Lílò Tí Jehofa Ń Lo “Ìwà-òmùgọ̀” Lati Gba Awọn Wọnni Ti Wọn Gbagbọ Là
“Niwọn bi, ninu ọgbọ́n Ọlọrun, ayé nipasẹ ọgbọ́n rẹ̀ kò mọ Ọlọrun, Ọlọrun rii pe o dara nipasẹ ìwà-òmùgọ̀ ohun ti a ń waasu lati gba awọn wọnni ti wọn ń gbagbọ là.”—1 KORINTI 1:21, NW.
1. Ni ero itumọ wo ni Jehofa yoo fi lo “ìwà-òmùgọ̀,” bawo ni a si ṣe mọ pe ayé ninu ọgbọ́n rẹ̀ kò mọ Ọlọrun?
KINLA? Jehofa yoo ha lo ìwà-òmùgọ̀ bi? Kò daju! Ṣugbọn oun le ṣe bẹẹ oun si ń lo ohun ti o farahan bii ìwà-òmùgọ̀ si ayé. Oun ń ṣe bẹẹ lati le gba awọn eniyan ti wọn mọ̀ ón ti wọn si nifẹẹ rẹ̀ là. Nipasẹ ọgbọ́n rẹ̀, ayé kò lè mọ Ọlọrun. Jesu Kristi mu eyi ṣe kedere nigba ti oun sọ ninu adura pe: “Baba olododo, ayé kò mọ̀ ọ́.”—Johannu 17:25.
2. Bawo ni o ṣe le dabi ẹni pe awọn ọ̀nà Jehofa ati awọn ọ̀nà ayé ń lọ ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu araawọn, ṣugbọn ki ni awọn otitọ naa?
2 Awọn ọ̀rọ̀ Jesu fihàn pe awọn ọ̀nà Jehofa yatọ si ti ayé. Lójú ó lè farahan pe ète Ọlọrun ati ti ayé yii ń lọ ní ifẹgbẹkẹgbẹ si araawọn. Ó le dabi ẹni pe awọn ète ayé yii ni ibukun Ọlọrun ninu. Fun apẹẹrẹ, Bibeli wi pe Ọlọrun yoo gbé ijọba ododo kan kalẹ ti yoo mu igbesi-aye ninu alaafia, idunnu, ati aasiki wá fun araye lori ilẹ̀-ayé. (Isaiah 9:6, 7; Matteu 6:10) Bakan-naa, ayé ń fun kàkàkí ète rẹ̀ lati fun awọn eniyan ni alaafia, aasiki, ati ijọba rere nipasẹ eto ayé titun ti a fẹnu lasan pe bẹẹ. Ṣugbọn awọn ète Ọlọrun ati awọn ti ayé kìí ṣe ọkan-naa. Ète Jehofa jẹ́ lati dá araarẹ lare gẹgẹ bi Ọba-Alaṣẹ agbaye Giga julọ. Eyi ni oun yoo ṣe nipasẹ ijọba ọ̀run kan ti yoo pa gbogbo awọn ijọba ayé run. (Danieli 2:44; Ìfihàn 4:11; 12:10) Nitori naa Ọlọrun kò ni ohunkohun ni ifarajọra pẹlu ayé yii. (Johannu 18:36; 1 Johannu 2:15-17) Idi niyẹn ti Bibeli fi sọ nipa oriṣi ọgbọ́n meji—“ọgbọn Ọlọrun” ati “ọgbọ́n ayé.”—1 Korinti 1:20, 21.
Olori Àléébù Ọgbọ́n Ayé
3. Bi o tilẹ jẹ pe ọgbọ́n ti ayé le dabi eyi ti ń wuni lori, eeṣe ti eto ayé titun ti eniyan ṣeleri kì yoo fi jẹ eyi ti ń tẹnilọrun lae?
