Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù June: Kí a fi ìwé Ìmọ̀ tàbí àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, Béèrè tàbí Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè lọni. Bí àwọn onílé bá ti ní àwọn ìwé wọ̀nyí lọ́wọ́, lo ìwé pẹlẹbẹ mìíràn tó bá ipò onílé mu tí ìjọ ní lọ́wọ́. July àti August: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 wọ̀nyí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Sún Mọ́ Jèhófà. Bí kò bá sí lọ́wọ́, ẹ lè lo ìwé Kíyè Sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, gẹ́gẹ́ bí àfidípò.