jú àgùntàn ni, ó sì tún ń ṣe iṣẹ́ kan tí kò jọjú láwọn ìgbà kan nínú ọdún, ìyẹn iṣẹ́ jíjá èso lórí igi àjàrà. (Ámósì 7:14, 15) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo si-E ojú ìwé 148 ìpínrọ̀ 1]
7. Ìwé Ọbadáyà ẹsẹ 16 sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé gbogbo àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Édómù ni a óò pa run nítorí ìkórìíra tí wọ́n ní fún àwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà. (Ọbad. 12) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 4/15 ojú ìwé 30, àpótí.]
8. Níní òye kíkún nípa òtítọ́ Ọlọ́run àtàwọn ète rẹ̀ jẹ́ ara “èdè mímọ́ gaara” tá a mẹ́nu kàn nínú Sefanáyà 3:9. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w01-YR 2/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 18.]
9. Ohun tó mú kí Jésù ní ẹ̀dùn ọkàn tó lé kenkà nínú ọgbà Gẹtisémánì ni pé, bí ikú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn tá a tẹ́ńbẹ́lú ṣe máa rí lára Jèhófà àti ipa tó máa ní lórí orúkọ mímọ́ Rẹ̀ ń ká a lára gan-an. (Mát. 26:38; Lúùkù 22:44) [w00-YR 11/15 ojú ìwé 23, ìpínrọ̀ 1]
10. “Filísínì” náà tó wá “dà bí séríkí ní Júdà,” gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà 9:6, 7, dúró fún àwọn kan lára àwọn àgùntàn mìíràn ti ọjọ́ òní, tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” dá lẹ́kọ̀ọ́ tí ó sì ń fún wọn ní ọlá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti nílò rẹ̀. (Mát. 24:45) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 7/1 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 14.]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:
11. Báwo la ṣe lè fi ẹrù iṣẹ́ wa láti wàásù wé ẹrù iṣẹ́ Ìsíkíẹ́lì tí í ṣe olùṣọ́? (Ìsík. 33:1-11) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 1/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 13.]
12. Ohun tó jọra pẹ̀lú àwọn egungun gbígbẹ inú ìran Ìsíkíẹ́lì wo la rí tó ṣẹlẹ̀ lóde òní? (Ìsík. 37:5-10) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 9/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 12.]
13. Kí nìdí tí Jèhófà fi gbé wòlíì Sekaráyà dìde? [w89-YR 6/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1]
14. Kí ni ìlú tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran dúró fún? (Ìsík. 48:15-17) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-YR 3/1 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 22.]
15. Àwọn ààlà wo ló yẹ kí àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ máa kíyè sí nígbà gbogbo? [fy-YR ojú ìwé 106 ìpínrọ̀ 11]
16. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ohun tí Dáníẹ́lì ṣe nígbà tí ọba ṣòfin pé kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ ṣe ìtọrọ lọ́wọ́ ọlọ́run èyíkéyìí tàbí èèyàn kankan yàtọ̀ sí ọba fún ọgbọ̀n ọjọ́? (Dán. 6:7-10) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo dp-YR ojú ìwé 125 ìpínrọ̀ 25 sí ojú ìwé 126 ìpínrọ̀ 28.]
17. Nínú pípolongo ìhìn Jèhófà wo ni àwọn àṣẹ́kù ti dà bíi kìnnìún láàárín àwọn orílẹ̀-èdè? (Míkà 5:8) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w82-YR 3/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 10.]
18. Nínú Hábákúkù 3:14, kí ni gbólóhùn náà, “o fi àwọn ọ̀pá tirẹ̀ gún orí àwọn jagunjagun rẹ̀,” túmọ̀ sí? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w00-YR 2/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 15; w82-YR 8/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 3 àti 4.]
19. Nínú Sefanáyà 2:3, kí ni ọ̀rọ̀ náà “bóyá,” túmọ̀ sí? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w01-YR 2/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 8.]
20. Gẹ́gẹ́ bí Sekaráyà 8:6 ti sọ, láti ọdún 1919, ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà ṣàṣeparí ohun tó ti lè dà bíi pé ó ṣòro gan-an lójú ẹ̀dá èèyàn? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 1/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 18 àti 19.]
Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tó yẹ kó wà ní àlàfo inú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
21. À ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ __________________________, ìyẹn ni fífi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀; ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀nà pàtàkì tó ń gbà bá wa sọ̀rọ̀ jẹ́ nípasẹ̀ __________________________. (Sm. 65:2; 2 Tím. 3:16) [w00-YR 10/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 2 àti 3]
22. Nígbà tí àwọn tó kọ Bíbélì bá ń tọ́ka sí àwọn Kristẹni gẹ́gẹ́ bí ẹrú Ọlọ́run, kì í ṣe fífi agbára __________________________ ni wọ́n ń tọ́ka sí; ohun tó túmọ̀ sí ni yíyọ̀ǹda ara ẹni __________________________, èyí tó sinmi lórí ìfẹ́ àtọkànwá fún Ọlọ́run àti ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. (Mát. 22:37; 2 Kọ́r. 5:14) [w00-YR 11/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 6]
23. “Ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́” ṣẹlẹ̀ ní ọdún __________________________, ó sì sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin ti àwọn ọdún, èyí tó wá sópin nígbà tí Mèsáyà náà fara hàn ní ọdún __________________________. (Dán. 9:25) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo dp-YR ojú ìwé 190 ìpínrọ̀ 20 sí ojú ìwé 191 ìpínrọ̀ 22.]
