Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí kò bá sí, a lè fi Iwe Itan Bibeli Mi, tàbí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni. Bí ìjọ kò bá ní èyíkéyìí lára àwọn ìwé tá a lè fi lọni ní àfidípò yìí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ béèrè bóyá àwọn ìjọ tó wà nítòsí yín ní púpọ̀ lọ́wọ́ tẹ́ ẹ lè rí lò. January: Ìwé èyíkéyìí tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1988 tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Bí ẹ kò bá ní èyíkéyìí lára àwọn ìwé wọ̀nyí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ béèrè bóyá àwọn ìjọ tó wà nítòsí yín ní ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ lọ́wọ́ tẹ́ ẹ lè rí lò. Àwọn ìjọ tí kò bá ní àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ lọ́wọ́ lè fi ìwé Mankind’s Search for God lọni. A óò ṣe àkànṣe ìsapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Láìpẹ́, a ó fi ìwé ìkésíni fún Ìṣe Ìrántí ọdún 2003 ránṣẹ́ sí ìjọ yín.
◼ Kí gbogbo akéde tó ti ṣèrìbọmi, tó bá wà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ January 6 gba káàdì Advance Medical Directive/Release, kí wọ́n sì gba Identity Card (Káàdì Ìdánimọ̀) fún àwọn ọmọ wọn.
◼ A ti ṣe àtúnṣe sí ọ̀nà tí a óò máa gbà darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká. Bẹ̀rẹ̀ láti January ọdún 2003, lẹ́yìn orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀, nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n la ó máa fi darí ilé ẹ̀kọ́ náà. A óò sọ àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ kan, ọ̀rọ̀ ìtọ́ni oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́wàá, àti kókó pàtàkì látinú Bíbélì tí yóò jẹ́ ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Kò ní sí iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kejì, ìkẹta, àti ìkẹrin. Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí a óò ṣe fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú yóò tẹ̀ lé ilé ẹ̀kọ́ náà. Lẹ́yìn orin kan, ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí alábòójútó àyíká yóò bójú tó fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú yóò wáyé, orin àti àdúrà ìparí yóò sì tẹ̀ lé e.