Wíwàásù Ń Mú Ká Lè Lo Ìfaradà
1 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká “fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.” (Héb. 12:1) Bí sárésáré kan ṣe gbọ́dọ̀ lo ìfaradà kó bàa lè borí nínú ìdíje làwa náà ṣe gbọ́dọ̀ lo ìfaradà ká tó lè gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. (Héb. 10:36) Ọ̀nà wo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni fi lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìṣòtítọ́ fara dà á títí dópin?—Mát. 24:13.
2 Ó Ń Fún Wa Lókun Nípa Tẹ̀mí: Bá a ṣe máa ń pòkìkí àwọn ìlérí àgbàyanu tó wà nínú Bíbélì nípa ayé tuntun òdodo máa ń jẹ́ kí ìrètí tá a ní túbọ̀ dá wa lójú dáadáa. (1 Tẹs. 5:8) Tá a bá ń lọ sóde ẹ̀rí déédéé, á ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ tá a ti kọ́ látinú Bíbélì. A máa ń láǹfààní láti gbèjà ìgbàgbọ́ wa, a sì tún máa ń tipa bẹ́ẹ̀ lókun sí i nípa tẹ̀mí.
3 Ká tó lè kọ́ àwọn èèyàn débi tóhun tá a kọ́ wọn á fi yé wọn, òye òtítọ́ inú Bíbélì gbọ́dọ̀ yé àwa alára yékéyéké. A gbọ́dọ̀ ṣe ìwádìí jinlẹ̀ ká sì ṣàṣàrò lórí ohun tá a fẹ́ sọ. Bá a bá sapá tọkàntọkàn, a ó lè ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ dáadáa, a ó lè túbọ̀ máa lo ìgbàgbọ́, ara á sì tù wá nípa tẹ̀mí. (Òwe 2:3-5) Nítorí náà, bá a bá ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tó làwa náà á ṣe máa lókun nípa tẹ̀mí tó.—1 Tím. 4:15, 16.
4 Fífi ìtara lọ́wọ́ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,” èyí tá a nílò ká bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí Èṣù àtàwọn ẹ̀mí Èṣù rẹ̀. (Éfé. 6:10-13, 15) Bí ọwọ́ wa ṣe máa ń dí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa máa ń jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó lè gbé wa ró, ká sì yàgò fún dídi ẹni tí ayé Sátánì sọ dìdàkudà. (Kól. 3:2) Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà là ń rán ara wa létí bó ṣe yẹ káwa náà máa hùwà mímọ́.—1 Pét. 2:12.
5 Ọlọ́run Ń Fún Wa Lókun: Lákòótán, iṣẹ́ ajíhìnrere tá à ń ṣe máa ń kọ́ wa láti gbọ́kàn lé Jèhófà. (2 Kọ́r. 4:1, 7) Ìbùkún yẹn mà ga o! Kíkọ́ tá à ń kọ́ láti ní irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ ń mú wa gbára dì, kì í ṣe láti lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeyọrí nìkan ni, ṣùgbọ́n ká tún lè rára gba ohun yòówù tó lè dé bá wa nígbèésí ayé sí. (Fílí. 4:11-13) Ní tòótọ́, ká tó lè ní ìfaradà, ó ṣe pàtàkì pé ká kọ́ láti máa gbára lé Jèhófà pátápátá. (Sm. 55:22) Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni iṣẹ́ ìwàásù gbà ń ràn wá lọ́wọ́ láti lo ìfaradà.