ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/04 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 26
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 3
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 4/04 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 12

Orin 93

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4, ṣe àṣefihàn méjì nípa bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ April 15 àti Jí! May 8 lọni. Lo àbá kẹta ní ojú ìwé 4 láti fi Jí! May 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, jẹ́ kí àwọn ará mọ bí a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, irú bí “Ọwọ́ mi dí.” (Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ewé 11.) Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù April sílẹ̀.

18 min: “Fífún Jèhófà Ní Ohun Tó Dára Jù Lọ.”a Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, ní kí àwọn ará sọ àwọn ọ̀nà pàtó tá a lè gbà fi ìfẹ́ hàn sí àwọn èèyàn nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí.

15 min: Sọ àwọn ìrírí tí a ní nígbà ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí àti nígbà àfikún ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn lóṣù March.

Orin 91 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 19

Orin 55

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

17 min: “Fara Wé Ẹ̀mí Ìrònú Jésù.”b Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, ní kí àwọn tó ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sọ àwọn àǹfààní tí wọ́n ti jẹ látinú ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà.

20 min: Máa Fi Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Lọ́ọ́lọ́ọ́ Nasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Láti Mú Kí Àwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Rẹ. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Mẹ́nu kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ mélòó kan tí àwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ìjọ. Báwo làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ṣe ń mú kí àwọn èèyàn ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la? Nípa lílo ìwé Reasoning, ojú ìwé 10 àti 11, sọ àwọn àbá díẹ̀ tá a lè lò láti fi múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan sílẹ̀ tó máa yọrí sí ìjíròrò nínú Bíbélì. Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn méjì tó bá ipò àdúgbò mu, tí a sì ti múra sílẹ̀ dáadáa.

Orin 80 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 26

Orin 46

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù April sílẹ̀. Sọ àwọn ìwé tí a ó fi lọni lóṣù May. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4, ṣe àṣefihàn méjì nípa bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ May 1 àti Jí! May 8 lọni. Lo àbá kẹrin ní ojú ìwé 4 láti fi Jí! May 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, fi hàn bá a ṣe lè wàásù fún ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ wa.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

18 min: Kí Nìdí Tí Àwọn Èèyàn Ò Fi Ní Ìgbàgbọ́? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. A sábà máa ń pàdé àwọn èèyàn tí ò fi bẹ́ẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́. (2 Tẹs. 3:2) Ká bàa lè sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ nípa Jèhófà fún wọn, ó yẹ ká kọ́kọ́ gbìyànjú láti mọ ohun tí kò jẹ́ kí wọ́n gba Ọlọ́run gbọ́. Ṣàyẹ̀wò àwọn kókó mẹ́rin tó wà nínú ìwé Reasoning, ojú ìwé 129 àti 130, èyí tó lè ṣèdíwọ́ fún àwọn èèyàn láti ní ìgbàgbọ́. Ní kí àwọn ará sọ ọ̀nà tá a lè gbà lo ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn kókó mẹ́rin náà. Sọ ìrírí kan nípa ọ̀nà tó múná dóko tí akéde kan gbà jíròrò pẹ̀lú onílé, tàbí kó o lo èyí tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí, August 22, 1993, ojú ìwé 14 àti 15.

Orin 38 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 3

Orin 48

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

20 min: “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!”c Ṣètò ṣáájú pé kí ọ̀dọ́ kan tàbí méjì sọ ètò tí wọ́n ṣe fún Bíbélì kíkà, àti bí wọ́n ṣe ń jàǹfààní látinú rẹ̀. Gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú pé kí wọ́n pinnu láti ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Fi àlàyé kún un látinú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 10, ìpínrọ̀ 4.

15 min: Àwọn Ìrírí Nípa Bí A Ṣe Ń Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò. Nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ April 19, a dábàá pé kí a máa fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ nasẹ̀ ọ̀rọ̀ láti mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, kí a lè ráyè báwọn jíròrò nínú iṣẹ́ ìsìn. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí dáradára tí wọ́n ti ní títí di àkókò yìí nípa fífi àwọn àbá wọ̀nyẹn sílò.

Orin 164 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́