Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù January: Ìwé èyíkéyìí tí a tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1988 tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Bí ẹ kò bá ní èyíkéyìí lára àwọn ìwé wọ̀nyí, ẹ béèrè bóyá àwọn ìjọ tó wà nítòsí yín ní ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ lọ́wọ́ tẹ́ ẹ lè rí lò. Àwọn ìjọ tí kò bá ní àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ lọ́wọ́ lè fi ìwé Mankind’s Search for God lọni. February: Sún Mọ́ Jèhófà. Bí kò bá sí lọ́wọ́, a lè lo ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! gẹ́gẹ́ bí àfidípò. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A ó sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Bí àwọn onílé bá ti ní ìwé yìí, a lè fi ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! lọ̀ wọ́n. April: Fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Nígbà tí o bá ń lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò àwọn tó fìfẹ́ hàn, yà lọ́dọ̀ àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí tàbí àwọn ìgbòkègbodò mìíràn nínú ìjọ àmọ́ tí wọn ò tíì wá sínú ètò àjọ Jèhófà. Pọkàn pọ̀ sórí fífi ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run lọni. Kí á sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, pàápàá jù lọ bí àwọn onílé kan bá ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tẹ́lẹ̀.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ March 15, 2004, a ó máa kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Sún Mọ́ Jèhófà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February, tàbí ó pẹ́ tán ní March 7, àsọyé fún gbogbo ènìyàn tuntun tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “ÌLÀNÀ TA LO MÁA Ń FỌWỌ́ PÀTÀKÌ MÚ?”
◼ Kí àwọn ìjọ ṣètò tó rọrùn láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́dún yìí ní ọjọ́ Sunday, April 4, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọyé náà lè bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí kiri kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ àyàfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Níwọ̀n bí a kò ti gbọ́dọ̀ ṣe ìpàdé kankan àyàfi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́jọ́ náà, kí a ṣe ìyípadà tó yẹ láti rí i pé a ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ní àkókò mìíràn. Àwọn alábòójútó àyíká ní láti ṣe ìyípadà sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé ọ̀sẹ̀ yẹn bó bá ṣe bá ipò ìjọ tí wọ́n ń bẹ̀ wò mu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ti dára ni pé kí ìjọ kọ̀ọ̀kan dá ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tiwọn, kì í ṣeé ṣe nígbà mìíràn. Tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan ni wọ́n jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè lọ gba ibòmíràn tí wọn yóò lò lálẹ́ ọjọ́ yẹn. A dábàá pé níbi tó bá ti ṣeé ṣe, kí ó tó ogójì ìṣẹ́jú ó kéré tán, lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ìjọ kan kí ti ìjọ tó tẹ̀ lé e tó bẹ̀rẹ̀ kí olúkúlùkù lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ayẹyẹ náà. Ó yẹ kí a tún ronú nípa bí àwọn ọkọ̀ tá a óò gbé wá kò ṣe ní ṣèdíwọ́ àti nípa ibi tí a óò gbé wọn sí, títí kan jíjá èrò sílẹ̀ àti gbígbé èrò. Kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà pinnu ètò tí yóò dára jù lọ fún ìjọ wọn.