3 Fun awọn ti ọgbọn Ọlọrun kò ṣamọna, o dabi ẹni pe ọgbọ́n ayé ń wúnilórí. Awọn ọgbọ́n imọ-ọran elero-giga ti ayé tí ń gbanilọkan wà. Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ibi idasilẹ ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ti o tubọ ga ju ni wọn ń funni ni isọfunni ti ó wá lati ọ̀dọ̀ awọn ti ọpọlọpọ kà si ọlọgbọnloye julọ ninu araye. Awọn ibi akojọ iwe kíkà pípọ̀níye ni wọn kunfọfọ fun akojọpọ ìmọ̀ nipa ọpọ ọrundun iriri eniyan. Bi o ti wu ki o ri, laika gbogbo eyi si, eto aye titun naa tí awọn alaṣẹ ayé pete lè jẹ́ iṣakoso kan lati ọwọ eniyan alaipe, ti ẹṣẹ ti tabuku si, ẹni kíkú. Nitori eyi, eto naa yoo jẹ́ alaipe, ti ń ṣatunṣe ọpọ awọn ìṣìnà ti o ti kọja ti kò si tẹ́ aini gbogbo araye lọrun lae.—Romu 3:10-12; 5:12.
4. Ki ni eto ayé titun ti a gbèrò naa wà labẹ rẹ̀, pẹlu iyọrisi wo si ni?
4 Eto ayé titun tí eniyan pète rẹ̀ wà labẹ kìí ṣe kiki ailera ẹda nikan ni ṣugbọn bakan-naa labẹ idari awọn ẹda-ẹmi buburu—bẹẹni, Satani Eṣu ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀. Satani ti sọ ọkàn awọn eniyan di afọju ki wọn ki o ma le gba “imọlẹ ihinrere Kristi” gbọ́. (2 Korinti 4:3, 4; Efesu 6:12) Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, ayé ń jìyà ailera kan lẹhin omiran. Ó ń jijakadi ó sì ń japoró ninu idawọle onijamba rẹ̀ lati ṣakoso araarẹ laisi iranlọwọ Ọlọrun ati laisi ọ̀wọ̀ fun ifẹ atọrunwa. (Jeremiah 10:23; Jakọbu 3:15, 16) Nipa bẹẹ, gẹgẹ bi aposteli Paulu ti sọ “ayé nipasẹ ọgbọ́n rẹ̀ kò mọ Ọlọrun.”—1 Korinti 1:21.
5. Ki ni olori àléébù ọgbọ́n ayé yii?
5 Nigba naa, ki ni olori àléébù ọgbọ́n ayé yii, titi kan awọn iṣeto rẹ̀ fun eto ayé titun kan? Oun ni pe aye dagunla si ohun ti kò ṣee dagunla si lae pẹlu aṣeyọrisirere — ipo jíjẹ́ ọba-alaṣẹ agbaye giga julọ ti Jehofa Ọlọrun. O fi igberaga kọ̀ lati mọyi ipo ọba-alaṣẹ atọrunwa. Ayé mọọmọ yọ Jehofa kuro ninu gbogbo iṣeto rẹ̀ o si gbarale agbara ati ipete tirẹ̀. (Fiwe Danieli 4:31-34; Johannu 18:37.) Bibeli mu un ṣe kedere pe “ibẹru Oluwa [“Jehofa,” NW] ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n.” (Owe 9:10; Orin Dafidi 111:10) Sibẹ, ayé kò tilẹ tii kẹkọọ ohun ṣiṣekoko ti ọgbọ́n beere fun yii. Nitori naa, laisi itilẹhin atọrunwa, bawo ni ó ṣe le ṣaṣeyọrisirere?—Orin Dafidi 127:1.
Iwaasu Ijọba—Ìwà-òmùgọ̀ Tabi Ohun Ti O Bá Ọgbọ́n Mu?
6, 7. (a) Awọn tí ọgbọ́n Ọlọrun ń ṣamọna ń waasu ki ni, ṣugbọn oju wo ni ayé fi ń wò wọn? (b) Ni ibamu pẹlu ọgbọ́n ta ni awọn alufaa Kristẹndọm fi ń waasu, pẹlu iyọrisi wo si ni?
6 Ni ọwọ miiran ẹ̀wẹ̀, awọn ti wọn mọ Ọlọrun ń fi ọgbọ́n Ọlọrun hàn wọn si yàn lati jẹ́ ki ó ṣamọna wọn. Gẹgẹ bi Jesu ti sọtẹlẹ, wọn ń waasu “ihinrere ijọba yii ni gbogbo ayé.” (Matteu 24:14; 28:19, 20) Ǹjẹ́ iru iwaasu bẹẹ ha gbeṣẹ nisinsinyi, nigba ti ayé wa kún fun aáwọ̀, biba ayika jẹ́, òṣì, ati ijiya eniyan bi? Si awọn ọlọgbọn ayé iru iwaasu bẹẹ nipa Ijọba Ọlọrun dabi kìkì ìwà-òmùgọ̀ paraku, ti kò gbeṣẹ. Wọn ka awọn oniwasu Ijọba Ọlọrun si ayọnilẹnu ti ń ṣediwọ fun Ijọba ti wọn si ń fawọ́ ilọsiwaju rẹ̀ siha ijọba oṣelu ti o bojumu sẹhin. Ninu eyi ni awọn alufaa Kristẹndọm ti tì wọn lẹhin, awọn ẹni ti wọn ń waasu ni ibamu pẹlu ọgbọ́n ayé yii ti wọn kò si sọ fun awọn eniyan ohun ti wọn nilati mọ̀ nipa ayé titun Ọlọrun ati iṣakoso Ijọba rẹ̀, bi o tilẹ jẹ pe eyi ni olori ikọnilẹkọọ Kristi.—Matteu 4:17; Marku 1:14, 15.
7 Opitan H. G. Wells pe afiyesi si ikuna awọn alufaa Kristẹndọm yii. Ó kọwe pe: “Ijẹpataki ńláǹlà ti Jesu fifun ẹ̀kọ́ ohun ti o pè ni Ijọba Ọrun, ati ifiwera aijamọ nǹkan rẹ̀ ninu ọ̀nà igbaṣe ati ẹ̀kọ́ ọpọ julọ awọn ṣọọṣi Kristian jẹ eyi ti o jọniloju.” Sibẹ, bi awọn eniyan ọrundun yii ba nilati jere iwalaaye, wọn nilati kọkọ gbọ́ nipa Ijọba Ọlọrun ti a ti gbekalẹ, lati ṣaṣepari iyẹn ẹnikan gbọdọ waasu ihinrere nipa rẹ̀.—Romu 10:14, 15.
8. Eeṣe ti wiwaasu ihinrere Ọlọrun fi jẹ́ ohun ti o ba ọgbọ́n mu julọ lati ṣe lonii, ṣugbọn ipa-ọna igbesẹ wo ni kì yoo ní anfaani pipẹtiti?
8 Nigba naa, wiwaasu ihinrere Ọlọrun, ni ohun ti o bá ọgbọ́n mu julọ lati ṣe lonii. Eyi ri bẹẹ nitori pe ihin-iṣẹ Ijọba naa pese ojulowo ireti kan ti o mú idunnu kun ọkàn eniyan lakooko awọn ọjọ ikẹhin yii nigba ti ‘ìgbà ti o lekoko ti wà nihin-in.’ (2 Timoteu 3:1-5; Romu 12:12; Titu 2:13) Nigba ti o jẹ́ pe iwalaaye ninu ayé yii kò daniloju ti o si kúrú, iwalaaye ninu ayé titun Ọlọrun yoo jẹ́ titi ayeraye, ninu idunnu, ọpọ yanturu, ati alaafia nihin-in lori ilẹ̀-ayé. (Orin Dafidi 37:3, 4, 11) Gẹgẹ bi Jesu Kristi ti sọ, “èrè ki ni fun eniyan, bi o jere gbogbo ayé, ti o si sọ ẹmi rẹ̀ nù? tabi ki ni eniyan iba fi ṣe paṣipaarọ ẹmi rẹ̀?” Bi ẹnikan ba padanu ẹ̀tọ́ naa lati gbé ninu ayé titun Ọlọrun, èrè ki ni ayé tí ń kọjalọ yii jẹ́? Gbigbadun tí iru ẹni bẹẹ ń gbadun ohun-ìní ti ara nisinsinyi ti jẹ́ òtúbáńtẹ́, asán, ati alaitọjọ.—Matteu 16:26; Oniwasu 1:14; Marku 10:29, 30.
