Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!
1 Onírúurú ìṣòro ló ń yọjú nígbà ọ̀dọ́, ó sì tún jẹ́ ìgbà tí ẹ ní láti ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Ọ̀pọ̀ lára ẹ̀yin ọ̀dọ́ Kristẹni ló jẹ́ pé ojoojúmọ́ lẹ̀ ń dojú kọ àwọn nǹkan tó lè mú yín tàpá sáwọn ìlànà Ọlọ́run nípa ìwà rere. Kó tó di pé ẹ ṣe ìpinnu nípa ẹ̀kọ́ ìwé, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti ìgbéyàwó, ó yẹ kẹ́ ẹ ti kọ́kọ́ ní àwọn góńgó tẹ̀mí tí ẹ óò máa lépa. Ọ̀nà yẹn nìkan lẹ fi lè ṣe àwọn ìpinnu mìíràn tó máa ṣe yín láǹfààní jálẹ̀ ìgbésí ayé yín. Àwọn góńgó tẹ̀mí tó ṣe pàtó á ràn yín lọ́wọ́ láti máa fi ọgbọ́n hùwà, èyí á sì mú kí nǹkan máa lọ déédéé fún yín. Bí ẹ bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ẹ sì ń ṣàṣàrò lórí rẹ̀ déédéé, ẹ óò lè máa fi ìmọ̀ràn rẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí sílò, àwọn ìsapá dáradára tẹ́ ẹ̀ ń ṣe yóò sì kẹ́sẹ járí.—Jóṣ. 1:8; Sm. 1:2, 3.
2 Báwo Ló Ṣe Máa Ṣe Yín Láǹfààní? Àwọn nǹkan tó lè súnni hùwà àìtọ́ pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ayé Sátánì yìí. (1 Jòh. 2:15, 16) O lè mọ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ kan tàbí àwọn ojúgbà rẹ mìíràn tó ti jẹ̀ka àbámọ̀ nítorí pé wọ́n jẹ́ kí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe nípa lórí wọn. Bó o bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì, wàá lè máa hùwà tó dára, wàá sì ní okun tẹ̀mí láti sá fún ẹ̀ṣẹ̀. Síwájú sí i, ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yàgò fún àwọn ìdẹkùn Sátánì tó fara sin. (2 Kọ́r. 2:11; Héb. 5:14) Rírìn ní ọ̀nà Ọlọ́run yóò jẹ́ kó o ní ojúlówó ayọ̀, ìfọ̀kànbalẹ̀ nìyẹn yóò sì jẹ́ fún ọ ní ìgbésí ayé.—Sm. 119:1, 9, 11.
3 Àwọn ìlànà inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí kò lè kùnà láé ju ọgbọ́n ẹ̀dá èèyàn lọ fíìfíì. (Sm. 119:98-100) Bó o bá mọ àwọn ìlànà Bíbélì, tó ò ń ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣí payá nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun yóò ṣe, tó o sì ń gba àdúrà àtọkànwá, wàá ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, ọlọ́gbọ́n gíga jù lọ tó ni Bíbélì. Ó ṣèlérí pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”—Sm. 32:8.
4 Ṣètò Àkókò Láti Máa Kà Á: Ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni kan pinnu pé òun á ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin, ó sì kà á tán láàárín ọdún kan. Báwo ló ṣe ṣe é láǹfààní? Ó sọ pé: “Mo kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà—àwọn nǹkan tó mú kí n túbọ̀ sún mọ́ ọn, tó sì mú kí n fẹ́ láti bẹ̀rù rẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé mi.” (Ják. 4:8) Ǹjẹ́ o ti ka Bíbélì látòkèdélẹ̀? Bí o kò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ṣe fi ṣe góńgó rẹ pé wàá kà á tán? Kò sí àní-àní pé Jèhófà yóò bù kún àwọn ìsapá rẹ, wàá sì jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀.