Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 8
Orin 37
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán gbogbo àwọn ará létí pé kí wọ́n mú ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà, wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ March 15 àti Jí! April 8 lọni. Lo àbá kẹta ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! April 8 lọni.
15 min: Fífi Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ohun tó sábà máa ń nira jù lọ nínú iṣẹ́ ìwàásù ni bíbẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. A lè fi ìwé àṣàrò kúkúrú bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, níbi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé àti láwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn sábà máa ń wà. Ní ṣókí, gbé ìwé àṣàrò kúkúrú méjì tàbí mẹ́ta tó lè fa àwọn èèyàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìjọ yẹ̀ wò. Kí làwọn ohun tá a lè kọ́kọ́ sọ nígbà tá a bá ń fi àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà lọni? Báwo la ṣe lè lo àwọn àpèjúwe tó wà nínú wọn? Àwọn ìbéèrè wo la lè rọra fi ọgbọ́n béèrè? Tọ́ka sí ìpínrọ̀ kan nínú ìwé àṣàrò kúkúrú kọ̀ọ̀kan tá a lè lò bí onílé bá fìfẹ́ hàn. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ìwé àṣàrò kúkúrú bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Ní kí akéde tó ṣàṣefihàn náà jíròrò ìpínrọ̀ kan látinú ìwé àṣàrò kúkúrú náà ní ṣókí, kó sì parí ìjíròrò náà nípa fífi ìwé Ìmọ̀ lọ onílé.
20 min: “Ẹ Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Gbogbo Ẹ̀yin Ẹni Ìdúróṣinṣin.”a Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwùjọ nípa bí wọ́n ti ṣe ké sí àwọn èèyàn wá sí ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí.
Orin 131 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 15
Orin 121
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àpótí náà, “Àwọn Ìránnilétí Nípa Ìṣe Ìrántí.” Sọ ìgbà tí a ó ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ní ọ̀sẹ̀ Ìṣe Ìrántí. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù March sílẹ̀.
15 min: Ìròyìn Nípa Àkànṣe Ìgbòkègbodò Nígbà Ìṣe Ìrántí. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ yìí. Sọ àwọn ètò àkànṣe tá a ti ṣe. Sọ àwọn ìrírí díẹ̀ tá a ti ní. Rọ àwọn tó bá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April àti May láti fi orúkọ sílẹ̀. Ní ṣókí, jíròrò àwọn kókó díẹ̀ látinú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February.
20 min: Jàǹfààní Látinú Ìwé Pẹlẹbẹ Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà. Ìwé pẹlẹbẹ yìí lè mú ká túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i nígbà tá a bá ń kà á tàbí tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ohun èlò wíwúlò kan nínú rẹ̀ ni atọ́ka rẹ̀. Ka Aísáyà 63:1, tó sọ pé Jèhófà ń bọ̀ láti Bósírà. Rọ gbogbo àwọn ará láti wá orúkọ náà, Bósírà nínú atọ́ka tó wà nínú Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà. Ṣàlàyé ohun tí “Bósírà 11 G11” túmọ̀ sí, nípa lílo àpótí tó wà lójú ewé 34, kó o sì wá Bósírà àti Édómù nínú àwòrán ilẹ̀ tá a tọ́ka sí. Lo atọ́ka náà láti wá ojú ọ̀nà tí Jésù gbà láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Síkárì. (Jòh. 4:3-5) Tún lò ó láti fi wá ibi tí odò adágún Bẹtisátà wà. (Jòh. 5:1-3) Lo àpẹẹrẹ kan tàbí méjì sí i látinú Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ké sí àwùjọ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn ibi tá a ti lè rí àwọn àgbègbè náà nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí, àti bí wíwo àwòrán ilẹ̀ náà ṣe lè ṣe wá láǹfààní. Ní ṣókí, tọ́ka sí díẹ̀ lára àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí, kó o sì mẹ́nu kan àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan wáyé níbẹ̀. Àwòrán ilẹ̀ tó wà lójú ìwé 18 àti 19 ló fi ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ilẹ̀ tó wà nínú Bíbélì hàn. Rọ gbogbo àwọn ará láti máa lo ìwé pẹlẹbẹ Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà dáadáa.