9. (a) Nigba ti ọkunrin kan ti a kesi lati jẹ ọmọlẹhin Jesu beere fun ìsún-àkókò-síwájú, ki ni Jesu gbà á nimọran lati ṣe? (b) Bawo ni idahun Jesu ṣe nilati nipa lori wá?
9 Ọkunrin kan ti Jesu kesi lati jẹ́ ọmọlẹhin rẹ̀ wi pe: “Jẹ́ ki emi ki o kọ́ lọ isinku baba mi ná.” Ki ni Jesu gbà á nimọran lati ṣe? Ni mímọ̀ pe ọkunrin naa yoo maa sún iṣẹ ṣiṣe pataki julọ kan siwaju kiki lati duro titi di ìgbà ti awọn obi rẹ̀ bá kú, Jesu dahun pe: “Jẹ́ ki awọn oku ki o maa sinku araawọn: ṣugbọn iwọ lọ ki o si maa waasu ijọba Ọlọrun.” (Luku 9:59, 60) Awọn ti wọn ń fi ọgbọ́n hàn nipa ṣiṣegbọran si Kristi kò le yipada kuro ninu mimu àṣẹ ti a fifun wọn lati waasu ihin-iṣẹ Ijọba naa ṣẹ. Ọgbọ́n atọrunwa mú wọn mọ̀ pe ayé yii ati awọn alakoso rẹ̀ ni a ti dẹbi iparun fun. (1 Korinti 2:6; 1 Johannu 2:17) Awọn ti wọn kọwọti jíjẹ́ ọba-alaṣẹ Ọlọrun mọ̀ pe ireti tootọ kanṣoṣo fun araye sinmilori ìdásí ọ̀ràn ati iṣakoso atọrunwa. (Sekariah 9:10) Nitori naa bi awọn ti wọn ni ọgbọ́n ti ayé yii kò ti gbagbọ ninu Ijọba Ọlọrun ti wọn kò si fẹ́ ijọba atọrunwa yẹn, awọn ti a ń dari nipasẹ ọgbọ́n atọrunwa ń ṣe ohun ti ń mú anfaani gidi wá fun awọn eniyan ẹlẹgbẹ wọn, ni mimura wọn silẹ fun iwalaaye ayeraye ninu ayé titun tí Jehofa ṣeleri.—Johannu 3:16; 2 Peteru 3:13.
“Ìwà-òmùgọ̀ si Awọn Ti Ń Ṣègbé”
10. (a) Nigba ti a yí Saulu ara Tarsu lọkan pada, iṣẹ wo ni oun nawọ́gán, oju wo ni o si fi wò ó? (b) Fun ki ni awọn ará Griki igbaani jẹ́ gbajumọ, ṣugbọn bawo ni Ọlọrun ṣe wo ọgbọ́n wọn?
