Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 14
Orin 20
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán gbogbo àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìlàjì oṣù April sílẹ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ April 15 àti Jí! May 8 lọni. Lo àbá àkọ́kọ́ tó wà ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! May 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ lé lórí.
10 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé tí alàgbà kan yóò sọ.
20 min: ‘Títàn bí Atànmọ́lẹ̀.’a Parí ìjíròrò yìí pẹ̀lú àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ June 1, 1997, ojú ìwé 14 àti 15, ìpínrọ̀ 8 sí 13. Tẹnu mọ́ ìdí tí a fi ń sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn láìfi bò.
Orin 134 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 21
Orin 25
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: A Jèrè Wọn Láìsọ̀rọ̀. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ìwà rere tí àwọn Kristẹni ń hù jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára. Ó ti sún àwọn ọkọ tàbí aya kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ láti di olùjọsìn Jèhófà. (1 Pét. 3:1, 2) Sọ àwọn ìrírí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 1999, ojú ìwé 4; Ilé Ìṣọ́ October 1, 1995, ojú ìwé 10 àti 11; àti ìwé 1995 Yearbook, ojú ìwé 46. Ṣètò ṣáájú kí àwọn akéde méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀ lórí àwọn àbájáde dáradára tí wọ́n ti rí látinú fífi àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì sílò lórí kókó yìí.
20 min: “Wá Àyè fún Un.”b Fọ̀rọ̀ wá akéde kan tàbí méjì lẹ́nu wò, tí wọ́n ń lo àǹfààní wíwà láìṣègbéyàwó láti fi mú kí ire Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú. Ní kí wọ́n sọ àwọn ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn wọn.
Orin 35 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 28
Orin 51
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìparí oṣù April sílẹ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ May 1 àti Jí! May 8 lọni. Lo àbá kejì ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! May 8 lọni.
35 min: “Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?” Àsọyé tí ń gbéni ró, èyí tí àwùjọ yóò lóhùn sí láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó o ti ṣètò sílẹ̀ fún ìpínrọ̀ 11 àti ìpínrọ̀ 16 sí 21. Rọ àwọn òbí láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ lórí fífi iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ṣe iṣẹ́ ìgbésí ayé wọn. Dámọ̀ràn pé kí àwọn ìdílé jíròrò ìsọfúnni inú àkìbọnú yìí pa pọ̀ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn.
Orin 197 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 5
Orin 120
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ àwọn ìtẹ̀jáde tí a ó fi lọni ní oṣù May. Jíròrò àpilẹ̀kọ náà, “Lo Ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Láti Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”
20 min: “Ìpadàbẹ̀wò Ń Ṣamọ̀nà sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”c Kí alàgbà kan bójú tó o, nípa lílo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà. Ké sí àwùjọ láti sọ̀rọ̀ ṣókí nípa àwọn ìrírí tí wọ́n ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, èyí tó bá kókó ọ̀rọ̀ tá à ń jíròrò lọ́wọ́ mu. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, ṣe àṣefihàn ìrírí tí akéde kan ní, nípa bó ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan ní ìpínlẹ̀ ìjọ.
15 min: Ìròyìn Tó Dára Máa Ń Fúnni Láyọ̀. (Òwe 15:30) Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ nípa àwọn àṣeyọrí tí ìjọ ṣe nígbà àkànṣe ìsapá tí a ṣe ní oṣù March àti April. Ké sí àwọn ará láti sọ àwọn ìrírí tí ń gbéni ró tí wọ́n ní nínú àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọ̀nyí: (1) Ríran olùfìfẹ́hàn kan lọ́wọ́ láti wá sí Ìṣe Ìrántí, (2) ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, (3) fífún akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ kan níṣìírí láti tún bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ, (4) ríran ẹni tuntun kan lọ́wọ́ láti di akéde ìhìn rere, àti (5) mímú kí àwọn olùfìfẹ́hàn tó wá sí Ìṣe Ìrántí tẹ̀ síwájú sí i. Ṣètò ṣáájú kí àwọn akéde kan múra díẹ̀ lára àwọn ìdáhùn wọ̀nyí sílẹ̀. Gbóríyìn fún àwọn ará, kó o sì rọ wọ́n láti máa bá a nìṣó ní kíkópa nínú àwọn ìgbòkègbodò wọ̀nyí lọ́jọ́ iwájú.
Orin 126 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.