ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/04 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 10
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 17
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 24
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 31
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 7
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 5/04 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 10

Orin 193

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù May sílẹ̀. Bí àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín, ẹ lò wọ́n láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ May 15 àti Jí! June 8 lọni. Lo àbá kẹta ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! June 8 lọni. Ẹ lè lo àwọn ọ̀nà mìíràn láti fi ìwé ìròyìn lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, jẹ́ kí àwọn ará mọ bá a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, irú bíi “Mo ní ìsìn tèmi.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 10.

15 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé tí alàgbà kan yóò sọ.

20 min: ‘Ẹ Mú Kí Ìfẹ́ Yín Gbòòrò Sí I.’a Fi àlàyé kún un látinú ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 150, ìpínrọ̀ 14.

Orin 18 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 17

Orin 188

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: “Ẹ Máa Fọpẹ́ Hàn.”b Bí àkókò bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, ní kí akéde kan tàbí méjì tó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ àwọn ìbùkún tí wọ́n ti gbà nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀.

20 min: À Ń Dàníyàn Nípa Ara Wa. (1 Kọ́r. 12:25, 26) Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, èyí tí a gbé ka ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 157 sí 159, lábẹ́ ìsọ̀rí “Ìdàníyàn fun Ara Wa Ẹnikinni Ẹnikeji.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé làwọn èèyàn Jèhófà ń gbé, a wà ní ìṣọ̀kan. Ó yẹ kí gbogbo wa máa gbàdúrà fún àwọn ará wa lójoojúmọ́. A tún máa ń pèsè àwọn ohun ìní ti ara láìjáfara nígbà tí àwọn ará wa bá nílò nǹkan wọ̀nyí ní kánjúkánjú. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣe kókó, kó o ṣàlàyé wọn, kó o sì fi ìrírí kan tàbí méjì kún un látinú àwọn ìwé wa.

Orin 100 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 24

Orin 128

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ June 1 àti Jí! June 8 lọni. Lo àbá kẹrin ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! June 8 lọni. Kí a ṣe àṣefihàn kọ̀ọ̀kan lọ́nà tí àwọn tó jẹ́ onísìn ní ìpínlẹ̀ ìjọ yóò fi lè tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ wa.

10 min: “Orin Tí Ń Mára Tuni.” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fi àlàyé kún un látinú ìwé ọdọọdún wa, 2002 Yearbook, ojú ìwé 175, àti Ilé Ìṣọ́ February 1, 1997, ojú ìwé 27, ìpínrọ̀ 1 àti 2.

25 min: “Àpéjọ Àgbègbè ‘Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn’ tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Yóò Ṣe ní Ọdún 2004.” Kí akọ̀wé ìjọ bójú tó o. Lẹ́yìn tó o bá ti ṣàlàyé ìpínrọ̀ 1, ka lẹ́tà April 1, 2004 tá a fi sọ àpéjọ àgbègbè tí a yan ìjọ kọ̀ọ̀kan sí. Nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀ lórí ìpínrọ̀ 2, tọ́ka sí àpótí tó wà ní ojú ìwé 3. Rọ gbogbo àwọn ará pé kí wọ́n tètè bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò àtilọ sí àpéjọ àgbègbè.

Orin 138 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 31

Orin 26

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù May sílẹ̀.

17 min: Ìwàláàyè—Ẹ̀bùn Tó Yẹ Ká Mọrírì Gidigidi. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, ojú ìwé 24 àti 25. Fi àlàyé kún un látinú ìwé ìròyìn Jí! May 22, 1993, ojú ìwé 10 àti 11. Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo ìṣẹ́yún fún ẹnì kan tó ronú pé ohun tó bá wu obìnrin kan ló lè fi ara rẹ̀ ṣe? Sọ ìrírí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2000, ojú ìwé 4, ìpínrọ̀ 4 àti 5.

20 min: “Fífi Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà Lọni.” Ìwé yìí ni a ó fi lọni lóṣù June. Tọ́ka sí àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀ inú ìwé náà, tá a ṣàpèjúwe ní ojú ìwé 7, ìpínrọ̀ 1 sí 3. Sọ pé kí àwùjọ sọ àwọn ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ nípa rẹ̀. Sọ̀rọ̀ nípa àwọn àbá tá a dá nípa bá a ṣe lè fi ìwé yìí lọni. Sọ bí a ṣe lè lo àwọn àwòrán inú rẹ̀ nígbà tá a bá ń fi ìwé náà lọni. Ní kí ọ̀dọ́ kan ṣe àṣefihàn àkọ́kọ́, kí àgbàlagbà kan sì ṣe ọ̀kan lára méjì yòókù. Bó bá jẹ́ pé ọ̀nà mìíràn ló máa dára jù lọ láti gbà fi ìwé yìí lọni ní ìpínlẹ̀ ìjọ, a lè jíròrò èyí ká sì ṣàṣefihàn rẹ̀ dípò ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn méjì yòókù.

Orin 24 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 7

Orin 136

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Ohun Tó Lè Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́.” Sọ díẹ̀ lára àwọn èdè tá a máa ń bá pàdé ní ìpínlẹ̀ ìjọ.

15 min: Ẹ Túbọ̀ Pàfiyèsí sí Ọ̀ràn Dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àsọyé tí alàgbà tó tóótun yóò sọ, èyí tá a gbé ka lẹ́tà sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ní Nàìjíríà tí déètì rẹ̀ jẹ́ June 10, 2003.

20 min: Máa Lo Àwọn Àpèjúwe Tó Múná Dóko Nígbà Tó O Bá Ń Kọ́ni. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, èyí tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ September 1, 2002, ojú ìwé 22 sí 24. Àwọn ohun mẹ́rin wo ló ń jẹ́ kí àpèjúwe múná dóko? Kí nìdí tó fi dára láti jẹ́ kí àpèjúwe rọrùn láti lóye? Ibo la ti lè rí àwọn àpèjúwe tó ṣe rẹ́gí? Sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé 23, kó o sì jíròrò ohun tó mú kí àpèjúwe kọ̀ọ̀kan múná dóko.

Orin 133 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́