10 Saulu ara Tarsu, ẹni ti o wá di Paulu aposteli Jesu Kristi, nọwọgan iṣẹ gbígba ẹmi là yii. O ha bọgbọnmu lati ronu pe nigba ti Jesu yí Saulu lọkan pada, Oun ń yanṣẹ fun un lati lọwọ ninu igbokegbodo kan ti o jẹ́ ti òmùgọ̀ bi? Paulu kò ronu bẹẹ. (Filippi 2:16) Ni akoko yẹn awọn Griki ni a kà si awọn eniyan olóye julọ ni agbaye. Wọn ń yangan nipa awọn onimọ nla ati ọkunrin ọlọgbọn wọn. Bi o tilẹ jẹ pe Paulu ń sọ ede Griki, oun kò tẹle awọn ọgbọ́n imọ ati ọran ẹkọ ilẹ Griki. Eeṣe? Nitori pe iru ọgbọ́n ayé yii bẹẹ jẹ ìwà-òmùgọ̀ lọdọ Ọlọrun.a Paulu wá ọgbọ́n atọrunwa, eyi ti o sun un lati waasu ihinrere naa lati ile de ile. Oniwaasu giga julọ ni gbogbo ayé, Jesu Kristi, ti fi apẹẹrẹ lelẹ o si ti fun un ni itọni lati ṣe iṣẹ kan-naa.—Luku 4:43; Iṣe 20:20, 21; 26:15-20; 1 Korinti 9:16.
11. Ni pataki julọ, ki ni Paulu sọ nipa aṣẹ iwaasu rẹ̀ ati ọgbọ́n ayé?
11 Paulu sọ eyi nipa aṣẹ ti a pa fun un lati waasu: “Kristi rán mi lọ . . . lati lọ maa kede ihinrere, kìí ṣe pẹlu ọgbọ́n ọ̀rọ̀ sisọ, ki a ma baa sọ òpó-igi ìdálóró Kristi di alaiwulo. Nitori ọ̀rọ̀ sisọ nipa òpó-igi ìdálóró naa [ẹbọ irapada Jesu] jẹ́ ìwà-òmùgọ̀ si awọn wọnni ti ń ṣègbé, ṣugbọn si awa ti a ń gbala agbara Ọlọrun ni. Nitori a ti kọ ọ pe: ‘Emi yoo mu ọgbọ́n awọn ọlọgbọn eniyan ṣègbé, ati òye awọn amoye eniyan ni emi yoo bì si ẹ̀gbẹ́ kan.’ Nibo ni ọlọgbọn eniyan naa wà? Nibo ni akọwe naa wà? [iru bi awọn ọlọgbọn imọ-ọran] Nibo ni olùja-ìjà-ọ̀rọ̀ eto awọn nǹkan yii wà? Ọlọrun kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé yii di ìwà-òmùgọ̀? Nitori niwọn bi, ninu ọgbọ́n Ọlọrun, ayé nipasẹ ọgbọ́n rẹ̀ kò mọ Ọlọrun, Ọlọrun rii pe o dara nipasẹ ìwà-òmùgọ̀ ohun ti a ń waasu lati gba awọn wọnni ti wọn ń gbagbọ là.”—1 Korinti 1:17-21, NW.
12. Ki ni Jehofa ń ṣaṣepare rẹ̀ nipasẹ “ìwà-òmùgọ̀ ohun ti a ń waasu,” bawo si ni awọn ti wọn ń fẹ́ “ọgbọ́n atọrunwa” yoo ṣe huwapada?
