Àǹfààní Títayọ Tó Wà Nínú Ọgbọ́n Ọlọ́run
1 Àwọn kan rò pé bí a ṣe máa dín ìṣòro tó dojú kọ aráyé kù ló yẹ kí akitiyan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá lé lórí. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò rí àǹfààní títayọ tó wà nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń ṣe. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún rí bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ gan-an, pé: “Ọ̀rọ̀ nípa òpó igi oró jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ lójú àwọn tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n lójú àwa tí a ń gbà là, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 1:18) A mọ̀ ní tòótọ́ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ lórí ilẹ̀ ayé lónìí.
2 Ìgbésí Ayé Tó Sàn Jù Nísinsìnyí: Ìwọ̀nba àṣeyọrí díẹ̀ ni gbogbo akitiyan àwọn ènìyàn láti yanjú ìṣòro aráyé ń ní. Òfin tí ìjọba ń ṣe kò ní kí ìwà ọ̀daràn dín kù. Àwọn àdéhùn àlàáfíà àtàwọn ọmọ ogun apẹ̀tùsááwọ̀ kò tíì fòpin sí ogun. Àwọn ètò bá-n-tán-ṣẹ̀ẹ́ kò tán ìṣẹ́ àwọn èèyàn. (Sm. 146:3, 4; Jer. 8:9) Ṣùgbọ́n ní ti ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, ó ti ran ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn lọ́wọ́ láti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wọ̀. (Róòmù 12:2; Kól. 3:9, 10) Nítorí pé wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń gbádùn ìgbésí ayé tó sunwọ̀n sí i nísinsìnyí.—1 Tím. 4:8.
3 Ọjọ́ Iwájú Tó Dára: Láfikún sí ríràn tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti kápá àwọn ìṣòro ìgbésí ayé ìsinsìnyí, ọgbọ́n Ọlọ́run tún ń mú ká lè múra sílẹ̀ nísinsìnyí de ọjọ́ iwájú. (Sm. 119:105) Ó ń yọ wá kúrò nínú fífi àkókò wa ṣòfò lórí títún ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí tò. (Oníw. 1:15; Róòmù 8:20) A mà dúpẹ́ o pé àwa kì í fi ọjọ́ ayé wa ṣòfò lórí lílépa àwọn ohun tó jẹ́ àlá tí ò lè ṣẹ! Kàkà bẹ́ẹ̀, orí ìlérí dídájú tí Jèhófà ṣe pé òun yóò mú “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” nínú èyí tí òdodo yóò máa gbé wá ni akitiyan wa dá lé. Nígbà tí ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà bá dé, yóò wá ṣe kedere sí gbogbo ènìyàn pé àwọn tó gbára lé ọgbọ́n Ọlọ́run ló ṣe ìpinnu tó tọ̀nà.—2 Pét. 3:10-13; Sm. 37:34.
4 Lóòótọ́, ọgbọ́n Ọlọ́run lè dà bí ohun tí kò wúlò lójú àwọn tó ti fara jin “ọgbọ́n ti ètò àwọn nǹkan yìí,” àmọ́ ká sòótọ́, òun nìkan ṣoṣo ni ọ̀nà tó dára láti tọ̀. (1 Kọ́r. 1:21; 2:6-8) Ìdí rèé tá a fi ń bá a nìṣó láti máa pòkìkí ìsọfúnni látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n,” káàkiri ayé.—Róòmù 16:27.