ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/03 ojú ìwé 6
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 6/03 ojú ìwé 6

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 30, 2003. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ May 5 sí ọ̀sẹ̀ June 30, 2003. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Kí nìdí tí yíyí ohùn padà fi ṣe pàtàkì nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀, ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣe èyí? [be-YR ojú ìwé 111 àpótí; ojú ìwé 112 àpótí]

2. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olùbánisọ̀rọ̀ kan gba ohun tó ń sọ gbọ́, tó sì fẹ́ràn Jèhófà, kí nìdí tó fi lè má lo ìtara nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀? [be-YR ojú ìwé 115 ìpínrọ̀ 3 sí 4; ojú ìwé 116 ìpínrọ̀ 1]

3. Kí ni yóò ran olùbánisọ̀rọ̀ lọ́wọ́ láti fi ọ̀yàyà hàn kó sì tún fi bí nǹkan ṣe rí lára hàn nígbà tó bá ní ọ̀rọ̀ sísọ, kí nìdí tí èyí sì fi ṣe pàtàkì? [be-YR ojú ìwé 119 ìpínrọ̀ 1 sí 4]

4. Kí ló máa pinnu bí a óò ṣe fi ìtara, ọ̀yàyà, bí nǹkan ṣe rí lára àti àwọn ànímọ́ mìíràn hàn bó ṣe yẹ nígbà tí a bá fẹ́ sọ̀rọ̀? [be-YR ojú ìwé 120 ìpínrọ̀ 2 sí 5]

5. Bẹ́ẹ̀ ni tàbí Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ìgbà tí olùgbọ́ rẹ bá ń wò ọ́ nìkan ló yẹ kí o máa fara ṣàpèjúwe kí o sì tún mú ìrísí ojú rẹ bá ọ̀rọ̀ rẹ mu. Ṣàlàyé. [be-YR ojú ìwé 121 ìpínrọ̀ 3]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Kí ni ohun tí ó ran Jòsáyà lọ́wọ́ láti yan ipa ọ̀nà tí ó tọ́ láìka bí ìgbà ọmọdé rẹ̀ ṣe nira tó sí? (2 Kíró. 34:1, 2) [w01-YR 4/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 sí 6; ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 3]

7. Kí ni ohun tí Òwe 9:7, 8a túmọ̀ sí, báwo ni a sì ṣe lè mú un lò nínú iṣẹ́ ìsìn pápá? [w01-YR 5/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 4 àti 5]

8. Kí ni ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ má ṣe gbàgbé o,’ báwo ni a sì ṣe lè ṣe é ká má máa gbàgbé nǹkan? (Di 4:9; 8:11) [be-YR ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 1 sí 3]

9. Báwo ni ọ̀rọ̀ àtọkànwá tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 32:1, 5 àti Sáàmù 51:10, 15 ṣe fi hàn pé kò yẹ kí ẹnì kan máa rò pé òun ò já mọ́ ohunkóhun lẹ́yìn tó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan àmọ́ tó wá ronú pìwà dà tọkàntọkàn? [w01-YR 6/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1 sí 3]

10. Kí la lè rí kọ́ nípa ọ̀nà tí a óò gbà bójú tó àwọn aláìní látinú ìtọ́ni tí Pọ́ọ̀lù pèsè nínú 1 Tímótì 5:3-16? [w01-YR 6/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 1]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Kí ni Jésù ń tọ́ka sí nígbà tó lo gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà ‘àtúnbí’, èyí tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Jòhánù 3:3? [w95-YR 7/1 ojú ìwé 9 sí 10 ìpínrọ̀ 4 àti 5]

12. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà lo ìmọ̀ tó ní, kí sì ni ẹ̀kọ́ pàtàkì tí a lè rí kọ́ láti inú rẹ̀? (Jòh. 7:15-18) [w96-YR 2/1 ojú ìwé 9 sí 10 ìpínrọ̀ 4 sí 7]

13. Kí nìdí tá a fi kọ ọ̀rọ̀ inú Jòhánù 7:53–8:11 sọ́tọ̀ nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun?

14. Báwo ni Jésù ṣe “wá bẹ́ẹ̀ ní irú ọ̀nà kan náà” tó gbà gòkè re ọ̀run? (Ìṣe 1:11) [w90-YR 6/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 5]

15. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé “kò sí ẹyọ ẹnì kan nínú àwọn mìíràn tí ó ní ìgboyà láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ [àwọn ọmọlẹ́yìn],” gẹ́gẹ́ bí Ìṣe 5:13 ṣe sọ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́