12 Bi o ti wu ki o dabi eyi ti ó ṣoro lati gbagbọ tó, awọn wọnni gan-an ti ayé ń pè ni òmùgọ̀ ni awọn ti Jehofa ń lò gẹgẹ bi oniwaasu rẹ̀. Bẹẹni, nipasẹ ìwà-òmùgọ̀ iṣẹ-ojiṣẹ awọn oniwaasu wọnyi, Ọlọrun ń gba awọn ti wọn gbagbọ là. Jehofa ń ṣeto awọn ọran ki o baa le jẹ pe awọn oniwaasu “ìwà-òmùgọ̀” yii kò ni le ṣogo nipa araawọn, awọn eniyan miiran kò si le fi ẹ̀tọ́ ṣogo nipa awọn wọnni ti wọn tipasẹ wọn gbọ́ ihinrere naa. Eyi ri bẹẹ nitori “ki ẹran-ara kankan ma le ṣogo niwaju Ọlọrun.” (1 Korinti 1:28-31; 3:6, 7, NW) Lotiitọ, oniwaasu naa kó ipa pataki kan, ṣugbọn ihin-iṣẹ naa ti a ti gbé fun un lati waasu ni ohun ti ń ṣiṣẹ siha igbala ẹnikan bi ẹni naa ba gba ihin-iṣẹ naa gbọ. Awọn wọnni ti wọn ń fẹ́ “ọgbọ́n ti o ti oke wá” ki yoo kọ ihin-iṣẹ awọn oniwaasu naa nitori oun dabi òmùgọ̀ ati ọlọkan-tutu, a ṣenunibini si i, o si ń lọ lati ile de ile. Kaka bẹẹ, awọn ọlọkan-tutu yoo bọwọ fun olupokiki Ijọba kan gẹgẹ bi oniwaasu kan ti Jehofa fi aṣẹ fun ti o si ń bọ̀ ni orukọ Ọlọrun. Wọn yoo so ijẹpataki nlanla mọ́ ihin-iṣẹ ti oniwaasu naa ń mú wa nipa ọ̀rọ̀ ẹnu ati nipa awọn oju-iwe ti a tẹ̀.—Jakọbu 3:17; 1 Tessalonika 2:13.
13. (a) Bawo ni awọn Ju ati awọn Griki ṣe wo iwaasu Kristi ti a kanmọgi? (b) Lati inu ẹgbẹ́ awọn awọn eniyan wo ni a kò ti pe ọpọlọpọ lati jẹ́ ọmọlẹhin Jesu, eesitiṣe?
13 Ni biba ijiroro rẹ̀ nipa awọn ọ̀nà Ọlọrun lọ, Paulu wi pe: “Nitori awọn Ju ń beere awọn àmì awọn Griki si ń wá ọgbọ́n; ṣugbọn awa ń waasu Kristi ti a kan mọgi, okunfa fun ikọsẹ fun awọn Ju ṣugbọn ìwà-òmùgọ̀ fun awọn orilẹ-ede; bi o ti wu ki o ri, fun awọn wọnni ti wọn jẹ́ ẹni ti a pè, ati awọn Ju ati awọn Griki, Kristi agbara Ọlọrun ati ọgbọ́n Ọlọrun. Nitori ohun òmùgọ̀ ti Ọlọrun gbọ́n ju awọn eniyan lọ, ati ohun ailera ti Ọlọrun lagbara ju awọn eniyan lọ. Nitori ẹyin rí ìpè rẹ̀ ti o pè yin, ẹyin ara, pe kìí ṣe ọpọ awọn ọlọgbọn ní ọ̀nà ti ara ni a pè, kì í ṣe ọpọ awọn alagbara, kìí ṣe ọpọ awọn ẹni-a-bíire; ṣugbọn Ọlọrun yan awọn ohun òmùgọ̀ ayé ki o baa le kó itiju bá awọn ọlọgbọn eniyan; Ọlọrun si yan awọn ohun alailera ayé, ki o baa le kó itiju bá awọn ohun alagbara.”—1 Korinti 1:22-27, NW; fiwe Isaiah 55:8, 9.
14. (a) Bi a ba bi wọn nipa ìwé-ẹ̀rí wọn, ki ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa maa ń tọka si? (b) Eeṣe ti Paulu fi kọ̀jalẹ lati tẹ́ awọn ara Griki lọrun pẹlu ṣiṣagbeyọ ọgbọ́n ayé lọnakọna?