24. Ó yẹ kí mímọ̀ tá a mọ̀ pé ọjọ́ __________________________ Jèhófà ti ń sún mọ́lé sún wa láti máa __________________________ ká sì máa ṣe __________________________. [w89-YR 3/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 5]
25. Nínú ọ̀rọ̀ tá a kéde lé __________________________ tí í ṣe olú-ìlú Ásíríà lórí, __________________________ fi hàn pé ẹ̀san Ọlọ́run ń bọ̀ lórí àwọn ọ̀tá tí wọn kò fún Un ní ìjọsìn tá a yà sọ́tọ̀ gédégbé. [w89-YR 5/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 3]
Mú ìdáhùn tó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó wà nísàlẹ̀ yìí:
26. Ní ọdún (1914; 1919; 1935), Jèhófà fi “olùṣọ́ àgùntàn kan,” Jésù Kristi, ṣe olórí ìyókù àwọn ẹni àmì òróró. [w88-YR 9/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 8]
27. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí àwọn agbára ayé ṣe ń yọjú ní ìtòtẹ̀léra àti nípa ohun tí díẹ̀ lára àwọn alákòóso wọn yóò ṣe jẹ́ apá pàtàkì lára ìwé (Aísáyà; Ìsíkíẹ́lì; Dáníẹ́lì). [w00-YR 5/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 13]
28. Níbàámu pẹ̀lú Dáníẹ́lì 2:34, 35, 45, òkúta tó kọ lu ère náà tó sì wó o wómúwómú dúró fún (Amágẹ́dọ́nì; ìdájọ́ mímúná táwọn èèyàn Ọlọ́run ń polongo rẹ̀; Ìjọba Mèsáyà náà). [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 4/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 10. si-E ojú ìwé 142 ìpínrọ̀ 20 àti 23]
29. Orílẹ̀-èdè ìṣàpẹẹrẹ tó kún fún eéṣú náà tá a sọ nípa rẹ̀ nínú Jóẹ́lì 1:4-6 dúró fún (orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì; àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró; ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù). (Ìṣe 2:1, 14-17) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w98-YR 5/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 9.]
30. Àwọn Kristẹni tí wọ́n wà déédéé kì í kọ ìtọ́jú ìṣègùn níwọ̀n ìgbà (tó bá ti máa mú kí aláìsàn náà bọ́ nínú ìrora; tí kò bá ti lòdì sí òfin Ọlọ́run; tí kò bá ti ta ko èrò àwọn dókítà tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́). [fy-YR ojú ìwé 124 ìpínrọ̀ 19]
So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí mọ́ èyí tó bá a mu lára àwọn gbólóhùn tí a tò sísàlẹ̀ yìí:
Hós. 6:6; Jóẹ́lì 2:32; Sek. 4:6, 7; 13:3; Róòmù 12:2
31. A kò gbọ́dọ̀ fàyè gba àṣà ìbílẹ̀ tàbí ọ̀pá ìdiwọ̀n ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí láti darí ìrònú wa. [w00-YR 11/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 5]
32. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹbọ tó ní ayẹyẹ ètò ìsìn nínú lohun tó ń múnú Ọlọ́run dùn, bí kò ṣe ṣíṣe àwọn ohun tó ń fi ìfẹ́ dídúróṣinṣin hàn, èyí tá a gbé ka mímọ̀ tá a mọ̀ Ọ́n. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo si-E ojú ìwé 145 ìpínrọ̀ 16.]
33. Mímọ ẹni náà tó ń jẹ́ orúkọ àtọ̀runwá náà, bíbọ̀wọ̀ fún un, àti gbígbáralé e, ṣe pàtàkì fún rírí ìgbàlà. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 3/15 ojú ìwé 30 àpótí.]
34. Kì í ṣe nípasẹ̀ agbára ẹ̀dá èèyàn kankan ni ète Ọlọ́run fi ń ní ìmúṣẹ, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run, èyí tó ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti lè borí àwọn ìdènà tó dà bí òkè àti láti ní ìfaradà nínú iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo si-E ojú ìwé 169 ìpínrọ̀ 2]
35. Ìdúróṣinṣin tá a fi ń dá ètò àjọ Jèhófà mọ̀ tayọ gbogbo àjọṣe ẹ̀dá èèyàn, irú èyí tó ń wà láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí. Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo si-E ojú ìwé 171 ìpínrọ̀ 24]