ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/03 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 11
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 18
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 25
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 1
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 8/03 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 11

Orin 101

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tí a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ August 15 àti Jí! September 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ lé lórí. Nínú ọ̀kan lára àṣefihàn náà, kí a fi hàn bí a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń pani lẹ́nu mọ́, irú bí “Ọwọ́ mi dí.”—Wo ìwé kékeré náà Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ewé 11.

15 min: “Fara Wé Ìwà Rere Jèhófà.” a Ní kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí ṣókí nípa bí inú rere tí wọ́n fi hàn ṣe ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìjẹ́rìí. Gbóríyìn fún àwọn ará nítorí ipá tí wọ́n ń sà láti ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́.

20 min: “Àwọn Ìbùkún Tó Wà Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà.”b Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Ní kí aṣáájú ọ̀nà kan tàbí méjì sọ ọ̀nà tí wọ́n ti gbà jàǹfààní nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Sọ fún àwọn ará pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lè gba ìwé ìwọṣẹ́ lọ́wọ́ akọ̀wé.

Orin 11 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 18

Orin 82

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìlàjì oṣù August sílẹ̀.

15 min: “Iṣẹ́ Tó Ń Tuni Lára.”c Ṣètò ẹni méjì tàbí mẹ́ta ṣáájú pé kí wọ́n sọ ọ̀nà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni gbà ń tù wọ́n lára.

20 min: “Mímú Kí Ibi Ìjọsìn Wa Wà ní Ipò Tó Bójú Mu.”d (Ìpínrọ̀ 1 sí 5) Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3 àti 4, sọ ètò tí ìjọ ṣe fún mímú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní. Sọ̀rọ̀ lórí ohunkóhun tó bá ń fẹ́ àbójútó. Gbóríyìn fún àwọn ará nítorí ipá tí wọ́n ń sà láti mú kí ibi ìjọsìn tòótọ́ wà ní ipò tó bójú mú.

Orin 114 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 25

Orin 175

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ September 1 àti Jí! September 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ lé lórí. Jẹ́ kí òbí kan àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin tí kò tíì pé ogún ọdún ṣe ìfidánrawò ọ̀nà tí wọn yóò gbà fi ìwé ìròyìn lọni. Ní ṣókí, kí wọ́n sọ̀rọ̀ lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a dábàá ṣáájú ṣíṣe àṣefihàn náà.

15 min: “Ẹ Yè Kooro ní Èrò Inú bí Òpin Ti Ń Sún Mọ́lé.”e Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3 àti 4, ní kí àwọn akéde sọ góńgó tẹ̀mí tí wọ́n ń lépa ní lọ́wọ́lọ́wọ́. Fi àlàyé tó wà nínú ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 175 àti 176 kún un.

20 min: Ẹ Máyà Le Láti Wàásù. (1 Tẹs. 2:2) Àsọyé tó ní ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ nínú. Ṣàlàyé ìdí tí ọ̀pọ̀ fi máa ń bẹ̀rù láti wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn. Kódà, èyí ò yọ àwọn akéde tí wọ́n ti ń ṣe déédéé láti ọ̀pọ̀ ọdún sílẹ̀. Sọ díẹ̀ lára àwọn ìrírí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ December 1, 1999, ojú ìwé 25; Ilé Ìṣọ́ December 15, 1999, ojú ìwé 25; àti Ilé Ìṣọ́nà April 1, 1996, ojú ìwé 31. Ní kí àwùjọ sọ bí wọ́n ṣe fi ìgboyà hàn láti wàásù ìhìn rere náà láwọn ìgbà kan tí ẹ̀rù ń bà wọ́n. Parí ìjíròrò yìí nípa fífún wọn níṣìírí láti máa gba agbára kún agbára látọ̀dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbé ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí ka ìsọfúnni tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ December 15, 1999, ojú ìwé 23 àti 24.

Orin 125 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 1

Orin 84

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìparí oṣù August sílẹ̀. Mẹ́nu kan àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù September.

10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

12 min: Ǹjẹ́ O Máa Ń Padà Lọ Gẹ́gẹ́ Bí O Ṣe Ṣèlérí? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ September 15, 1999, ojú ìwé 10 àti 11, lábẹ́ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ náà “Àwọn Ọ̀nà Mìíràn Láti Mú Ìlérí Wa Ṣẹ.” Nígbà tá a bá rí àwọn èèyàn tó fìfẹ́ hàn sí ọ̀rọ̀ wa lóde ẹ̀rí, a sábà máa ń ṣètò láti máa bá ìjíròrò náà lọ lákòókò mìíràn. Ṣé lóòótọ́ la máa ń padà lọ gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣèlérí? Ṣàlàyé àwọn ìlànà Bíbélì tó yẹ kó sún wa láti máa mú ìlérí wa ṣẹ. Ní kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí tó fi bí wọ́n ṣe ń jàǹfààní nípa títètè padà lọ hàn.

18 min: “Mímú Kí Ibi Ìjọsìn Wa Wà ní Ipò Tó Bójú Mu.”f (Ìpínrọ̀ 6 sí 12) Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì mímú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní ipò tó bójú mu, kí o sì sọ̀rọ̀ lórí kókó inú àpótí tó wà ní ojú ìwé 5. Fi ìròyìn ṣókí nípa ipò tí Gbọ̀ngàn Ìjọba yín wà kún un, kí o sì jẹ́ káwọn ará mọ ètò tó wà nílẹ̀ fún mímú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní ipò tó bójú mu tàbí àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mìíràn.

Orín 41 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

f Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́