14 Nigba ti Jesu wà lori ilẹ̀-ayé, awọn Ju beere fun àmì kan lati ọ̀run. (Matteu 12:38, 39; 16:1) Ṣugbọn Jesu kọ̀ jalẹ lati fun wọn ni àmì eyikeyii. Bakan-naa, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii kò ṣagbeyọ awọn ìwé-ẹ̀rí eyikeyii ti o dabi àmì. Kaka bẹẹ, wọn tọka si aṣẹ ti a fun wọn lati waasu ihinrere naa, bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu awọn ẹsẹ Bibeli bii Isaiah 61:1, 2; Mark 13:10; ati Ìfihàn 22:17. Awọn Griki igbaani wá ọgbọn, imọ-iwe ti o gaju ninu awọn ohun ti ayé yii. Nigba ti a dá Paulu lẹkọọ ninu ọgbọ́n ayé yii, oun kọ̀ lati tẹ́ awọn Griki lọrun nipa ṣiṣagbeyọ rẹ̀ lọnakọna. (Iṣe 22:3) Oun sọrọ o si kọwe ni ede Griki tí awọn eniyan gbaatuu fi ń sọrọ, dipo ede Griki ti awọn gbajumọ. Paulu wi fun awọn ara Korinti pe: “Nigba ti mo wá sí ọ̀dọ̀ yin, ẹyin ará, [emi] kò wá pẹlu irekọja-aala iwoyeronu ọ̀rọ̀ sisọ tabi ti ọgbọ́n ni kikede aṣiri mímọ́-ọlọ́wọ̀ Ọlọrun fun yin. . . . Ọ̀rọ̀ sisọ mi ati ohun ti mo waasu rẹ̀ kìí ṣe pẹlu ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti ń yinilọkanpada bikoṣe pẹlu àṣefihàn ẹmi ati agbara ki igbagbọ yin má lè wà ninu ọgbọ́n eniyan, bikoṣe ninu agbara Ọlọrun.”—1 Korinti 2:1-5, NW.
15. Nipa ki ni Peteru rán awọn apẹgan ihinrere leti, bawo si ni ipo ti lọọlọọ ṣe ri bakan-naa pẹlu ti ọjọ Noa?
15 Ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyii, awọn apẹ̀gàn ihinrere ayé titun Ọlọrun tí ń bọwa ati opin ayé yii tí ń sunmọle ni aposteli Peteru rán leti pe “omi bò ayé ti o wà” ni ọjọ Noa, “ti o si ṣègbé.” (2 Peteru 3:3-7) Ni didojukọ opin oníjàábá òjijì yẹn, ki ni Noa ṣe? Ọpọ eniyan ronu nipa rẹ̀ gẹgẹ bi kìkì akankọ̀ kan. Ṣugbọn Peteru sọ pe nigba ti Ọlọrun mu Ikun-omi naa wá sori ayé igbaani, Oun “pa Noa pẹlu awọn meje miiran mọ́, oniwaasu òdodo.” (2 Peteru 2:5) Ninu ọgbọ́n ti ayé wọn, awọn eniyan alaiwa-bi-Ọlọrun ti o wà ṣaaju ikun-omi naa laisi aniani kẹgan ohun ti Noa ń waasu wọn sì pè é ni òmùgọ̀, olùméfò, ati alailoye. Lonii, awọn Kristian tootọ ń koju ipo kan-naa, niwọn bi Jesu ti fi iran wa wé ti ọjọ Noa. Bi o ti wu ki o ri, laika awọn apẹgan si, iwaasu ihinrere Ijọba naa ju kiki ọ̀rọ̀ lasan lọ. Gẹgẹ bi iwaasu ti Noa ṣe, o tumọsi igbala fun oniwaasu naa ati fun awọn wọnni ti wọn fetisilẹ si i!—Matteu 24:37-39; 1 Timoteu 4:16.
