A Lè Ṣe Ohun Tí Jèhófà Ní Ká Ṣe
1. Ìrònú nípa àwọn nǹkan wo ló lè máa dà wá láàmú nígbà míì, kí nìdí tí èyí sì fi rí bẹ́ẹ̀?
1 Pípa àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà mọ́ ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà gbé ìgbésí ayé lónìí, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la ayérayé. (Sm. 19:7-11; 1 Tím. 6:19) Àmọ́, ayé Sátánì ń mú pákáǹleke tí kì í ṣe kékeré bá wa. Ara àìpé wa náà sì tún mú kí ìṣòro yìí burú sí i. Gbogbo nǹkan lè sú wa nígbà míì níbi tá a ti ń gbìyànjú láti ṣe ojúṣe tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ fún wa. (Sm. 40:12; 55:1-8) A tiẹ̀ lè máa wò ó pé bóyá la lè ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà ní ká ṣe. Nírú àwọn ìgbà bẹ́ẹ̀, kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti dúró sán-ún nípa tẹ̀mí?
2. Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìfòyebánilò hàn nínú ohun tó ní ká ṣe?
2 Àwọn Àṣẹ Jèhófà Kò Nira: Jèhófà kì í béèrè ohun tí agbára wa ò ní lè gbé lọ́wọ́ wa. Àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira, àmọ́ àǹfààní wa ni wọ́n wà fún. (Diu. 10:12, 13; 1 Jòhánù 5:3) Ó mọ ibi tí agbára ẹ̀dá èèyàn mọ, ó ń “rántí pé ekuru ni wá.” (Sm. 103:13, 14) Ọlọ́run ń fi àánú gba ohunkóhun tá a bá sa gbogbo ipá wa láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, kódà bí ipò tá a bá ara wa ò bá jẹ́ ká lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́. (Léf. 5:7, 11; Máàkù 14:8) Ó ń ké sí wa pé ká ju ẹrù ìnira wa sọ́dọ̀ òun, ó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé òun á mú kó ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́ olùṣòtítọ́.—Sm. 55:22; 1 Kọ́r. 10:13.
3. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fún wa lókun ká bàa lè ní ìfaradà?
3 A Nílò Ẹ̀mí Ìfaradà: Àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa àwọn adúróṣinṣin bí Èlíjà, Jeremáyà àti Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ ìdí tá a fi nílò ìfaradà. (Heb. 10:36) Jèhófà mú wọn dúró nígbà ìpọ́njú àti ìrẹ̀wẹ̀sì. (1 Ọba 19:14-18; Jer. 20:7-11; 2 Kọ́r. 1:8-11) Bákan náà, ìdúróṣinṣin àwọn arákùnrin wa lóde òní tún ń fún wa níṣìírí. (1 Pét. 5:9) Ríronú jinlẹ̀ lórí irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa rẹ̀wẹ̀sì.
4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa rántí àwọn ìlérí Ọlọ́run nígbà gbogbo?
4 Ìrètí nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run jẹ́ “ìdákọ̀ró fún ọkàn.” (Héb. 6:19) Òun ló sún Ábúráhámù àti Sárà láti ṣègbọràn nígbà tí Jèhófà sọ pé kí wọ́n fi ilé wọn sílẹ̀, kí wọ́n lọ “ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí.” Ìrètí ló fún Mósè lókun láti fi àìṣojo ṣe ìjọsìn tòótọ́. Òun ló sì fún Jésù lágbára láti fara da òpó igi oró. (Héb. 11:8-10, 13, 24-26; 12:2, 3) Bákan náà, fífi ìlérí Ọlọ́run nípa ayé tuntun tí òdodo yóò ti gbilẹ̀ sọ́kàn nígbà gbogbo yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin.—2 Pét. 3:11-13.
5. Kí nìdí tí ríronú nípa bá a ṣe fi ìdúróṣinṣin hàn sẹ́yìn fi lè fún wa níṣìírí?
5 Láfikún sí i, bá a bá ń rántí bí àwa fúnra wa ti ṣe fi ìdúróṣinṣin, ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ àti ìgboyà hàn sẹ́yìn, èyí lè fún wa lókun nínú iṣẹ́ ìsìn wa. (Héb. 10:32-34) Ó tún ń jẹ́ ká rántí ayọ̀ tá a máa ń ní nígbà tá a bá fún Jèhófà ní ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ wa, ìyẹn ni pé ká sìn ín tọkàntọkàn.—Mát. 22:37.