ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/03 ojú ìwé 3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 11/03 ojú ìwé 3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù November: Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí kò bá sí, a lè lo Iwe Itan Bibeli Mi tàbí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, gẹ́gẹ́ bí àfidípò. January: Ìwé èyíkéyìí tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1988 tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Bí ìjọ yín ò bá ní èyíkéyìí lára ìwọ̀nyí lọ́wọ́, ẹ béèrè lọ́wọ́ àwọn ìjọ tó wà nítòsí yín bí wọ́n bá ní ọ̀pọ̀ àwọn ìwé ọlọ́jọ́ pípẹ́ tẹ́ ẹ lè lò. Àwọn ìjọ tí kò bá ní àwọn ìwé ọlọ́jọ́ pípẹ́ lè fi ìwé Mankind’s Search for God lọni. February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà. Bí kò bá sí lọ́wọ́, ẹ lè lo ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! gẹ́gẹ́ bí àfidípò.

◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní December 1 tàbí bó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣàyẹ̀wò rẹ̀ tán, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ nígbà tí ẹ bá tún ń ka ìròyìn ìnáwó.

◼ Ẹ̀ka ọ́fíìsì ti ní àwọn fọ́ọ̀mù tí òfin yọ̀ǹda pé a lè lò láti sọ ìdúró wa nípa ẹ̀jẹ̀ di mímọ̀. Àwọn fọ́ọ̀mù náà á pèsè ààbò síwájú sí i fún wa lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀. Àwọn fọ́ọ̀mù náà tún wúlò fún àwọn ọ̀ràn mìíràn tó jẹ mọ́ ìlera, irú bí ṣíṣe àwọn ìpinnu tó lè la ọ̀ràn ikú lọ. Nítorí náà, wọ́n ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú káàdì Advance Medical Directive/Release láti sọ ohun tó o fẹ́ àtèyí tóò fẹ́ nípa ìtọ́jú ìlera rẹ di mímọ̀. Kò pọn dandan pé kí àwọn akéde ní fọ́ọ̀mù yìí lọ́wọ́. Kí àwọn tí wọ́n bá nílò rẹ̀ (bí àpẹẹrẹ, àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ fún tàbí àwọn tí wọ́n fẹ́ sọ ohun tí wọ́n fẹ́ àtèyí tí wọn ò fẹ́ nípa ìtọ́jú ìlera wọn di mímọ̀ fún dókítà ṣáájú kí wọ́n tó gbàtọ́jú) lọ gbà á lọ́wọ́ akọ̀wé ìjọ. Akọ̀wé á tún fún wọn ní ìwé kan tó ní ìbéèrè àti ìdáhùn nínú, ìyẹn Advance Directive Guide, èyí tó ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tí fọ́ọ̀mù náà wà fún àti ọ̀nà tí a lè gbà lò ó.

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà:

CD-ROM, Watchtower Library—2001 Edition —Gẹ̀ẹ́sì

Ìdìpọ̀ Jí! ọdún 2002 —Gẹ̀ẹ́sì

Ìdìpọ̀ Ilé Ìṣọ́ ọdún 2002 —Gẹ̀ẹ́sì

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tó Wà Báyìí:

Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí—Ìdìpọ̀ 9 —Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà ti Amẹ́ríkà

Iwe Itan Bibeli Mi—Ìdìpọ̀ 2, 3, 4 —Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà ti Amẹ́ríkà

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tó Wà Báyìí fún Àwọn Afọ́jú:

Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run —Èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìpele kejì

Jehovah’s Witnesses—Who Are They? What Do They Believe? —Èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìpele kejì

Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! —Èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìpele kejì

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kọ ọ̀rọ̀ náà, ATTENTION: BRAILLE DESK sórí ìwé tẹ́ ẹ bá fi béèrè fún àwọn ìtẹ̀jáde tó jẹ́ ti àwọn afọ́jú. Kí ẹ sì kọ orúkọ ẹni tó fẹ́ kà á àti àdírẹ́sì onítọ̀hún ránṣẹ́ sí wa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́