‘Dídi Òmùgọ̀ Lati Le Di Ọlọgbọn’
16. Ki ni yoo ṣẹlẹ si ọgbọ́n ayé yii ni Armageddoni, ta ni yoo si laaja sinu ayé titun Ọlọrun?
16 Laipẹ, ni Armageddoni, Jehofa Ọlọrun yoo “pa ọgbọ́n awọn ọlọgbọn run.” Oun yoo si “sọ òye awọn olóye di asán,” awọn ti wọn ń sọ asọtẹlẹ nipa bi eto ayé titun wọn yoo ṣe mú awọn ipo didara ju wá fun araye. “Ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” yoo fi ina pa gbogbo ọgbọ́n ẹ̀tàn, ọgbọ́n imọ-ọran, ati ọgbọ́n ayé yii run. (1 Korinti 1:19; Ìfihàn 16:14-16) Kiki awọn ti yoo la ogun yẹn já ti wọn yoo si jere iwalaaye ninu ayé titun Ọlọrun ni awọn ti wọn ṣegbọran si ohun ti ayé yii ń pè ni ìwà-òmùgọ̀—bẹẹni, ihinrere ologo ti Ijọba Jehofa.
17. Bawo ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ṣe di ‘òmùgọ̀,’ ki si ni awọn oniwaasu ihinrere ti Ọlọrun ti ṣetan lati ṣe?
17 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ti ẹmi rẹ̀ ń darí, kò tiju lati waasu ohun ti ayé ń pè ni ìwà-òmùgọ̀. Dipo gbigbiyanju lati jẹ ọlọgbọn sipa ti ayé, wọn ti di ‘òmùgọ̀.’ Bawo? Nipa ṣiṣe iṣẹ iwaasu Ijọba naa ki wọn baa le gbọ́n, gẹgẹ bi Paulu ti kọwe pe: “Bi ẹnikẹni ninu yin ba rò pe oun gbọ́n ninu eto awọn nǹkan yii, jẹ ki o di òmùgọ̀, ki o baa le di ọlọgbọn.” (1 Korinti 3:18-20) Awọn oniwaasu ihinrere ti Jehofa mọ ijẹpataki gbigba ẹmi là ihin-iṣẹ wọnni wọn yoo si maa baa lọ ni wiwaasu rẹ̀ laidawọduro titi de opin ayé yii ati ọgbọ́n rẹ̀ ni ogun Armageddoni. Laipẹ, Jehofa Ọlọrun yoo dá ipo ọba-alaṣẹ agbaye rẹ̀ lare yoo si mu iye ayeraye wa fun gbogbo awọn wọnni ti ń gbagbọ ti wọn si ń gbegbeesẹ nisinsinyi lori “iwa òmùgọ̀ ohun ti a ń waasu rẹ̀.”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Laika gbogbo awọn ariyanjiyan ọlọgbọn imọ-ọran ati iṣewadii awọn ọkunrin ọlọgbọn ti Griki igbaani si, awọn akọsilẹ wọn fihàn pe wọn kò rí ojulowo ipilẹ kankan fun ireti. Awọn ọjọgbọn J. R. S. Sterrett ati Samuel Angus tọka pe: “Kò si iwe kíkà kan ti o tubọ ni awọn ìdárò amunikaanu lori awọn ibanujẹ igbesi-aye, irekọjalọ ifẹ, itanjẹ nipa ireti, ati bi ikú ti jẹ́ alailaanu tó ninu.”—Funk and Wagnalls New “Standard” Bible Dictionary, 1936, oju-iwe 313.
Ki Ni Idahun Rẹ?
◻ Iru oriṣi ọgbọn meji wo ni o wà?
◻ Ki ni olori àléébù ọgbọ́n ayé?
◻ Eeṣe ti wiwaasu ihinrere naa fi jẹ́ ohun ti o gbeṣẹ julọ lati ṣe?
◻ Ki ni yoo ṣẹlẹ laipẹ si gbogbo ọgbọ́n ayé?
◻ Eeṣe ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò fi tiju lati waasu ohun ti ayé pe ni ìwà-òmùgọ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Awọn ara Griki wa ọgbọ́n ti ayé wọn si saba maa ń wo iwaasu Paulu bii ìwà-òmùgọ̀