Orin 63 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 22
Orin 191
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán gbogbo àwọn ará létí láti tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà fún Ìṣe Ìrántí tá a ṣètò fún March 30 sí April 4, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2004 àti kàlẹ́ńdà wa, 2004 Calendar.
15 min: “Lílọ Sípàdé Déédéé—Ohun Tó Yẹ Kó Gbapò Iwájú.”b Ṣètò ṣáájú pé kí ẹnì kan tàbí méjì sọ àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n ti gbé kí wọ́n lè máa wà ní gbogbo ìpàdé ìjọ.
20 min: “Ogun Jíjà Àwọn Agẹṣinjagun Kan Tó Kàn Ọ́.”c Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí, kó o sì ṣàlàyé wọn bí àkókò bá ṣe wà sí.
Orin 181 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 29
Orin 129
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù March sílẹ̀. Sọ ìwé tí a ó fi lọni lóṣù April. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ April 1 àti Jí! April 8 lọni. Lo àbá kẹrin ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! April 8 lọni.
15 min: “Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Ń Tẹ̀ Síwájú ní Nàìjíríà.”d (Ìpínrọ̀ 1 sí 6) Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 6, ní kí àwọn ará kan sọ ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Tẹnu mọ́ ọn fún àwọn ará pé ojúṣe ìjọ ni láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti kópa nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, lẹ́yìn náà kí wọ́n máa pèsè owó tí a ó máa fi bójú tó gbọ̀ngàn náà, kí wọ́n sì máa tún un ṣe déédéé.
20 min: Òtítọ́ Ń So Ìdílé Pọ̀ Ṣọ̀kan. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Nígbà míì, àwọn olùfìfẹ́hàn máa ń lọ́ tìkọ̀ láti sin Jèhófà nítorí àtakò àwọn ìdílé wọn. Sọ díẹ̀ lára àwọn ìrírí wọ̀nyí: Ilé Ìṣọ́, January 1, 2002, ojú ìwé 14 àti 15; Ilé Ìṣọ́, December 1, 2000, ojú ìwé 8; Ilé Ìṣọ́, September 1, 1999, ojú ìwé 32; Ilé Ìṣọ́, January 1, 1999, ojú ìwé 4; àti Jí!, February 22, 1998, ojú ìwé 31. Tẹnu mọ́ ọn pé nǹkan sábà máa ń dára sí i nínú ìdílé bí a bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò kódà bí ò tiẹ̀ ju ẹyọ ẹnì kan nínú ìdílé tó ń fi sílò.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 5
Orin 126
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
20 min: Wíwà Ní Mímọ́ Tónítóní Nípa Tara Ń Fi Wá Sípò Ìtẹ́wọ́gbà. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ June 1, 2002, ojú ìwé 19 sí 21. Ṣètò pé kí a ṣe àṣefihàn kan, nínú èyí tí alàgbà kan á ṣàlàyé fún aṣáájú ọ̀nà kan nípa bó ṣe lè rọra fi ọgbọ́n ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lọ́wọ́ láti rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí ilé àti àyíká rẹ̀ máa mọ́ tónítóní; kí alàgbà náà lo ẹ̀kọ́ 9, ìpínrọ̀ 5, nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè.
15 min: “Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Ń Tẹ̀ Síwájú ní Nàìjíríà.”e (Ìpínrọ̀ 7 sí 12) Ka ìpínrọ̀ 7 sí 10. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 8, sọ fún ìjọ nípa bí wọ́n ṣe ń fi ọrẹ ṣètìlẹyìn sí fún Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n fẹ́ kọ́ tàbí fún àbójútó èyí tí wọ́n ń lò báyìí. Rọ àwọn ará láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú àwọn ètò tí ètò àjọ Ọlọ́run ṣe, kí wọ́n sì wà ní ìtẹríba fún àwọn tí ń mú ipò iwájú.—Hébérù 13:17.
Orin 25 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o sì bójú tó ìjíròrò náà nípa lílo ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o sì bójú tó ìjíròrò náà nípa lílo ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o sì bójú tó ìjíròrò náà nípa lílo ìbéèrè àti ìdáhùn.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o sì bójú tó ìjíròrò náà nípa lílo ìbéèrè àti ìdáhùn.
e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o sì bójú tó ìjíròrò náà nípa lílo ìbéèrè àti ìdáhùn.