ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/03 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 10
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 17
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 24
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 3
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 2/03 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 10

Orin 4

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti wo fídíò Faithful Under Trials—Jehovah’s Witnesses in the Soviet Union ní ìmúrasílẹ̀ fún ìjíròrò tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ February 24. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ February 15 àti Jí! March 8 lọni. Lo àbá àkọ́kọ́ ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! March 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan ṣoṣo la óò sọ̀rọ̀ lé lórí.

35 min: “Wàásù Kí O sì Tún Jẹ́rìí Kúnnákúnná.”a Alábòójútó iṣẹ́-ìsìn ni kó bójú tó o. Rọ gbogbo àwọn tó bá lè ṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March àti April pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó ṣe aṣáájú ọ̀nà ní sáà Ìṣe Ìrántí tó kọjá. Báwo ni wọ́n ṣe ṣètò àwọn ìgbòkègbodò wọn tí wọ́n fi lè ṣe aṣáájú ọ̀nà? Àwọn ìsapá àti àtúntò wo ni èyí béèrè fún? Àwọn ìbùkún àti ayọ̀ wo ni wọ́n rí nínú rẹ̀? Jíròrò àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tá a dámọ̀ràn nínú àpótí tó wà ní ojú ìwé 4. Ṣèfilọ̀ pé àwọn ará yóò rí fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ gbà lẹ́yìn ìpàdé yìí.

Orin 30 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 17

Orin 48

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Sọ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù March. Mẹ́nu kan ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì fún fífi ìwé Ìmọ̀ lọni, nípa lílo àwọn àbá tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002. Tẹnu mọ́ ọn pé kí gbogbo àwọn ará ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

7 min: Jíròrò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun.” Ṣèfilọ̀ déètì tí ẹ óò ṣe àpéjọ àkànṣe tí ń bọ̀, kí o sì rọ gbogbo àwọn ará láti tètè dé kí wọ́n sì fetí sílẹ̀ sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Fún àwọn akéde níṣìírí pé kí wọ́n ké sí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn láti wá.

30 min: “Jíjàǹfààní Ní Kíkún Látinú Àpéjọ Àgbègbè ‘Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run.’” Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ni kó bójú tó o. Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ oníṣẹ̀ẹ́jú kan, darí ìjíròrò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè pẹ̀lú àwùjọ, nípa lílo àwọn ìbéèrè tí a pèsè nínú àpilẹ̀kọ náà. Pín àkókò tó o máa lò lórí ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan dáadáa. O lè fi àwọn àlàyé ṣókí kún un láti fi mú kí àwùjọ rántí àwọn kókó pàtàkì. Nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, béèrè lọ́wọ́ àwùjọ bí wọ́n ti ṣe ń fi àwọn ohun tí wọ́n kọ́ sílò àti àwọn àǹfààní tí wọ́n ń rí látinú ṣíṣe bẹ́ẹ̀.

Orin 194 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 24

Orin 74

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn fún oṣù February sílẹ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àwọn àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ March 1 àti Jí! March 8 lọni. Lo àbá kejì ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! March 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan ṣoṣo la óò sọ̀rọ̀ lé lórí.

10 min: “Ìrànlọ́wọ́ ní Àkókò Tó Tọ́.” Àsọyé tí alàgbà kan yóò sọ. Tẹnu mọ́ kókó náà pé, àkànṣe ìsapá tí à ń ṣe láti ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ ń fi àníyàn onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ní sí àwọn èèyàn rẹ̀ hàn.

25 min: “Fídíò Tó Máa Là Ọ́ Lóye Tí Yóò sì fún Ọ Níṣìírí!” Bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò fídíò Faithful Under Trials pẹ̀lú àwùjọ láìjáfara, ní lílo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà. Pín àkókò tó o máa lò lórí ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan dáadáa kí àyè lè wà fún ọ̀pọ̀ ìdáhùn lórí ìbéèrè tó kẹ́yìn. Kádìí ìjíròrò yìí nípa kíka ọ̀rọ̀ inú àpótí tó wà lójú ìwé 192 nínú ìwé 2002 Yearbook. Ní àfirọ́pò, jíròrò “Irú Ojú Wo Ló Yẹ Ká Máa Fi Wo Àdánwò?” Àsọyé tí alàgbà kan yóò sọ. A gbé e ka Ilé Ìṣọ́ September 1, 2002, ojú ìwé 29 sí 31.

Orin 56 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 3

Orin 14

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ní ṣókí, jíròrò “Ìṣètò Tuntun fún Àwọn Ibi Ìkówèésí Tó Wà Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.” Dárúkọ ẹni tí yóò máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ibi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Kí Lò Ń Fi Sí Ipò Àkọ́kọ́?”b Ṣètò ṣáájú pé kí akéde kan tàbí méjì sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ṣe àtúnṣe nínú ìgbòkègbodò wọn kí wọ́n bàa lè túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.

Orin 57 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́