ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/03 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 13
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 20
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 27
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 3
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 10/03 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 13

Orin 215

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ àtàwọn Ìfilọ̀ tí a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìlàjì oṣù October sílẹ̀. Rọ gbogbo àwọn ará láti mú ìwé pẹlẹbẹ Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, kí wọ́n sì ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ tí wọ́n kọ nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká tó kọjá, láti múra sílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 1, ṣe àṣefihàn kan tó bá ipò àdúgbò mu nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ October 15 lọni. Nínú àṣefihàn náà, kí a fi hàn bí a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tí à ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé. Ṣètò fún ìbẹ̀wò tí yóò tẹ̀ lé e nípa pípe àfiyèsí onílé sí àpótí náà, “Nínú Ìtẹ̀jáde Wa Tí Ń Bọ̀.”—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1998, ojú ìwé 8, ìpínrọ̀ 7 àti 8.

20 min: Máa Lo Idà Ẹ̀mí. (Éfé. 6:17) Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 143 àti 144. Ké sí àwùjọ láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: (1) Kí nìdí tí a fi ń lo Bíbélì nígbà tá a bá ń dáhùn ìbéèrè? (2) Kí ni orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi hàn nípa wa? (3) Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀, báwo la sì ṣe lè fara wé e? (4) Ní ìpínlẹ̀ ìjọ, àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ wo la lè fi bẹ̀rẹ̀ àlàyé ọ̀rọ̀ nípa Bíbélì? (5) Kí nìdí tó fi dára láti máa ka ọ̀rọ̀ inú Bíbélì jáde tààràtà nígbàkigbà tó bá ti ṣeé ṣe? (6) Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti máa lo Bíbélì déédéé? Ṣètò fún àṣefihàn kan tí a ti múra sílẹ̀ dáadáa, èyí tí a gbé ka ìdánrawò tó wà lójú ìwé 144, nínú èyí tí akéde tó dáńgájíá kan ti lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ó kéré tán láti dáhùn ìbéèrè kan. Rọ gbogbo àwọn ará láti fi ṣe góńgó wọn láti máa lo Bíbélì ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń jẹ́rìí.

15 min: Dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ń Mú Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Wá. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Sọ àwọn ìrírí bíi mélòó kan látinú àwọn ìtẹ̀jáde wa nípa àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ń tẹ̀ síwájú. (w00-YR 3/1 ojú ìwé 6; yb98-E ojú ìwé 55 sí 60) Ké sí àwùjọ láti sọ̀rọ̀ lórí ohun tí a lè rí kọ́ látinú àwọn ìrírí wọ̀nyí àti bí a ṣe ń jàǹfààní nínú dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Orin 172 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 20

Orin 86

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

20 min: “Fífi Ìwé Pẹlẹbẹ Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? Lọni.” Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó o gẹ́gẹ́ bí àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ṣètò pé kí a ṣàṣefihàn méjì lára àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Nínú àṣefihàn kan, jẹ́ kí àwọn ará rí bí a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. O lè rọ àwọn ìdílé àtàwọn ẹlòmíràn láti fi àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dánra wò nílé. Kí gbogbo àwọn ará lo ìwé pẹlẹbẹ tuntun yìí dáadáa gẹ́gẹ́ bí ìwé ìfilọni fún oṣù November. Lẹ́yìn oṣù náà, kí wọ́n máa lò ó dáadáa ní ìpínlẹ̀ ìjọ, kí wọ́n sì máa fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

20 min: “Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Kí O sì Máa Ṣe Rere.” (Sm. 37:3) Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí, láti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn kókó ọ̀rọ̀ tí a gbádùn nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká tí a ṣe ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá. Ké sí àwùjọ láti sọ bí ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti fi àwọn kókó pàtàkì tí wọ́n kọ́ sílò lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Jíròrò àwọn apá wọ̀nyí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà: (1) “Fífi Ìgbẹ́kẹ̀lé Tá A Ní Nínú Jèhófà Hàn.” Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà hàn nínú gbogbo apá ìgbésí ayé? (it-2-E ojú ìwé 521) Báwo ni ìwé Watch Tower Publications Index ṣe lè ràn wá lọ́wọ́? (2) “Yàgò fún Àwọn Ohun Asán Tó Wà Nínú Ìgbésí Ayé.” (Oníw. 2:4-8, 11) Àwọn ohun asán wo la gbọ́dọ̀ yàgò fún, báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? (3) “Ẹ Yàgò fún Ohun Búburú, Ẹ Jẹ́ Olùṣe Ohun Rere.” Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Jèhófà? (Aísá. 5:20) Àwọn iṣẹ́ rere wo ló yẹ ká jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú wọn? (4) “Ṣíṣàìjẹ́ Kí Ìgbẹ́kẹ̀lé Tá A Ní Nínú Jèhófà Yìnrìn.” Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in lójú àdánwò àti ìdẹwò? Kí nìdí tó fi yẹ ká fi àwọn ọ̀ràn kan sílẹ̀ fún Jèhófà? (5) “Ǹjẹ́ A Óò Kà Ọ́ Yẹ fún Ìjọba Ọlọ́run?” (Kól. 1:10) Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló ń sún wa láti máa rìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà? (6) “Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà.” Báwo ni ṣíṣe èyí yóò ṣe nípa lórí ìgbésí ayé wa?

