ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/03 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 10
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 17
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 24
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 31
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 7
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 3/03 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 10

Orin 5

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ March 15 àti Jí! April 8 lọni. Lo àbá àkọ́kọ́ tó wà ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! April 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ lé lórí.

15 min: Jíròrò Ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàlàyé ètò tó wà láti máa lo ìwé náà gẹ́gẹ́ bí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kejì. (km–YR 6/00, ojú ìwé 4, ìpínrọ̀ 5 àti 6) Ké sí àwùjọ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí nínú ìtẹ̀jáde náà. Ṣàlàyé pé àwọn apá kan nínú ìwé náà ní àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí yóò mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà ronú jinlẹ̀ lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lo àpẹẹrẹ tó wà lójú ìwé 47 sí 49, ìpínrọ̀ 13.

20 min: “Jẹ́ Onítara fún Ohun Rere!”a (Ìpínrọ̀ 1-12) Lẹ́yìn jíjíròrò ìpínrọ̀ 6, ní ṣókí, ṣe àṣefihàn kan nípa akéde tó ń ké sí mọ̀lẹ́bí rẹ̀, aládùúgbò rẹ̀, ọmọléèwé ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tàbí òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan wá sí Ìṣe Ìrántí, nípa lílo ìwé ìkésíni tí a tẹ̀. Bí ìwé ìkésíni sí Ìṣe Ìrántí náà kò bá tíì tẹ àwọn akéde lọ́wọ́, kí a rí i pé wọ́n rí i gbà lẹ́yìn ìpàdé.

Orin 19 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 17

Orin 34

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán gbogbo àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìlàjì oṣù March sílẹ̀.

15 min: Jàǹfààní Nínú Ìwé 2003 Yearbook. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Jíròrò àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso,” èyí tá a fi ránṣẹ́ pẹ̀lú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 2003. Sọ àwọn ọ̀nà tá a lè gbà darí àwọn ẹni tuntun sínú ètò àjọ Jèhófà àti bí a ṣe lè fún wọn níṣìírí láti máa wá sípàdé.

20 min: “Jẹ́ Onítara fún Ohun Rere!”b (Ìpínrọ̀ 13-26) Alábòójútó olùṣalága ni kó bójú tó o. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 14, ṣe àṣefihàn alàgbà kan tó ń bẹ arákùnrin kan tó jẹ́ aláìlera wò láti fún un níṣìírí, tó sì lo àkókò náà láti ṣàlàyé fún arákùnrin náà lọ́nà pẹ̀lẹ́tù nípa bó ṣe lè kópa púpọ̀ sí i nínú ìgbòkègbodò tí ìjọ ṣètò rẹ̀ fún sáà Ìṣe Ìrántí.

Orin 53 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 24

Orin 72

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ April 1 àti Jí! April 8 lọni. Lo àbá kejì ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! April 8 lọni.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Ṣe Àwùjọ Láǹfààní. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Nígbà mìíràn, àǹfààní máa ń yọjú láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àti àpẹẹrẹ wa ṣe ń ṣàǹfààní fún àwùjọ. Ké sí àwọn ará láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó tó wà nísàlẹ̀ yìí: (1) À ń kọ́ àwọn èèyàn láti gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì nípa ìwà rere. (2) À ń kọ́ wọn láti jẹ́ olóòótọ́ àti láti jẹ́ ẹni tó ń bọ̀wọ̀ fún àwọn tó wà nípò àṣẹ. (3) À ń kọ́ wọn nípa bí ìṣọ̀kan ṣe lè wà láàárín àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àtàwọn tí ipò wọn láwùjọ yàtọ̀ síra. (4) À ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mú kí ìdílé wọn jẹ́ aláyọ̀ nípa rírọ̀ wọ́n láti máa mú àwọn ìlànà Bíbélì lò. (5) A ti kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn láti mọ̀ ọ́n kọ kí wọ́n sì mọ̀ ọ́n kà. (6) À ń sa gbogbo ipá wa láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ní àkókò àjálù. (7) A ti ṣe gudugudu méje láti jẹ́ kí òfin òmìnira ìsìn fẹsẹ̀ múlẹ̀, èyí tí gbogbo èèyàn ń jàǹfààní rẹ̀.—Wo ìwé Proclaimers, ojú ìwé 699.

Orin 121 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 31

Orin 130

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìparí oṣù March sílẹ̀. Sọ ìwé tí a óò fi lọni ní oṣù April, ní pàtàkì jù lọ, sọ pé kí àwọn ará sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tán. Jíròrò “Àwọn Ìránnilétí Nípa Ìṣe Ìrántí.”

13 min: Àwọn ìrírí tí àwọn akéde ní. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní lásìkò ìgbòkègbodò tá a mú gbòòrò sí i tó wáyé ní oṣù March. Yìn wọ́n fún ìsapá wọn, kó o sì rọ gbogbo àwọn ará láti kópa ní kíkún dé ibi tí ipò wọn bá yọ̀ǹda fún wọn dé ní oṣù April.

20 min: “Jèhófà Yẹ fún Ìyìn Gidigidi.”c Tẹnu mọ́ ìdí tí Ìṣe Ìrántí fi ṣe pàtàkì gan-an. Sọ bí gbogbo wa ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wà níbẹ̀. Ṣàlàyé ohun tá a lè ṣe láti kàn sí àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ láti mú kí ìfẹ́ wọn sọjí padà. Ké sí àwùjọ láti sọ ìrírí èyíkéyìí tó ń fúnni níṣìírí tí wọ́n ní nígbà ayẹyẹ ti ọdún tó kọjá.

Orin 173 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 7

Orin 191

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò “Ìṣe Ìràntí—Àkókò Tó Gba Ìrònújinlẹ̀.”

15 min: Bí A Ṣe Lè Ronú Pa Pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Èèyàn látinú Ìwé Mímọ́. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Báwo la ṣe lè di ẹni tó mọ bí a ṣeé ronú pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́nà tó gbẹ́ṣẹ́? (1) Gba ìmọ̀ tó jíire látinú Ìwé Mímọ́ nípa ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti wíwá sí ìpàdé déédéé. (2) Ṣàṣàrò lórí ohun tó o kọ́, kó o sì gbé àwọn òtítọ́ tó o kọ́ yẹ̀ wò ní oríṣiríṣi ọ̀nà. (3) Má ṣe wá àwọn àlàyé tí Ìwé Mímọ́ ṣe nìkan àmọ́ kó o tún gbìyànjú láti mọ ìdí tí Ìwé Mímọ́ fi ṣe àwọn àlàyé náà. (4) Ronú lórí bí wàá ṣe ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún onírúurú èèyàn. (5) Ronú nípa bó o ṣe lè lo àpèjúwe láti fi ṣàlàyé àwọn kókó kan pàtó.

20 min: “Bí Òtítọ́ Ṣe Ń Sọ Wá Di Òmìnira.”d Fi àlàyé kún un látinú àpótí tó wà ní ojú ìwé 6 nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 1998. Ké sí àwùjọ láti sọ bí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ wọ́n di òmìnira.

Orin 217 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́