Fífún Jèhófà Ní Ohun Tó Dára Jù Lọ
1 Nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ fún wọn pé àwọn ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rúbọ sí òun gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí “ara rẹ̀ dá ṣáṣá.” Jèhófà kò ní tẹ́wọ́ gba ẹran èyíkéyìí tó bá ní àbùkù lára. (Léf. 22:18-20; Mál. 1:6-9) Síwájú sí i, nígbà tí wọ́n bá rúbọ, Jèhófà ló ni gbogbo ọ̀rá, èyí tó jẹ́ apá tó dára jù lọ lára ẹran náà. (Léf. 3:14-16) Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Baba àti Atóbilọ́lá Ọ̀gá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó tọ́ kí wọ́n fún un ní ohun tó dára jù lọ.
2 Bíi ti ayé ọjọ́un, Ọlọ́run ń kíyè sí irú ẹbọ tí à ń rú sí i lónìí. Ó yẹ kí iṣẹ́ ìsìn wa fi hàn pé a ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Jèhófà. Ká sòótọ́, ipò wa yàtọ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò ara wa fínnífínní láti rí i dájú pé ohun tó dára jù lọ là ń fún un.—Éfé. 5:10.
3 Iṣẹ́ Ìsìn Àtọkànwá: Bá a bá fẹ́ fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa bọlá fún Jèhófà, kí ọ̀rọ̀ wa sì wọ àwọn tá à ń wàásù fún lọ́kàn, ó gbọ́dọ̀ máa wá látinú ọkàn wa. Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ tí à ń sọ nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun ribiribi tó fẹ́ láti ṣe máa wá látinú ọkàn tó kún fún ìmọrírì. (Sm. 145:7) Èyí fi hàn pé ó ṣe pàtàkì pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ka Bíbélì ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ déédéé.—Òwe 15:28.
4 Síwájú sí i, ọ̀nà kan tá a lè gbà fún Jèhófà ní ohun tó dára jù lọ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn. (Éfé. 5:1, 2) Ìfẹ́ tá a ní fún àwọn èèyàn yóò sún wa láti gbìyànjú láti lọ sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ń fúnni níyè fún gbogbo àwọn tá a bá lè rí. (Máàkù 6:34) Ó ń sún wa láti fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sí àwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀. Ó ń jẹ́ ká máa ronú nípa wọn lẹ́yìn ìbẹ̀wò àkọ́kọ́, ó sì ń sún wa láti tún padà lọ sọ́dọ̀ wọn. Ìfẹ́ yìí tún ń mú ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—Ìṣe 20:24; 26:28, 29.
5 “Ẹbọ Ìyìn”: Ọ̀nà mìíràn tá a lè gbà fún Jèhófà ní ohun tó dára jù lọ ni pé ká jẹ́ aláápọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Bá a bá ṣètò àwọn ìgbòkègbodò wa dáadáa tá a sì pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ìsapá wa á lè méso jáde níwọ̀nba àkókò tó kù fún ayé yìí. (1 Tím. 4:10) Bá a bá múra sílẹ̀ dáadáa, a ó lè fi ìdánilójú sọ̀rọ̀, a ó sì lè sọ ọ́ lọ́nà tó máa yéni yékéyéké, èyí sì lè mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ wa. (Òwe 16:21) Bí a ṣe ń sọ ìhìn rere fún àwọn èèyàn, ó tọ́ bí a bá pe àwọn ọ̀rọ̀ tó ń ti ọkàn wa wá ní “ẹbọ ìyìn.”—Héb. 13:15.