Orin 58 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 27

Orin 64

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìparí oṣù October sílẹ̀. Rọ gbogbo àwọn ará láti ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ tí wọ́n kọ nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe tó kọjá, láti múra sílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 1, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ November 1 àti Jí! November 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ lé lórí. Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, fi hàn bí a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, irú bíi “Mi ò fẹ́ gbọ́.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 8.

20 min: “Ẹ Fi Ayọ̀ Yíyọ̀ Sin Jèhófà.”a Lẹ́yìn tí o bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 4, sọ fún àwùjọ pé lóṣù November ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè ni a ó fi lọni. Ní ṣókí, ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀kan lára àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dábàá ní ojú ìwé 8 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù yìí. Lẹ́yìn náà, ṣètò fún àṣefihàn kan láti ṣe ìfidánrawò ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Rọ gbogbo àwọn ará láti máa múra sílẹ̀ dáadáa fún iṣẹ́ òjíṣẹ́.

13 min: Àwọn ìrírí tí àwọn akéde ní. Ké sí àwọn ará láti sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń ṣe ìjẹ́rìí aláìjẹ́-bí-àṣà níbi iṣẹ́, ní ilé ẹ̀kọ́ tàbí níbòmíràn.

Orin 52 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 3

Orin 147

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

25 min: Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà. (1 Tím. 6:18) Nípa lílo àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí, kí alàgbà kan bójú tó ìjíròrò yìí pẹ̀lú àwùjọ, èyí tí a gbé ka ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe tí a ṣe kọjá. Ké sí àwùjọ láti sọ bí wọ́n ṣe fi àwọn ohun tí wọ́n kọ́ sílò. (A lè yan àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ lórí apá kọ̀ọ̀kan ṣáájú.) Jíròrò àwọn apá tó tẹ̀ lé e yìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà: (1) “Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà Ń Mú Èrè Ńlá Wá.” (Oníw. 2:11) Kí nìdí tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fi ń sapá láti ṣe àwọn iṣẹ́ àtàtà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dípò kí wọ́n máa ṣe àwọn iṣẹ́ asán tó wà nínú ayé? (2) “Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Lójú Ọlọ́run.” (Mát. 6:20) Báwo ni àwọn kan ti ṣe ‘to ìṣúra jọ pa mọ́ ní ọ̀run,’ àwọn àǹfààní wo ló sì wà nínú èyí? (3) “Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Ládùn Sí I Nípa Dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” (om-YR ojú ìwé 91) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká sì máa darí rẹ̀ nìṣó? (4) “Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà ní Àkókò Ìkórè Yìí.” (Mát. 13:37-39) Àpẹẹrẹ àwọn iṣẹ́ àtàtà wo làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi lélẹ̀, báwo sì ni iṣẹ́ Ìjọba náà ti ṣe gbilẹ̀ tó lónìí? (5) “Ẹ Jẹ́ Kí Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà Yín Fi Ògo fún Jèhófà.” (Mát. 5:14-16) Báwo ni àwọn kan ti ṣe ‘jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn’? (6) “Gbígbóríyìn fún Àwọn Ọ̀dọ́ Nítorí Iṣẹ́ Àtàtà Tí Wọ́n Fi Ń Yin Jèhófà.” (Sm. 148:12, 13) Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tó wà nínú àyíká wa ṣe ń yin Jèhófà? (7) “Máa Bá Ṣíṣe Iṣẹ́ Àtàtà Lọ Kí O sì Rí Ìbùkún Jèhófà Gbà.” (Òwe 10:22) Bí a bá jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú ṣíṣe àwọn iṣẹ́ àtàtà, àwọn ìbùkún wo la lè rí gbà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ìjọ àti gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ tó kárí ayé?

Orin 180 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́