Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí ni a óò dáhùn ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 23, 2004. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ January 5 sí February 23, 2004. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, kí o fúnra rẹ ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Kí la lè ṣe láti rí i dájú pé àwùjọ rí bí ọ̀rọ̀ wa ṣe wúlò ní kedere, wọ́n sì jàǹfààní gidigidi nínú rẹ̀? [be-YR ojú ìwé 158, ìpínrọ̀ 2 sí 4]
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká fara balẹ̀ yan ọ̀rọ̀ tí a ó lò? [be-YR ojú ìwé 160, ìpínrọ̀ 1 àti àpótí kejì]
3. Kí ni ohun pàtàkì kan téèyàn ní láti ṣe tó bá fẹ́ sọ̀rọ̀ tó múná dóko gẹ́gẹ́ bí 1 Kọ́ríńtì 14:9 ṣe fi hàn, báwo la sì ṣe lè lo ìlànà yìí nígbà tá a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́? [be-YR ojú ìwé 161, ìpínrọ̀ 1 sí 4]
4. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i kà nínú Mátíù 5:3-12 àti Máàkù 10:17-21, kí ni ọ̀nà títayọ kan tí Jésù máa ń gbà kọ́ni tá a lè fara wé? [be-YR ojú ìwé 162, ìpínrọ̀ 4]
5. Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tàbí nígbà tá a bá ń dáhùn ìbéèrè ní ìpàdé ìjọ, kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo ọ̀rọ̀ tó ń tani jí, ọ̀rọ̀ tó ń fi bí nǹkan ṣe rí lára hàn àti ọ̀rọ̀ àpọ́nlé? (Mát. 23:37, 38) [be-YR ojú ìwé 163, ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 164 ìpínrọ̀ 1]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Kí ni ẹṣin ọ̀rọ̀, báwo sì ni fífi í sọ́kàn ṣe lè ṣèrànwọ́ nígbà tá a bá ń yan àwọn kókó tá a fẹ́ lò nínú ọ̀rọ̀ wa, tá a sì ń tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ? [be-YR ojú ìwé 39, ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 40 ìpínrọ̀ 1]
7. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ mímọ́ nípa tẹ̀mí, kí nìdí tá a sì fi lè sọ pé ìjẹ́mímọ́ tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù lọ? (b) Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè yẹra fún ìwà àìmọ́ tó wọ́pọ̀ nínú ayé? [w02-YR 2/1 ojú ìwé 5 àti 6]
8. Nínú gbogbo ìlànà tó wà nínú Bíbélì, àwọn wo ló tẹ̀wọ̀n jù lọ? [w02-YR 2/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1, 4, 6]
9. Kí ni ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, báwo sì ni Jésù ṣe fi ànímọ́ yìí hàn? [w02-YR 4/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 4 àti 5]
10. Báwo ni Òwe 11:11 ṣe kan àwọn ìjọ àwọn èèyàn Jèhófà? [w02-YR 5/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Kí ni “igi ìyè” tí Bíbélì mẹ́nu kàn nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:9 dúró fún?
12. Kí nìdí tí aya Lọ́ọ̀tì fi fẹ̀mí ara rẹ̀ ṣòfò? (Jẹ́n. 19:26) [w90-YR 4/15 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 10]
13. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí 24, ta lẹni tí àwọn tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí dúró fún: (a) Ábúráhámù, (b) Ísákì, (d) Élíésérì, ìránṣẹ́ Ábúráhámù, (e) àwọn ràkúnmí mẹ́wàá, àti (ẹ) Rèbékà?
14. Ǹjẹ́ Ọlọ́run ti kádàrá ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Jákọ́bù àti Ísọ̀? (Jẹ́n. 25:23)
15. Báwo ni Rákélì ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere nípa ẹni tó ṣe ìsapá àtọkànwá, tí Jèhófà sì bù kún un? (Jẹ́n. 30:1-8) [w02-YR 8/1 ojú ìwé 29 àti 30]